Ǹjẹ́ Ẹnì Kan Tiẹ̀ Lè Yí Ayé Yìí Padà?
Ǹjẹ́ Ẹnì Kan Tiẹ̀ Lè Yí Ayé Yìí Padà?
“Àwọn tálákà sọ fún wa pé, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn lohun táwọn ń fẹ́ jù lọ, lẹ́yìn ìyẹn, àwọ́n tún ń wá àǹfààní tó máa jẹ́ káyé àwọn dára sí i. Wọ́n fẹ́ àwọn ètò tí kò ní ojúsàájú nínú lórílẹ̀-èdè wọn àti ní gbogbo ayé, káwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àtàwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá má bàa máa fi agbára wọn dojú ìsapá wọn dé.”
ÈYÍ lohun tí olùdarí àjọ kan tó ń ṣèrànwọ́ kárí ayé fáwọn tí àjálù bá sọ nípa ohun táwọn tálákà ń fẹ́ tí wọ́n sì ń retí. Ká sòótọ́, ńṣe lọ̀rọ̀ obìnrin yìí jẹ́ ká túbọ̀ mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo àwọn tí ohun burúkú àti àìdáa inú ayé ń ṣẹlẹ̀ sí. Gbogbo wọn ló ń fẹ́ ayé kan tó ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Ǹjẹ́ irú ayé bẹ́ẹ̀ máa wà lóòótọ́? Ǹjẹ́ ẹnì kan tiẹ̀ wà tó lágbára láti yí ayé tí gbogbo èèyàn mọ̀ pé nǹkan ò ti dọ́gba yìí padà?
Ohun Táwọn Èèyàn Ti Ṣe Láti Yí Ipò Nǹkan Padà
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbìyànjú láti yí ipò nǹkan padà. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Florence Nightingale fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe iṣẹ́ nọ́ọ̀sì. Ó bójú tó ọ̀ràn ìmọ́tótó, tàánútàánú ló sì fi ṣètọ́jú àwọn aláìsàn. Nígbà ayé obìnrin yẹn, ìyẹn káwọn oògùn apakòkòrò àti oògùn tó ń gbógun ti àrùn tóó dé, ìtọ́jú táwọn èèyàn ń gbà ní ọsibítù kò dára bíi tòde òní. Ìwé kan sọ pé, “Púrúǹtù làwọn nọ́ọ̀sì wọ́n sì tún ya ọ̀bùn, gbogbo èèyàn ló sì mọ̀ wọ́n sí ọ̀mùtí paraku àti oníṣekúṣe.” Ǹjẹ́ Florence Nightingale ṣàṣeyọrí nínú ìsapá rẹ̀ láti yí ohun táwọn nọ́ọ̀sì ń ṣe yìí padà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣàṣeyọrí. Bákan náà làwọn èèyàn tí kò mọ tara wọn nìkan tí wọ́n jẹ́ aláàánú ti ṣàṣeyọrí lọ́nà tó tayọ nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ làwọn ọ̀nà mìíràn, irú bíi mímọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ìmọ̀ ìṣègùn, ètò ilé gbígbé, ìpèsè oúnjẹ, ká kàn mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n gbé ṣe. Èyí sì ti mú kí nǹkan túbọ̀ dára sí i fún ẹgbàágbèje àwọn èèyàn tí nǹkan ò ṣẹnuure fún.
Àmọ́ ṣá o, a ò lè mójú kúrò lára ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ni ogun, ìwà ọ̀daràn, àìsàn, ìyàn àtàwọn àjálù mìíràn ń pọ́n lójú. Àjọ ilẹ̀ Ireland kan tó ń jẹ́ Concern tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn sọ pé: “Ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] èèyàn ni iṣẹ́ àti òṣì ń pa lójoojúmọ́.” Kódà ìfiniṣẹrú, tí ọ̀pọ̀ àwọn alátùn-únṣe sọ pé àwọn á mú kúrò láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ṣì wà káàkiri lónìí.” Ìwé kan tó ń jẹ́ Disposable People—New Slavery in the Global Economy tó sọ̀rọ̀ nípa ìfiniṣẹrú lóde òní, sọ pé: “Àwọn ẹrú tó wà lóde òní pọ̀ ju gbogbo àwọn èèyàn tí wọ́n jí kó nílẹ̀ Áfíríkà lọ sókè òkun nígbà òwò ẹrú.”
Kí ni kò jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti mú ìyípadà rere tó máa wà títí láé wá? Ṣé àwọn olówó àtàwọn alágbára tó ń jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí nìkan ló ń fà á ni àbí nǹkan mìíràn tún wà tó ń fà á?
