Ọlọ́run Kà Wá Yẹ Láti Gba Ìjọba Kan
Ọlọ́run Kà Wá Yẹ Láti Gba Ìjọba Kan
“Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, tí ń ṣamọ̀nà sí kíkà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”—2 TẸS. 1:5.
1, 2. Kí ni Ọlọ́run ti pinnu láti ṣe, ta ló sì máa lò láti ṣèdájọ́ aráyé?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù wà nílùú Áténì ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni. Ara rẹ̀ kò gbà á bó ṣe rí i pé ìbọ̀rìṣà gbilẹ̀ nílùú náà, ìdí nìyẹn tó fi bá wọn sọ àgbà ọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ tó fi dé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ládé ti ní láti wọ àwọn abọ̀rìṣà tó ń fetí sí i lọ́kàn gan-an. Ó ní: “Nísinsìnyí, [Ọlọ́run] ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà. Nítorí pé ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde kúrò nínú òkú.”—Ìṣe 17:30, 31.
2 Ẹ ò rí i pé nǹkan ńlá ni téèyàn bá tún rántí pé Ọlọ́run ti dá ọjọ́ kan tó máa ṣèdájọ́ aráyé! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Áténì kò sọ ẹni tó máa ṣèdájọ́ náà, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jésù Kristi tí Ọlọ́run jí dìde ni ẹni náà. Ìdájọ́ tí Jésù yóò ṣe yìí máa túmọ̀ sí ìyè fáwọn kan àti ikú fáwọn míì.
3. Kí nìdí tí Jèhófà fi bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú, ta ló sì kópa pàtàkì nínú ìmúṣẹ rẹ̀?
3 Ìdájọ́ yẹn máa gba ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. Jésù tó máa jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ni yóò ṣojú Jèhófà nígbà ìdájọ́ náà, àmọ́ Jèhófà kò ní dá òun nìkan dáa. Jèhófà ti yan àwọn kan nínú aráyé pé kí wọ́n bá Jésù jọba, kí wọ́n sì bá a ṣèdájọ́ nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún náà. (Fi wé Lúùkù 22:29, 30.) Jèhófà fi ìpìlẹ̀ Ọjọ́ Ìdájọ́ yẹn lélẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn, nígbà tó bá Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ dá májẹ̀mú. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18.) Ó hàn gbangba pé májẹ̀mú yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1943 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, Ábúráhámù kò lóye ohun tí májẹ̀mú náà máa túmọ̀ sí fún aráyé délẹ̀délẹ̀. Ṣùgbọ́n àwa lónìí lóye rẹ̀ dáadáa pé, gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ti fi hàn, irú-ọmọ Ábúráhámù kópa pàtàkì nínú mímú ìpinnu Ọlọ́run láti ṣèdájọ́ aráyé ṣẹ.
4, 5. (a) Ta ni olórí irú-ọmọ Ábúráhámù, kí ló sì sọ nípa Ìjọba náà? (b) Ìgbà wo ni àǹfààní ṣí sílẹ̀ fáwọn kan láti wà lára àwọn tí yóò ṣàkóso nínú Ìjọba náà?
4 Jésù ni olórí irú-ọmọ Ábúráhámù yẹn. Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yàn án lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí tàbí Kristi. (Gál. 3:16) Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó tẹ̀ lé e ni Jésù fi wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn Júù. Lẹ́yìn tí wọ́n fàṣẹ ọba mú Jòhánù Oníbatisí, Jésù sọ pé àwọn míì máa láǹfààní láti wà lára Ìjọba náà, ó sọ pé: “Láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Oníbatisí títí di ìsinsìnyí, ìjọba ọ̀run ni góńgó tí àwọn ènìyàn ń fi ìsapá lépa, àwọn tí ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú sì ń gbá a mú.”—Mát. 11:12.
5 Ohun kan wà tó gbàfiyèsí, ìyẹn ni ohun tí Jésù sọ ṣáájú kó tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí yóò “gbá” Ìjọba ọ̀run “mú,” ó ní: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, Láàárín àwọn tí obìnrin bí, a kò tíì gbé ẹnì kan dìde tí ó tóbi ju Jòhánù Oníbatisí lọ; ṣùgbọ́n ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba ọ̀run tóbi jù ú.” (Mát. 11:11) Kí nìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ yìí? Ìdí ni pé, ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jáde ni àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fáwọn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ láti wà lára àwọn tí yóò ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run, kó tó di àsìkò yìí kò sí àǹfààní náà. Jòhánù Oníbatisí sì ti kú kó tó di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yìí.—Ìṣe 2:1-4.
