Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Inú Bíbélì Ṣé Òótọ́ Ni Àbí Àròsọ?

Ìtàn Inú Bíbélì Ṣé Òótọ́ Ni Àbí Àròsọ?

Ìtàn Inú Bíbélì Ṣé Òótọ́ Ni Àbí Àròsọ?

CHAIM HERZOG tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà kan rí àti Mordechai Gichon tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn ní Yunifásítì Tel Aviv sọ̀rọ̀ kan nínú ìwé tí wọ́n jọ kọ tó ń jẹ́ Battles of the Bible (Àwọn Ogun Inú Bíbélì), wọ́n ní:

“Ìtàn àwọn ogun inú Bíbélì . . . kò lè jẹ́ ìtàn àròsọ rárá. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò láti fi hàn pé òótọ́ làwọn ìtàn wọ̀nyẹn nípa fífi ogun méjì kan wéra. Ìkíní ni ogun tí Gídíónì bá àwọn ará Mídíánì àtàwọn tó wá ràn wọ́n lọ́wọ́ jà, èyí tí ìtàn rẹ̀ wà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ orí kẹfà sí ìkẹjọ. Èkejì sì ni Ogun Trojan tí òǹkọ̀wé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Homer ṣàpèjúwe nínú ewì tó pe àkọlé rẹ̀ ní Iliad. Nínú ìtàn àròsọ tí Homer sọ yìí, èèyàn lè lo etíkun èyíkéyìí tí ìlú olódi wà nítòsí rẹ̀ láti fi ṣe àpẹẹrẹ ibi tí Ogun Trojan ti wáyé . . . Àmọ́ o, ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ nínú ogun tí Bíbélì ròyìn pé Gídíónì jà. Bíbélì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ohun táwọn ọmọ ogun Gídíónì àtàwọn tí wọ́n ń bá jà ṣe nínú ogun náà, ó sì sọ bí ibi tí wọ́n ti ja ogun náà ṣe rí. Ó tún sọ ibi tí wọ́n ja ogun náà dé, pé ó tó nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà síbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀. Ó hàn gbangba pé kò síbòmíràn téèyàn tún lè tọ́ka sí pé ó dà bí ibi tí wọ́n ti ja ogun náà . . . Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò sóhun téèyàn lè ṣe ju pé kó gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé ni kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ogun inú Bíbélì.”

Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ogun Gídíónì, o lè wo àwòrán ilẹ̀ tó wà lójú ìwé 18 àti 19 nínú ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. a Bí ìtàn yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé “gbogbo Mídíánì àti Ámálékì àti àwọn Ará Ìlà-Oòrùn . . . kóra jọpọ̀ bí ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọdá, wọ́n sì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jésíréélì.” Gídíónì pe àwọn ẹ̀yà tó wà nítòsí pé kí wọ́n wá ran òun lọ́wọ́. Wọ́n wá gbéra láti ibi kànga Háródù lọ sí òkè Mórè, látibẹ̀ ni ogun náà ti dé Àfonífojì Jọ́dánì. Nígbà tí Gídíónì lé àwọn ọ̀tá kọjá Odò Jọ́dánì, ó borí wọn.—Àwọn Onídàájọ́ 6:33–8:12.

Wàá rí àwọn àgbègbè pàtàkì tí Bíbélì mẹ́nu kàn àtàwọn ohun tó wà níbẹ̀ nínú àwòrán ilẹ̀ tó wà lójú ìwé 18 àti 19 nínú ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. Nínú àwòrán ilẹ̀ mìíràn (èyí tó wà lójú ìwé 15), wàá rí àwọn ilẹ̀ tó jẹ́ tàwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì. Àwòrán ilẹ̀ méjèèjì yìí á jẹ́ kó o mọ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé ni gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa ogun tí Gídíónì jà.

Èyí jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Yohanan Aharoni tó ti di olóògbé túbọ̀ yéni yékéyéké. Ó ní: “Tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn, bí àgbègbè kọ̀ọ̀kan ṣe rí àti ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ wọnú ara wọn débi pé a ò lè lóye ọ̀kan bá ò bá mọ èkejì.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Àwòrán ilẹ̀ tó hàn fírífírí: A gbé e ka àwọn àwòrán ilẹ̀ tí ẹ̀tọ́ àdàkọ rẹ̀ jẹ́ ti Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel