“Jèhófà Ni Okun Mi”
“Jèhófà Ni Okun Mi”
Gẹ́gẹ́ bí Joan Coville ti sọ ọ́
Wọ́n bí mi ní oṣù July ọdún 1925 nílùú Huddersfield, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Èmi ni ọmọ kan ṣoṣo lọ́wọ́ àwọn òbí mi, mo sì jẹ́ aláìlera. Kódà, bàbá mi máa ń sọ fún mi pé: “Bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ yẹ́ẹ́ báyìí, ń ṣe ni àìsàn rẹ máa dé.” Ó sì jọ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn!
NÍGBÀ tí mo wà lọ́mọdé, àwọn àlùfáà máa ń gbàdúrà kíkankíkan fún àlàáfíà, àmọ́ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, àwọn kan náà ni wọ́n tún ń gbàdúrà fún ìṣẹ́gun. Èyí tojú sú mi, ó sì gbin iyèméjì sí mi lọ́kàn. Àkókò yẹn gan-an ni Annie Ratcliffe, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣoṣo lágbègbè wa wá sílé wa.
Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Annie fún wa ní ìwé Salvation, ó sì pe màmá mi wá sí ìjíròrò Bíbélì tí yóò wáyé nílé rẹ̀. a Màmá mi sì sọ pé kí n ká lọ. Mo ṣì rántí ìjíròrò àkọ́kọ́ yẹn dáadáa. Ọ̀rọ̀ nípa ìràpadà ni ìjíròrò yẹn dá lé, ó sì jọ mí lójú pé ọ̀rọ̀ náà kò súni rárá. Ìjíròrò náà jẹ́ kí n rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè mi. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé, a tún lọ síbẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni wọ́n ṣàlàyé. Àwọn ohun tó ń báni nínú jẹ́ tó wà nínú ayé yìí, tí èmi àti màmá mi ṣàkíyèsí mú ká tètè mọ̀ pé òtítọ́ lohun tá à ń kọ́ yìí. Lọ́jọ́ yẹn gan-an ni wọ́n pè wá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Nínú gbọ̀ngàn yẹn, mo bá àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan pàdé tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lára wọn ni Joyce Barber (tó ń jẹ́ Ellis nísinsìnyí), tó ṣì ń sin pẹ̀lú Peter ọkọ rẹ̀, ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London. Èrò mi ni pé gbogbo èèyàn ló ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, nítorí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọgọ́ta wákàtí wàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń lọ sílé ìwé.
Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, ní February 11, ọdún 1940, èmi àti ìyá mi ṣèrìbọmi ní ìpàdé àyíká tá a ṣe nílùú Bradford nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bàbá mi kò ta ko ẹ̀sìn wa tuntun yìí, àmọ́ kò di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lákòókò tí mo ṣèrìbọmi ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Èmi náà bá wọn ṣe iṣẹ́ ìwàásù ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, mo màá ń gbé àpò ìwé ìròyìn àti páálí fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ méjì tá a kọ nǹkan sí dání. Lọ́jọ́ Sátidé kan, wọ́n ní kí n ṣiṣẹ́ ní apá ilé ìtajà kan tí èrò máa ń pọ̀ sí. Nígbà yẹn, mo ṣì máa ń bẹ̀rù láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ó sì jọ pé gbogbo àwọn ọmọ ilé ìwé mi ló gba ibi tí mo dúró sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà náà kọjá!
