Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn ní Àrọko Ọsirélíà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn ní Àrọko Ọsirélíà

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn ní Àrọko Ọsirélíà

ỌDÚN méjìlá gbáko làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi wàásù láwọn apá ibi tó jìnnà réré láwọn àgbègbè gbígbòòrò ní àrọko Ọsirélíà. Nítorí ìdí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Darwin tó jẹ́ olú ìlú Apá Àríwá ilẹ̀ Ọsirélíà ṣètò láti fi odindi ọjọ́ mẹ́sàn-án wàásù ní àgbègbè náà, kí wọ́n lè wá àwọn ẹni yíyẹ tó wà níbẹ̀ rí.—Mátíù 10:11.

Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra ìrìn àjò yìí sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ láti nǹkan bí ọdún kan ṣáájú àkókò yẹn, wọ́n ya àwòrán ilẹ̀ náà, ibẹ̀ sì fẹ̀ tó ogójì ọ̀kẹ́ [800,000] kìlómítà níbùú lóòró, ìyẹn ni pé àgbègbè náà gbòòrò tó ìlọ́po mẹ́ta orílẹ̀-èdè New Zealand. Láti mọ bí àgbègbè tó gbòòrò gan-an yìí ṣe wà ní àdádó tó, fojú inú wò ó pé ọkọ̀ kan yà kúrò lójú títì, ó sì yà sínú ọgbà ẹran ọ̀sìn kan. Lẹ́yìn náà ó wá rin ìrìn tó lé ní ọgbọ̀n kìlómítà láti ibi tó ti yà yẹn kó tó lè dé ibi tí ilé wà! Yàtọ̀ síyẹn, àwọn abúlé kan tún wà níbẹ̀ tó jẹ́ pé nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] kìlómítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi jìnnà síra wọn.

Ogóje ó lé márùn-ún [145] ni àpapọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí. Àwọn kan wá láti ìlú Tasmania tó jìnnà gan-an. Ọkọ̀ arinkòtò-ringegele làwọn kan gbé wá, wọ́n sì kó àwọn ohun tí wọ́n máa lò lọ́hùn-ún àtàwọn ẹ̀yà ara àwọn ọkọ̀ náà dání, wọ́n tún gbé epo pẹtiróòlù dání pẹ̀lú. Inú ọkọ̀ àfiṣelé làwọn kan kó ohun èlò tiwọn sí. Láfikún sí i, wọ́n tún gba bọ́ọ̀sì méjì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń kó èèyàn méjìlélógún, àwọn bọ́ọ̀sì yẹn ló kó àwọn tí kò ní ọkọ̀ arinkòtò-ringegele tó lè lọ sí irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀. Àwọn tó wà nínú bọ́ọ̀sì yìí ló ń wàásù fáwọn tó ń gbé láwọn ìlú kéékèèké ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti fẹ́ wàásù náà.

Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà làwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ yìí ti ṣètò àwọn àsọyé àtàwọn àṣefihàn tó máa jẹ́ káwọn ará mọ báwọn á ṣe wàásù ìhìn rere náà ní ìpínlẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó ní béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè wàásù fáwọn ará ibẹ̀, èèyàn sì tún gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa àwọn àṣà wọn. Wọ́n tún jíròrò àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká náà kí wọ́n má bàa pa àwọn ẹranko ìgbẹ́ tó wà níbẹ̀ lára.

Ọ̀pọ̀ ìrírí tó dára gan-an làwọn ará ní. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣètò láti sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì ní ibùdó kan tó jẹ́ ti àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ìyálóde àgbègbè náà fúnra rẹ̀ ló lọ ń sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n wá síbi àsọyé ọ̀hún. Lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn, ìwé ńlá márùn-ún àti ìwé pẹlẹbẹ mọ́kànlélógójì làwọn tó wá síbi àsọyé náà gbà. Ní àgbègbè mìíràn, wọ́n tún rí ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀. Kódà ọkùnrin náà ní Bíbélì. Ẹ̀dà ti King James ló ní, àmọ́ Bíbélì náà ti gbó, ó sì ti ya. Nígbà tí wọ́n béèrè bóyá ó mọ orúkọ Ọlọ́run, ó dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó wá mú ògbólógbòó Ilé Ìṣọ́ kan jáde látinú àpò ẹ̀wù rẹ̀ kan. Ó ka ibi tí ìwé ìròyìn náà ti ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú Máàkù 12:30, èyí tó kà pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ.” Ó ní, “Mo fẹ́ràn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn gan-an.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá a fèrò wérò gan-an látinú Bíbélì, ó wá gba Bíbélì tuntun kan àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣàlàyé Bíbélì.

Nítòsí ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Carpentaria, ọkùnrin kan tó jẹ́ baálẹ̀ nínú ọgbà ẹran kan tó fẹ̀ tó ogún ọ̀kẹ́ [400,000] hẹ́kítà ilẹ̀, fi ìfẹ́ hàn sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n fi Iwe Itan Bibeli Mi àti ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun a hàn án, ó béèrè bóyá wọ́n ní ìwé èyíkéyìí lédè Kriol. Ohun tó béèrè yìí ṣàjèjì gan-an nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ ló lè sọ èdè Kriol, àwọn tó lè kà á ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn akéde náà wá rí i pé gbogbo àwọn àádọ́ta òṣìṣẹ́ tó wà ní ibùdó náà ló lè ka èdè Kriol. Inú baálẹ̀ náà dùn gan-an láti gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Kriol, tayọ̀tayọ̀ ló sì fi fún àwọn ará ní nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀ kí wọ́n lè máa bá a sọ̀rọ̀.

Láàárín ọjọ́ mẹ́sàn-án tí wọ́n fi jẹ́rìí kúnnákúnná yẹn, ọgọ́fà [120] Bíbélì, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́rin [770] ìwé ńlá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún [705] ìwé ìròyìn, àti ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-un mẹ́sàn-án àti márùnlélọ́gọ́ta [1,965] ìwé pẹlẹbẹ ni wọ́n fi sóde. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé ogún [720] ìpadàbẹ̀wò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [215].

Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ àwọn ẹni yíyẹ tébi tẹ̀mí ń pa tí wọ́n wà káàkiri àgbègbè gbígbòòrò yìí ló ti rí oúnjẹ tẹ̀mí báyìí.—Mátíù 5:6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ỌSIRÉLÍÀ

APÁ ÀRÍWÁ

Darwin

Ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Carpentaria

Sydney

TASMANIA