Wàásù Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Wàásù Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
“Nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà gbọ́ ọ̀rọ̀ [Ápólò], wọ́n mú un wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.”—ÌṢE 18:26.
1. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘iná ẹ̀mí ń jó nínú Àpólò,’ kí ló kù fún un? (b) Kí ni Àpólò ní láti ṣe kó tó lè ní òye àwọn nǹkan tẹ̀mí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
PÍRÍSÍLÀ àti Ákúílà, tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, rí Ápólò níbi tó ti ń wàásù nínú sínágọ́gù kan ní ìlú Éfésù. Àpólò gba àfiyèsí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ gan-an nítorí pé sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, ó sì tún ní ọgbọ́n ìyíniléròpadà. ‘Iná ẹ̀mí ń jó nínú rẹ̀,’ ó sì “ń fi àwọn nǹkan nípa Jésù kọ́ni pẹ̀lú ìpérẹ́gí.” Àmọ́, ó hàn gbangba pé “ìbatisí Jòhánù nìkan ni” Ápólò mọ̀. Òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Àpólò ń wàásù nípa Kristi, àmọ́ òye rẹ̀ kò tó. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé ìmọ̀ rẹ̀ ò jinlẹ̀ dáadáa. Àpólò ní láti fi kún ìmọ̀ tó ní lórí ipa tí Jésù Kristi kó nínú mímú ète Jèhófà ṣẹ.—Ìṣe 18:24-26.
2. Iṣẹ́ bàǹtàbanta wo ni Pírísílà àti Ákúílà tẹ́wọ́ gbà?
2 Láìlọ́tìkọ̀ rárá, Pírísílà àti Ákúílà múra tán láti ran Àpólò lọ́wọ́ kó lè dẹni tí yóò máa pa “gbogbo ohun tí” Kristi pa láṣẹ mọ́. (Mátíù 28:19, 20) Àkọsílẹ̀ náà sọ pé wọ́n mú Àpólò “wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan kan wà tí ì bá mú káwọn Kristẹni kan lọ́ tìkọ̀ láti kọ́ Àpólò lẹ́kọ̀ọ́. Kí làwọn nǹkan náà? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú bí Pírísílà àti Ákúílà ṣe sapá láti ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún Àpólò? Báwo ni gbígbé àkọsílẹ̀ onítàn yìí yẹ̀ wò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Fiyè Sóhun Tí Àwọn Èèyàn Nílò
3. Kí nìdí tí irú ẹni tí Àpólò jẹ́ kò fi dí Pírísílà àti Ákúílà lọ́wọ́ láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?
3 Nítorí pé Júù ni Àpólò, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìlú Alẹkisáńdíríà ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Alẹkisáńdíríà ni olú ìlú Íjíbítì nígbà náà, ilé ẹ̀kọ́ ńlá ti Yunifásítì kan sì wà níbẹ̀ tí ibi ìkówèésí rẹ̀ ga lọ́lá. Àwọn Júù tó wà ní ìlú náà pọ̀ gan-an, títí kan àwọn ọ̀mọ̀wé. Kódà, ibẹ̀ ni wọn ti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì, tí wọ́n pè ní Septuagint. Abájọ tí Àpólò fi “jẹ́ ògbóǹkangí nínú Ìwé Mímọ́”! Iṣẹ́ àgọ́ pípa ni Ákúílà àti Pírísílà ń ṣe. Ǹjẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí Ápólò jẹ́ dẹ́rù bà wọ́n? Rárá o. Nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní, wọ́n wo irú ẹni tó jẹ́, wọ́n mọ ohun tó nílò, wọ́n sì wá ọ̀nà láti ràn án lọ́wọ́.
4. Ibo ni Àpólò tí rí ìrànlọ́wọ́ tó nílò gbà, báwo ló sì ṣe rí i gbà?
4 Bó ti wu kí Àpólò jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó, síbẹ̀ ó nílò ìtọ́ni. Kò lè rí ìrànlọ́wọ́ tó nílò yẹn gbà ní Yunifásítì kankan àmọ́ ó rí i gba láàárín àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Àpólò máa tó jàǹfààní látinú àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí yóò jẹ́ kó túbọ̀ ní òye pípé nípa ètò tí Ọlọ́run ṣe fúnni láti rí ìgbàlà. Pírísílà àti Ákúílà “mú un wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.”