Jèhófà Polongo Irú-Ọmọ Ábúráhámù ní Olódodo
6, 7. (a) Ọ̀nà wo ni irú-ọmọ Ábúráhámù yóò gbà “dà bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run”? (b) Ìbùkún wo ni Ábúráhámù gbà, ìbùkún wo ni irú-ọmọ rẹ̀ náà gbà?
6 Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé irú-ọmọ rẹ̀ yóò di púpọ̀, wọn yóò sì “dà bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run” àti bí àwọn egunrín iyanrìn etíkun. (Jẹ́n. 13:16; 22:17) Èyí fi hàn pé nígbà ayé Ábúráhámù, àwọn èèyàn kò lè mọ iye tó máa para pọ̀ jẹ́ irú-ọmọ náà. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ọlọ́run wá jẹ́ ká mọ iye tó máa wà nínú Ìjọba ọ̀run lára irú-ọmọ rẹ̀. Yàtọ̀ sí Jésù, iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].—Ìṣí. 7:4; 14:1.
7 Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sọ nípa ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ó ní: “[Ábúráhámù] ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà; òun sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sí òdodo fún un.” (Jẹ́n. 15:5, 6) Ká sòótọ́, kò séèyàn kankan tó lè jẹ́ olódodo délẹ̀délẹ̀. (Ják. 3:2) Àmọ́, nítorí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Ábúráhámù ní, Jèhófà bá a lò bí olódodo, kódà ó tiẹ̀ pè é ní ọ̀rẹ́ òun. (Aísá. 41:8) Jèhófà polongo àwọn tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run ní olódodo, èyí sì jẹ́ kí wọ́n gba ìbùkún tó ju ti Ábúráhámù lọ.
8. Àǹfààní wo làwọn tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní?
8 Jèhófà polongo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní olódodo torí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Róòmù 3:24, 28) Lójú Jèhófà wọ́n ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀, Ọlọ́run sì lè fẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n kí wọ́n lè di ọmọ Ọlọ́run kí wọ́n sì jẹ́ arákùnrin Jésù Kristi. (Jòh. 1:12, 13) Ọlọ́run mú wọn wọnú májẹ̀mú tuntun, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16; Lúùkù 22:20) Àǹfààní ńlá mà lèyí jẹ́ fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró o! Nítorí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn yìí, wọn ò retí pé àwọn yóò máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n yááfì ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé torí ayọ̀ tí kò láfiwé tí wọ́n ní, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa wà pẹ̀lú Jésù ní Ọjọ́ Ìdájọ́ àti bí wọ́n á ṣe ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run.—Ka Róòmù 8:17.
9, 10. (a) Ìgbà wo ni Jèhófà kọ́kọ́ fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Kristẹni, kí ló sì ń bẹ níwájú wọn? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró rí gbà?
9 Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni làǹfààní ṣí sílẹ̀ fáwọn àwùjọ èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ láti wà lára àwọn tí yóò bá Jésù ṣèjọba ní Ọjọ́ Ìdájọ́. Nǹkan bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ batisí, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di àkọ́kọ́ nínú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Àmọ́, ńṣe lèyí wulẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ kí wọ́n tó lè rí ìyè ayérayé gbà ní ọ̀run. Látìgbà yẹn lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láìka àwọn àdánwò tí Sátánì máa jẹ́ kí wọ́n dojú kọ sí. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú kí wọ́n bàa lè gba adé ìyè ní ọ̀run.—Ìṣí. 2:10.
10 Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ń fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró níṣìírí àti ìyànjú tí wọ́n nílò nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Tẹsalóníkà, ó ní: “A . . . ń bá a nìṣó ní gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú, àti ní títù yín nínú àti ní jíjẹ́rìí yín, bí baba ti ń ṣe sí àwọn ọmọ rẹ̀, fún ète pé kí ẹ lè máa bá a lọ ní rírìn lọ́nà tí ó yẹ Ọlọ́run, ẹni tí ń pè yín sí ìjọba àti ògo rẹ̀.”—1 Tẹs. 2:11, 12.