Lọ́dún 1940, wọ́n fẹ́ pín ìjọ tá à wà sí méjì. Nígbà tí wọ́n pín in, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ojúgbà mi ló wà nínú ìjọ kejì. Mo sọ bí ọ̀rọ̀ yìí kò ṣe dùn mọ́ mi nínú fún ìránṣẹ́ ìjọ (tá à ń pè ní alága àwọn alábòójútó nísinsìnyí). Ó sọ fún mi pé: “Tó o bá ń wá àwọn ọ̀dọ́ bíi tìrẹ tó o lè máa bá kẹ́gbẹ́, jáde lọ wá wọn, kó o sì wàásù fún wọn.” Ohun tí mo sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn! Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí mo pàdé ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́
Elsie Noble. Ọ̀dọ́bìnrin yìí kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì wá di ọ̀rẹ́ mi títí lọ.Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà àti Ìbùkún Tó Ń Mú Wá
Lẹ́yìn tí mo parí ẹ̀kọ́ mi nílé ìwé, mo bá onímọ̀ ìṣirò owó kan ṣiṣẹ́. Àmọ́, mo kíyè sí i pé àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa ń láyọ̀ púpọ̀, èyí mú kí ìfẹ́ mi láti máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà pọ̀ sí i. Lóṣù May ọdún 1945, inú mi dùn gan-an láti bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ jáde lọ wàásù lẹ́yìn tí mo di aṣáájú-ọ̀nà, òjò rọ̀ gan-an. Síbẹ̀, inú mi dùn gan-an pé mi ò jẹ́ kí òjò yẹn dí mi lọ́wọ́. Ká sòótọ́, jíjáde lọ wàásù lójoojúmọ́ àti gígun kẹ̀kẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ti mú kára mi túbọ̀ lé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú ni mí, kò tíì sígbà kan rí tí mo ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo tí wá rí i pé “Jèhófà ni okun mi.”—Sm. 28:7.
Wọ́n rán mi lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbi tí kò ti sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan kí n lọ dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Mo kọ́kọ́ sìn nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fún ọdún mẹ́ta, lẹ́yìn náà, mo tún sìn nílẹ̀ Ireland fún ọdún mẹ́ta. Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílùú Lisburn, nílẹ̀ Ireland, mo ń kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó jẹ́ igbákejì pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kan báyìí. Bí ọkùnrin náà ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ nínú Bíbélì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ láwọn ohun tuntun tó ń kọ́. Àwọn kan lára ọmọ ìjọ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà, wọ́n sì ní kó ṣàlàyé ìdí tó fi ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ láwọn ẹ̀kọ́ náà. Ó sọ fún wọn pé ojúṣe òun gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ni láti sọ fún àwọn ọmọ ìjọ pé òun ti kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ilé rẹ̀ ta kò ó, síbẹ̀ ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì sìn ín tọkàntọkàn títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
Nílẹ̀ Ireland, ìlú Larne ni ibi kejì tí wọ́n ní kí n ti lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo dá nìkan ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, nítorí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ti lọ sí àpéjọ kan tí wọ́n ṣe nílùú New York, nílẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́dún 1950, tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní, Ìbísí Ìjọba Ọlọ́run. Nǹkan ò rọrùn fún mi nígbà yẹn. Ó wù mí gan-an pé kémi náà lọ sí àpéjọ yẹn. Àmọ́ ṣá o, mo ní àwọn ìrírí tó wúni lórí gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́fà yẹn. Mo pàdé ọkùnrin àgbàlagbà kan tó ti gba ọ̀kan lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lóhun tó lé lógún ọdún sẹ́yìn. Láti àwọn ọdún wọ̀nyẹn wá, ó ti kà á lọ́pọ̀ ìgbà débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ sórí. Níkẹyìn, òun àti ọmọbìnrin rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Mo Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Lọ́dún 1951, wọ́n pe èmi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà mẹ́wàá míì láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá sí kíláàsì kẹtàdínlógún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní South Lansing, ní ìpínlẹ̀ New York. Mo mà gbádùn ìtọ́ni Bíbélì tí wọ́n fún wa láwọn oṣù wọ̀nyẹn o. Lákòókò yẹn àwọn arábìnrin ò tíì máa forúkọ sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láwọn ìjọ wọn. Àmọ́, àwa arábìnrin máa ń níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, a sì máa ń sọ ìròyìn nípa orílẹ̀-èdè wa. Ẹ̀rù máa ń bà wá gan-an tá a bá ti fẹ́ sọ̀rọ̀ nílé ẹ̀kọ́ yìí! Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ ṣiṣẹ́, ńṣe lọ́wọ́ tí mo fi di ìwé mú ń gbọ̀n títí mo fi parí iṣẹ́ náà. Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà, Arákùnrin Maxwell Friend, sọ lọ́nà àwàdà pé: “Gbogbo sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ ni ẹ̀rù máa ń kọ́kọ́ bà níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀
wọn, àmọ́ kì í ṣe ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni ẹ̀rù ti bà ọ́, ńṣe ni ẹ̀rù bà ọ́ títí tó o fi parí ọ̀rọ̀ rẹ.” Nígbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, gbogbo wa pátá la kọ́ bá a ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dá ṣáká níwájú kíláàsì. Ká tó wí, ká tó fọ̀, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ti parí, wọ́n sì yan àwa akẹ́kọ̀ọ́yege sáwọn ilẹ̀ òkèèrè mélòó kan. Wọ́n ní kí n lọ sìn nílẹ̀ Thailand!“Ilẹ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìn-ín Ẹ̀yẹ”
Ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà ló jẹ́ lójú mi pé Arábìnrin Astrid Anderson ni wọ́n ní kó wá ṣe alábàáṣiṣẹ́ mi nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Thailand. A lo ọ̀sẹ̀ méje gbáko nínú ọkọ̀ òkun akẹ́rù ká tó débẹ̀. Nígbà tá a dé olú ìlú Thailand, ìyẹn Bangkok, a rí àwọn ọjà táwọn èèyàn ń ná wìtìwìtì, a sì tún rí àwọn ipa odò táwọn èèyàn ń gbé ọkọ̀ ojú omi gbà lọ sí àwọn ọjà náà. Lọ́dún 1952, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà nílẹ̀ Thailand kò tó àádọ́jọ.
Nígbà tá a kọ́kọ́ rí Ilé Ìṣọ́ lédè Thai, a ṣe kàyéfì pé: ‘Ǹjẹ́ a lè mọ èdè yìí sọ láé?’ Kò rọrùn rárá láti mọ̀ bóyá ohùn òkè tàbí ohùn ìsàlẹ̀ lèèyàn máa fi pe àwọn ọ̀rọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ yìí, khaù tó túmọ̀ sí “ìrẹsì” ni wọ́n ń fi ohùn òkè àti ìsàlẹ̀ pè. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ló túmọ̀ sí “ìròyìn,” ohùn ìsàlẹ̀ tó rinlẹ̀ ni wọ́n sì fi ń pè é. Nítorí náà, nígbà tá a jáde lọ wàásù, pẹ̀lú ìtara la kọ́kọ́ fi ń sọ fáwọn èèyàn pé, “A mú ìrẹsì rere wá fún yín o,” ohun tá a sì fẹ́ sọ ni pé, “A mú ìròyìn rere wá fún yín o”! Ṣùgbọ́n ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ẹ̀rín, a mọ èdè náà sọ.
Àwọn èèyàn ilẹ̀ Thailand jẹ́ ọlọ́yàyà. Abájọ tí wọ́n fi ń pe orílẹ̀-èdè Thailand ní Ilẹ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìn-ín Ẹ̀yẹ. Wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ sí ìlú Khorat (tó ń jẹ́ Nakhon Ratchasima nísinsìnyí), a sìn níbẹ̀ fún ọdún méjì. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní ká lọ sílùú Chiang Mai. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Thailand jẹ́ onísìn Buddha, wọn ò sì mọ Bíbélì. Ní ìlú Khorat, mo ń kọ́ ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ọ̀gá ilé ìfìwéránṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mò ń sọ fún un nípa Ábúráhámù baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti inú Bíbélì. Nítorí pé ọkùnrin yìí ti gbọ́ orúkọ náà Ábúráhámù tẹ́lẹ̀, ó ń mi orí rẹ̀ láti fi hàn pé òun mọ̀ ọ́n dáadáa. Àmọ́, mo wá mọ̀ nígbà tó yá pé Ábúráhámù témi ń sọ nípa rẹ̀ kọ́ ni ọkùnrin yìí mọ̀. Ọ̀gbẹ́ni Abraham Lincoln, tó jẹ́ ààrẹ Amẹ́ríkà nígbà kan rí ló rò pé mo ń sọ!
