Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
“Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—HÉB. 6:10.
1, 2. (a) Kí ni rírí àgbàlagbà tó ti ní ewú lórí lè mú ọ rántí? (b) Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn Kristẹni tó ti dàgbàlagbà?
NÍGBÀ tó o bá ń rí àwọn àgbàlagbà inú ìjọ tí wọ́n ti ní ewú lórí, ǹjẹ́ kò máa mú ọ rántí àkọsílẹ̀ kan nínú ìwé Dáníẹ̀lì? Nínú ìran kan tí Jèhófà Ọlọ́run fi han Dáníẹ̀lì, Jèhófà ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ bí ẹni tó ní irun funfun. Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé sì jókòó. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ìrì dídì gẹ́lẹ́, irun orí rẹ̀ sì dà bí irun àgùntàn tí ó mọ́.”—Dán. 7:9.
2 Ńṣe ni irun àgùntàn sábà máa ń funfun. Irun funfun tó wà lórí Jèhófà àti orúkọ oyè náà, “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” jẹ́ ká mọ̀ pé àtayébáyé ló ti wà àti pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé, èyí tó yẹ kó mú wa máa bọ̀wọ̀ fún un lọ́nà tó jinlẹ̀. Irú ojú wo wá ni Jèhófà tó jẹ́ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé fi ń wo àwọn àgbàlagbà olóòótọ́, lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìrísí Kristẹni olóòótọ́ tó dẹni tó ti dàgbà tó sì ní ewú lórí máa ń lẹ́wà lójú Ọlọ́run. Ṣé irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ti dàgbà yẹn nìwọ náà fi ń wò wọ́n?
Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ṣe Pàtàkì Tó Bẹ́ẹ̀?
3. Kí nìdí tá a fi ka àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa tó ti darúgbó sí ẹni ọ̀wọ́n?
3 Irú àwọn àgbàlagbà ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n wà lára àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tó ṣì ń sìn lọ́wọ́ àtàwọn tó ti ṣíwọ́, wọ́n sì wà lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara àtàwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run. Inú àwọn ìjọ wa gbogbo sì làwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà wọ̀nyí wà. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan lára wọn tó ti fìtara wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí àpẹẹrẹ rere wọn ti fún àwọn tọ́jọ́ orí wọn ṣì kéré níṣìírí, tó sì ti tún ìgbésí ayé wọn ṣe. Àwọn kan lára àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa tó ti darúgbó yìí ti ṣe àwọn iṣẹ́ ribiribi nínú ètò Ọlọ́run, wọ́n sì ti fara da inúnibíni nítorí ìhìn rere. Jèhófà mọrírì àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn àtohun tí wọ́n ń ṣe báyìí láti ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà sì mọrírì rẹ̀.—Mát. 24:45.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà ká sì máa gbàdúrà fún wọn?
4 Ó yẹ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run máa fẹ̀mí ìmoore hàn sáwọn olóòótọ́ tó ti darúgbó yìí, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè tiẹ̀ so bíbọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà àti gbígba tiwọn rò mọ́ ìbẹ̀rù Jèhófà. (Léf. 19:32) Ó dára ká máa gbàdúrà fáwọn olóòótọ́ wọ̀nyí déédéé, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún iṣẹ́ àṣekára tí ìfẹ́ sún wọn ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá gbàdúrà fáwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n, tàgbà tèwe.—Ka 1 Tẹsalóníkà 1:2, 3.
5. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìfararora pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tó jẹ́ àgbàlagbà?
5 Síwájú sí i, gbogbo ará ìjọ ló lè jàǹfààní látinú ìfararora pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti dàgbà yìí ti ní ìmọ̀ tó ṣeyebíye látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́, àkíyèsí àti ìrírí wọn. Wọ́n ti mọ béèyàn ṣe ń jẹ́ onísùúrù àti ẹni tó ń fọ̀rọ̀ ro ara rẹ̀ wò, bí wọ́n sì ṣe ń fi ohun tí wọ́n ti mọ̀ kọ́ àwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn wọn máa ń fún wọn láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Sm. 71:18) Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n, kẹ́ ẹ sì gba ìmọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà yìí, bí ìgbà tẹ́ ẹ ń fa omi jáde látinú kànga jíjìn.—Òwe 20:5.
