Bí A Ṣe Lè Fi Jèhófà Ṣe Ọlọ́run Wa
Bí A Ṣe Lè Fi Jèhófà Ṣe Ọlọ́run Wa
N Í àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n sún mọ́ Jèhófà gan-an, débi pé, Bíbélì pe Jèhófà ní Ọlọ́run wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ pe Jèhófà ni “Ọlọ́run Ábúráhámù,” “Ọlọ́run Dáfídì,” àti “Ọlọ́run Èlíjà.”—Jẹ́nẹ́sísì 31:42; 2 Àwọn Ọba 2:14; 20:5.
Báwo làwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe dẹni tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ lára wọn kí àjọṣe tó dára lè wà láàárín àwa àti Ẹlẹ́dàá wa kí àjọṣe náà má sì bà jẹ́?
Ábúráhámù Ní “Ìgbàgbọ́ Nínú Jèhófà”
Ábúráhámù lẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí ó ní nínú Jèhófà. Ìgbàgbọ́ ni olórí ànímọ́ tó jẹ́ kí Ábúráhámù rí ojú rere Ọlọ́run. Ká sòótọ́, Ábúráhámù rí ojú rere Jèhófà gan-an débi pé, nígbà tí Ẹlẹ́dàá ń sọ nípa ara rẹ̀ fún Mósè lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ní òun ni “Ọlọ́run Ábúráhámù” àti Ọlọ́run ọmọ rẹ̀, Ísákì, àti ti ọmọ ọmọ rẹ̀, Jékọ́bù.—Jẹ́nẹ́sísì 15:6; Ẹ́kísódù 3:6.
Báwo ni Ábúráhámù ṣe dẹni tó ní irú ìgbàgbọ́ yìí nínú Ọlọ́run? Lákọ̀ọ́kọ́, orí ìpìlẹ̀ tó lágbára ni Ábúráhámù gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ká. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ṣémù ọmọ Nóà ló kọ́ Ábúráhámù nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. Ṣémù fojú ara rẹ̀ rí iṣẹ́ ìgbàlà tí Ọlọ́run ṣe. Ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jèhófà “pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 2:5) Ṣémù lè ti sọ fún Ábúráhámù pé tí Jèhófà bá sọ pé òun máa ṣe nǹkan kan, ó dájú pé yóò ṣe ohun náà. Yálà Ṣémù ló kọ́ ọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí Ọlọ́run wá ṣèlérí fún Ábúráhámù, inú rẹ̀ dùn, ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ sì fi hàn pé ó dá a lójú pé ìlérí náà yóò nímùúṣẹ.
Níwọ̀n bí ìgbàgbọ́ Ábúráhámù ti wà lórí ìpìlẹ̀ tó dára, àwọn ohun tó ṣe túbọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ náà lágbára sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a pè é, fi ṣègbọràn ní jíjáde lọ sí ibì kan tí a ti yàn án tẹ́lẹ̀ láti gbà gẹ́gẹ́ bí ogún; ó sì jáde lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí òun ń lọ.” (Hébérù 11:8) Ìgbọràn Ábúráhámù mú kí ìgbàgbọ́ tó ti ní tẹ́lẹ̀ túbọ̀ lágbára, èyí ló mú kí Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ a sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé.”—Jákọ́bù 2:22.
Láfikún sí i, Jèhófà yọ̀ǹda ká dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò, èyí sì tún mú kí ìgbàgbọ́ náà lágbára sí i. Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dán an wò, kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán.” Ìdánwò Hébérù 11:17; 1 Pétérù 1:7.
máa ń mú kí ìgbàgbọ́ jẹ́ ojúlówó, ó máa ń jẹ́ kó lágbára sí i, ó sì ń jẹ́ kó di èyí tó “níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà” lọ.—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù kò rí ìmúṣẹ gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe, síbẹ̀ inú rẹ̀ dùn pé àwọn mìíràn tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun. Nínú Bíbélì, Ọlọ́run yin Sárà ìyàwó Ábúráhámù àtàwọn mẹ́ta mìíràn látinú ìdílé rẹ̀, ìyẹn Ísákì, Jékọ́bù, àti Jósẹ́fù nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.—Hébérù 11:11, 20-22.
