Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ẹ̀kọ́ wo ni Òwe 24:27 ń kọ́ni?
Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Òwe ń gba ọ̀dọ́kùnrin kan nímọ̀ràn, ó sọ pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ara rẹ ní pápá. Lẹ́yìn ìgbà náà, kí o gbé agbo ilé rẹ ró pẹ̀lú.” Kókó wo ni òwe tí Ọlọ́run mí sí yìí ń gbé jáde? Kókó náà ni pé ó yẹ kí ọmọkùnrin kan múra sílẹ̀ dáadáa kó tó sọ pé òun ń gbéyàwó tóun sì ń bímọ, ó yẹ kó mọ ojúṣe ẹni tó bá ti láya nílé tó sì lọ́mọ.
Àlàyé tá a ṣe lórí ẹsẹ Bíbélì yìí látẹ̀yìnwá ni pé, ọkọ tó tún jẹ́ bàbá ní láti máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ó sì tún gbọ́dọ̀ máa sapá láti fún agbo ilé rẹ̀ níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, kó máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àlàyé yẹn tó sì bá Ìwé Mímọ́ mu, ó dà bíi pé kì í ṣèyẹn gan-an ni kókó ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Gbé ìdí méjì yẹ̀ wò.
Ìdí àkọ́kọ́, ẹsẹ Bíbélì yìí kò sọ̀rọ̀ gbígbé agbo ilé tó ti wà tẹ́lẹ̀ ró nípa fífún un níṣìírí tàbí fífún un lágbára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ nípa kíkọ́ ilé gidi kan. Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí ‘gbé ró’ yẹn lọ́nà àpẹẹrẹ. Wọ́n lè lò ó láti fi ṣàpẹẹrẹ gbígbé agbo ilé kalẹ̀, tàbí dídi ẹni tó ní ìdílé, ìyẹn dídi ẹni tó ní aya àti ọmọ.
Ìdí kejì, ẹsẹ yẹn tún sọ̀rọ̀ nípa ohun tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ ṣe kó tó ṣe ohun tó tẹ̀ lé e, bí ìgbà tá a sọ pé, “Lẹ́yìn tó o bá ṣe tibí ni kó o tó ṣe tọ̀hún.” Nítorí náà, ṣé ohun tí òwe náà ń sọ ni pé dídi ẹni tó ní iṣẹ́ lápá láti gbọ́ bùkátà ìdílé ló yẹ kó ṣáájú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni? Rárá, kì í ṣèyẹn ló ń sọ!
Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ “gbé agbo ilé [rẹ̀] ró,” ìyẹn ni pé tó bá fẹ́ gbéyàwó kó sì ní ìdílé tirẹ̀, ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mo ti ṣe tán láti bójú tó aya àtàwọn ọmọ tá a bá bí kí n sì máa gbọ́ bùkátà wọn?’ Kó tó ní ìdílé, ó ní láti ṣiṣẹ́, kó bójú tó oko rẹ̀, tàbí irè oko rẹ̀. Nítorí náà, bí gbólóhùn náà ṣe kà kedere nínú Bíbélì Today’s English Version ní èdè Gẹ̀ẹ́sì rèé: “O kò gbọ́dọ̀ tíì kọ́ ilé rẹ tàbí kó o fìdí ilé rẹ múlẹ̀ títí dìgbà tí irè oko rẹ á fi jáde, tó sì dá ọ lójú pé o lè rí nǹkan mú relé láti ibẹ̀.” Ǹjẹ́ ìlànà kan náà ṣeé lò lóde òní?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọkùnrin kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó ní láti múra sílẹ̀ dáadáa láti ṣe ojúṣe rẹ̀. Tí ara rẹ̀ bá le ó ní láti ṣiṣẹ́. Àmọ́, iṣẹ́ àṣekára tí ọkùnrin ní láti ṣe kó tó lè bójú tó ìdílé rẹ̀ kò mọ sórí pípèsè nǹkan tara nìkan. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ọkùnrin tí kì í bá bójú tó nǹkan tara tí ìdílé rẹ̀ nílò, tí kì í sì í bójú tó ẹ̀dùn ọkàn wọn àti ohun tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ. (1 Tím. 5:8) Nítorí náà, ó yẹ kí ọmọkùnrin tó ń gbèrò àtigbéyàwó kó sì bímọ bi ara rẹ̀ láwọn ìbéèrè bí: ‘Ǹjẹ́ mo ti múra sílẹ̀ débi tó lápẹẹrẹ láti pèsè nǹkan ti ara fún ìdílé tí mo máa ní? Ṣé mo ti múra tán láti di olórí ìdílé tá a máa múpò iwájú nínú ìjọsìn? Ǹjẹ́ màá lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ mi déédéé?’ Ó dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹnu mọ́ àwọn iṣẹ́ pàtàkì wọ̀nyẹn.—Diu. 6:6-8; Éfé. 6:4.
Nítorí náà, ọ̀dọ́kùnrin tó ń wá ìyàwó ní láti ronú dáadáa nípa ìlànà tó wà nínú Òwe 24:27. Bákan náà, ọ̀dọ́bìnrin ní láti béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ bóyá òun ti múra láti ṣe ojúṣe ìyàwó àti ìyá. Tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tí wọ́n sì ń gbèrò àtibímọ tàbí àwọn méjì tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní láti bi ara wọn ní irú àwọn ìbéèrè yẹn. (Lúùkù 14:28) Táwọn èèyàn Ọlọ́run bá ń tẹ̀ lé amọ̀nà tí Ọlọ́run mí sí yìí, wọ́n á yẹra fún ọ̀pọ̀ ìrora ọkàn, wọ́n á sì gbádùn ìgbé ayé ìdílé tó ń mérè wá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Àwọn ìbéèrè wo nípa ìgbéyàwó ló yẹ kí ọ̀dọ́kùnrin kan bi ara rẹ̀?