Ìsìnkú Kristẹni—Kó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì, Kó Lọ́wọ̀, Kó Dára Lójú Ọlọ́run
Ìsìnkú Kristẹni—Kó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì, Kó Lọ́wọ̀, Kó Dára Lójú Ọlọ́run
LÁWỌN ibì kan láyé, tí wọ́n bá ń sìnkú ńṣe ni igbe àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa gbalẹ̀ kan. Wọ́n lè wọ aṣọ dúdú, kí wọ́n máa pohùn réré ẹkún, kí wọ́n sì máa janra mọ́lẹ̀. Àwọn míì á máa jó sí ìró ìlù tó ń dún kíkankíkan. Bẹ́ẹ̀ làwọn míì á máa ṣàríyá lọ ní tiwọn, wọ́n á máa jẹ, wọ́n á máa mu, wọ́n á sì máa rẹ́rìn-ín kèékèé. Àwọn míì lè ti yó bìnàkò, kí wọ́n sùn gbalaja sílẹ̀ẹ́lẹ̀ torí pé ẹmu àti ọtí bíà ń ṣàn níbẹ̀. Báwọn kan ṣe ń ṣòkú nìyẹn, táwọn èrò rẹpẹtẹ á wá síbẹ̀ pé àwọn wá kí olóògbé náà pé ó dìgbòóṣe.
Púpọ̀ lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń gbé láàárín àwọn ẹbí àti àwọn ará àdúgbò tí wọ́n gba onírúurú nǹkan tí kì í ṣòótọ́ gbọ́ nípa òkú, tí wọ́n sì bẹ̀rù òkú gidigidi. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà gbọ́ pé tẹ́nì kan bá kú, á di ara àwọn alálẹ̀, ìyẹn àwọn baba ńlá tó ti kú, tí wọ́n lè ran alààyè lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n pa wọ́n lára. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ló bí púpọ̀ nínú onírúurú ààtò ìsìnkú táwọn èèyàn ń ṣe. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú ká banú jẹ́ lórí ikú ẹnì kan. Kódà, àwọn ìgbà kan wà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà kẹ́dùn lórí ikú àwọn ojúlùmọ̀ wọn. (Jòh. 11:33-35, 38; Ìṣe 8:2; 9:39) Àmọ́ kò sí ìgbà kankan tí wọ́n ṣọ̀fọ̀ lọ́nà àṣejù bíi tàwọn èèyàn ìgbà ayé wọn. (Lúùkù 23:27, 28; 1 Tẹs. 4:13) Kí nìdí? Ìdí kan ni pé wọ́n mọ òtítọ́ nípa ikú.
Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé nísinsìnyí . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [ìyẹn ipò òkú], ibi tí ìwọ ń lọ.” (Oníw. 9:5, 6, 10) Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí yìí fi hàn pé tẹ́nì kan bá ti kú, kò mọ ohunkóhun mọ́. Kò lè ronú, kò lè mọ ohunkóhun lára, kò lè bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀, kò sì lè lóye ohunkóhun. Bá a ṣe wá lóye òtítọ́ pàtàkì yìí látinú Bíbélì, ipa wo ló yẹ kó ní lórí bí àwa Kristẹni ṣe máa ṣe ètò ìsìnkú wa?
Ẹ “Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́kan Ohun Àìmọ́”
Inú ẹ̀yà yòówù ká ti wá, ohun yòówù kí àṣà ìbílẹ̀ wa jẹ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń yàgò pátápátá fún gbogbo ààtò ìsìnkú tó dá lórí ìgbàgbọ́ pé òkú ṣì mọ ohun tó ń lọ àti pé wọ́n ṣì lè ṣe nǹkan kan fáwọn alààyè. Ohun àìmọ́ ni àwọn àṣà bí àìsùn òkú, ayẹyẹ ìsìnkú, ayẹyẹ ìrántí olóògbé, ètùtù òkú àti gbogbo ààtò ilé opó jẹ́. Nǹkan wọ̀nyí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú nítorí pé orí ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù pé ọkàn tàbí ẹ̀mí èèyàn kì í kú ni wọ́n dá lé, èyí tó lòdì sí Ìwé Mímọ́. (Ìsík. 18:4) Àwa Kristẹni tòótọ́ “kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” Nítorí náà, a kì í lọ́wọ́ sí irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 10:21) Àṣẹ Ọlọ́run yìí la máa ń pa mọ́, ó ní: “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, . . . kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.” (2 Kọ́r. 6:17) Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti tẹ̀ lé àṣẹ yìí.
