Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Mú Kí Àdúrà Rẹ Sunwọ̀n Sí I
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Mú Kí Àdúrà Rẹ Sunwọ̀n Sí I
“Áà, Jèhófà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ.”—NEH. 1:11.
1, 2. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àdúrà tó wà nínú Bíbélì?
AÒ LÈ kóyán àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kéré nínú ọ̀ràn ìjọsìn tòótọ́. (1 Tẹs. 5:17; 2 Tím. 3:16, 17) Lóòótọ́ Bíbélì kì í ṣe ìwé àdúrà, síbẹ̀ àdúrà pọ̀ nínú rẹ̀, lára wọn ni èyí tá a rí nínú ìwé Sáàmù.
2 Bó o ṣe ń ka Bíbélì tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn àdúrà kan tó bá ipò tó dojú kọ ẹ́ mu. Àní, tó o bá fi àwọn gbólóhùn inú àdúrà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kún àdúrà rẹ, yóò jẹ́ kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i. Kí lo lè rí kọ́ látara àwọn tó tọrọ ìrànlọ́wọ́ Jèhófà tí wọ́n sì rí ìdáhùn àdúrà wọn gbà, kí lo sì lè rí kọ́ látinú àdúrà wọn?
Máa Wá Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Kó O sì Máa Tẹ̀ Lé E
3, 4. Iṣẹ́ wo ni Ábúráhámù rán ìránṣẹ́ rẹ̀, kí la sì lè rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe darí ọ̀ràn náà?
3 Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á túbọ̀ mú kó o rí i kedere pé ó yẹ kó o máa gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ábúráhámù Baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán ìránṣẹ́ rẹ̀ tó dàgbà jù lọ, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Élíésérì, lọ sí ilẹ̀ Mesopotámíà pé kó lọ wá aya tó bẹ̀rù Ọlọ́run wá fún Ísáákì. Ní àkókò tí àwọn obìnrin ń pọn omi níbi kànga kan báyìí, ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbàdúrà pé: “Jèhófà . . . , kí ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́bìnrin tí èmi bá wí fún pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ ìṣà omi rẹ kalẹ̀, kí èmi lè mu,’ tí yóò sì wí ní ti gidi pé, ‘Mu, èmi yóò sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí rẹ,’ ẹni yìí ni kí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ, fún Ísákì; kí o sì tipa èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ dídúró ṣinṣin hàn sí ọ̀gá mi.”—Jẹ́n. 24:12-14.
4 Jèhófà dáhùn àdúrà ìránṣẹ́ Ábúráhámù nígbà tí Rèbékà fún àwọn ràkúnmí ìránṣẹ́ náà lómi mu. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló tẹ̀ lé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì tó sì di aya rere lọ́ọ̀dẹ̀ Ísákì. Lóòótọ́, o ò lè máa retí pé kí Ọlọ́run fún ọ ní àmì àrà ọ̀tọ̀ kan. Síbẹ̀, yóò tọ́ ọ sọ́nà nígbèésí ayé rẹ, tó o bá ń gbàdúrà tó o sì pinnu pé wàá jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ máa darí rẹ.—Gál. 5:18.
Àdúrà Máa Ń Dín Àníyàn Kù
5, 6. Kí lo kíyè sí nípa àdúrà tí Jékọ́bù gbà nígbà tó fẹ́ lọ pàdé Ísọ̀?
5 Àdúrà lè dín àníyàn wa kù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jékọ́bù ń bẹ̀rù pé Ísọ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ ìbejì lè gbéjà ko òun, ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, . . . èmi kò yẹ fún gbogbo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti gbogbo ìṣòtítọ́ tí o ti ṣe sí ìránṣẹ́ rẹ . . . Mo bẹ̀ ọ́, dá mi nídè lọ́wọ́ arákùnrin mi, lọ́wọ́ Ísọ̀, nítorí tí àyà rẹ̀ ń fò mí, pé ó lè dé, kí ó sì fipá kọlù mí dájúdájú, àti ìyá àti àwọn ọmọ mi. Àti pé ìwọ, ìwọ ti sọ pé, ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èmi yóò ṣe dáadáa sí ọ, èmi yóò sì mú irú-ọmọ rẹ dà bí àwọn egunrín iyanrìn òkun, tí kì yóò níye nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.’”—Jẹ́n. 32:9-12.