Bá A Ṣe Lè Ní Irú Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Lónìí
Bí ẹnì kan bá fẹ fi Jèhófà ṣe Ọlọ́run rẹ̀, ó ṣe pàtàkì gan-an kí onítọ̀hún ní ìgbàgbọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa.’ (Hébérù 11:6) Báwo lẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi ti Ábúráhámù?
A gbọ́dọ̀ gbé ìgbàgbọ́ wa karí ìpìlẹ̀ tó lágbára gan-an bíi ti Ábúráhámù. Ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń jẹ́ ká lóye Bíbélì. Tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tí à ń kà, èyí á mú kó dá wa lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ṣẹ. Èyí yóò wá sún wa láti máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé ìrètí náà dá wa lójú. Ìgbàgbọ́ wa á tún lágbára sí i tá a bá ń ṣègbọràn, ara ṣíṣègbọràn sì ni pé ká máa lọ́wọ́ nínú ìṣẹ́ ìwàásù ká sì máa wá sáwọn ìpàdé táwa Kristẹni ń ṣe.—Mátíù 24:14; 28:19, 20 Hébérù 10:24, 25.
Ó dájú pé àwọn nǹkan kan yóò dán ìgbàgbọ́ wa wò. Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ àtakò, àìsàn líle, tàbí kéèyàn wa kan kú tàbí káwọn nǹkan mìíràn ṣẹlẹ̀ sí wa. Tá a bá dúró ṣinṣin ti Jèhófà nígbà ìdánwò, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára, yóò sì tún wá di èyí tó níye lórí ju wúrà lọ. Yálà a wà láàyè nígbà tí Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ tá a sì fojú wa rí i tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tá a bá ní ìgbàgbọ́, a óò túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́, àpẹẹrẹ wa yóò jẹ́ káwọn mìíràn fẹ́ láti ní ìgbàgbọ́ bíi tiwa. (Hébérù 13:7) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ralph nìyẹn. Ó rí ìgbàgbọ́ àwọn òbí rẹ̀ ó sì fara wé wọn. Ó ṣàlàyé pé:
“Nígbà tí mo wà nílé, àwọn òbí mi fún gbogbo wa níṣìírí pé ká máa tètè jí ká lè jọ máa ka Bíbélì pa pọ̀. Èyí jẹ́ ká lè ka Bíbélì tán látìbẹ̀rẹ̀ dópin.” Títí dòní olónìí ni Ralph ṣì ń ka Bíbélì lárààárọ̀, èyí sì ń jẹ́ kó ní èrò Ọlọ́run lọ́kàn kó tó bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò rẹ̀ ojoojúmọ́. Nígbà tí Ralph wà ní kékeré, òun àti bàbá rẹ̀ jọ máa ń lọ sí òde ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó sọ pé: “Ìgbà yẹn ni mo ti mọ béèyàn ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò àti béèyàn ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù ni Ralph ti ń ṣiṣẹ́ báyìí. Ìgbàgbọ́ àwọn òbí rẹ̀ mà mú èrè wá gan-an o!