Ní ilẹ̀ Áfíríkà àtàwọn ibòmíì, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé téèyàn ò bá tẹ̀ lé àwọn àṣà ìsìnkú kan, èèyàn lè rí ìbínú àwọn alálẹ̀. Wọ́n gbà pé àìtẹ̀lé àṣà wọ̀nyẹn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó lè fa ègún tàbí ibi bá àwọn ará ìlú. Ọ̀pọ̀ èèyàn Jèhófà làwọn aráàlú wọn tàbí mọ̀lẹ́bí wọn ti bẹnu àtẹ́ lù, tí wọ́n ti bú, tí wọ́n sì kà sí ẹni ìtanù torí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ààtò ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Wọ́n sọ pé àwọn míì lára wọn kẹ̀yìn síbi
táyé kọjú sí àti pé ńṣe ni wọ́n ń hùwà àrífín sí olóògbé. Àwọn ìgbà míì wà táwọn aláìgbàgbọ́ ti fipá já ètò ìsìnkú ẹni tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí gbà mọ́ àwọn ará wa lọ́wọ́. Nítorí náà, kí la lè ṣe tá ò fi ní máa forí gbárí pẹ̀lú àwọn tó bá fárígá pé dandan àwọn máa tẹ̀ lé àwọn ààtò ìsìnkú tínú Ọlọ́run ò dùn sí? Èyí tó tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì jù ni pé, kí la lè ṣe láti ta kété sí àwọn ààtò àti àṣà àìmọ́ tó rọ̀ mọ́ ìsìnkú, èyí tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?Jẹ́ Kí Wọ́n Mọ Ìlànà Tó O Máa Tẹ̀ Lé
Láwọn apá ibì kan láyé, àwọn àgbààgbà àdúgbò àtàwọn ẹbí sábà máa ń wà lára àwọn tó máa ṣèpinnu nípa bí wọ́n ṣe máa sìnkú ẹnì kan. Nítorí náà, Kristẹni olóòótọ́ tí òkú kú fún gbọ́dọ̀ jẹ́ kó yé àwọn tọ́ràn kàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ṣètò bí ìsìnkú náà ṣe máa rí, àwọn ló sì máa sin òkú náà ní ìlànà ti Bíbélì. (2 Kọ́r. 6:14-16) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun tó lè da ẹ̀rí ọkàn àwọn ará láàmú wáyé níbi ìsìnkú Kristẹni. A ò sì gbọ́dọ̀ fàyè gba ohun tó lè mú ìkọ̀sẹ̀ bá àwọn tó mọ ohun tá a gbà gbọ́ tá a sì fi ń kọ́ni nípa ipò tí òkú wà.
Tí wọ́n bá ní kí aṣojú kan látinú ìjọ Kristẹni bójú tó ètò ìsìnkú, kí àwọn alàgbà ìjọ pàfiyèsí àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lára àwọn èèyàn ẹni tó kú náà sí àwọn ìlànà Bíbélì lórí ọ̀ràn ìsìnkú, kí gbogbo ètò ìsìnkú náà lè bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Bí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá wá fẹ́ gbé àwọn àṣà àìmọ́ wọnú ètò ìsìnkú náà, ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe fàyè gba irú ìgbàkugbà bẹ́ẹ̀, àmọ́ ká fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ìlànà àwa Kristẹni lórí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láìbẹ̀rù. (1 Pét. 3:15) Tí àwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá wá ta kú pé àwọn ní láti mú àwọn ààtò àìmọ́ wọnú ètò ìsìnkú náà ńkọ́? Àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lára àwọn èèyàn ẹni tó kú náà lè fi òkú yẹn sílẹ̀ fún wọn. (1 Kọ́r. 10:20) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, a kàn lè lọ sọ àsọyé ìsìnkú ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí níbòmíì tó bójú mu láìjẹ́ pé òkú náà wà níbẹ̀, ká lè fi sọ̀rọ̀ “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́” fún àwọn tí inú wọn bà jẹ́ lóòótọ́ nítorí èèyàn wọn tó kú. (Róòmù 15:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí òkú olóògbé náà níbẹ̀, irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ yóò lọ́wọ̀, kò sì ní sóhun tó burú níbẹ̀. (Diu. 34:5, 6, 8) Bí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá fagídí já ìsìnkú gbà mọ́ni lọ́wọ́, ó lè dá kún ìnira àti ìbànújẹ́ tó báni lásìkò náà. Ṣùgbọ́n ìtùnú ló máa jẹ́ fún wa bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run, ẹni tó lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” rí gbogbo ìsapá wa láti ṣe ohun tó tọ́.—2 Kọ́r. 4:7.