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jékọ́bù ṣe àwọn ohun tí kò ní jẹ́ kí Ísọ̀ gbéjà kò ó, àdúrà rẹ̀ gbà bóun àti Ísọ̀ tún ṣe pa dà rẹ́. (Jẹ́n. 33:1-4) Fara balẹ̀ ka àdúrà yẹn, wàá rí i pé kì í ṣe pé Jékọ́bù tọrọ ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan. Ó tún sọ ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa Irú-ọmọ kan, ó sì fi ìmọrírì hàn fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ṣé ohun kan wà tó mú kí “ìbẹ̀rù wà nínú” tìrẹ náà? (2 Kọ́r. 7:5) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀bẹ̀ Jékọ́bù lè rán ọ létí pé àdúrà lè jẹ́ kí àníyàn dín kù. Àmọ́, kì í ṣe ohun tá à ń tọrọ nìkan ló yẹ kó máa wà nínú àdúrà wa, ó yẹ kí àdúrà wa tún máa fi hàn pé a nígbàgbọ́.
Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Ọ Ní Ọgbọ́n
7. Kí nìdí tí Mósè fi gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí òun mọ ọ̀nà rẹ̀?
7 Bó bá ń wù wá pé ká máa ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sí, a ó máa gbàdúrà pé kó fún wa ní ọgbọ́n. Mósè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí òun mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀. Ó ní: “Wò ó, ìwọ sọ fún mi pé, ‘Mú àwọn ènìyàn yìí gòkè lọ [láti Íjíbítì]’ . . . Wàyí o, jọ̀wọ́, bí mo bá rí ojú rere lójú rẹ, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, . . . kí n lè rí ojú rere lójú rẹ.” (Ẹ́kís. 33:12, 13) Ọlọ́run dá Mósè lóhùn, ó jẹ́ kó túbọ̀ mọ ọ̀nà òun, ó sì pọn dandan fún Mósè láti mọ ọ̀nà Jèhófà kó tó lè ṣe aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀.
8. Àǹfààní wo lo lè rí nínú ṣíṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tó wà ní 1 Ọba 3:7-14?
8 Dáfídì náà gbàdúrà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà.” (Sm. 25:4) Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì náà bẹ Ọlọ́run pé kó fún òun ní ọgbọ́n tóun á fi lè ṣe iṣẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. Inú Jèhófà dùn sí àdúrà Sólómọ́nì, torí náà ó fún un ní ọgbọ́n tó tọrọ, ó sì tún fún un ní ọrọ̀ àti ògo. (Ka 1 Ọba 3:7-14.) Tó o bá ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó dà bíi pé ó fẹ́ kà ọ́ láyà, o lè gbàdúrà fún ọgbọ́n kó o sì ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ọlọ́run á ràn ọ́ lọ́wọ́ tí wàá fi ní ìmọ̀, tí wàá sì fi lè lo ọgbọ́n tó máa mú kó o lè ṣe iṣẹ́ náà bó ṣe tọ́ pẹ̀lú ìfẹ́.
Gbàdúrà Látọkàn Wá
9, 10. Nínú àdúrà tí Sólómọ́nì gbà níbi ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì, kí lo kíyè sí nípa ohun tó sọ nípa ọkàn?
9 Kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ gbà á látọkàn wá. Ní ọdún 1026 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sólómọ́nì gba àdúrà àtọkànwá níwájú ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn tó pé jọ ní Jerúsálẹ́mù nígbà ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì Jèhófà. Àdúrà yẹn wà nínú 1 Ọba orí 8. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí sí Ibi Mímọ́ Jù Lọ, tí àwọsánmà Jèhófà sì kún inú tẹ́ńpìlì, Sólómọ́nì yin Ọlọ́run lógo.
10 Ṣàyẹ̀wò àdúrà Sólómọ́nì yẹn dáadáa kó o sì fiyè sí ohun tó sọ nípa ọkàn nínú rẹ̀. Sólómọ́nì gbà pé Jèhófà nìkan ló mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn. (1 Ọba 8:38, 39) Àdúrà kan náà yẹn fi hàn pé ìrètí wà fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó bá ‘fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.’ Ó tún fi hàn pé tí àwọn ọ̀tá bá kó àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ ní òǹdè, Jèhófà á gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn tí ọkàn wọn bá pé pérépéré sọ́dọ̀ rẹ̀. (1 Ọba 8:48, 58, 61) Ó ṣe kedere nígbà náà pé àdúrà rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ àtọkànwá.
