Ṣé Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Jẹ́ Ìrètí Tó Wà Fáwọn Kristẹni?
Ṣé Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Jẹ́ Ìrètí Tó Wà Fáwọn Kristẹni?
“[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́.”—ÌṢÍ. 21:4.
1, 2. Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé?
Ọ̀DỌ́KÙNRIN ọlọ́rọ̀ kan tó gbajúmọ̀ láwùjọ sáré wá sọ́dọ̀ Jésù, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú Jésù, ó sì bí i pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” (Máàkù 10:17) Ọ̀dọ́kùnrin náà ń béèrè ohun tó yẹ kóun ṣe kóun tó lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun, àmọ́ ṣé lọ́run ni àbí lórí ilẹ̀ ayé? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọlọ́run ti ṣèlérí fáwọn Júù pé àjíǹde àti ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé máa wà. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ṣì ní ìrètí yìí títí dìgbà yẹn.
2 Ó hàn pé àjíǹde sí orí ilẹ̀ ayé ni Màtá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ní òun mọ̀ pé Lásárù àbúrò òun tó kú “yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòh. 11:24) Lóòótọ́, àwọn Sadusí ìgbà yẹn kò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde. (Máàkù 12:18) Àmọ́, nínú ìwé kan tí Ọ̀jọ̀gbọ́n George Foot Moore kọ nípa ẹ̀sìn àwọn Júù, ó ní: “Àwọn ìwé . . . tí wọ́n ń kọ láti bí ọgọ́rùn-ún méjì ọdún ṣáájú ìgbà Kristi fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn nígbàgbọ́ pé tó bá di àkókò kan, àwọn tó ti kú tipẹ́tipẹ́ yóò jíǹde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé.” Nítorí náà, ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó lọ bá Jésù yẹn fẹ́ láti ní.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn onísìn àtàwọn ọ̀mọ̀wé tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì kò gbà pé wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìrètí tó wà fáwọn Kristẹni. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn nírètí pé lẹ́yìn táwọn bá kú, àwọn yóò máa bá ìgbé ayé àwọn lọ láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé nígbà táwọn èèyàn bá rí ọ̀rọ̀ náà “ìyè àìnípẹ̀kun” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀pọ̀ wọn máa ń rò pé ìyè ti ọ̀run nìkan ṣáá ló ń sọ. Ṣóòótọ́ ni? Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun? Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà gbọ́? Ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì kọ́ni pé èèyàn lè ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé?
Ìyè Àìnípẹ̀kun “ní Àtúndá”
4. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ “ní àtúndá”?
4 Bíbélì kọ́ni pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò jíǹde sí ọ̀run, àtibẹ̀ sì ni wọn yóò ti máa ṣàkóso ayé. (Lúùkù 12:32; Ìṣí. 5:9, 10; 14:1-3) Àmọ́ nígbà tí Jésù bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun, kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó máa lọ sọ́run yẹn nìkan ni Jésù máa ń sọ. Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn ti fi ìbànújẹ́ lọ nígbà tó gbọ́ pé òun ní láti fi gbogbo nǹkan ìní òun sílẹ̀ kóun wá di ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ka Mátíù 19:28, 29.) Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé wọn yóò wà lára àwọn tó máa ṣàkóso bí ọba, wọn yóò sì ṣèdájọ́ “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá,” ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn tí kò sí lára àwọn tó máa ṣàkóso ní ọ̀run. (1 Kọ́r. 6:2) Ó tún sọ̀rọ̀ nípa èrè tí “olúkúlùkù” ẹni tó bá tọ̀ ọ́ lẹ́yìn máa rí gbà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ náà “yóò jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni yóò ṣẹlẹ̀ “ní àtúndá.”
5. Ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “àtúndá.”
5 Kí ni ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ náà “àtúndá”? Nínú Bíbélì Atọ́ka, wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí “ayé titun.” Bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ ni “àkókò atúnda ayé.” Níwọ̀n bí Jésù ti lo ọ̀rọ̀ náà láìṣàlàyé rẹ̀, ó ṣe kedere pé ìrètí táwọn Júù ti ní fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ló ń sọ nípa rẹ̀. Ìyẹn ìrètí pé àkókò kan ń bọ̀ tí ipò àwọn nǹkan ní ayé yóò di àtúndá, táá fi jẹ́ pé àwọn nǹkan yóò pa dà rí bí wọ́n ṣe wà ní ọgbà Édẹ́nì ṣáájú kí Ádámù àti Éfà tó dẹ́ṣẹ̀. Àtúndá náà yóò jẹ́ ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe, pé òun “yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.”—Aísá. 65:17.
6. Kí ni àpèjúwe àgùntàn àti ewúrẹ́ kọ́ wa nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun?
6 Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun nígbà tó ń ṣàlàyé nípa ìparí ètò àwọn nǹkan. (Mát. 24:1-3) Ó sọ pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” Àwọn tó bá gba ìdálẹ́bi “yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.” “Àwọn olódodo” tí yóò gba ìyè àìnípẹ̀kun ni àwọn tó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “arákùnrin” Kristi. (Mát. 25:31-34, 40, 41, 45, 46) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti yan àwọn ẹni àmì òróró láti jẹ́ alákòóso ní Ìjọba ọ̀run, “àwọn olódodo” yẹn ní láti jẹ́ àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba yẹn lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “[Ọba tí Jèhófà yàn] yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò dé òpin ilẹ̀ ayé.” (Sm. 72:8) Àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba yìí yóò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.