Ọkùnrin Kan Tó Tẹ́ Jèhófà Lọ́rùn
Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] ọdún lẹ́yìn àkókò Ábúráhámù ni wọ́n bí Dáfídì, ọ̀kan pàtàkì sì ni Dáfídì jẹ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. Nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì ń sọ ìdí tó fi jẹ́ pé Dáfídì ni Jèhófà yàn láti di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú, ó sọ pé: “Dájúdájú, Jèhófà yóò wá ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà rẹ̀ lọ́rùn.” Àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti Dáfídì dára gan-an débi pé, nígbà tí wòlíì Aísáyà ń bá Ọba Hesekáyà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 13:14; 2 Àwọn Ọba 20:5; Aísáyà 38:5.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, síbẹ̀ àwọn àkókò kan wà tó jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn òun sún òun ṣe ohun tí kò dára. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣe àwọn àṣìṣe tó burú jáì. Àkọ́kọ́, ó jẹ́ kí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú 2 Sámúẹ́lì 6:2-10; 11:2-27; 24:1-9.
lọ́nà tí kò yẹ nígbà tí wọ́n ń gbé e lọ sí Jerúsálẹ́mù. Èkejì, ó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà ó sì mú kí wọ́n pa Ùráyà, ọkọ obìnrin náà. Ẹ̀kẹta, ó ní kí wọ́n ka gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà, bẹ́ẹ̀ Jèhófà ò sọ pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Dáfídì rú Òfin Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tó ṣe yìí.—Àmọ́, nígbà tí wọ́n bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fún un, ó máa ń gbà pé lóòótọ́ lòun dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà kò sì ń di ẹ̀bi ru ẹlòmíràn. Ó gbà pé bí òun ṣe ṣètò gbígbé àpótí májẹ̀mú náà kò bójú mu rárá, ó tiẹ̀ sọ pé “a kò wá [Jèhófà] gẹ́gẹ́ bí àṣà.” Nígbà tí wòlíì Nátánì lọ sọ ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí Dáfídì dá fún un, èsì tó fún wòlíì náà ni pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” Nígbà tí Dáfídì sì rí i pé ìwà òmùgọ̀ lòun hù ní ti bí òun ṣe ka àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà, ó gbà pé òun dẹ́ṣẹ̀, ó sì sọ pé: “Mo ti ṣẹ̀ gidigidi nínú ohun tí mo ti ṣe.” Dáfídì ronú pìwà dà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi Jèhófà sílẹ̀ rárá.—1 Kíróníkà 15:13; 2 Sámúẹ́lì 12:13; 24:10.
Tá A Bá Dẹ́ṣẹ̀
Àpẹẹrẹ Dáfídì lè fún wa níṣìírí bá a ti ń sapá láti fi Jèhófà ṣe Ọlọ́run wa. Tí Dáfídì, ẹni tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn gan-an bá lè dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀ yẹn, kò yẹ ká sọ̀rètí nù tá a bá ṣàṣìṣe nígbà mìíràn láìka gbogbo ìsapá wa sí tàbí tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú pàápàá. (Oníwàásù 7:20) Tá a bá ń rántí pé Ọlọ́run dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì jì í nígbà tó ronú pìwà dà, èyí lè tù wá nínú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Uwe a nìyẹn lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn.
Alàgbà ni Uwe nínú ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà. Lákòókò kan, ó jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn rẹ̀ sún un láti hu ìwà pálapàla. Bíi ti Dáfídì Ọba, Uwe gbìyànjú láti ṣe ọ̀rọ̀ náà ní bòókẹ́lẹ́, nírètí pé Jèhófà á mójú kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn Uwe kò jẹ́ kó gbádùn mọ́ rárá débi pé ó lọ jẹ́wọ́ fún arákùnrin kan tí wọ́n jọ jẹ́ alàgbà, wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ láti ran Uwe lọ́wọ́ kó lè kọ́fẹ padà nínú àjálù tẹ̀mí tó dé bá a.
Uwe ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi Jèhófà àti ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀. Ó mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún un gan-an débi pé, lọ́sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó kọ lẹ́tà sáwọn alàgbà náà láti dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ wọn àti láti fi hàn pé òun mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fóun. Nínú ìwé tó kọ, ó ní: “Ẹ ti ràn mí lọ́wọ́ láti mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà.” Ó ṣeé ṣe fún Uwe láti máa bá àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà nìṣó, kò sì pẹ́ tí wọ́n tún fi yàn án láti jẹ́ ìránṣẹ́ nínú ìjọ yẹn kan náà.