A máa ń gbádùn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a máa ń kọ́ àwọn ará Thailand tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn. Àmọ́ àwọn ará Thailand pẹ̀lú kọ́ wa bá a ṣe lè máa gbé ìgbé ayé aláyọ̀ kí ojú wa sì mú ọ̀nà kan. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wa yẹn ṣeyebíye gan-an ni, nítorí pé kò sí iná mànàmáná àti omi ẹ̀rọ nílé táwa míṣọ́nnárì kọ́kọ́ gbé ní Khorat. Ní irú ibi tí wọ́n yàn wá sí yìí, a “ti kọ́ àṣírí . . . bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.” Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, a ti rí ohun tó túmọ̀ sí láti ‘ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fúnni.’—Fílí. 4:12, 13.
Mo Ní Alábàáṣiṣẹ́ Tuntun àti Iṣẹ́ Tuntun
Lọ́dún 1945, mo ṣèbẹ̀wò sílùú London. Lákòókò ìbẹ̀wò yẹn, èmi pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan àtàwọn ará Bẹ́tẹ́lì lọ sí ilé ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti British Museum. Ọ̀kan lára wọn ni Allan Coville, tó jẹ́ pé lẹ́yìn ìgbà tá a pàdé yẹn, ó lọ sí kíláàsì kọkànlá ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Wọ́n rán an lọ sí orílẹ̀-èdè Faransé, lẹ́yìn náà ó tún lọ sí orílẹ̀-èdè Belgium. b Lẹ́yìn ìgbà yẹn, tí mò ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Thailand, ló ní òun fẹ́ fẹ́ mi, mo sì gbà.
A ṣègbéyàwó nílùú Brussels, lórílẹ̀-èdè Belgium, ní July 9, ọdún 1955. Ó ti wà lọ́kàn mi tipẹ́tipẹ́ pé lẹ́yìn tí mo bá ṣègbéyàwó, ìlú Paris ni mo ti máa lọ lo ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì. Nítorí náà, Allan ṣètò pé ká lọ sí àpéjọ tó máa wáyé níbẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé ìgbéyàwó wa. Àmọ́, nígbà tá a débẹ̀, ṣe ni wọ́n sọ fún ọkọ mi pé kó wá bá wọn ṣe ògbufọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ ní àpéjọ náà. Ó ní láti tètè kúrò nílé lójoojúmọ́, alẹ́ pátápátá la sì máa ń pa dà sílé tá a dé sí. Lóòótọ́, mo lo ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì ẹ̀yìn ìgbéyàwó mi nílùú Paris, àmọ́, orí pèpéle lọ́ọ̀ọ́kán ni mo ti máa ń rí ọkọ mi! Àní bó tiẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ náà, inú mi dùn gan-an láti rí ọkọ mi tó ń sin àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀. Ó dá
mi lójú pé tá a bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbéyàwó wa, a ó máa láyọ̀.Ìgbéyàwó mi tún gbé mi dé ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun, ìyẹn orílẹ̀-èdè Belgium. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo mọ̀ nípa ilẹ̀ Belgium kò ju pé ibẹ̀ ni wọ́n ti ja àwọn ogun mélòó kan, àmọ́ láìpẹ́ mo wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Belgium jẹ́ èèyàn àlàáfíà. Ohun tó tún di ara iṣẹ́ mi ni láti kọ́ èdè Faransé, nítorí pé èdè yìí ni wọ́n ń sọ ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè náà.