Àwọn Ohun Tí Kò Jẹ́ Kí Ìyípadà Ṣeé Ṣe
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wí, Sátánì Èṣù ni kò jẹ́ kí ìsapá èèyàn láti mú kí ayé gún régé ní àṣeyọrí. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ fún wa pé, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Àní sẹ́, ní bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, Sátánì “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Àyàfi bá a bá mú ibi tí Sátánì ń fà yìí kúrò ni àwọn èèyàn á tó bọ́ lọ́wọ́ aburú àti ìrẹ́nijẹ. Kí ló fa ipò búburú yìí?
Ọlọ́run fi àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà sínú ayé tó máa di Párádísè tí ò lábùkù, tí gbogbo ìràn èèyàn yóò máa gbé, ìyẹn ayé kan tó “dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Kí ló wá mú kí nǹkan yí padà? Sátánì ni. Ó sọ pé Ọlọ́run kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe òfin táwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin á máa tẹ̀ lé. Ó tún dọ́gbọ́n sọ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso kò tọ́. Ó ti Ádámù àti Éfà láti ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n wà lómìnira ara wọn kí wọ́n bàa lè máa fúnra wọn pinnu ohun tó dára tàbí ohun tí kò dára. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Èyí ló wá yọrí sí ohun kejì tí kò jẹ́ kí ìsapá èèyàn láti mú kí ayé tó dára tí kò sì ní ìrẹ́jẹ ṣeé ṣe. Ohun náà ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé.—Róòmù 5:12.
Kí Nídìí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gbà Á?
Àwọn èèyàn kan lè béèrè pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé wáyé? Kí ló dé tí kò lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà kúrò kó sì tún àwọn èèyàn mìíràn dá?’ Ó lè jọ pé ìyẹn ló máa yanjú ìṣòro náà lọ́gán. Àmọ́ ṣá o, ọ̀nà tẹ́nì kan ń gbà lo agbára gba ìṣọ́ra. Àbí kì í ṣe àṣìlò agbára ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa ẹ̀hónú àwọn tálákà àtàwọn tójú ń pọ́n nínú ayé? Ǹjẹ́ inú kì í bí àwọn tí kò fẹ́ ìrẹ́jẹ nígbà tí wọ́n bá rí aláṣẹ kan tó ń lo agbára rẹ̀ láti pa ẹni tó bá ta ko èròǹgbà rẹ̀?
Kí Ọlọ́run lè mú un dá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lójú pé òun kì í ṣe aláṣẹ tó ń lo agbára nílòkulò, ó fàyè gba Sátánì àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyẹn fúngbà díẹ̀ láti ṣàìka òfin àti ìlànà òun sí. Bí àkókò ti ń lọ, yóò hàn gbangba pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó tọ́. Èyí á jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo òfin tó ṣe fún wa jẹ́ fún àǹfààní wa. Ká sòótọ́, àwọn nǹkan ìbànújẹ́ tó jẹ yọ látinú ṣíṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run ti fi hàn pé àǹfààní wa làwọn òfin náà wà fún lóòótọ́. Àwọn àjálù náà ti jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó dára ni Ọlọ́run ń ṣe bó ṣe ń lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú gbogbo ìwà ibi kúrò nígbà tó bá wù ú. Èyí yóò sì ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 18:23-32; Diutarónómì 32:4; Sáàmù 37:9, 10, 38.
Kí Ọlọ́run tó ṣe èyí, kò sọ́gbọ́n tá a fi lè bọ́ nínú ayé tí nǹkan ò ti dọ́gba yìí, nínú èyí táwọn èèyàn ‘ń kérora pa pọ̀ tí wọ́n sì wà nínú ìrora pa pọ̀.’ (Róòmù 8:22) Ohun yòówù tá ò báà ṣe láti yí ipò nǹkan padà, a ò lè mú Sátánì kúrò bẹ́ẹ̀ la ò sì lè mú àìpé tó jẹ́ pé òun ló ń fa gbogbo ìṣòro wa kúrò. Ó kọjá agbára wa láti mú àwọn ohun tó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kúrò.—Sáàmù 49:7-9.
Jésù Kristi Yóò Mú Ìyípadà Rere Tó Máa Wà Títí Láé Wá
Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé kò sí ohun tá a lè ṣe sí ọ̀ràn náà? Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ọlọ́run ti fi sí ìkáwọ́ ẹnì kan tó lágbára ju èèyàn ẹlẹ́ran ara lọ láti mú ìyípadà rere tó máa wà títí láé wá. Ta lẹni náà? Jésù Kristi ni. Bíbélì pè é ní Olórí Aṣojú tí Ọlọ́run yóò lò fún ìgbàlà ìran ènìyàn.—Ìṣe 5:31.
