“Wọn Kò Ṣe Ohun Tó Lòdì Sí Ìgbàgbọ́ Wọn”
“Wọn Kò Ṣe Ohun Tó Lòdì Sí Ìgbàgbọ́ Wọn”
JÉSÙ KRISTI sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.” (Mátíù 5:11) Lóde òní, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn nítorí pé ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ Kristi àti ohun tó fi kọ́ni, “wọn kì í ṣe apá kan ayé,” wọn kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú rárá, wọn kì í sì í yà kúrò nínú ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ lábẹ́ ipòkípò.—Jòhánù 17:14; Mátíù 4:8-10.
Nínú ìwé Kirik keset küla (Ṣọ́ọ̀ṣì Tó Wà Láàárín Abúlé) tí Toomas Paul, atúmọ̀ Bíbélì kan tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Luther kọ, ó sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn ilẹ̀ tí Ìjọba Soviet Union tó wà nígbà kan rí ń ṣàkóso títí kan àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Estonia, kò ṣe ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn rárá. Ó ní: “Ìwọ̀nba èèyàn ló tíì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kìíní oṣù April ọdún 1951. Ìjọba gbógun láti palẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti gbogbo àwọn tó ń ní àjọṣe pẹ̀lú wọn mọ́. Ọ̀ọ́dúnrún ó dín mọ́kànlélógún [279] èèyàn ni wọ́n mú lóǹdè lọ sí ilẹ̀ Sàìbéríà . . . Ìjọba sọ pé tí wọn ò bá fẹ́ lọ tàbí kí wọ́n sẹ́wọ̀n, kí wọ́n fọwọ́ sí ìwé kan tó máa fi hàn pé wọn ò ṣẹ̀sìn wọn mọ́. . . . Àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n mú lóǹdè jẹ́ ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín méje [353]. Ó kéré tán, àwọn mọ́kànléláàádọ́sàn-án [171] tí wọ́n kàn ṣì ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sípàdé ló wà lára àwọn tí wọ́n kó yìí. Síbẹ̀ wọn kò ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn, kódà ní Sàìbéríà lọ́hùn-ún pàápàá. . . . Kò wọ́pọ̀ pé ká rí nínú àwọn tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì [Estonian Lutheran] tó nígbàgbọ́ bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé yóò ran àwọn lọ́wọ́ káwọn lè jẹ́ olóòótọ́ sí i láìfi inúnibíni pè. Inú wọn máa ń dùn nítorí wọ́n mọ̀ pé èrè ńlá ń bẹ fún àwọn táwọn bá jẹ́ olóòótọ́.—Mátíù 5:12.