“Awọn Ti Nsọkalẹ Lọ si Okun Ninu Ọkọ̀”
“Awọn Ti Nsọkalẹ Lọ si Okun Ninu Ọkọ̀”
ÈRE atukọ̀ òkun kan tó fẹ́ tu ọkọ̀ la àárín ìjì líle kọjá lójú òkun wà ní èbúté ìlú Gloucester, ní ìpínlẹ̀ Massachusetts, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ère náà, wọ́n sì kọjú rẹ̀ sí èbúté yẹn. Wọ́n ṣe ère náà ní ìrántí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn apẹja ìlú Gloucester tó kú sínú agbami òkun. Ọ̀rọ̀ Sáàmù 107:23, 24 ni wọ́n kọ sí ìsàlẹ̀ ère yìí àti sára ògiri itòsí rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla. Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú.”—Bibeli Mimọ.
Iṣẹ́ eléwu niṣẹ́ àwọn tó bá ń pẹja níbi tí ẹja pọ̀ sí láàárín agbami òkun Àtìláńtíìkì. Ó ti tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún, òjìdínnírínwó ó lé mẹ́jọ [5,368] èèyàn ìlú Gloucester tó ti kú sómi nígbà tí wọ́n lọ pẹja lójú òkun. Àwọn èèyàn ìlú Gloucester lé ní ọ̀kẹ́ kan àti ààbọ̀ [30,000] báyìí. Lára ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára ohun ìrántí yìí ni pé: “Ìjì líle láti ìhà àríwá àti ìgbì tó ga bí òkè bo àwọn kan mọ́lẹ̀ láàárín agbami òkun. Ńṣe làwọn mìíràn tó wà nínú ọkọ̀ kékeré tí wọ́n fi ń pẹja sọ nù tí wọn ò mọ̀nà padà dé ìdí ọkọ̀ ńlá tí wọ́n gbé wá sójú agbami òkun mọ́. Ìjì ńlá fi orí àwọn ọkọ̀ òkun míì gbára wọn, wọ́n sì rì sínú òkun. Àwọn ọkọ̀ míì rì nígbà tí ọkọ̀ òkun ńlá kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.”
Ère náà ń rán àwọn èèyàn létí wàhálà táwọn apẹja ń ṣe àti ewu tó ń wu wọ́n láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá. Ẹ̀yin ẹ wo ẹkún kíkorò táwọn èèyàn á ti máa sun nítorí pé wọn ò rí ọkọ, bàbá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò tàbí ọmọ wọn mọ́. Ṣùgbọ́n ohun tó dájú ni pé Jèhófà Ọlọ́run kò gbàgbé àwọn opó àti ọmọ òrukàn wọ̀nyí àtàwọn mìíràn tó kú sómi. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.” (Ìṣípayá 20:13) Dájúdájú, àwọn tó sọ̀ kalẹ̀ ‘lọ sí òkun nínú ọkọ̀ yóò rí iṣẹ́ ìyanu Olúwa’ nígbà àjíǹde.