6. Báwo lo ṣe lè jẹ́ káwọn àgbàlagbà mọ̀ pé o mọyì wọn?
6 Ǹjẹ́ o máa ń jẹ́ káwọn àgbàlagbà mọ̀ pé o mọyì wọn bí Jèhófà ṣe mọyì wọn? Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe é ni pé, kó o máa sọ fún wọn pé o mọrírì wọn nítorí ìṣòtítọ́ wọn àti pé o máa ń ka ìmọ̀ràn wọn sí gan-an. Ìyẹn nìkan kọ́ o, tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn, ńṣe lò ń fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún wọn lóòótọ́. Ọ̀pọ̀ Kristẹni tó ti dàgbà ṣì máa ń rántí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí àwọn àgbàlagbà olóòótọ́ fún wọn àti bí títẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn ṣe ṣe àwọn láǹfààní gan-an ní ìgbésí ayé. a
Ṣe Àwọn Ohun Tó Máa Fi Hàn Pé O Bọ̀wọ̀ fún Wọn
7. Àwọn wo ni Jèhófà gbé ojúṣe bíbójú tó àwọn àgbàlagbà lé lọ́wọ́?
7 Àwọn ìdílé ni Ọlọ́run gbé ìtọ́jú àwọn èèyàn wọn tó ti dàgbà lé lọ́wọ́. (Ka 1 Tímótì 5:4, 8.) Inú Jèhófà máa ń dùn táwọn ìdílé bá ń ṣe ojúṣe wọn fáwọn èèyàn wọn tó ti dàgbàlagbà, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n bìkítà fáwọn àgbàlagbà bí Jèhófà ṣe bìkítà fún wọn. Ọlọ́run máa ń ran irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ó sì máa ń bù kún wọn fún ìsapá wọn àti gbogbo ìtìlẹ́yìn wọn. b
8. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ará ìjọ máa ran àwọn ará tó ti dàgbàlagbà lọ́wọ́?
8 Bákan náà, inú Jèhófà máa ń dùn táwọn ará ìjọ bá ń ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn àgbàlagbà olóòótọ́ tó nílò ìrànlọ́wọ́ àmọ́ tí kò sí ara ìdílé wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tàbí èyí tó ṣe tán láti ṣèrànlọ́wọ́ fún wọn. (1 Tím. 5:3, 5, 9, 10) Àwọn ará ìjọ á tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn ń fi ‘ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, àwọn ní ìfẹ́ni ará àti ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́’ fáwọn àgbàlagbà. (1 Pét. 3:8) Pọ́ọ̀lù fi àpèjúwe kan tó bá a mu ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ káwọn ará ìjọ máa ran àwọn tó ti dàgbà lọ́wọ́ nígbà tó sọ pé bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, “gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.” (1 Kọ́r. 12:26) Tá a bá ń fẹ̀mí ìyọ́nú ṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà ńṣe là ń fi hàn pé a ń tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.”—Gál. 6:2.
9. Ìnira wo ni ọjọ́ ogbó lè mú báni?
9 Àwọn nǹkan wo ló ń fa ìnira fáwọn àgbàlagbà? Ó máa ń tètè rẹ ọ̀pọ̀ lára wọn. Wọ́n lè máa rò pé agbára àwọn kò lè gbé ṣíṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, bíi lílọ sọ́dọ̀ dókítà, lílọ san owó iná, owó omi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, títún ilé ṣe àti síse oúnjẹ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oúnjẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́nu mọ́, tí òùngbẹ kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ gbẹni béèyàn ṣe ń dàgbà sí i, àwọn àgbàlagbà lè má máa jẹun kí wọ́n sì máa mu omi tó bó ṣe yẹ. Ó sì lè máa ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀ náà tó bá dọ̀rọ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sípàdé. Ara tó ti dara àgbà lè mú kí kíkàwé àti gbígbọ́rọ̀ nípàdé nira fún wọn, àní títí kan mímúra láti lọ sípàdé. Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn ará wá lè ṣe fún irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀?
Bó O Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́
10. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti rí i dájú pé àwọn àgbàlagbà rí ìrànwọ́ tó mọ́yán lórí gbà?
