Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọ Ilẹ̀ Áfíríkà Kan Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọmọ Ilẹ̀ Áfíríkà Kan Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọmọ Ilẹ̀ Áfíríkà Kan Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

ÓMÁA ń ya àwọn èèyàn tó bá wá sílẹ̀ Áfíríkà lẹ́nu láti rí i pé ó rọrùn gan-an láti bá àwọn èèyàn ibẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Àwọn èèyàn ilẹ̀ Áfíríkà máa ń fẹ́ mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi, “Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?” tàbí “Ǹjẹ́ ọ̀nà gidi kan wà láti yanjú àwọn ìṣòro bí àìtó oúnjẹ, àrùn, ogun, àti ìwà ọ̀daràn?” Tayọ̀tayọ̀ ni ọ̀pọ̀ lára wọn á sì fi gbà pé kí ẹni tí wọn ò tiẹ̀ mọ̀ rí dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí fún wọn látinú Bíbélì. Èyí sábà máa ń mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Bí wọ́n sì ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n máa ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, wọ́n á sì di Kristẹni tó ṣèrìbọmi.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìwé Ìṣe 8:26-40. Ọmọ ilẹ̀ Etiópíà lọkùnrin náà, ó sì rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.

Bá a ti rí i nínú àwòrán tó wà nísàlẹ̀ yìí, ọkùnrin ará Etiópíà yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó ń padà sílé, ó sì ń ka ibì kan nínú àkájọ ìwé tó ṣí sọ́wọ́. Ẹnì kan tí kò mọ̀ rí wá bá a, ẹni náà sì bi í léèrè pé: “Ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ lọmọ ilẹ̀ Etiópíà yìí fi gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́, ó sì bẹ àjèjì náà, ìyẹn Fílípì ajíhìnrere, pé kó wọlé sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin òun. Lẹ́yìn náà, ó ní kí Fílípì ṣàlàyé ibi tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán nínú Ìwé Mímọ́ náà fóun. Fílípì ṣàlàyé fún un pé ibi tó kà yẹn jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú tí Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Fílípì tún sọ àwọn nǹkan míì tó ní í ṣe pẹ̀lú “ìhìn rere nípa Jésù” fún un, ó sì dájú pé àjíǹde Jésù á wà lára àwọn àlàyé tí Fílípì ṣe.

Lẹ́yìn tí ará Etiópíà náà gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó dùn mọ́ ọn nínú yìí, ó wù ú láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ó sì bi Fílípì pé: “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Lẹ́yìn tọ́mọ ilẹ̀ Áfíríkà tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ yìí ṣèrìbọmi tán, tayọ̀tayọ̀ ló fi forí lé ọ̀nà ilé rẹ̀, Bíbélì kò sì sọ ohunkóhun nípa rẹ̀ mọ́.

Ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé lónìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa irú “ìhìn rere” yìí. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn ni wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.