Bí Sáàmù Ṣe Lè Mú Àdúrà Rẹ Sunwọ̀n Sí I
11, 12. Kí lo rí kọ́ látinú àdúrà ọmọ Léfì kan tí kò ṣeé ṣe fún láti lọ sí ibùjọsìn Ọlọ́run láàárín àkókò kan?
11 Tó o bá ṣàyẹ̀wò Sáàmù dáadáa, ó lè mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i, ó sì lè kọ́ ọ láti máa dúró de Ọlọ́run kó wá dáhùn àdúrà rẹ. Jẹ́ ká wo bí ọmọ Léfì kan tó wà nígbèkùn ṣe ní sùúrù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún un láti lọ sí ibùjọsìn láàárín àkókò kan, síbẹ̀ ó kọ ọ́ lórin pé: “Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi, èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi? Dúró de Ọlọ́run, nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára àti gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mi.”—Sm. 42:5, 11; 43:5.
12 Kí lo lè rí kọ́ látara ọmọ Léfì yẹn? Tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n sọ ẹ́ sẹ́wọ̀n nítorí òdodo, téyìí kò sì jẹ́ kó o lè máa bá àwọn ará pé jọ nílé ìpàdé fún àwọn ìgbà kan, fi sùúrù dúró de Ọlọ́run kó wá dìde fún ìrànlọ́wọ́ rẹ. (Sm. 37:5) Máa ṣàṣàrò lórí ayọ̀ tó o ti ní nígbà kan nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kó o sì máa gbàdúrà fún ìfaradà bó o ṣe ń “dúró de Ọlọ́run” pé kó jẹ́ kó tún ṣeé ṣe fún ọ láti pa dà máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé jọ.
Máa Fi Ìgbàgbọ́ Gbàdúrà
13. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Jákọ́bù 1:5-8, kí nìdí tó fi yẹ kó o máa gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́?
13 Ohun yòówù kó dojú kọ ẹ́, máa fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà nígbà gbogbo. Nígbà tí ohun tó ń dán ìwà títọ́ rẹ wò bá dojú kọ ọ́, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, má ṣiyè méjì pé ó lè fún ọ ní ọgbọ́n tí wàá fi lè fara da ìṣòro rẹ. (Ka Jákọ́bù 1:5-8.) Ọlọ́run mọ ohunkóhun tó lè máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ, ó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ tọ́ ọ sọ́nà kó sì fi tù ọ́ nínú. Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un, ní ìgbàgbọ́ “láìṣiyèméjì rárá,” sì fara mọ́ ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí rẹ̀ àti ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
14, 15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Hánà ní ìgbàgbọ́ pé àdúrà òun yóò gbà?
14 Obìnrin kan wà tó ń jẹ́ Hánà, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìyàwó méjì tí Ẹlikénà ọmọ Léfì kan báyìí fẹ́. Hánà gbàdúrà ó sì ní ìgbàgbọ́ pé àdúrà òun yóò gbà. Torí pé Hánà yàgàn, Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ tó bí ọmọ mélòó kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọmọ bú u. Hánà gbàdúrà nínú àgọ́ ìjọsìn, ó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé tóun bá rí ọmọkùnrin bí, Jèhófà lòun máa fi fún. Nítorí pé ètè rẹ̀ nìkan ló ń mì nígbà tó ń gbàdúrà, Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà rò pé ó ti mutí yó ni. Nígbà tó rí i pé Hánà kò mutí yó, ó sọ pé: “Kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Hánà kò mọ bí àdúrà òun ṣe máa gbà gan-an, síbẹ̀ ó nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà òun. Nítorí náà, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.” Ìyẹn ni pé ìbànújẹ́ kò dorí rẹ kodò mọ́.—1 Sám. 1:9-18.
15 Lẹ́yìn tí Hánà ti bí Sámúẹ́lì tó sì ti já a lẹ́nu ọmú, ó mú un wá fún Jèhófà kó lè máa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn. (1 Sám. 1:19-28) Tó o bá ń ṣàṣàrò lórí àdúrà tí Hánà gbà yẹn, ó lè mú kí àdúrà tìrẹ náà sunwọ̀n sí i. Ó sì tún lè jẹ́ kó o rí i pé o lè borí ìbànújẹ́ tí ìṣòro líle fà bá ọ, tó o ń bá gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Jèhófà yóò dá ọ́ lóhùn.—1 Sám. 2:1-10.
