Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìfẹ́ Kristi!
Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìfẹ́ Kristi!
LÁLẸ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:34, 35) Láìsí àní-àní, ó yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:25) Báwo ni ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí sílò nínú ìgbéyàwó ẹ̀, àgàgà tí ìyàwó ẹ̀ bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti yara ẹ̀ sí mímọ́?
Kristi Ṣìkẹ́ Ìjọ
Bíbélì sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.” (Éfé. 5:28, 29) Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tọkàntọkàn, kò sì fọ̀rọ̀ wọn ṣeré rárá. Ńṣe ló máa ń ṣìkẹ́ wọn. Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, ó máa ń ṣe wọ́n pẹ̀lẹ́, ó sì láàánú wọn. Torí pé ìfẹ́ ọkàn ẹ̀ ni láti “mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ìdángbinrin rẹ̀,” ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dáa sí ló máa ń wò.—Éfé. 5:27.
Bí Kristi ṣe fìfẹ́ hàn sí ìjọ, ó yẹ kí ọkọ náà máa fìfẹ́ hàn sí aya ẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Bí ọkọ kan bá ń fìfẹ́ hàn sí aya rẹ̀ nígbà gbogbo, ṣìnkìn ni inú aya ẹ̀ á máa dùn pé ọkọ òun ń kẹ́ òun, ó sì ń gẹ òun. Ìbànújẹ́ ńláǹlà ló máa ń jẹ́ fún aya kan tó ní gbogbo ohun amáyédẹrùn nílé, àmọ́ tí ọkọ ẹ̀ pa á tì.
Báwo lọkọ ṣe lè fi hàn pé òun ń ṣìkẹ́ aya òun? Ó yẹ kó máa pọ́n aya ẹ̀ lé nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ fáwọn èèyàn, kó sì máa yìn ín lójú àwọn èèyàn fún ìtìlẹ́yìn tó bá ṣe. Kò gbọ́dọ̀ ni ín lára láti sọ ọ́ lójú àwọn èèyàn bí aya ẹ̀ bá ti kópa tó jọjú nínú mímú kí ìdílé wọn ṣàṣeyọrí. Tí wọ́n bá dá wà, aya ẹ̀ máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ó nífẹ̀ẹ́ òun tọkàntọkàn. Ó lè dà bíi pé, ká dini mú, ká rẹ́rìn-ín músẹ́ síni, ká gbáni mọ́ra àti ká sọ̀rọ̀ ìmọrírì síni ò já mọ́ nǹkan kan, àmọ́ kì í tètè kúrò lọ́kàn obìnrin.
“Ojú Kò Tì Í Láti Pè Wọ́n Ní ‘Arákùnrin’”
‘Ojú kò ti Kristi Jésù láti pe àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní “arákùnrin.”’ (Héb. 2:11, 12, 17) Àwọn Kristẹni tó ti láya ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé Kristẹni arábìnrin wọn laya wọn tún jẹ́. Ìyàsímímọ́ rẹ̀ fún Jèhófà ló gba ipò iwájú lórí ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ì báà jẹ́ pé ó ti fẹ́ ọ kó tó ṣèrìbọmi tàbí lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi ló fẹ́ ọ. Tí wọ́n bá fẹ́ pe aya rẹ láti lóhùn sí ìpàdé, “Arábìnrin” ni arákùnrin tó ń darí apá ìpàdé náà máa pè é. Torí náà, arábìnrin tìẹ náà ló jẹ́, kì í ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba nìkan, ó tún jẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ẹ nínú ilé. Bó ti ṣe pàtàkì pé kó o ṣe é jẹ́jẹ́, kó o sì bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ló ṣe ṣe pàtàkì tẹ́ ẹ bá wà nínú ilé.
Bó o bá láfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, nígbà míì, ó lè má rọrùn láti bójú tó ọ̀ràn ìjọ àti ti ìdílé kí ọ̀kan má sì pa èkejì lára. Báwọn
alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ará, tí wọ́n ń yan àwọn iṣẹ́ fún wọn láti bójú tó nínú ìjọ, èyí á jẹ́ kó o ráyè fún ìyàwó ẹ tó jẹ́ arábìnrin tó nílò rẹ jù lọ. Rántí pé àwọn arákùnrin míì wà tí wọ́n lè ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún ẹ nínú ìjọ, àmọ́ ìwọ nìkan lo lè ṣọkọ ìyàwó ẹ, òun sì ni arábìnrin tó nílò rẹ jù lọ.Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ ni orí aya ẹ. Bíbélì sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́r. 11:3) Báwo ló ṣe yẹ kó o lo ipò orí yìí? Lọ́nà onífẹ̀ẹ́, kì í ṣọ̀rọ̀ pé kó o máa tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì tá a sọ lókè yìí fún ìyàwó ẹ, kó o sì máa sọ fún un pé ó yẹ kó o bọ̀wọ̀ fún mi. Ohun tó o lè ṣe tó o bá fẹ́ máa lo ipò orí lọ́nà tó dáa ni pé kó o máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi nínú ọ̀nà tó o gbà ń bá ìyàwó ẹ lò.—1 Pét. 2:21
“Ọ̀rẹ́ Mi Ni Yín”
Jésù sọ pé ọ̀rẹ́ òun làwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó sọ fún wọn pé: “Èmi kò pè yín ní ẹrú mọ́, nítorí pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣùgbọ́n mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.” (Jòh. 15:14, 15) Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa. Wọ́n tún máa ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀. Wọ́n pe “Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀” sí ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe ní Kánà. (Jòh. 2:2) Wọ́n láwọn ibi tí wọ́n yàn láàyò, irú bí ọgbà Gẹtisémánì. Bíbélì sọ pé “ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti pàdé pọ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.”—Jòh. 18:2.
Ìyàwó gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n lára pé òun lòun sún mọ́ ọkọ òun jù lọ. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀yin ọkọ àtàwọn ìyàwó yín jọ máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀! Ẹ máa sin Ọlọ́run pa pọ̀. Ẹ jẹ́ kó mọ́ yín lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. Ẹ jọ máa rìn pọ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ pọ̀, kẹ́ ẹ sì jọ máa jẹun. Ẹ má ṣe jẹ́ tọkọtìyàwó nìkan, ẹ tún jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ fún ara yín.
“Ó Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin”
Jésù ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dé òpin.’ (Jòh. 13:1) Àwọn ọkọ kan kì í tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi lápá yìí. Wọ́n tiẹ̀ lè pa ‘aya ìgbà èwe wọn’ tì, bóyá torí àti lè lọ fẹ́ ọmọge kan.—Mál. 2:14, 15.
Àmọ́, àwọn kan bí Arákùnrin Willi tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Nítorí àìsàn, ìyàwó Arákùnrin yìí nílò àbójútó lóòrèkóòrè fún ọ̀pọ̀ ọdún. Báwo lọ̀ràn náà ṣe rí lára ẹ̀? Ó ní: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń wo aya mi ọ̀wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mo sì mọrírì ẹ̀ pé ó jẹ́ bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọgọ́ta ọdún [60] sẹ́yìn ni mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé màá máa ṣìkẹ́ ẹ̀ nígbà tí nǹkan bá rọrùn àti nígbà tí nǹkan bá le. Mi ò ní gbàgbé ẹ̀jẹ́ yẹn láé.”
Ẹ̀yin Kristẹni ọkọ, ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Kristi. Ẹ máa ṣìkẹ́ ìyàwó yín tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, arábìnrin yín àti ọ̀rẹ́ yín.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ṣé ìyàwó ẹ ló sún mọ́ ẹ jù lọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
‘Máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ aya rẹ’