10 Lọ́pọ̀ ìjọ, ọ̀nà táwọn ará ń gbà bójú tó àwọn àgbàlagbà jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń lọ bá wọn ra nǹkan, wọ́n ń bá wọn se oúnjẹ, wọ́n sì máa ń bá wọn tún ilé ṣe. Wọ́n máa ń ṣèrànlọ́wọ́ fún wọn kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè múra láti lọ sípàdé, kí wọ́n má sì gbẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà máa ń bá wọn jáde, wọ́n sì máa ń ṣètò ohun ìrìnnà. Táwọn àgbàlagbà míì kò bá lè jáde nílé, àwọn ará máa ń ṣètò bí wọ́n á ṣe gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé lórí tẹlifóònù tàbí kí wọ́n fi kásẹ́ẹ̀tì gbà á sílẹ̀ fún wọn. Àwọn alàgbà máa ń rí i dájú pé àwọn ṣètò tó mọ́yán lórí láti bójú tó ìṣòro àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ wọn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. c
11. Sọ ìrírí bí ìdílé kan ṣe ran arákùnrin àgbàlagbà kan lọ́wọ́.
11 Àwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan náà lè máa pe àwọn àgbàlagbà wá sílé wọn, kí wọ́n sì tún máa fi ìwà ọ̀làwọ́ hàn sí wọn. Ẹ wo ìrírí yìí. Lẹ́yìn tí ìyàwó arákùnrin àgbàlagbà kan kú, arákùnrin náà kò lè san owó ilé tó ń gbé mọ́ torí pé kò rí owó ìfẹ̀yìntì aya rẹ̀ gbà mọ́. Àmọ́ nígbà kan rí, òun àti aya rẹ̀ ti kọ́ tọkọtaya kan àti ọ̀dọ́mọbìnrin wọn méjì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìdílé náà sì ní ilé ńlá kan tí wọ́n ń gbé. Ìdílé yìí wá fún arákùnrin àgbàlagbà yìí ní yàrá méjì nínú ilé wọn pé kó máa gbébẹ̀. Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló fi gbé pẹ̀lú wọn, tí wọ́n jọ ń jẹun, tí wọ́n jọ ń ṣeré, tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ ará hàn síra wọn. Àwọn tó ṣì kéré lọ́jọ́ orí nínú ìdílé náà kẹ́kọ̀ọ́ lára ìgbàgbọ́ àti ìrírí rẹ̀, òun náà sì jàǹfààní látinú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin yẹn. Ọ̀dọ̀ wọn ni arákùnrin àgbàlagbà yẹn gbé títí tó fi kú lẹ́ni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89]. Ìdílé náà ṣì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àǹfààní tí wọ́n jẹ látinú ìfararora pẹ̀lú rẹ̀. Wọn kò “pàdánù èrè” wọn bí wọ́n ṣe ran arákùnrin tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi yẹn lọ́wọ́.—Mát. 10:42. d
12. Kí lo lè ṣe láti fi hàn pé ò ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ti dàgbàlagbà?
12 Ó ṣeé ṣe kó o má lè ran àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin tó ti dàgbà lọ́wọ́ lọ́nà tí ìdílé yẹn gbà ran arákùnrin yẹn lọ́wọ́, síbẹ̀ o lè máa ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn àgbàlagbà kí wọ́n lè máa wá sí ìpàdé, kí wọ́n sì máa jáde òde ẹ̀rí. O tún lè máa pè wọ́n wá sí ilé rẹ tàbí kó o ṣètò pé kẹ́ ẹ jọ ṣeré jáde. O lè lọ kí wọn nílé, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ń ṣàìsàn tàbí tí wọn ò bá lè jáde nílé. Ní àfikún sí i, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà. Tẹ́ ẹ bá sì fẹ́ ṣe ìpinnu nípa àwọn Kristẹni tó ti dàgbà yìí, ẹ jẹ́ kí wọ́n wà níbẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ṣì ń lóye ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ. Kódà, àwọn tó ń ṣarán pàápàá máa ń mọ̀ táwọn èèyàn bá bọ̀wọ̀ fún wọn tàbí tí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀.