11. Àkọsílẹ̀ wo ni Jèhófà pèsè fáwọn tó jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”?
11 Ní ohun tó ju ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí Jèhófà yan apá àkọ́kọ́ nínú ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó rí i pé yóò dáa kí àkọsílẹ̀ títí láé kan wà tó dá lórí bí Jésù ṣe ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀nà tí Òun gbà bá àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró lò àti ọ̀nà tóun gbà tọ́ wọn sọ́nà. Àkọsílẹ̀ yìí ló di Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí Jèhófà fi kún Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó ti wà tẹ́lẹ̀, Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí ló sì ní ìmísí Ọlọ́run. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run dìídì pèsè Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fún, ìyẹn sì jẹ́ nígbà táwọn àti Ọlọ́run ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀. “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn gẹ́gẹ́ bí arákùnrin Kristi, tí wọ́n sì tún jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì wà fún ní pàtàkì. Ṣùgbọ́n o, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò lè ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kí wọ́n sì jàǹfààní nínú rẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni tí kì í ṣe ẹni àmì òróró ń jàǹfààní tí kò láfiwé nígbà tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n kọ́ ṣèwà hù.—Ka 2 Tímótì 3:15-17.
12. Kí ni Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró létí?
12 Jèhófà ka àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sí olódodo, ó sì fẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti gba ogún wọn ní ọ̀run. Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn kan nínú wọn á wá máa jọba lórí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà tí wọ́n ṣì wà láyé. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kan lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbàgbé èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ọlá fún ara wọn nínú ìjọ. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi bi wọ́n pé: “Ẹ ti yó báyìí, àbí? Ẹ ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ báyìí, àbí? Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba láìsí àwa, àbí? Ì bá wù mí ní tòótọ́ pé kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, kí àwa náà lè ṣàkóso pẹ̀lú yín gẹ́gẹ́ bí ọba.” (1 Kọ́r. 4:8) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù rán àwọn ẹni àmì òróró ìgbà ayé rẹ̀ létí pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín.”—2 Kọ́r. 1:24.
Bí Iye Àwọn Ẹni Àmì Òróró Ṣe Pé
13. Báwo ni yíyàn tí Ọlọ́run ń yan àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń tẹ̀ síwájú lẹ́yìn ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
13 Kì í ṣe gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ni Jèhófà yàn ní ọ̀rúndún kìíní. Yíyàn tí Ọlọ́run ń yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń bá a lọ ní gbogbo ìgbà táwọn àpọ́sítélì fi wà láyé, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tí Ọlọ́run yàn. Àmọ́, kì í kúkú ṣe pé Ọlọ́run ò yan ẹnì kankan mọ́ láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyẹn wá títí di òde òní. (Mát. 28:20) Nígbà tí Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914 àwọn tí Ọlọ́run ń yàn túbọ̀ pọ̀ sí i.
14, 15. Kí lohun tó ti ṣẹlẹ̀ lóde òní nínú bí Ọlọ́run ṣe ń yan àwọn ẹni àmì òróró?
14 Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù fọ ọ̀run mọ́ nípa gbígbá ohunkóhun tó lè ta ko ìṣàkóso Ọlọ́run dà nù. (Ka Ìṣípayá 12:10, 12.) Lẹ́yìn náà ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tí yóò bá a ṣèjọba jọ kí iye wọn lè pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ìlàjì ọdún 1930 sí 1939, iye àwọn ẹni àmì òróró ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbọ́ ìwàásù náà tí wọ́n sì ń di ìránṣẹ́ Jèhófà kò retí láti lọ sí ọ̀run. Ẹ̀mí mímọ́ kò bá ẹ̀mí wọn jẹ́rìí pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. (Fi wé Róòmù 8:16.) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé “àgùntàn mìíràn,” tó ń retí láti máa gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé làwọn. (Jòh. 10:16) Nítorí náà, lẹ́yìn ọdún 1935, olórí ìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ni láti kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jọ, ìyẹn àwọn tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran pé wọ́n máa la “ìpọ́njú ńlá” já.—Ìṣí. 7:9, 10, 14.