5. Kí lo lè sọ nípa ipò tí Pírísílà àti Ákúílà wà nípa tẹ̀mí?
5 Pírísílà àti Ákúílà jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí, wọ́n sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́. Ó sì ní láti jẹ́ pé wọ́n ‘máa ń múra tán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ wọn ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú wọn,’ onítọ̀hún ì bàá jẹ́ ọlọ́rọ̀, ì bàá jẹ́ òtòṣì, yálà ọ̀mọ̀wé ni tàbí ẹrú. (1 Pétérù 3:15) Ó ṣeé ṣe fún Ákúílà àti aya rẹ̀ láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Ó hàn gbangba pé wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lójú méjèèjì. Ìtọ́ni tí Àpólò gbà yìí wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, níwọ̀n bí wọ́n ti mú un jáde látinú ‘ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó yè, tó sì ń sa agbára,’ tó ń sún ọkàn ṣiṣẹ́.—Hébérù 4:12.
6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Àpólò mọrírì ìrànlọ́wọ́ tó rí gbà?
6 Àpólò mọrírì àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ rẹ̀, ó sì túbọ̀ di ògbóṣáṣá nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ó lo ìmọ̀ rẹ̀ dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ nínú ìṣẹ́ pípolongo ìhìn rere náà, àgàgà láàárín àwọn Júù. Àpólò wúlò gan-an nínú yíyí àwọn Júù lérò padà nípa Kristi. Nítorí pé ‘ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Ìwé Mímọ́,’ ó ṣeé ṣe fún un láti fi ẹ̀rí hàn fún wọn pé gbogbo wòlíì ìgbàanì ló ń wọ̀nà fún dídé Kristi. (Ìṣe 18:24) Àkọsílẹ̀ náà fi kún un pé Àpólò wá forí lé Ákáyà, níbi tó ti “ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún àwọn tí wọ́n ti gbà gbọ́ ní tìtorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run]; nítorí pé pẹ̀lú ìgbónájanjan, ó fi hàn délẹ̀délẹ̀ ní gbangba pé àwọn Júù kò tọ̀nà, bí ó ti fi hàn nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.”—Ìṣe 18:27, 28.
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Olùkọ́ Mìíràn
7. Báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe di olùkọ́ tó jáfáfá?
7 Báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe di ẹni tó ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó pegedé bẹ́ẹ̀? Yàtọ̀ sí pé wọn ò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìdákẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì máa ń lọ sí ìpàdé déédéé, àjọṣe tímọ́tímọ́ tí wọ́n ní pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù ti ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an. Odindi ọdún kan àtààbọ̀ ni Pọ́ọ̀lù fi gbé ilé Pírísílà àti Ákúílà ní Kọ́ríńtì. Wọ́n jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n ń pàgọ́, wọ́n sì ń tún àgọ́ ṣe. (Ìṣe 18:2, 3) Fojú inú wo ìjíròrò Ìwé Mímọ́ tí yóò ti wáyé láàárín wọn lákòókò yẹn. Irú àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù yẹn ti ní láti jẹ́ kí ipò tẹ̀mí wọn dára sí i gan-an! Ìwé Òwe 13:20 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” Ìbákẹ́gbẹ́ rere yìí ní ipa tó dára lórí ojúṣe wọn nípa tẹ̀mí.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
8. Ẹ̀kọ́ wo ni Pírísílà àti Ákúílà kọ́ lára Pọ́ọ̀lù nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
8 Nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà fara balẹ̀ wo ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà ń ṣe nǹkan gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n rí i pé olùkọ́ tó dáńgájíá ni. Àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìṣe sọ pé Pọ́ọ̀lù “a máa sọ àsọyé nínú sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì, a sì máa yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò padà.” Ìgbà tó yá, tí Sílà òun Tímótì wá dára pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù ni ọwọ́ rẹ̀ wá “bẹ̀rẹ̀ sí dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn pé Jésù ni Kristi náà.” Nígbà táwọn tó wà nínú sínágọ́gù kò fi bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn, Pírísílà àti Ákúílà rí i pé Pọ́ọ̀lù yí ibi tó ti ń wàásù padà sí ibi kan tó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ìyẹn ní ilé kan tó wà nítòsí sínágọ́gù. Ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti rí ọ̀nà láti ran Kírípọ́sì “tí ó jẹ́ alága sínágọ́gù” lọ́wọ́, tó fi di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sì ṣeé ṣe kí Pírísílà àti Ákúílà ṣàkíyèsí pé sísọ tí àpọ́sítélì náà sọ ọkùnrin yìí di ọmọ ẹ̀yìn ní ipa tó lágbára lórí ìpínlẹ̀ náà, ó sì méso jáde. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Kírípọ́sì . . . di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo agbo ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n sì gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbà gbọ́, a sì ń batisí wọn.”—Ìṣe 18:4-8.