Jèhófà Kò Ní Gbàgbé Iṣẹ́ Yín
13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ro bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ará tó dàgbàlagbà?
13 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ro bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn àgbàlagbà nínú àwọn ohun tá a bá ń ṣe. Èyí yẹ bẹ́ẹ̀ torí pé, àwọn àgbàlagbà sábà máa ń kẹ́dùn nítorí pé wọn ò lágbára mọ́ láti ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà tí eegun ọ̀dọ́ ṣì wà lára wọn. Wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ti sin Jèhófà fún nǹkan bí àádọ́ta ọdún, tó sì tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àìsàn kan sọ arábìnrin yìí di olókùnrùn, èyí tó jẹ́ kí lílọ sípàdé di ìṣòro ńlá fún un. Nígbà tó fi iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ìsinsìnyí wé ohun tó ti ṣe sẹ́yìn, ńṣe ló bú sẹ́kún. Ó dorí kodò, ó wá sọ tomijé-tomijé pé, “èmi ni mo wá dẹni tí kò lè lọ sóde ẹ̀rí mọ́ báyìí.”
14. Ìṣírí wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti dàgbàlagbà lè rí gbà látinú ìwé Sáàmù?
14 Tó bá jẹ́ àgbàlagbà ni ọ́, ǹjẹ́ o máa ń ní irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀? Àbí ìgbà míì wà tó o máa ń rò ó pé Jèhófà ti pa ọ́ tì? Ó ṣeé ṣe kí onísáàmù kan nírú èrò bẹ́ẹ̀ nígbà tó dàgbà, torí ó bẹ Jèhófà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀. Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀.” (Sm. 71:9, 18) Ó dájú pé kì í ṣe pé Jèhófà ń fẹ́ láti pa ẹni tó kọ sáàmù yẹn tì o, kò sì ní pa ìwọ náà tì. Nínú sáàmù míì, Dáfídì sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó dá a lójú gan-an ni pé Ọlọ́run á ti òun lẹ́yìn. (Ka Sáàmù 68:19.) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé tó o bá jẹ́ Kristẹni olóòótọ́ tó ti dàgbàlagbà, Jèhófà kò ní fi ọ́ sílẹ̀, ńṣe ni yóò máa gbé ọ ró lójoojúmọ́.
15. Kí ló lè jẹ́ káwọn àgbàlagbà máa ní èrò tó dára?
15 Jèhófà máa ń rántí ohun tẹ́yin Ẹlẹ́rìí rẹ̀ tó ti darúgbó ti ṣe sẹ́yìn àtohun tẹ́ ẹ ń ṣe báyìí láti fi gbé e ga. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Nítorí náà, ẹ má ṣe rò pé, nítorí ẹ ti dàgbà ẹ ò wúlò fún Jèhófà mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kẹ́ ẹ máa fi èrò tó dára rọ́pò àwọn àròdùn àti èrò tó lè múni soríkọ́ tẹ́ ẹ bá ní. Ẹ jẹ́ kí àwọn ìbùkún tẹ́ ẹ ní àti ìrètí ọjọ́ iwájú máa fún yín láyọ̀! Ẹlẹ́dàá wa ti mú un dá wa lójú pé a ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan,” ìyẹn sì ni ìrètí tó dára jù. (Jer. 29:11, 12; Ìṣe 17:31; 1 Tím. 6:19) Ẹ máa ronú nípa ìrètí tẹ́ ẹ ní yìí, ẹ máa túra ká, kẹ́ ẹ má sì ṣe gbàgbé pé wíwà tẹ́ ẹ wà nínú ìjọ ṣàǹfààní gan-an! e
16. Kí nìdí tí arákùnrin àgbàlagbà kan fi ronú pé kò yẹ kóun jẹ́ alàgbà mọ́, báwo sì ni ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ṣe fún un ní ìṣírí?