15 Síbẹ̀, láti àwọn ọdún 1930 títí di báyìí Ọlọ́run ṣì ń yan àwọn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n máa lọ sí ọ̀run. Kí nìdí? Ìdí ni pé, nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n rọ́pò ẹnì kan tí Ọlọ́run ti pè tẹ́lẹ̀, àmọ́ tónítọ̀hún wá di aláìṣòótọ́. (Fi wé Ìṣípayá 3:16.) Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ nípa àwọn kan tó mọ̀ tí wọ́n ti kúrò nínú òtítọ́. (Fílí. 3:17-19) Irú èèyàn wo ni Jèhófà máa pè láti fi rọ́pò àwọn tó bá di aláìṣòótọ́? Ọwọ́ Jèhófà nìyẹn wà. Síbẹ̀, ó jọ pé kò ní pe ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí òtítọ́, ẹni tó ti jẹ́ adúróṣinṣin dé ìwọ̀n àyè kan, bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ló máa pè. a—Lúùkù 22:28.
16. Ètò tó ṣàǹfààní wo ni Jèhófà ṣe nípa àwọn ẹni àmì òróró, kí ló sì dá wa lójú pé ó máa ṣẹlẹ̀?
16 Ṣùgbọ́n ó jọ pé kì í ṣe gbogbo ẹni tí Jèhófà pè sí ìrètí ti ọ̀run láti ọdún 1930 ló jẹ́ àfirọ́pò ẹnì kan tó di aláìṣòótọ́. Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà ti ṣètò lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò wà láàárín wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìsinsìnyí títí dìgbà tí “Bábílónì ńlá” yóò fi pa run. b (Ìṣí. 17:5) A ní ìdánilójú pé iye àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa pé nígbà tó bá tákòókò lójú Jèhófà, gbogbo wọn yóò sì ṣàkóso nínú Ìjọba náà. Ọkàn wa balẹ̀ sóhun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n ń pọ̀ sí i yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Láìpẹ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yóò “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá” tí Ọlọ́run máa mú wá sórí ayé Sátánì, wọn yóò sì fi tayọ̀tayọ̀ wọ ayé tuntun Ọlọ́run.
Àwọn Tí Yóò Ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Pé!
17. Gẹ́gẹ́ bí 1 Tẹsalóníkà 4:15-17 àti Ìṣípayá 6:9-11 ṣe wí, kí ló ti ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jólóòótọ́ títí dójú ikú?
17 Láti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni wá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára gan-an nínú Ọlọ́run, tí wọ́n sì ti fara dà á títí dójú ikú. Nítorí náà, Ọlọ́run kà wọ́n yẹ fún Ìjọba kan, wọ́n sì ti gba èrè yẹn ní ọ̀run, èyí sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi.—Ka 1 Tẹsalóníkà 4:15-17; Ìṣípayá 6:9-11.
18. (a) Ìdánilójú wo làwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ní? (b) Irú ojú wo làwọn àgùntàn mìíràn fi ń wo àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró?
18 Ó dá àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lójú pé àwọn máa tó gba èrè àwọn ní ọ̀run táwọn bá ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Táwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn bá ń ronú lórí ìgbàgbọ́ táwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró ní, wọ́n máa ń gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ẹni àmì òróró tó wà ní Tẹsalóníkà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa fúnra wa ń fi yín yangàn láàárín àwọn ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni yín àti àwọn ìpọ́njú tí ẹ ń mú mọ́ra. Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, tí ń ṣamọ̀nà sí kíkà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ẹ ń jìyà fún ní tòótọ́.” (2 Tẹs. 1:3-5) Ìgbàkígbà tí èyí tó kẹ́yìn nínú àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé bá kú làwọn tí yóò ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run yóò pé. Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ náà máa jẹ́ fáwọn tó wà lọ́run àtàwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 1992, ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 17.
b Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2007.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni Ọlọ́run fi han Ábúráhámù, èyí tó kan Ọjọ́ Ìdájọ́?
• Kí nìdí tí Ọlọ́run fi polongo Ábúráhámù ní olódodo?
• Kí ni pípolongo tí Ọlọ́run polongo àwọn tó jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní olódodo yọrí sí fún wọn?
• Kí lohun tó dá gbogbo Kristẹni lójú?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa wá Ìjọba Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Inú àwọn àgùntàn mìíràn ń dùn pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wà pẹ̀lú wọn lákòókò òpin yìí