9. Báwo ni Pírísílà àti Ákúílà ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?
9 Àwọn ẹlòmíràn tó jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba náà, bíi Pírísílà àti Ákúílà fara wé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Àpọ́sítélì náà gba àwọn Kristẹni yòókù níyànjú pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 11:1) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, Pírísílà àti Ákúílà náà ran Àpólò lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni lọ́nà tó túbọ̀ ṣe rẹ́gí. Òun náà sì tún ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ó dájú pé Pírísílà àti Ákúílà ṣèrànwọ́ láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní Róòmù, ní Kọ́ríńtì, àti ní Éfésù.—Ìṣe 18:1, 2, 18, 19; Róòmù 16:3-5.
10. Ẹ̀kọ́ wo lo ti kọ́ látinú ìwé Ìṣe orí 18 tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?
10 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bá a ṣe gbé ìtàn inú ìwé Ìṣe orí 18 yẹ̀ wò? Tóò, gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣeé ṣe kí Ákúílà àti Pírísílà ti kọ́ lára Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè mú kí ọgbọ́n wa láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ pọ̀ sí i nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ tó mọ bí a tí ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. A lè máa bá àwọn tí ‘ọwọ́ wọn ń dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà’ àtàwọn tí wọ́n “ń jẹ́rìí kúnnákúnná” fún àwọn ẹlòmíràn kẹ́gbẹ́. (Ìṣe 18:5, Ìtumọ̀ ti Kingdom Interlinear) A lè kíyè sí bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn nípa lílo ọgbọ́n ìkọ́ni tó ń yíni lérò padà. Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbà tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a lè dá a lábàá pé kó pe àwọn yòókù nínú ìdílé rẹ̀ tàbí àwọn aládùúgbò rẹ̀ wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tàbí ká sọ fún un pé kó jẹ́ ká mọ ẹlòmíràn tá a lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ̀.—Ìṣe 18:6-8.
Wá Ọ̀nà Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
11. Ibo la ti lè rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun?
11 Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá ọ̀nà láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn nípa wíwàásù láti ilé dé ilé, níbi ọjà, àti nígbà tí wọ́n ń rin ìrìn àjò, àní níbi gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí onítara òṣìṣẹ́ Ìjọba náà, tó ń wá ọ̀nà láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn, ǹjẹ́ o lè mú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ gbòòrò sí i? Ǹjẹ́ o lè lo àwọn àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti wá àwọn ẹni yíyẹ rí kó o sì wàásù fún wọn? Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo làwọn tó jẹ́ akéde ìhìn rere bíi tiwa ti gbà láti rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù yẹ̀ wò.
12-14. Sọ ìrírí ti ara rẹ tàbí èyí tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí láti ṣàpèjúwe àǹfààní jíjẹ́rìí lórí tẹlifóònù.