16, 17. Kí ló ṣẹlẹ̀ torí pé Nehemáyà gbàdúrà tó sì nígbàgbọ́ pé àdúrà òun yóò gbà?
16 Ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Nehemáyà tó gbé ayé ní nǹkan bí ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni gbàdúrà, ó sì nígbàgbọ́ pé àdúrà òun yóò gbà. Ó bẹ̀bẹ̀ pe: “Áà, Jèhófà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ó ní inú dídùn sí bíbẹ̀rù orúkọ rẹ; jọ̀wọ́, sì yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere fún ìránṣẹ́ rẹ lónìí, kí o sì sọ ọ́ di ẹni ìṣojú-àánú-sí níwájú ọkùnrin yìí.” Ta ni “ọkùnrin” tí Nehemáyà gbàdúrà nípa rẹ̀ yẹn? Atasásítà ọba Páṣíà tí Nehemáyà ń ṣe agbọ́tí rẹ̀ ni.—Neh. 1:11.
17 Nehemáyà fi ọjọ́ púpọ̀ gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ lẹ́yìn tó mọ̀ pé àwọn Júù tí wọ́n dá sílẹ̀ lóko òǹdè Bábílónì wà “nínú ipò ìṣòro tí ó burú gidigidi àti nínú ẹ̀gàn; ògiri Jerúsálẹ́mù [sì] ti wó lulẹ̀.” (Neh. 1:3, 4) Àdúrà Nehemáyà gbà kọjá bó ṣe rò. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Atasásítà Ọba gbà á láyè láti lọ sí Jerúsálẹ́mù kó sì tún odi rẹ̀ mọ. (Neh. 2:1-8) Kò pẹ́ tí wọ́n fi tún ògiri náà ṣe tán. Ọlọ́run dáhùn àdúrà Nehemáyà torí pé ó dá lórí ìjọsìn tòótọ́, ó sì gbà á pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ṣé bí àdúrà tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn?
Máa Rántí Yin Jèhófà Kó O sì Máa Dúpẹ́
18, 19. Fún àwọn ìdí wo ló fi yẹ kí ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa yìn ín kó sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀?
18 Tó o bá ń gbàdúrà, máa rántí yin Jèhófà, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ló ń wu Dáfídì ṣáá láti máa gbé Jèhófà ga gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Ka Sáàmù 145:10-13.) Ṣé àwọn àdúrà rẹ máa ń fi hàn pé o mọyì àǹfààní tó o ní láti máa kéde Ìjọba Jèhófà? Ọ̀rọ̀ àwọn tó kọ Sáàmù tún lè jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run látọkàn wá fún àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.—Sm. 27:4; 122:1.
19 Tó o bá mọrírì àjọṣe ṣíṣeyebíye tó wà láàárín ìwọ àti Ọlọ́run, ìyẹn lè mú kó o máa fi tọkàntọkàn gba irú àdúrà yìí, pé: “Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ láàárín àwọn ènìyàn, Jèhófà; èmi yóò máa kọ orin atunilára sí ọ láàárín àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè. Nítorí tí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ga títí dé ọ̀run, àti òótọ́ rẹ títí dé sánmà. Kí a gbé ọ ga lékè ọ̀run, Ọlọ́run; kí ògo rẹ wà lókè gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sm. 57:9-11) Àdúrà yìí mà múni lọ́kàn yọ̀ gan-an ni o! Ṣé ìwọ náà gbà pé irú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń wọni lọ́kàn bẹ́ẹ̀ látinú Sáàmù lè mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i?
Máa Bẹ Ọlọ́run Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀
20. Báwo ni Màríà ṣe fi hàn pé olùfọkànsin Ọlọ́run lòun?
20 Ọ̀wọ̀ tá a ní fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa hàn nínú àdúrà wa. Àdúrà tí Màríà gbà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nígbà tó mọ̀ pé òun lòun máa bí Mèsáyà jọ èyí tí Hánà gbà nígbà tó mú Sámúẹ́lì ọmọ rẹ̀ lọ láti máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn. Ọ̀wọ̀ tí Màríà ní fún Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ, ó ní: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga lọ́lá, ẹ̀mí mi kò sì lè dẹ́kun yíyọ ayọ̀ púpọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.” (Lúùkù 1:46, 47) Ṣé ìwọ náà lè fi irú ọ̀rọ̀ kan náà kún àdúrà rẹ kó bàa lè sunwọ̀n sí i? Abájọ tó fi jẹ́ pé Màríà tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ìyá Jésù tó jẹ́ Mèsáyà!
21. Báwo ni àdúrà Jésù ṣe fi ọ̀wọ̀ àti ìgbàgbọ́ hàn?
21 Jésù gbàdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó jí Lásárù dìde, ó “gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run, ó sì wí pé: ‘Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, èmi mọ̀ pé ìwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo.’” (Jòh. 11:41, 42) Ṣé àdúrà tìrẹ náà máa ń fi irú ọ̀wọ̀ àti ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn? Fara balẹ̀ ka àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wàá rí i pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àdúrà yẹn ni kí orúkọ Jèhófà di mímọ́, kí Ìjọba rẹ̀ dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe. (Mát. 6:9, 10) Ronú nípa àdúrà tìrẹ náà. Ṣó máa ń fi hàn pé dídé Ìjọba Jèhófà, bí ìfẹ́ rẹ̀ yóò ṣe di ṣíṣe àti bí orúkọ rẹ̀ yóò ṣe di mímọ́ ṣe pàtàkì lọ́kàn rẹ? Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn.
22. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá ọ lójú pé Jèhófà yóò fún ọ nígboyà tí wàá fi máa polongo ìhìn rere?
22 Nítorí inúnibíni àtàwọn àdánwò míì, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sábà máa ń gbàdúrà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ láti lè máa fi ìgboyà sìn ín. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pàṣẹ fún Pétérù àti Jòhánù pé wọn ò gbọ́dọ̀ “kọ́ni ní orúkọ Jésù” mọ́, àwọn àpọ́sítélì yẹn dúró tìgboyàtìgboyà, wọn ò ṣíwọ́ kíkọ́ni. (Ìṣe 4:18-20) Nígbà tí wọ́n fi wọ́n sílẹ̀, wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn ará wọn yòókù. Gbogbo wọn wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún àwọn ní ìgboyà táwọn á fi máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ wo bí yóò ti dùn mọ́ wọn nínú tó nígbà tí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wọn, tí wọ́n “kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”! (Ka Ìṣe 4:24-31.) Ohun tí ìyẹn yọrí sí ni pé ogunlọ́gọ̀ ńlá di olùjọsìn Jèhófà. Àdúrà tún lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti máa fi ìgboyà polongo ìhìn rere.
Máa Mú Àdúrà Rẹ Sunwọ̀n Sí I
23, 24. (a) Sọ àwọn àpẹẹrẹ míì tó fi hàn pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i. (b) Kí lo máa ṣe láti mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i?
23 Àpẹẹrẹ ṣì pọ̀ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní tá a lè tọ́ka sí láti fi hàn pé kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lè mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ náà lè gba irú àdúrà Jónà, kó o sọ ohun tó fi hàn pé o gbà pé “ti Jèhófà ni ìgbàlà.” (Jónà 2:1-10) Tó o bá dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan tó ń dà ọ́ láàmù tó o sì ti wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà, nígbà tó o bá ń gbàdúrà, o lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú àdúrà rẹ̀ láti fi hàn pé o ti ronú pìwà dà. (Sm. 51:1-12) Nígbà míì tó o bá ń gbàdúrà, o lè yin Jèhófà bí Jeremáyà ṣe yìn ín. (Jer. 32:16-19) Tó o bá ń wá ọkọ tàbí aya, tó o bá ṣàyẹ̀wò àdúrà tó wà nínú Ẹ́sírà orí 9, tó o sì ń bẹ Jèhófà lójú méjèèjì, ìyẹn yóò mú kó o dúró lórí ìpinnu rẹ láti ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ.—1 Kọ́r. 7:39; Ẹ́sírà 9:6, 10-15.
24 Máa ka Bíbélì nìṣó, máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kó o sì máa wá inú rẹ̀. Máa kíyè sí àwọn kókó tó o lè máa fi sínú àdúrà rẹ. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti fi àwọn ọ̀rọ̀ tó o rí nínú Ìwé Mímọ́ sínú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ pẹ̀lú àdúrà ìdúpẹ́ àti ti ìyìn rẹ. Ó dájú pé ńṣe ni wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó o bá ń mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ká sì máa tẹ̀ lé e?
• Kí nìdí to fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n?
• Báwo ni ìwé Sáàmù ṣe lè mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ọ̀wọ̀?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà ń gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìjọsìn Ìdílé lè mú kí àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i