Kí Ni Ìhìn Rere Jòhánù Fi Hàn?
7, 8. Ìrètí méjì wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún Nikodémù?
7 Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù àti Lúùkù, Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “ìyè àìnípẹ̀kun” láwọn ibi tá a ti mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ tá à ń bá bọ̀. Ó tó nǹkan bí ìgbà mẹ́tàdínlógún tá a rí i nínú Ìhìn Rere Jòhánù pé Jésù sọ̀rọ̀ nípa wíwàláàyè títí láé. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára wọn yẹ̀ wò ká lè mọ ohun tí Jésù sọ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.
8 Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Jòhánù, ìgbà tí Jésù kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun ni ìgbà tó ń bá Farisí kan tó ń jẹ́ Nikodémù sọ̀rọ̀. Jésù sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi àti ẹ̀mí kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run.” Èyí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ tún àwọn tí wọn yóò wọ Ìjọba ọ̀run bí. (Jòh. 3:3-5) Jésù kò parí ọ̀rọ̀ náà síbẹ̀ yẹn. Ó tún sọ ìrètí kan tó wà fún gbogbo aráyé. (Ka Jòhánù 3:16.) Jésù ń sọ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun ní ọ̀run fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn yòókù.
9. Ìrètí wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún obìnrin ará Samáríà?
9 Lẹ́yìn tí Jésù ti bá Nikodémù sọ̀rọ̀ tán ní Jerúsálẹ́mù, ó forí lé ọ̀nà Gálílì ní ìhà àríwá. Bó ṣe ń lọ, ó pàdé obìnrin kan níbi ìsun omi Jékọ́bù létí ìlú Síkárì. Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ láé, ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” (Jòh. 4:5, 6, 14) Omi yìí dúró fún ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe láti jẹ́ kí gbogbo aráyé pa dà rí ìyè àìnípẹ̀kun, títí kan àwọn tí yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ìwé Ìṣípayá ṣàlàyé pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ ni èmi yóò fi fún láti inú ìsun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 21:5, 6; 22:17) Èyí fi hàn pé ohun tí Jésù sọ fún obìnrin ará Samáríà náà nípa ìyè àìnípẹ̀kun kì í ṣe fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ajogún Ìjọba Ọlọ́run nìkan, àmọ́ ó tún kan àwọn ọmọ aráyé tó nígbàgbọ́, tí wọ́n sì nírètí láti gbé orí ilẹ̀ ayé.
10. Lẹ́yìn tí Jésù ti mú ọkùnrin kan lára dá ní adágún odò Bẹtisátà, kí ni Jésù sọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn onísìn tó ń ta kò ó?
10 Ní ọdún tó tẹ̀lé e, Jésù tún wá sí Jerúsálẹ́mù. Ó mú ọkùnrin aláìsàn kan lára dá níbi adágún odò Bẹtisátà. Jésù ṣàlàyé fáwọn Júù tó ń ta kò ó lórí ohun tó ṣe yìí pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe.” Lẹ́yìn tí Jésù ti sọ fún wọn pé Baba “ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọ lọ́wọ́,” ó fi kún un pé: “Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Jésù tún sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Ọmọ ènìyàn], wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Jòh. 5:1-9, 19, 22, 24-29) Ohun tí Jésù ń sọ fáwọn Júù tó ń ṣenúnibíni sí i yẹn ni pé òun lẹni tí Ọlọ́run yàn láti fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, èyí táwọn Júù ti ń retí, bóun sì ṣe máa ṣe é ni pé òun á jí àwọn òkú dìde.
11. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé wà lára ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 6:48-51?
11 Ní Gálílì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí oúnjẹ tí Jésù fiṣẹ́ ìyanu pèsè bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ nípa oríṣi oúnjẹ mìíràn, ìyẹn “oúnjẹ ìyè.” (Ka Jòhánù 6:40, 48-51.) Ó sọ pé: “Oúnjẹ tí èmi yóò fi fúnni ni ẹran ara mi.” Kì í ṣe torí àwọn tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run nìkan ni Jésù ṣe fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀, àmọ́ ó tún fi lélẹ̀ “nítorí ìyè ayé,” ìyẹn aráyé tó ṣeé rà pa dà. “Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí,” ìyẹn ni pé bí ẹnikẹ́ni bá lo ìgbàgbọ́ nínú agbára ẹbọ Jésù tó lè rani pa dà, onítọ̀hún yóò ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Ara ohun tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, pé èèyàn lè “wà láàyè títí láé” ni ìrètí táwọn Júù ti ní tipẹ́tipẹ́, ìyẹn ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé nígbà ìṣàkóso Mèsáyà.
12. Ìrètí wo ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé ‘òun yóò fún àwọn àgùntàn òun ní ìyè àìnípẹ̀kun’?