12 Nígbà táwọn ará ń jẹ́rìí láti ilé dé ilé ní Brazil, Kristẹni kan tá a ń pè ní Maria mú ìwé àṣàrò kúkúrú fún ọ̀dọ́bìnrin kan tó wà nínú ilé kan báyìí. Àkọlé ìwé àṣàrò kúkúrú náà ni Maria fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó béèrè pé “Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?” Obìnrin náà dáhùn pé “Mó fẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé olùkọ́ ni mí, kíkọ́ tí mò ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé sì máa ń gba gbogbo àkókò mi.” Maria ṣàlàyé pé àwọn á jọ máa yẹ àwọn àkòrí Bíbélì wò láti orí tẹlifóònù. Obìnrin náà wá kọ nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀ fún Maria, alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ló bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ láti orí tẹlifóònù, wọ́n ń lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? a
13 Nígbà tí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ń jẹ́rìí lórí tẹlifóònù ní Etiópíà, ó yà á lẹ́nu pé bó ṣe ń bá ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ ló tún ń gbọ́ ariwo ìjà lábẹ́lẹ̀. Ọkùnrin náà wá sọ pé kó padà pe òun. Nígbà tó padà pè é, ọkùnrin náà bẹ̀bẹ̀, ó sì sọ pé nígbà tó kọ́kọ́ pe òun yẹn, ìjà kan ń lọ́ lọ́wọ́ láàárín òun àti ìyàwó òun lákòókò yẹn. Arábìnrin náà wá lo ohun tó sọ yìí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti tọ́ka sí ìtọ́sọ́nà ọlọ́gbọ́n tí Bíbélì fúnni lórí bá a ṣe ń yanjú ìṣòro ìdílé. Ó sọ fún un pé ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé ti ran ọ̀pọ̀ ìdílé lọ́wọ́, ìyẹn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn tí ọkùnrin náà rí ìwé ọ̀hún gbà ni arábìnrin yìí tún pè é lórí tẹlifóònù. Ńṣe ló pariwo pé: “Ìwé yìí ti kó ìgbéyàwó mi yọ nínú ewu!” Kódà, ọkùnrin yìí ti pe ìpàdé ìdílé kó lè sọ àwọn ohun rere tó kà nínú ìwé náà fáwọn tó kù. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, kò sì pẹ́ rárá tí ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí wá sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé.
14 Ẹnì kan tó jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba ní Denmark, tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nípa jíjẹ́rìí lórí tẹlifóònù sọ pé: “Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn gbà mí níyànjú pé kí n máa jẹ́rìí lórí tẹlifóònù. Mo kọ́kọ́ ń lọ́ tìkọ̀, mó sọ pé: ‘Mi ò lè ṣèyẹn o jàre.’ Àmọ́, lọ́jọ́ kan mo lo ìgboyà, mo sì tẹ onílé àkọ́kọ́ láago. Sonja dáhùn, lẹ́yìn tá a sì jíròrò díẹ̀, ó gba láti gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé karí Bíbélì. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, a jíròrò nípa ìṣẹ̀dá, ó sì sọ pé òun á fẹ́ láti ka ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation. b Mo wá sọ pé ì bá dára ká ríra sójú ká sì jọ jíròrò lórí kókó náà. Ó fara mọ́ ohun tí mo sọ yìí. Sonja ti gbára dì fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ là sì ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà náà.” Kristẹni arábìnrin wa yìí wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ń gbàdúrà kí n lè ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, àmọ́ mi ò retí pé ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù ló máa jẹ́ kí n ní ọ̀kan.”