Àwọn akéde ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [4,500] ló wà ní Belgium lọ́dún 1955. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta tí èmi àti Allan, ọkọ mi fi sìn ní Bẹ́tẹ́lì àti nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Kẹ̀kẹ́ la fi ń rìnrìn àjò wa fún ọdún méjì ààbọ̀ àkọ́kọ́ nínú àwọn ọdún yẹn, tá à ń já sí kòtò já sí gegele, lójò lẹ́ẹ̀rùn. Ní gbogbo àwọn ọdún yẹn, ilé àwọn ará tá a sùn sí ju ẹgbẹ̀rún méjì lọ! Mo sábà máa ń rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìlera àmọ́ tí wọ́n ń fi gbogbo okun wọn sin Jèhófà. Àpẹẹrẹ wọn ti fún mi ní níṣìírí láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn mi. Ọ̀pọ̀ ìṣírí la máa ń rí gbà lópin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan tá à ń lò láwọn ìjọ tá a ń bẹ̀ wò. (Róòmù 1:11, 12) Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ ni Allan, ọkọ mi jẹ́ fún mi. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà ní Oníwàásù 4:9, 10 pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, . . . nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde”!
Àwọn Ìbùkún Tí Mo Rí Nínú Gbígbára Lé ‘Okun Jèhófà’ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Mi
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, èmi àti Allan ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń fún wa láyọ̀ bá a ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1983 a ṣèbẹ̀wò sí ìjọ Faransé kan tó wà ní Antwerp, a sì dé sọ́dọ̀ ìdílé kan tó gbàlejò ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Benjamin Bandiwila. Ó wá láti orílẹ̀-èdè Zaire (tó ń jẹ́ Democratic Republic of Congo nísinsìnyí). Benjamin wá sí ilẹ̀ Belgium láti kàwé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ó sọ fún wa pé: “Ìgbésí ayé tẹ́ ẹ̀ ń gbé wù mí, tẹ́ ẹ fi gbogbo ìgbésí ayé yín ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Allan dáhùn pé: “O sọ pé ìgbésí ayé wa wù ẹ́, síbẹ̀ nǹkan ayé lò ń lépa. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ohun tó o sọ kọ́ lò ń ṣe?” Ọ̀rọ̀ tó sojú abẹ níkòó yẹn mú kí Benjamin ronú nípa ìgbésí ayé rẹ̀. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílẹ̀ Zaire. Nísinsìnyí ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka nílẹ̀ Zaire.
Lọ́dún 1999, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi láti mú egbò kan tó wa ní ọ̀nà ọ̀fun mi kúrò. Láti ìgbà yẹn ni mo ti fọn, tí ìwọ̀n mi kò sì ju ọgbọ̀n kìlógíráàmù lọ. Ká sòótọ́, ẹlẹgẹ́ èèyàn ni mí, mo sì ti wá dà bí ‘ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe.’ Síbẹ̀ mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi, Jèhófà mú kó ṣeé ṣe fún mi láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọkọ mi lọ nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò. (2 Kọ́r. 4:7) Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ kan ní oṣù March ọdún 2004, Allan, ọkọ mi sùn, ó sì gbabẹ̀ kú. Àárò rẹ̀ máa ń sọ mí gan-an ni, àmọ́ mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Jèhófà kò gbàgbé rẹ̀ máa ń tù mí nínú.
Ní báyìí, tí mo ti di ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin, mo ti lo ohun tó ju ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Mo ṣì ń wàásù dáadáa, mo máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé, mo sì tún ń lo àwọn àǹfààní tí mò ń rí lójoojúmọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun àgbàyanu tí Jèhófà fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn. Nígbà mìíràn, mo máa ń ronú pé, ‘Báwo ni ìgbésí ayé mi ì bá ṣe rí ká ní mi ò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1945?’ Nígbà yẹn, ó jọ pé àìlera mi jẹ́ ìdí tí ì bá dá mi dúró tí mi ò fi ní lè ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́! Mo ti láǹfààní láti rí i fúnra mi pé tá a bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́, yóò jẹ́ okun wa.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọdún 1939 la tẹ ìwé Salvation jáde. Àmọ́, a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
b Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Coville wà nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 1961, lédè Gẹ̀ẹ́sì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Èmi àti Astrid Anderson tá a jọ ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, (òun nìyẹn lápá ọ̀tún)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Èmi àti ọkọ mi lẹ́nu iṣẹ́ ìrìn-àjò lọ́dún 1956
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Èmi àti Allan, ọkọ mi lọ́dún 2000