Má Ṣe Fàyè Gba “Ẹ̀mí Ayé”
Má Ṣe Fàyè Gba “Ẹ̀mí Ayé”
“Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”—1 KỌ́R. 2:12.
1, 2. (a) Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń gbé ẹyẹ ìbákà sáwọn ibi ìwakùsà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà kan? (b) Ewu wo ló dojú kọ àwa Kristẹni?
ÌJỌBA ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣòfin kan lọ́dún 1911 láti lè máa dóòlà ẹ̀mí àwọn awakùsà tó ń wa èédú. Wọ́n ṣòfin pé kí wọ́n máa ní ẹyẹ ìbákà méjì níbi ìwakùsà kọ̀ọ̀kan. Torí kí ni? Bíná bá sọ níbi ìwakùsà kan, àwọn tó fẹ́ lọ yọ àwọn awakùsà tó wà níbẹ̀ máa gbé ẹyẹ náà dání lọ sábẹ́ ilẹ̀. Òórùn èéfín olóró máa ń tètè da àwọn ẹyẹ tín-tìn-tín yìí láàmù. Àwọn ẹyẹ yìí á máa fi hàn pé ara ti ń ni àwọn bí èéfín olóró bá ti dà pọ̀ mọ́ afẹ́fẹ́, kódà wọ́n lè jábọ́ látorí ibi tí wọ́n dúró lé. Tí wọ́n bá ti rí i pé ara ń ni ẹyẹ yẹn, wọ́n á mọ̀ pé ìkìlọ̀ pàtàkì nìyẹn fáwọn. Èéfín kan wà tí kò ṣeé fojú rí, tí kì í sì í rùn. Bó ṣe máa ń pààyàn ni pé kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ lè gbé afẹ́fẹ́ tára nílò káàkiri inú ara. Láìjẹ́ pé ohun kan wà tó máa ta àwọn tó fẹ́ lọ yọ àwọn awakùsà náà lólobó pé ewu ń bẹ, wọ́n lè dákú, kí wọ́n sì gbabẹ̀ kú kí wọ́n tiẹ̀ tó mọ̀ pé àwọn ti ń fa èéfín olóró símú.
2 Lọ́nà kan náà, àwa Kristẹni ń dojú kọ ipò kan tó dà bíi tàwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà yẹn. Lọ́nà wo? Nígbà tí Jésù gbé iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà jákèjádò ayé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́, ó mọ̀ pé ibi eléwu lòun ń rán wọn lọ, ìyẹn inú ayé tí Sátánì àti ẹ̀mí ayé ń darí. (Mát. 10:16; 1 Jòh. 5:19) Èyí ló mú kọ́rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ká a lára débi tó fi gbàdúrà sí Baba rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la tó máa kú, ó ní: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.”—Jòh. 17:15.
3, 4. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí sì nìdí tí ìkìlọ̀ náà fi kàn wá?
3 Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé àwọn ohun eléwú kan wà láyìíká wọn tó lè kùn wọ́n lóorun nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì lè gbabẹ̀ kú tí wọn ò bá wà lójúfò. Ọ̀rọ̀ tó sọ ṣe pàtàkì fún wa nítorí pé àkókò ìparí ètò àwọn nǹkan la wà yìí. Ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa wà lójúfò . . . kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:34-36) Àmọ́, inú wa dùn pé Jésù tún ṣèlérí pé Baba òun á fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ táá máa rán wọn létí àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́, kí wọ́n bàa lè máa wà lójúfò, kí wọ́n sì lè jẹ́ alágbára.—Jòh. 14:26.
4 Àwa náà ńkọ́? Ṣé ẹ̀mí mímọ́ náà ṣì wà láti ràn wá lọ́wọ́ lónìí? Tó bá wà, kí la lè ṣe ká tó lè rí i gbà? Kí ni ẹ̀mí ayé, báwo ló sì ṣe ń ṣiṣẹ́? Kí la sì lè ṣe láti dènà rẹ̀?—Ka 1 Kọ́ríńtì 2:12.
Ẹ̀mí Mímọ́ Tàbí Ẹ̀mí Ayé
5, 6. Kí ni ẹ̀mí mímọ́ lè ṣe fún wa, ṣùgbọ́n kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a fi máa rí i gbà?
5 Kì í ṣàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nìkan ni ẹ̀mí mímọ́ wà fún. Ó wà fáwa náà lónìí, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣohun tó tọ́, kó sì fún wa lágbára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Róòmù 12:11; Fílí. 4:13) Ó tún lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó ń tuni lára bí ìfẹ́, inú rere àti ìwà rere, tí wọ́n jẹ́ ànímọ́ tó wà nínú “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22, 23) Àmọ́ o, Jèhófà Ọlọ́run kì í fi tipátipá fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún ẹni tí kò bá fẹ́.