“Ènìyàn Tí Ó Ní Ìmọ̀lára Bí Tiwa”
Ọ̀kan lára àwọn wòlíì tí Jèhófà lò gan-an nílẹ̀ Ísírẹ́lì ni Èlíjà, ọgọ́rùn-ún ọdún kan lẹ́yìn àkókò Dáfídì ló sì gbé ayé. Nígbà tí ìwà jẹgúdújẹrá àti ìwà pálapàla gbòde kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì, Èlíjà kò fọwọ́ kékeré mú ìjọsìn mímọ rárá kò sì káàárẹ̀ nínú fífọkàn sin Jèhófà. Abájọ nígbà kan tí Èlíṣà tó di wòlíì lẹ́yìn rẹ̀ fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Èlíjà”!—2 Àwọn Ọba 2:14.
Síbẹ̀, èèyàn bíi tiwa ni Èlíjà, kì í ṣe áńgẹ́lì. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Èlíjà jẹ́ ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.” (Jákọ́bù 5:17) Bí àpẹẹrẹ, lẹyìn tó ti rẹ́yìn àwọn tó ń jọ́sìn Báálì ní Ísírẹ́lì, Jésíbẹ́lì Ayaba sọ pé pípa lòun máa pa á. Kí ni Èlíjà ṣe? Ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù ó sì sá lọ sínú aginjù. Níbi tí Èlíjà jókòó sí lábẹ́ igi ọ̀pẹ kan nínú aginjù náà ló ti ń sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò, nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.” Èlíjà kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ wòlíì mọ́, ó ní ó sàn kóun kúkú kú.—1 Àwọn Ọba 19:4.
Àmọ́, Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ náà ti rí lara Èlíjà. Ọlọ́run wá fún Èlíjà lókun ó sì mú un dá a lójú pé òun nìkan kọ́ ni wòlíì tó ṣẹ́ kù, nítorí pé àwọn kan ṣì wà táwọn náà ò yà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Ìyẹn nìkan kọ́, Jèhófà ṣì fọkàn tán Èlíjà ó sì ní iṣẹ́ tó máa fún un ṣe.—1 Àwọn Ọba 19:5-18.
Ìbànújẹ́ tó dorí Èlíjà kodò kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan lẹ́yìn náà, nígbà tí Kristi Jésù yí padà di ológo níwájú Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù, ta lẹni tí Jèhófà jẹ́ kó fara hàn nínú ìran náà pẹ̀lú Jésù? Mósè àti Èlíjà ni. (Mátíù 17:1-9) Èyí fi hàn kedere pé Jèhófà ka Èlíjà sí wòlíì tó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” ni Èlíjà, Ọlọ́run mọyì iṣẹ́ takuntakun tó ṣe láti rí i pé ìjọsìn mímọ́ padà sílẹ̀ Ísírẹ́lì àti bó ṣe sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́.
Bí Ìbánújẹ́ Bá Dorí Wa Kodò
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní náà lè rẹ̀wẹ̀sì nígbà mìíràn tàbí kí wọ́n ní ìdààmú ọkàn. Ẹ ò rí i pé ohun ìtùnú ló jẹ́ láti mọ̀ pé irú ohun bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà náà! Ẹ wo bó ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó pé bí Jèhófà ṣe lóye Èlíjà ni yóò ṣe lóye àwa náà nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò.—Sáàmù 103:14.
Ohun mìíràn tún ni pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa, ó sì wù wá láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn ni pé ká polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. Àmọ́, táwọn èèyàn ò bá tẹ́tí sí ìwàásù wa, èyí lè máa bà wá lọ́kàn jẹ́. A sì lè máa ní ìdààmú ọkàn nígbà táwọn ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ bá ń halẹ̀ mọ́ wa. Ṣùgbọ́n bí Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́ kó lè máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, ó ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ náà lọ́wọ́ lónìí. Jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ Herbert àti Gertrud ṣe àpẹẹrẹ.
