Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ta ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ ní Jẹ́nẹ́sísì 3:22 nígbà tó sọ pé “ọ̀kan lára wa”?
Ó jọ pé Jèhófà Ọlọ́run ń darí ọ̀rọ̀ náà sí ara rẹ̀ àti Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo nígbà tó sọ pé: “Ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:22) Ẹ jẹ́ ká gbé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.
Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tó kéde ìdájọ́ tó ṣe fún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Àwọn èèyàn kan sọ pé ọ̀rọ̀ náà “ọ̀kan lára wa” jẹ́ èdè iyì. Àmọ́ ṣá o, Donald E. Gowan, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ nípa Jẹ́nẹ́sísì 1:26 àti 3:22 pé: “Kò sí ìtìlẹ́yìn kankan nínú Májẹ̀mú Láéláé fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àlàyé táwọn èèyàn ṣe pé: ‘wa,’ jẹ́ èdè iyì, ‘wa’ jẹ́ ọ̀rọ̀ tá a mọ̀ọ́mọ̀ sọ, ó jẹ́ èdè ṣíṣe nǹkan láṣepé, tàbí ìtọ́ka sí àwọn èèyàn nínú Ọlọ́run ẹlẹ́ni mẹ́ta. . . . Kò sí ìkankan nínú àwọn àlàyé yìí tó fi bẹ́ẹ̀ túmọ̀ ‘ọ̀kan lára wa’ ní [Jẹ́nẹ́sísì] 3:22.”
Àbí Jèhófà ń darí ọ̀rọ̀ yẹn sí Sátánì Èṣù ni, ẹni tó ti bẹ̀rẹ̀ sí pinnu ohun tó jẹ́ “rere àti búburú” tó sì ti nípa lórí àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ìyẹn ò bá nǹkan tá à ń sọ mu. Nígbà tí Jèhófà lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀kan lára wa.” Nígbà yẹn Sátánì kò sí lára àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ Jèhófà mọ́, nítorí náà, a ò lè kà á mọ́ àwọn tó wà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà.
Ṣé àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ni Ọlọ́run wá ń bá sọ̀rọ̀ ni? A ò lè sọ ní pàtó. Àmọ́ ìjọra tó wà láàárín ọ̀rọ̀ tí ńbẹ ní Jẹ́nẹ́sísì 1:26 àti 3:22 jẹ́ ká rí ojútùú kan. Ní Jẹ́nẹ́sísì 1:26, a kà ohun tí Jèhófà sọ níbẹ̀ pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa.” Ta ni Ọlọ́run darí ọ̀rọ̀ yìí sí? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dá ẹ̀mí tó di Jésù, ènìyàn pípé, ó sọ pé: “Òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá; nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Kólósè 1:15, 16) Bẹ́ẹ̀ ni, ó dà bíi pé ní Jẹ́nẹ́sísì 1:26, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé Jèhófà ń bá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sọ̀rọ̀, “àgbà òṣìṣẹ́,” ẹni tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń dá ọ̀run àti ayé. (Òwe 8:22-31) Ọ̀rọ̀ tó jọ ọ́ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:22 dábàá pé Jèhófà ló tún ń bá ẹni tó sún mọ́ ọ jù lọ sọ̀rọ̀, ìyẹn Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo.
Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ní ìmọ̀ ohun “rere àti búburú.” Ó ti pẹ́ tó ti nímọ̀ yìí nígbà tó wà lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dájú pé ó ti mọ èrò Bàbá rẹ̀, àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdíwọ̀n rẹ̀ dáadáa. Nítorí tí ó dá Jèhófà lójú pé Ọmọ òun mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí tó sì ń fi ìdúróṣinṣin ṣe wọn, ó ṣeé ṣe kí o ti fún Ọmọ rẹ̀ lómìnira dé ìwọ̀n àyè kan láti bójú tó àwọn ọ̀ràn láìjẹ́ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń bá Òun nígbà gbogbo. Nítorí náà, ó lè ṣeé ṣe fún Ọmọ débi tó yẹ láti pinnu ohun tó jẹ́ rere àti búburú. Àmọ́ ṣá o, Jésù kò dà bíi Sátánì, Ádámù àti Éfà nítorí kò gbé ìlànà tó ta ko ti Jèhófà kalẹ̀.