Ọmọdébìnrin Tó Jẹ́ Ọ̀làwọ́
Ọmọdébìnrin Tó Jẹ́ Ọ̀làwọ́
LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ọmọdébìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lórílẹ̀-èdè Brazil pín owó tó ti tọ́jú pa mọ́ sọ́nà méjì, láìsẹ́ni tó kọ́ ọ. Apá kan jẹ́ dọ́là méjìdínlógún, apá kejì sì jẹ́ dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Ó fi dọ́là méjìdínlógún sínú àpótí ọrẹ fún ìnáwó ìjọ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ó wá fi dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì kọ lẹ́tà kékeré kan mọ́ ọn. Ohun tó wà nínú lẹ́tà náà rèé: “Mo fẹ́ fi owó yìí ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Ó wù mí láti ran ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin kárí ayé lọ́wọ́ láti máa wàásù ìhìn rere. Ìfẹ́ ńlá tí mo ní fún Jèhófà ló mú kí n fowó yìí ṣètọrẹ.”
Àwọn òbí ọmọdébìnrin yìí ti kọ́ ọ pé ó ṣe pàtàkì kóun náà máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n sì tún ti gbìn ín sí i lọ́kàn pé ó gbọ́dọ̀ máa ‘fi àwọn ohun ìní rẹ̀ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.’ (Òwe 3:9) Bíi ti ọmọdébìnrin yẹn, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa fi ìtara lọ́wọ́ nínú ìtẹ̀síwájú gbogbo ohun tó jẹ́ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lágbègbè wa àti kárí ayé!