Kọ Bó O Ṣe Fẹ́ Kí Wọ́n Ṣe Ìsìnkú Rẹ Sílẹ̀
Téèyàn bá ti kọ ìtọ́ni nípa ìsìnkú ara rẹ̀ sílẹ̀, ó máa ń jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn láti rí àlàyé ṣe fáwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọn kì í sábà fẹ́ yí ọ̀rọ̀ tí olóògbé kọ sílẹ̀ kó tó kú pa dà. Ara nǹkan pàtàkì tó yẹ kó wà lákọọ́lẹ̀ ni béèyàn ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe ìsìnkú òun, ibi tó fẹ́ kí wọ́n ti ṣe é àti ẹni tó máa ṣe kòkáárí gbogbo ètò ìsìnkú náà. (Jẹ́n. 50:5) Téèyàn bá buwọ́ lu àkọsílẹ̀ náà lẹ́yìn tó ti kọ ọ́ tán, táwọn ẹlẹ́rìí sì fọwọ́ sí i, ìyẹn á mú kó túbọ̀ lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Àwọn tó ń fi ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n tó wà nínú ìlànà Bíbélì ṣètò sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú mọ̀ pé kò yẹ káwọn dúró dìgbà táwọn bá darúgbó tàbí táwọn bá ń ṣàìsàn tó máa gbẹ̀mí àwọn káwọn tó máa ronú láti ṣe irú ètò bẹ́ẹ̀.—Òwe 22:3; Oníw. 9:12.
Kì í wu àwọn kan kí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ irú àwọn ìtọ́ni bẹ́ẹ̀. Àmọ́ téèyàn bá ṣe é, ńṣe ló máa fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹni náà àti pé ó gba tàwọn èèyàn rẹ̀ rò. (Fílí. 2:4) Ó sàn kéèyàn fúnra rẹ̀ ti bójú tó nǹkan wọ̀nyí ju pé kó dá gbogbo rẹ̀ dá ìdílé rẹ̀ tí ọkàn wọn ti máa pòrúurùu débi pé tí wọ́n bá fúngun mọ́ wọn, wọ́n lè fàyè gba àṣà àìmọ́ tí olóògbé náà kò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí kò sì nífẹ̀ẹ́ sí nígbà ayé rẹ̀.
Jẹ́ Kí Ètò Ìsìnkú Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Lọ́pọ̀ ibi nílẹ̀ Áfíríkà, èrò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn ni pé ayé gbọ́dọ̀ gbọ́ kí ọ̀run sì mọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sìnkú kí wọ́n má bàa rí ìbínú àwọn alálẹ̀. Àwọn míì máa ń fi ìsìnkú ṣe “ṣekárími,” láti fi jẹ́ káyé mọ̀ báwọn ṣe lówó tó àti báwọn ṣe gbajúmọ̀ tó láwùjọ. (1 Jòh. 2:16) Wọ́n á náwó nára sorí ìsìnkú láti rí i pé àwọn ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn ayé kà sí ẹ̀yẹ ìkẹyìn tí wọ́n ń ṣe fún òkú. Kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn bàa lè wá síbẹ̀, wọ́n á ya àwòrán olóògbé sínú bébà fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀, wọ́n á wá lẹ̀ ẹ́ káàkiri láti fi kéde ikú àti ìsìnkú rẹ̀ fáyé gbọ́. Wọ́n lè ṣe ẹ̀wù péńpé tí wọ́n ya àwòrán olóògbé sí, wọ́n á pín in fáwọn tó wá ṣòkú kí wọ́n wọ̀ ọ́. Wọ́n á lọ ra pósí olówó ńlá aláràbarà káwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí wọn. Kódà, ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, wọ́n bá a débi pé wọ́n máa ń ṣe pósí tó dà bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọkọ̀ òfuurufú, ọkọ̀ ojú omi tàbí àwọn nǹkan míì, láti fi jẹ́ káráyé rí i pé ìsìnkú náà jẹ́ ti ẹni ńlá, ẹni iyì, àti ẹni tó rí já jẹ. Wọ́n lè gbé òkú olóògbé náà jáde nínú pósí rẹ̀, kí wọ́n wá tẹ́ ẹ nítẹ̀ẹ́ ẹ̀yẹ sórí bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Tó bá jẹ́ obìnrin ni, wọ́n lè wọ aṣọ ìyàwó funfun sí i lọ́rùn, kí wọ́n fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye àti ẹ̀gbà ọrùn ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n sì tún ṣe ojú rẹ̀ lóge. Ǹjẹ́ ó bójú mu káwa èèyàn Ọlọ́run máa lọ́wọ́ sí irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀?
Àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn mọ̀ pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí afẹfẹyẹ̀yẹ̀ àwọn èèyàn tí kò mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run tàbí tí wọn ò ka àwọn ìlànà náà sí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé àwọn àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn afẹfẹyẹ̀yẹ̀ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ ayé tí ń kọjá lọ. (1 Jòh. 2:15-17) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi fún ẹ̀mí ìdíje tí kò yẹ Kristẹni, èyí táá mú ká fẹ́ máa wá bí ìsìnkú tiwa ṣe máa ta yọ tàwọn ẹlòmíì. (Gál. 5:26) Gẹ́gẹ́ bó ṣe sábà máa ń rí, tí ìbẹ̀rù òkú bá ti wà nínú àṣà àti ìṣe àwọn èèyàn kan, wọn kì í sábàá fi ìsìnkú mọ ní kékeré. Irú ayẹyẹ ìsìnkú bẹ́ẹ̀ sì máa ń ṣòro láti bójú tó nítorí pé tó bá yá apá ò ní ká a mọ́. Jíjúbà òkú lè tètè mú kí orí àwọn aláìgbàgbọ́ wú débi tí wọ́n á fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun àìmọ́. Níbi irú ìsìnkú bẹ́ẹ̀, igbe àti ìpohùnréré ẹkún lè gbalẹ̀ kan, àwọn èèyàn lè máa dì mọ́ òkú náà, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ sí i bíi pé ó ń gbọ́ wọn. Wọ́n tún lè sin owó àtàwọn nǹkan míì mọ́ òkú náà. Tí irú nǹkan báyìí bá lọ wáyé níbi ìsìnkú Ẹlẹ́rìí kan, ẹ̀gàn ńlá nìyẹn máa kó bá orúkọ Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.—1 Pét. 1:14-16.
Láìsí àní-àní, ó yẹ kí mímọ̀ tá a mọ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà jẹ́ ká ní ìgboyà láti yàgò fún ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ àṣà ayé nígbà ìsìnkú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Éfé. 4:17-19) Jésù ni ọkùnrin tó tóbi lọ́lá jù tó sì tún jẹ́ ẹni pàtàkì jù lọ láyé, síbẹ̀, ètò ìsìnkú tó mọ níwọ̀n ni wọ́n ṣe fún un láìsì afẹfẹyẹ̀yẹ̀. (Jòh. 19:40-42) Àwọn tó bá “ní èrò inú ti Kristi” mọ̀ pé kò sí àbùkù kankan nínú irú ètò ìsìnkú tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì bẹ́ẹ̀, láìní afẹfẹyẹ̀yẹ̀ kankan nínú. (1 Kọ́r. 2:16) Dájúdájú, jíjẹ́ kí ìsìnkú Kristẹni wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì láìsí afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ni ọ̀nà tó dáa jù láti gbà yàgò fún àwọn àṣà tó lòdì sí Ìwé Mímọ́, òun sì ni ọ̀nà tó dára jù láti jẹ́ kí ìsìnkú lọ́wọ̀, kó bójú mu, kó sì yẹ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ṣàríyá Níbi Ìsìnkú?