15, 16. Àwọn ìrírí wo lo lè sọ láti fi hàn pé àǹfààní wà nínú wíwà lójúfò láti lo onírúurú ọ̀nà fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
15 Ọ̀pọ̀ ló ti ṣàṣeyọrí nítorí pé wọ́n fi àwọn àbá tó sọ pé ká jẹ́rìí fáwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá wà sílò. Obìnrin Kristẹni kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ sẹ́gbẹ́ ọkọ̀ èrò kan níbi táwọn èèyàn ń gbé ọkọ̀ sí. Nígbà tí obìnrin kan tó wà nínú ọkọ̀ èrò náà rí i, obìnrin Kristẹni yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ọ̀nà tá a gbà ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún un. Obìnrin náà fetí sílẹ̀, ó jáde nínú ọkọ̀ èrò tó wà, ó si wá bá arábìnrin náà nídìí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. Obìnrin náà sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé o dúró láti bá mi sọ̀rọ̀. Ó ti pẹ́ ti mo ti gba àwọn ìwé tẹ́ ẹ fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbẹ̀yìn. Àti pé, mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣé wàá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́?” Bí arábìnrin wá ṣe lo àǹfààní àyè tó ṣí sílẹ̀ yìí láti wàásù ìhìn rere náà nìyẹn.
16 Ìrírí tí arábìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní nígbà tó lọ sí ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó rèé: Ó kọ́kọ́ bá olùdarí àwọn ẹ̀ka kan nínú ilé náà sọ̀rọ̀. Ó sọ fún un pé òun fẹ́ yọ̀ǹda ara òun láti ṣèrànwọ́ ní bíbójútó ohun tí àwọn olùgbé ibẹ̀ ń fẹ́ nípa tẹ̀mí. Arábìnrin wá tún fi kún un pé inú òun yóò dùn láti máa kọ́ gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Olùdarí náà fún un láyè láti ṣèbẹ̀wò sí yàrá onírúurú èèyàn tó ń gbébẹ̀. Láìpẹ́, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀, ọ̀kan lára wọn sì ti ń wá sípàdé déédéé.
17. Ọ̀nà wo ló sábà máa ń gbéṣẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé?
17 Fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni ní tààràtà ti mú èso rere jáde fún àwọn olùpòkìkí Ìjọba kan. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ìjọ kan tó ní akéde márùnlélọ́gọ́rùn-ún sapá lọ́nà àkànṣe láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ gbogbo onílé tí wọ́n bá bá sọ̀rọ̀. Àwọn akéde mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún ló jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ náà, lẹ́yìn tí wọ́n lo wákàtí méjì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n rí i pé ó kéré tán ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ti bẹ̀rẹ̀.
Máa Bá A Lọ ní Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Rí
18, 19. Àṣẹ pàtàkì wo ló ti ọ̀dọ̀ Jésù wá tá a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn, kí ló sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpinnu wa ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀?
18 Gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà, o lè fẹ́ gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àbá tá a mẹ́nu kan nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́ ṣá o, á dára ká gbé àwọn àṣà àdúgbò yẹ̀ wò nígbà tá a bá ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tá a lè gbà jẹ́rìí. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rántí àṣẹ tí Jésù pa pé kí a wá àwọn ẹni yíyẹ rí, ká sì ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 10:11; 28:19.
19 Láti ṣe èyí, ẹ jẹ́ kí a máa “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” A le ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo ìyíniléròpadà lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn tó fẹ́ gbọ́ lọ́kàn, ìyẹn á sì sún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n gbọ́. Bá a ṣe ń gbára lé Jèhófà tàdúràtàdúrà, a lè ran àwọn díẹ̀ lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Ẹ sì wo bí iṣẹ́ yìí ṣe máa ń mú èrè wá tó! Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ‘sa gbogbo ipá wa láti fi ara wa hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà,’ ká máa bọlá fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà gẹ́gẹ́ bí olùfìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa wàásù pẹ̀lú ète sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—2 Tímótì 2:15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi yẹ láti làdí ọ̀nà Ọlọ́run lọ́nà tó túbọ̀ pé rẹ́gí fún Àpólò?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Pírísílà àti Ákúílà gbà kẹ́kọ̀ọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?
• Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ látinú ìwé Ìṣe orí 18 nípa sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?
• Báwo lo ṣe lè wá ọ̀nà láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Pírísílà àti Ákúílà “làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún [Àpólò] lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àpólò di ògbóṣáṣá nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Pọ́ọ̀lù wàásù níbi gbogbo tó lọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Wá ọ̀nà láti wàásù