6 Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà ká bi ara wa léèrè pé, ‘Kí ni mo lè ṣe tí màá fi rí ẹ̀mí mímọ́ gbà?’ Bíbélì fi hàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà tá a lè ṣe. Àmọ́ ohun pàtàkì kan wà tó yẹ kó o ṣe tó sì rọrùn, òun ni pé kó o ṣáà ti béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run. (Ka Lúùkù 11:13.) Ohun míì tún ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ mí sí, ká sì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀. (2 Tím. 3:16) Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo ẹni tó bá kàn ti ka Bíbélì ló máa rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà. Ṣùgbọ́n tí Kristẹni kan bá fi òótọ́ ọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ojú tó fi ń wo nǹkan á lè bá ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí mu. Ó tún ṣe pàtàkì ká gbà pé Jèhófà ti yan Jésù gẹ́gẹ́ bí aṣojú àti pé nípasẹ̀ Jésù ni Ọlọ́run gbà ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. (Kól. 2:6) Ìdí nìyẹn tá a fi ní láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni. (1 Pét. 2:21) Bá a bá ṣe ń sapá láti dà bíi Kristi tó, bẹ́ẹ̀ náà ni a ó ṣe rí ẹ̀mí mímọ́ gbà tó.
7. Báwo ni ẹ̀mí ayé ṣe ń nípa lórí àwọn èèyàn?
7 Ẹ̀mí ayé yàtọ̀ sí ẹ̀mí mímọ. Nítorí ńṣe lẹ̀mí ayé ń ti àwọn èèyàn kí wọ́n máa hùwà bíi Sátánì. (Ka Éfésù 2:1-3.) Oríṣiríṣi ọ̀nà ló gbà ń ṣiṣẹ́. Bá a ṣe ń rí i káàkiri lónìí, ẹ̀mí ayé ń mú kí àwọn èèyàn pa àwọn ìlànà Ọlọ́run tì. Ó ń ṣagbátẹrù “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòh. 2:16) Ó máa ń mú káwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ tara, irú bí àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, owú, ìrufùfù ìbínú àti ìmutípara. (Gál. 5:19-21) Òun ló sì wà nídìí ọ̀rọ̀ ìpẹ̀yìndà tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́. (2 Tím. 2:14-18) Láìsí àní-àní, bí ẹnì kan bá ṣe gbà kí ẹ̀mí ayé darí òun tó, bẹ́ẹ̀ náà lonítọ̀hún á ṣe fìwà jọ Sátánì tó.
8. Ìpinnu wo ló dojú kọ gbogbo wa?
8 Kò sọ́gbọ́n tá a lè dá tí ẹ̀mí kankan ò fi ní máa darí wa. Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ pinnu èyí tá a máa gbà kó máa dárí ìgbésí ayé wa, ṣé ẹ̀mí mímọ́ ni àbí ẹ̀mí ayé. Ó ṣeé ṣe fáwọn tí ẹ̀mí ayé ń darí nísinsìnyí láti já ara wọn gbà lọ́wọ́ rẹ̀ kí wọ́n sì gbà kí ẹ̀mí mímọ́ máa dárí ìgbésí ayé wọn. Àmọ́ ìdàkejì ohun tá a sọ yìí náà ṣeé ṣe. Ẹ̀mí ayé lè dẹkùn mú àwọn kan tí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí tẹ́lẹ̀. (Fílí. 3:18, 19) Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní fàyè gba ẹ̀mí ayé.
Tètè Dá Àwọn Àmì Tó Ń Kìlọ̀ fún Ẹ Mọ̀
9-11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àmì tó máa jẹ́ ká tètè mọ̀ pé ẹ̀mí ayé ti fẹ́ máa darí wa?
9 Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi ìwakùsà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ ń lo àwọn ẹyẹ ìbákà gẹ́gẹ́ bí àmì táá jẹ́ kí wọ́n tètè mọ̀ pé afẹ́fẹ́ oró ti dà pọ̀ mọ́ afẹ́fẹ́ táwọn ń mí. Bí wọ́n bá rí i tí ẹyẹ kan ṣubú látorí ibi tó dúró sí, wọ́n mọ̀ pé àwọn ní láti bẹ́sẹ̀ àwọn sọ̀rọ̀ kíá. Tá a bá mú àpẹẹrẹ yìí wá sórí ọ̀rọ̀ tẹ̀mí, àwọn àmì wo ló máa ń jẹ́ ká tètè mọ̀ pé ẹ̀mí ayé ti fẹ́ máa darí wa?
10 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé pẹ̀lú ìtara la fi ń ka Bíbélì nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tá a sì ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà. Bóyá a kì í sì í fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré. Inú wa sì máa ń dùn láti lọ sí ìpàdé ìjọ, ìpàdé kọ̀ọ̀kan dà bí àkókò ìtura tẹ̀mí fún wa, tá a sì wá ka ìpàdé sí orísun omi fẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ. Àwọn ohun tá à ń ṣe yẹn ló jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí ayé, òun ni kò sì jẹ́ káyé padà kéèràn ràn wá.
11 Àmọ́ ní báyìí, ṣé a ṣì ń gbìyànjú láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? (Sm. 1:2) Ṣé àdúrà wa kò ti di ìdákúrekú, ṣé a ṣì máa ń gbà á tọkàntọkàn? Ǹjẹ́ a ṣì nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìpàdé ìjọ, tá a sì ń sapá láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? (Sm. 84:10) Àbí a ti ń pa díẹ̀ lára àwọn nǹkan dáadáa tó ti mọ́ wa lára wọ̀nyí tì? Lóòótọ́, a lè ní ojúṣe tó pọ̀ tá à ń bojú tó, tíyẹn sì lè máa gba àkókò àti okun wa tó sì lè jẹ́ kó ṣòro fún wa láti múra sí ìjọsìn Ọlọ́run. Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé ẹ̀mí ayé tó ti ń ràn wá ló jẹ́ ká máa pa àwọn kan lára nǹkan dáadáa tá à ń ṣe wọ̀nyí tì díẹ̀díẹ̀? Ṣé a máa sapá gidigidi nísinsìnyí ká lè tún padà máa múra sí ìjọsìn Ọlọ́run?
Má Ṣe Di Ẹni “Tí A Dẹrù Pa”
12. Ta ni Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “kíyè sí,” kí sì nìdí?
12 Kí la tún lè ṣe láti dènà ẹ̀mí ayé? Nígbà tí Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “máa wà lójúfò,” ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kìlọ̀ fún wọn tán nípa àwọn ohun kan tó lè wu wọ́n léwu ni. Ó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.”—Lúùkù 21:34, 35.
13, 14. Àwọn ìbéèrè wo ló tọ́ ká bi ara wa nípa jíjẹ àti mímu?
13 Ronú lórí ìkìlọ̀ yẹn ná. Ṣé Jésù sọ pé ó burú kéèyàn fi oúnjẹ àti ohun mímu tó dára síkùn ni? Rárá o! Ó mọ ohun tí Sólómọ́nì sọ, pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn [fáwọn ọmọ aráyé] ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé ẹni; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníw. 3:12, 13) Síbẹ̀, Jésù mọ̀ pé ńṣe ni ẹ̀mí ayé máa ń ti èèyàn sídìí àjẹjù àti àmujù.
14 Báwo la ṣe lè mọ̀ dájú pé ẹ̀mí ayé ò tíì dọ́gbọ́n sọ wá di alájẹjù àti ọ̀mùtíyó-kẹ́ri? A lè bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe nígbà tí mo bá ka nǹkan kan nípa àjẹkì nínú Bíbélì tàbí nínú àwọn ìwé wa? Ṣé mo máa ń ka ìmọ̀ràn yẹn sí ìmọ̀ràn tí kò ṣeé tẹ̀ lé tàbí èyí tó ti le jù, bóyá mo tiẹ̀ máa ń wá àwáwí tí màá fi lè sọ pé ohun tí mo ń ṣe ò burú? a Ojú wo ni mo fi ń wo ìmọ̀ràn náà pé tá a bá tiẹ̀ máa mu ọtí rárá, ká mu ún níwọ̀nba, ká sì rí i dájú pé a yẹra fún “mímu àmuyíràá”? Ṣé mi ò máa fojú kéré irú ìmọ̀ràn yìí, tí mo wá ń ronú pé fún ìdí kan, kò kàn mí? Táwọn èèyàn bá kọminú sí bí mo ṣe ń mutí, ǹjẹ́ mo máa ń fẹ́ gbèjà ara mi àbí mo máa ń dà á sí ìbínú? Ṣé mi ò máa kọ́ àwọn ẹlòmíì náà pé kí wọ́n má ka irú ìmọ̀ràn Bíbélì bẹ́ẹ̀ sí ìmọ̀ràn pàtàkì?’ Dájúdájú, ìṣesí èèyàn wà lára ohun téèyàn á fi mọ̀ bóyá ó ti ń fàyè gba ẹ̀mí ayé.—Fi wé Róòmù 13:11-14.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Àníyàn Bò Ọ́ Mọ́lẹ̀