Ohun tí Jésù ń dúró dè báyìí ni ‘àkókò tí [Ọlọ́run] yàn kalẹ̀’ fún un láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. (Ìṣípayá 11:18) Kí lohun náà gan-an tó fẹ́ ṣe? Jésù yóò mú “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo” ṣẹ, “èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé.” (Ìṣe 3:21) Bí àpẹẹrẹ, Jésù yóò “dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. . . . Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 72:12-16) Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò mú kí “ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé” nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Sáàmù 46:9) Ọlọ́run tún ṣèlérí pé “kò sì sí olùgbé kankan [ní ilẹ̀ ayé tí òun yóò fọ̀ mọ́] tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Àwọn afọ́jú, odi, arọ, àní gbogbo àwọn aláìsàn àtàwọn tó lárùn lára ni ara wọn á tún le koko padà. (Aísáyà 33:24; 35:5, 6; Ìṣípayá 21:3, 4) Kódà àwọn tí wọ́n ti kú lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn yóò jàǹfààní. Ọlọ́run ṣèlérí láti jí àwọn tó kú sínú ìpọ́njú àti ìrẹ́jẹ dìde.—Jòhánù 5:28, 29.
Ìyípadà tí Jésù Kristi máa mú wá kò ní wà fún ìgbà kúkúrú, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ṣe é láàbọ̀. Yóò mú gbogbo ohun tí kò jẹ́ kí ayé gún régé kúrò pátápátá. Yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé kúrò yóò sì pa Sátánì Èṣù àti gbogbo àwọn tó ń hùwà ọ̀tẹ̀ bíi tirẹ̀ run. (Ìṣípayá 19:19, 20; 20:1-3, 10) Wàhálà àti ìyà tí Ọlọ́run ti fàyè gbà fúngbà díẹ̀ “kì yóò dìde nígbà kejì.” (Náhúmù 1:9) Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì di ṣíṣe “gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
Ṣùgbọ́n o lè sọ pé, ‘Ṣebí Jésù fúnra rẹ̀ ló sọ pé ẹ óò “ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo”? Ǹjẹ́ ìyẹn kò fi hàn pé ìrẹ́jẹ àti ipò òṣì yóò máa wà nígbà gbogbo?’ (Mátíù 26:11) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù sọ pé àwọn òtòṣì yóò máa wà nígbà gbogbo. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó yí gbólóhùn rẹ̀ ká àti ìlérí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fi hàn pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn òtòṣì yóò máa fìgbà gbogbo wà níwọ̀n ìgbà tí ètò àwọn nǹkan yìí bá ṣì ń bá a lọ. Jésù mọ̀ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè mú ipò òṣì àti ìrẹ́jẹ inú ayé kúrò. Ó tún mọ̀ pé òun lòun máa ṣe é. Láìpẹ́ yóò mú ètò àwọn nǹkan tuntun wá, ìyẹn “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” nínú èyí tí ìrora, àìsàn, ipò òṣì àti ikú kì yóò sí mọ́.—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1.
“Ẹ Má Gbàgbé Rere Ṣíṣe”
Ǹjẹ́ ìyẹn wá sọ pé ṣíṣe gbogbo ohun téèyàn bá lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kò wúlò? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o. Bíbélì fún wa ní ìṣírí pé ká máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nígbà tí àdánwò àti ìṣòro bá dojú kọ wọ́n. Sólómọ́nì ọba ìgbàanì kọ̀wé pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—Hébérù 13:16.
Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fún wa níṣìírí pé ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Nínú àpèjúwe kan, ó sọ ìtàn ará Samáríà kan tó rí ọkùnrin kan tí àwọn ọlọ́ṣà lù tí wọ́n sì kó ẹrù rẹ̀ lọ. Jésù sọ pé “àánú ṣe” ará Samáríà náà débi pé ó lo ohun tó ní láti de ojú ọgbẹ́ ibi tí wọ́n ti lu ọkùnrin náà, ó sì ràn án lọ́wọ́ títí tára rẹ̀ fi yá. (Lúùkù 10:29-37) Aláàánú ará Samáríà yẹn kò yí ayé yìí padà o, àmọ́ ó mú àyípadà rere bá ayé ẹnì kan. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Àmọ́ ṣá, ohun tí Jésù Kristi máa ṣe ju pé kó kàn ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lásán. Ó lè yí àwọn nǹkan padà sí rere, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìpẹ́ yìí. Nígbà tó bá ṣe èyí, ìgbésí ayé àwọn tí ìyà ti jẹ nítorí àìdọ́gba inú ayé yìí yóò wá di èyí tó dára sí i wọ́n á sì ní ojúlówó àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.—Sáàmù 4:8; 37:10, 11.
Bá a ti ń dúró kí ìyípadà náà ṣẹlẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ ká lọ́ra láti máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara, ká “máa ṣe ohun rere” fún gbogbo àwọn tójú wọn ń rí màbo nínú ayé tí nǹkan ò ti dọ́gba yìí.—Gálátíà 6:10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Florence Nightingale mú àyípadà rere bá iṣẹ́ nọ́ọ̀sì
[Credit Line]
Nípa ìyọ̀ǹda National Library of Medicine
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa ń ṣe ohun rere fún àwọn èèyàn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
The Star, Johannesburg, S.A.