Ìlú Leipzig lórílẹ̀-èdè Jámánì ni Herbert àti Gertrud ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1952. Nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lákòókò náà nítorí pé ìjọba fòfin de iṣẹ́ wọn. Kí ni Herbert sọ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé ṣe rí lákòókò náà?
Ó sọ pé: “Nígbà mìíràn, ọkàn wa kì í balẹ̀ rárá. Tá a bá lọ wàásù láti ilé dé ilé, a kì í mọ̀ bóyá àwọn agbófinró máa yọ lójijì tí wọ́n á sì kó wa.” Kí ló ran Herbert àtàwọn mìíràn lọ́wọ́ láti borí ẹ̀rù tó ń bà wọ́n? Ó sọ pé: “Ẹni kọ̀ọ̀kan wa máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, Jèhófà sì fún wa lókun láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ.” Bí Herbert ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, oríṣiríṣi ìrírí ló ní, àwọn ìrírí náà sì túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun, kódà wọ́n máa ń dẹ́rìn-ín pa òun gan-an alára.
Herbert bá obìnrin kan tó ti dàgbà díẹ̀ pàdé, obìnrin náà sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí Herbert padà lọ sọ́dọ̀ obìnrin náà ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ọ̀dọ́kùnrin kan jókòó tì wọ́n, ó sì ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, Herbert rí ohun kan tó mú kí ẹrù bà á gan-an. Àga kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan yàrá náà, fìlà ọlọ́pàá sì wà lórí àga náà. Ọ̀dọ́kùnrin yẹn ló ni ín, ó dájú pé ọlọ́pàá ni, ó sì ṣe tán láti mú Herbert.
Ọkùnrin náà sọ fún Herbert pé: “Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Fún mi ní káàdì ìdánimọ̀ rẹ.” Ni Herbert bá fi káàdì ìdánimọ̀ rẹ̀ lé ọkùnrin náà lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ohun tí Herbert kò retí ṣẹlẹ̀. Obìnrin tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà yíjú sí ọlọ́pàá yẹn ó sì sọ fún un pé: “Ṣé o rí i, tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run yìí, mi ò gbọ́dọ̀ rẹ́sẹ̀ ẹ mọ́ nínú ilé yìí.”
Ọ̀dọ́kùnrin náà ronú fún ìṣẹ́jú díẹ̀, ló bá dá káàdì ìdánimọ̀ Herbert padà fún un ó sì jẹ́ kó máa lọ. Ẹ̀yìn náà ni Herbert wá mọ̀ pé ńṣe ni ọlọ́pàá náà ń fẹ́ ọmọ obìnrin yẹn. Láìsí àní-àní, ọlọ́pàá yẹn mọ̀ pé ó sàn kóun máa fẹ́ ọmọ obìnrin yẹn nìṣó ju kóun mú Herbert.
Ẹ Jẹ́ Ká Fi Jèhófà Ṣe Ọlọ́run Wa
Kí la lè kọ́ lára gbogbo àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn yìí? Bíi ti Ábúráhámù, ìgbàgbọ́ tiwa náà gbọ́dọ̀ lágbára gan-an nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe. Tá a bá ṣẹ̀, ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn bíi ti Dáfídì. Ó tún yẹ ká gbára lé Jèhófà bíi ti Èlíjà, kó lè fún wa lókun nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, a ó lè fi Jèhófà ṣe Ọlọ́run wa lákòókò yìí àti títí láé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn, ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.”—1 Tímótì 4:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Nítorí pé Ábúráhámù máa ń ṣègbọràn ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe lágbára
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Bíi ti Dáfídì, ó yẹ ká ronú pìwà dà tá a bá dẹ́ṣẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Bí Jèhófà ṣe lóye bí nǹkan ṣe rí lára Èlíjà ló ṣe lóye bí nǹkan ṣe rí lára àwa náà