15. Kí lohun táwa èèyàn sábà máa ń ṣe tí Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀?
15 Ohun pàtàkì míì tá a lè ṣe tá ò fi ní fàyè gba ẹ̀mí ayé ni ṣíṣàì kó àníyàn lé ọkàn. Jésù mọ̀ pé torí jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé ẹ̀dá, a máa ń fẹ́ ṣàníyàn lórí ọ̀ràn àtijẹ àtimu. Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn.” (Mát. 6:25) A mọ̀ pé àwọn nǹkan pàtàkì kan lè gbà wá lọ́kàn, irú bíi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bíbójú tó ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àti pípèsè àwọn ohun tó pọn dandan fún ìdílé wa. (1 Kọ́r. 7:32-34) Kí wá lohun tá a lè rí kọ́ látinú ìkìlọ̀ Jésù?
16. Ipa wo ni ẹ̀mí ayé ń ní lórí ọ̀pọ̀ èèyàn?
16 Ohun tó wọ́pọ̀ báyìí ni pé ẹ̀mí ayé ń mú káwọn èèyàn máa fi ọrọ̀ wọn ṣe ṣekárími, èyí sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe àníyàn tó léwu fún ìlera wọn. Àwọn èèyàn ayé máa fẹ́ ká gbà gbọ́ pé téèyàn bá ti lówó lọ́wọ́, ẹ̀mí rẹ̀ dè, àti pé kì í ṣe àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tẹ́nì kan ní ló ń fi í hàn bí èèyàn pàtàkì bí kò ṣe irú àwọn dúkìá tó ní àti bí wọ́n ṣe pọ̀ tó. Àwọn tí wọ́n ti fi èrò yìí tàn jẹ máa ń ṣiṣẹ́ bí ẹrú kí wọ́n lè di ọlọ́là, àníyàn tó sì máa ń wà lórí ẹ̀mí wọn ni bí wọ́n ṣe máa ní nǹkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, tó jẹ́ nǹkan ńlá, tí kò sì lẹ́gbẹ́. (Òwe 18:11) Irú èrò òdì báyìí nípa ohun ìní máa ń jẹ́ kéèyàn ṣàníyàn tí kì í jẹ́ kéèyàn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Ka Mátíù 13:18, 22.
17. Kí la lè ṣe tí àníyàn ò fi ní bò wá mọ́lẹ̀?
17 Àníyàn ò ní bò wá mọ́lẹ̀ tá a bá tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run].” Jésù mú un dá wa lójú pé tá a bá ṣe ohun tóun pa láṣẹ yìí, àwọn ohun tá a dìídì nílò la ó fi kún un fún wa. (Mát. 6:33) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gba ìlérí yìí gbọ́? Ọ̀nà kan ni pé ká kọ́kọ́ wá òdodo Ọlọ́run, ìyẹn ni pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tó bá kan ọ̀ràn owó. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa purọ́ nípa iye owó orí tó yẹ ká máa san fún ìjọba tàbí ká máa pa àwọn irọ́ “kéékèèké” nídìí òwò wa. A óò máa rí i pé a sa gbogbo agbára wa láti san àwọn owó tó yẹ ká san. Tó bá sì kan ọ̀ràn ká san àwọn gbèsè tá a jẹ ká jẹ́ kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni.’ (Mát. 5:37; Sm. 37:21) Irú ìwà àìlábòsí bẹ́ẹ̀ lè má jẹ́ kéèyàn dolówó, àmọ́ ó máa ń jẹ́ kéèyàn rí ojú rere Ọlọ́run, kéèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ó sì máa ń dín àníyàn kù gan-an.
18. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa, àǹfààní wo la sì máa jẹ tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
18 Wíwá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ kan mímọ ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò. Láwọn ìgbà míì, ó máa ń wọ ojúlówó aṣọ tó jojú ní gbèsè. (Jòh. 19:23) Òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tòótọ́ máa ń gbádùn oúnjẹ àti wáìnì pa pọ̀. (Mát. 11:18, 19) Àmọ́, bí èròjà tó ń mú oúnjẹ dùn lásán làwọn ìgbádùn wọ̀nyẹn jẹ́ fún Jésù, àwọn gan-an kọ́ loúnjẹ rẹ̀. Oúnjẹ rẹ̀ ni láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Jòh. 4:34-36) Àǹfààní tá a máa rí á mà pọ̀ tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù o! Inú wa á máa dùn bá a ṣe ń ran àwọn táyé ń pọ́n lójú lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́. Àwọn ará yóò máa nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n á sì máa tì wá lẹ́yìn. Àá sì tún máa mú ọkàn Jèhófà yọ̀. Tá a bá fohun tó tọ́ ṣe àkọ́kọ́ nígbèésí ayé, àwọn ohun ìní tara àti ìgbádùn kò ní jọ̀gá lé wa lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ó máa lò wọ́n bí ìránṣẹ́ tàbí ohun èlò tí a ó fi máa sin Jèhófà. Bá a bá sì ṣe ń jára mọ́ àwọn iṣẹ́ tó ń ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe ní rọrùn tó pé kí ẹ̀mí ayé borí wa.
Máa ‘Gbe Èrò Inú Rẹ Ka Ẹ̀mí’
19-21. Báwo la ṣe lè máa ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí,’ kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
19 Ńṣe lèèyàn máa ń ronú kó tó ṣe nǹkan. Ìgbà téèyàn bá ń ronú bí ẹlẹ́ran ara lèèyàn sábà máa ń hu àwọn ìwà tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí ìwà àìnírònú. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rán wa létí pé ó yẹ ká máa ṣọ́ èrò inú wa. Ó sọ pé: “Àwọn tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí gbé e ka àwọn ohun ti ẹ̀mí.”—Róòmù 8:5.
20 Báwo la ṣe lè ṣọ́ra kí ẹ̀mí ayé má bàa máa darí èrò inú wa kó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ darí àwọn ìwà tá à ń hù? A gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ọkàn wa nípa ṣíṣàṣàyàn ohun tá à ń rò, ká sapá láti dènà èrò ayé débi tó bá lè ṣeé ṣe dé. Bí àpẹẹrẹ, lórí ọ̀ràn eré ìnàjú, a ò ní jẹ́ káwọn ètò tó ń gbé ìṣekúṣe tàbí ìwà ipá lárugẹ kó èérí bá ọkàn wa. A mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ kò ní gbénú ọkàn tó dọ̀tí. (Sm. 11:5; 2 Kọ́r. 6:15-18) Bákàn náà, à ń pe ẹ̀mí Ọlọ́run wá sínú ọkàn wa nípasẹ̀ Bíbélì kíkà déédéé, àdúrà gbígbà, ṣíṣàṣàrò àti lílọ sípàdé. A sì tún ń gba ẹ̀mí yẹn láyè bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé.
21 Dájúdájú, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ẹ̀mí ayé àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tó ń gbé lárugẹ. Àmọ́, tá a bá sa gbogbo ipá wa lórí èyí, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ torí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ni pé, “gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú, ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.”—Róòmù 8:6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àjẹkì jẹ́ ìwà tó máa ń mọ́ èèyàn lára, ohun tá a sì fi máa ń mọ alájẹkì ni pé á máa fi ìwọra jẹun tàbí kó máa jẹun ní àjẹjù. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ẹnì kan ṣe tóbi tó kọ́ ló fi í hàn ní alájẹkì bí kò ṣe bó ṣe máa ń ṣe tọ́rọ̀ oúnjẹ bá délẹ̀. Ẹnì kan lè má sanra síbẹ̀ kó jẹ́ alájẹkì, èèyàn pẹ́lẹ́ńgẹ́ pàápàá lè jẹ́ alájẹkì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nígbà míì àìlera lè mú kí ẹnì kan wú jù tàbí kí àbùdá ẹnì kan mú kó sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Kókó ibẹ̀ ni pé alájẹkì lẹ́ni tó bá ń ki àṣejù bọ ọ̀ràn oúnjẹ, ẹni náà ì báà sanra tàbí kó má sanra.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2004.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí la lè ṣe tá a ó fi rí ẹ̀mí mímọ́ gbà?
• Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni ẹ̀mí ayé lè gbà nípa lórí wa?
• Báwo la ò ṣe ní fàyè gba ẹ̀mí ayé?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kó o tó lọ síbi iṣẹ́ tàbí ilé ìwé, gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
A gbọ́dọ̀ máa rí i pé ọkàn wa wà ní mímọ́, ká máa ṣòótọ́ nídìí òwò wa, ká sì máa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú jíjẹ àti mímu