12 Nígbà tó yá, Jésù sọ fún àwọn alátakò rẹ̀ níbi Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ ní Jerúsálẹ́mù, pé: “Ẹ kò gbà gbọ́, nítorí ẹ kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn àgùntàn mi. Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi. Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 10:26-28) Ṣé kìkì ìyè àìnípẹ̀kun lọ́run ni Jésù ń sọ ni àbí ó tún ní ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́kàn? Kò tíì pẹ́ sígbà yẹn tí Jésù tu àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú nípa sísọ pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) Àmọ́ ní àkókò Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ yìí kan náà ni Jésù sọ pé: “Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe ara ọ̀wọ́ yìí; àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá.” (Jòh. 10:16) Nítorí náà, nígbà tí Jésù ń bá àwọn alátakò rẹ̀ sọ̀rọ̀, ìrètí iyè ti ọ̀run fún “agbo kékeré” àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ìrètí Tí Kò Nílò Àlàyé
13. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”?
13 Nígbà tí Jésù ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró, ó sọ ọ̀rọ̀ kan tó fìdí ìrètí aráyé múlẹ̀ lọ́nà tí kò ṣeé jiyàn lé lórí. Aṣebi tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù ṣèlérí fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:42, 43) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Júù ni ọkùnrin yìí, kò nílò àlàyé kankan nípa Párádísè mọ́. Ó ti mọ̀ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú lórí ilẹ̀ ayé.
14. (a) Kí ló fi hàn pé ìrètí ti ọ̀run ṣòro fáwọn àpọ́sítélì láti lóye? (b) Ìgbà wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wá lóye ìrètí tọ̀run?
14 Àmọ́ ṣá o, ohun tó nílò àlàyé ni ìrètí ti ọ̀run tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun ń lọ sọ́run láti pèsè àyè sílẹ̀ fún wọn, ohun tó ní lọ́kàn kò yé wọn. (Ka Jòhánù 14:2-5.) Ó tún sọ fún wọn nígbà tó yá pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí èyíinì bá dé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 16:12, 13) Ẹ̀yìn ìgbà àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti di ọba ni wọ́n tó lóye pé ọ̀run ni ìtẹ́ àwọn máa wà. (1 Kọ́r. 15:49; Kól. 1:5; 1 Pét. 1:3, 4) Ìrètí ogún ti ọ̀run ló jẹ́ ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì wá di lájorí ohun táwọn lẹ́tà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ń sọ. Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn ìwé yìí náà tún sọ pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé wà fún èèyàn?
Kí Ni Àwọn Lẹ́tà Onímìísí Wí?
15, 16. Báwo ni ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù àti ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe fi hàn pé ìrètí wà pé aráyé máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé?
15 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó pe àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní “ará mímọ́, alábàápín ìpè ti ọ̀run.” Àmọ́, ó tún sọ pé Ọlọ́run ti fi “ilẹ̀ ayé gbígbé tí ń bọ̀” sábẹ́ Jésù. (Héb. 2:3, 5; 3:1) Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a túmọ̀ sí “ilẹ̀ ayé gbígbé” máa ń tọ́ka sí ilẹ̀ ayé táwọn èèyàn ń gbé lórí rẹ̀. Nítorí náà, “ilẹ̀ ayé gbígbé tí ń bọ̀” túmọ̀ sí ètò àwọn nǹkan ti ọjọ́ iwájú lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi. Ìgbà yẹn ni Jésù yóò mú ìlérí Ọlọ́run ṣẹ, pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sm. 37:29.
16 Ọlọ́run tún mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti kọ̀wé nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé. Ó ní: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pét. 3:7) Kí ni yóò rọ́pò àwọn ọ̀run, tó túmọ̀ sí ìjọba tó wà nísinsìnyí àti ilẹ̀ ayé, tó túmọ̀ sí àwùjọ àwọn èèyàn búburú tó wà nísinsìnyí? (Ka 2 Pétérù 3:13.) Ohun tí yóò rọ́pò wọn ni “àwọn ọ̀run tuntun,” ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run níkàáwọ́ Mèsáyà àti “ilẹ̀ ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run.
17. Báwo ni Ìṣípayá 21:1-4 ṣe ṣàlàyé ìrètí aráyé?
17 Ìran kan tó ń múni lọ́kàn yọ̀ wà nínú ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, èyí tó fi hàn pé aráyé yóò pa dà di pípé. (Ka Ìṣípayá 21:1-4.) Láti ìgbà tí aráyé ti di aláìpé nínú ọgbà Édẹ́nì ni èyí ti jẹ́ ìrètí tó wà fáwọn tó nígbàgbọ́. Àwọn olódodo yóò máa gbé inú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí lọ láìsí pé wọ́n darúgbó. Ìrètí yìí fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó sì jẹ́ ohun tó ń fún àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lókun títí dòní olónìí.—Ìṣí. 22:1, 2.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ náà “àtúndá”?
• Kí ni Jésù bá Nikodémù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
• Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún aṣebi tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀?
• Báwo ni ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù àti ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe jẹ́rìí sí i pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé wà?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ẹni bí àgùntàn yóò gba ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn èèyàn