Ó lè jẹ́ àṣà àwọn kan pé kí àwọn mọ̀lẹ́bí, ojúlùmọ̀ àtàwọn míì kóra jọ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sin òkú, kí wọ́n pagbo àríyá, kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n máa mu, kí wọ́n sì máa jó sí ìlú àtorin tó rinlẹ̀. Mímu ọtí àmuyíràá àti oríṣiríṣi ìwà ìbàjẹ́ sì sábà máa ń wáyé níbi irú àríyá bẹ́ẹ̀. Àwọn kan sọ pé ńṣe ni irú àríyá bẹ́ẹ̀ máa ń mú ìbànújẹ́ ikú náà kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn. Àwọn míì sì máa ń sọ pé ara àṣà ìbílẹ̀ àwọn ni. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ó pọn dandan káwọn ṣe irú àríyá aláriwo bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣeyẹ ìkẹyìn fún olóògbé, láti fi kí i pé ó dìgbòóṣe, kí ẹ̀mí rẹ̀ lè dé ọ̀run láyọ̀, kó sì sùn re.
Àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀ dájú pé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ yìí bọ́gbọ́n mu gan-an, ó ní: “Ìbìnújẹ́ sàn ju ẹ̀rín, nítorí nípa ìfàro ojú ni ọkàn-àyà fi ń di èyí tí ó wà ní ipò tí ó sàn jù.” (Oníw. 7:3) Yàtọ̀ síyẹn, a mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ronú jinlẹ̀ lórí bí ìgbésí ayé ọmọ èèyàn ṣe kúrú tó àti nípa ìrètí àjíǹde. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, lójú àwọn tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ‘ọjọ́ ikú sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.’ (Oníw. 7:1) Nítorí náà, mímọ̀ tá a mọ̀ pé ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù àti onírúurú ìwà ìbàjẹ́ máa ń wà nínú àríyá òkú, mú kó jẹ́ ohun tí kò bójú mu rárá àti rárá fáwa Kristẹni tòótọ́ láti ṣe irú àríyá bẹ́ẹ̀, tàbí ká tiẹ̀ lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣe é pàápàá. Tá a bá wà níbi tí wọ́n ti ń ṣe àríyá òkú, ńṣe là ń fi hàn pé a kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni a ò sì gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ará wa yòókù tó ń sin Jèhófà rò.
Jẹ́ Káwọn Èèyàn Rí I Pé A Yàtọ̀
A mà dúpẹ́ o pé a bọ́ lọ́wọ́ jìnnìjìnnì òkú tó sábà máa ń bo àwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí! (Jòh. 8:32) Gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ìmọ́lẹ̀,” bí a ṣe máa ń fi ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn tiwa hàn fi hàn pé Ọlọ́run ti là wá lóye. Ìyẹn ni pé a máa ń jẹ́ kó mọ níwọ̀n, kó lọ́wọ̀, kó sì tún fi hàn pé ìrètí àjíǹde tó dájú ń tù wá nínú. (Éfé. 5:8; Jòh. 5:28, 29) Ìrètí àjíǹde yìí kò ní jẹ́ ká banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ bíi tàwọn “tí kò ní ìrètí.” (1 Tẹs. 4:13) Yóò jẹ́ ká lè ní ìgboyà tá a ó fi dúró gbọn-in gbọ́n-in lórí ìlànà ìjọsìn mímọ́, láìní fàyè gba ìbẹ̀rù èèyàn.—1 Pét. 3:13, 14.
Tá a bá dúró gbọ́n-in láìyẹsẹ̀ lórí ìlànà Ìwé Mímọ́, á jẹ́ káwọn èèyàn lè ‘rí ìyàtọ̀ láàárín àwọn tí ń sin Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín.’ (Mál. 3:18) Ọjọ́ ń bọ̀ tí ikú kò ní sí mọ́. (Ìṣí. 21:4) Bá a ṣe ń dúró de ìmúṣẹ ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe yẹn, ǹjẹ́ kí Jèhófà lè rí wa ní àìléèérí, ní àìlábààwọ́n, àti pé a ti ya ara wa sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ayé burúkú yìí àtàwọn àṣà ayé tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run.—2 Pét. 3:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká kọ ìtọ́ni nípa ìsìnkú wa sílẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìsìnkú Kristẹni gbọ́dọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kó sì fi ọ̀wọ̀ hàn