16 Ẹ wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Johan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún. Kò ráyè ṣe iṣẹ́ míì ju pé kó bójú tó Arábìnrin Sannie ìyàwó rẹ̀ olóòótọ́ tó ń ṣàìsàn. f Ńṣe làwọn arábìnrin máa ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn níbi tí wọ́n ti ń dúró ti Arábìnrin Sannie, kí Arákùnrin Johan ọkọ rẹ̀ lè lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀rọ̀ náà sú Arákùnrin Johan débi tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kò yẹ kóun jẹ́ alàgbà mọ́ nínú ìjọ. Pẹ̀lú omijé lójú ló fi béèrè pé, “kí làǹfààní jíjẹ́ tí mo jẹ́ alàgbà ń ṣe fún ìjọ? Mi ò kúkú lè ṣe ohun gidi kan mọ́.” Àmọ́ àwọn alàgbà tó kù jẹ́ kó mọ̀ pé ìrírí àti òye rẹ̀ wúlò gan-an fáwọn. Wọ́n wá rọ̀ ọ́ pé kó má ṣe fi iṣẹ́ alàgbà sílẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tó lè ṣe. Ìṣírí gidi lèyí jẹ́ fún arákùnrin Johan. Ó ń bá iṣẹ́ alàgbà náà lọ, ìjọ sì ń jàǹfààní rẹ̀.
Jèhófà Bìkítà fún Wọn Gan-an
17. Ìdánilójú wo ni Bíbélì mú káwọn Kristẹni àgbàlagbà ní?
17 Ìwé Mímọ́ mú kó ṣe kedere pé àwọn àgbàlagbà ṣì lè máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wọn láìka àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó sí. Onísáàmù kan sọ pé: “Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà. . . yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀.” (Sm. 92:13, 14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó ṣeé ṣe kóun náà máa bá àìlera jìjàkadì, ‘kò juwọ́ sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó jẹ́ ní òde ń joro.’—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:16-18.
18. Kí nìdí táwọn àgbàlagbà olóòótọ́ àtàwọn tó ń tọ́jú wọn fi nílò ìrànlọ́wọ́?
18 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ òde òní ti fi hàn pé àwọn àgbàlagbà ṣì lè “máa gbèrú.” Àmọ́ ìṣòro àìsàn àti ọjọ́ ogbó tún lè máa kó ìdààmú bá wọn, èyí kò sì yọ àwọn àgbàlagbà tó ní àwọn mọ̀lẹ́bí tó ń tọ́jú wọn dáadáa sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ wọn tiẹ̀ lè sú àwọn tó ń tọ́jú wọn pàápàá. Torí náà, àǹfààní àti ojúṣe ló jẹ́ fáwọn ará ìjọ láti máa ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà yìí àtàwọn tó ń tọ́jú wọn. (Gál. 6:10) Irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé, a ò kàn sọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n máa lọ ‘kí ara wọn yá gágá, kí wọ́n sì jẹun yó dáadáa,’ láìjẹ́ pé a ṣe ohun kan pàtó láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ják. 2:15-17.
19. Kí nìdí tí ọkàn àwọn Kristẹni àgbàlagbà fi lè balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la?
19 Lọ́nà kan ṣá, ọjọ́ ogbó lè yí ìgbòkègbodò Kristẹni kan padà, àmọ́ kì í dín ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó jẹ́ àgbàlagbà kù. Gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí ló ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run, kò sì ní fi wọ́n sílẹ̀ láé. (Sm. 37:28; Aísá. 46:4) Jèhófà yóò máa gbé wọn ró, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn títí wọn yóò fi kú.—Sm. 48:14.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìbùkún Làwọn Àgbàlagbà Jẹ́ Fáwọn Ọ̀dọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 2007.
b Wo Jí! February 8, 1994, ojú ìwé 3 sí 10.
c Láwọn ilẹ̀ kan, èyí lè kan ṣíṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà kí wọ́n lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ ìjọba. Wo àpilẹ̀kọ tó sọ pé, “Ọlọ́run Mọyì Àwọn Arúgbó,” nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 2006.
d Wo àpilẹ̀kọ náà “Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Wa,” nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2003.
e Wo àpilẹ̀kọ náà “Ògo-ẹwà Orí-ewú,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti March 15, 1993.
f A ti yí àwọn orúkọ padà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó o fi ka àwọn Kristẹni àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ sẹ́ni tó ṣe pàtàkì?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará wa tó ti dàgbàlagbà?
• Kí ló lè mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti dàgbà máa ní èrò tó dára?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ará ìjọ máa ń bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fáwọn àgbàlagbà