Báwo Ni Ọlọ́run—Ṣe Ń dá Sí Ọ̀ràn Ẹ̀dá Èèyàn?
Báwo Ni Ọlọ́run—Ṣe Ń dá Sí Ọ̀ràn Ẹ̀dá Èèyàn?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹjọ ṣáájú Sànmánì Tiwa, Hesekáyà Ọba Júdà tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì nígbà yẹn gbọ́ pé àìsàn tó máa gbẹ̀mí òun ló ń ṣe òun. Ọ̀rọ̀ náà bá Hesekáyà nínú jẹ́ gan-an, ó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run wo òun sàn. Ọlọ́run sì gba ẹnu wòlíì rẹ̀ dá a lóhùn pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ. Kíyè sí i, èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ rẹ.”—Aísáyà 38:1-5.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá sí ọ̀ràn yìí? Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn, 2 Sámúẹ́lì 7:16; Sáàmù 89:20, 26-29; Aísáyà 11:1) Hesekáyà kò tíì ní ọmọkùnrin kankan nígbà tí àìsàn yẹn kọ lù ú. Ìlà ìràn Dáfídì sì tipa bẹ́ẹ̀ wà nínú ewu dídi èyí tó máa pa run. Nítorí náà, ìdí tí Ọlọ́run fi dá sí ọ̀ràn Hesekáyà ni pé ó fẹ́ pa ìlà ìràn tá a ti máa bí Mèsáyà mọ́.
Ọlọ́run ṣèlérí fún Dáfídì Ọba olódodo nì pé: “Ilé rẹ àti ìjọba rẹ yóò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin dájúdájú fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ pàápàá yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ọlọ́run tún sọ pé ìlà ìdílé Dáfídì ni a ó ti bí Mèsáyà. (Kí Jèhófà lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ ló ṣe dá sí ọ̀ràn àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà láwọn àkókò tí ẹ̀sìn Kristẹni kò tíì dé. Nígbà tí Mósè ń sọ nípa ìdáǹdè Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú Íjíbítì, ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Ó jẹ́ nítorí níní tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, àti nítorí pípa tí ó pa gbólóhùn ìbúra tí ó búra fún àwọn baba ńlá yín mọ́, ni Jèhófà fi fi ọwọ́ líle mú yín jáde.”—Diutarónómì 7:8.
Bákan náà ni Ọlọ́run ṣe dá sí àwọn ọ̀ràn ní ọ̀rúndún kìíní, kí ó lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ bó ti ṣe ní ìṣáájú. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀nà tó lọ sí Damásíkù, Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù rí ìràn àgbàyanu kan kí ó lè jáwọ́ nínú bó ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ìyípadà ọ̀gbẹ́ni yìí, tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù níkẹyìn, kó ipa pàtàkì nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.—Ìṣe 9:1-16; Róòmù 11:13.
Ṣé Gbogbo Ọ̀ràn ni Ọlọ́run Máa Ń Dá Sí?
Ṣé dandan ni kí Ọlọ́run dá sí gbogbo ọ̀ràn, àbí ìgbà tó bá wù ú ló lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwé Mímọ́ mú un ṣe kedere pé kì í ṣe dandan kó ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run da àwọn ọ̀dọ́ 2 Kíróníkà 24:20, 21; Dáníẹ́lì 3:21-27; 6:16-22; Hébérù 11:37) Iṣẹ́ ìyanu la fi mú Pétérù kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní tì í mọ́. Síbẹ̀ ọba kan náà yìí ló pa àpọ́sítélì Jákọ́bù, Ọlọ́run ò sì dá sí ọ̀ràn náà kí ó má bàa hùwà ìkà yìí. (Ìṣe 12:1-11) Ọlọ́run fún àwọn àpọ́sítélì lágbára láti mú aláìsàn lára dá, kódà wọ́n lè jí òkú dìde pàápàá, síbẹ̀ kò mú ‘ẹ̀gún inú ẹran ara’ tó ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fínra kúrò, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìsàn kan tó ń yọ ọ́ lẹ́nu.— 2 Kọ́ríńtì 12:7-9; Ìṣe 9:32-41; 1 Kọ́ríńtì 12:28.
Hébérù mẹ́ta yẹn nídè kúrò nínú ìléru oníná tí ń jó, ó sì dá wòlíì Dáníẹ́lì náà nídè kúrò ní ihò kìnnìún, síbẹ̀ kò gba àwọn wòlíì mìíràn lọ́wọ́ ikú. (Ọlọ́run kò dáwọ́ inúnibíni líle koko tí Nero Olú Ọba Róòmù gbé dìde sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi dúró. Wọ́n dá àwọn Kristẹni lóró, wọ́n dáná sun wọ́n láàyè, wọ́n sì jù wọ́n sáwọn ẹranko ẹhànnà. Àmọ́, inúnibíni yìí kò ya àwọn Kristẹni ìjímìjí lẹ́nu, ò sì dájú pé kò mú kí wọ́n sọ pé kò sí Ọlọ́run. Ó ṣe tán, Jésù ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé a ó fà wọ́n lọ sílé ẹjọ́ àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti jìyà kódà wọ́n lè kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn pàápàá.—Mátíù 10:17-22.
Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe nígbà àtijọ́, ó dájú pé ó lágbára láti yọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kúrò nínú ewu lóde òní pẹ̀lú, a ò sì gbọ́dọ̀ jiyàn pẹ̀lú àwọn tó bá sọ pé Ọlọ́run dáàbò bo àwọn nínú ọ̀ràn kan. Síbẹ̀, a ò lè sọ ní pàtó pé Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà tàbí kò dá sí i. Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ló fara pa nígbà tí ohun kan bú gbàù ní ilé iṣẹ́ kẹ́míkà kan nílùú Toulouse nílẹ̀ Faransé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni olóòótọ́ ló sì kú lábẹ́ ìjọba Násì àti nínú àwọn àgọ́ Kọ́múníìsì, tàbí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú mìíràn, Ọlọ́run ò sì dá sí ọ̀ràn náà láti má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀. Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi dá sí ọ̀kan ò jọ̀kan àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí kó sì yọ gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ kúrò nínú ewu?—Dáníẹ́lì 3:17, 18.
“Ìgbà àti Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí A Kò Rí Tẹ́lẹ̀”
Nígbà tí ohun búburú bá ṣẹlẹ̀, ẹnikẹ́ni ló lè kàn, jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run kò sì ní kí nǹkan búburú má ṣẹlẹ̀ síni. Nígbà tí kẹ́míkà kan bú gbàù nílé iṣẹ́ kan nílùú Toulouse nílẹ̀ Faransé, níbi tí Alain àti Liliane ti sá àsálà, ọgbọ̀n èèyàn ló kú, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn sì fara pa láìjẹ́ pé wọ́n hùwà búburú kankan. Ní gbogbo gbòò, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti kú nípasẹ̀ ìwà ipá, wíwakọ̀ láìlo ìkóra-ẹni-níjàánu, tàbí ogun, a ò sì lè dẹ́bi fún Ọlọ́run nítorí ohun búburú tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí. Bíbélì rán wa létí pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí” olúkúlùkù.—Oníwàásù 9:11.
Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ènìyàn ní láti ṣàìsàn, kó darúgbó, kó sì kú. Kódà àwọn kan tó rò pé Ọlọ́run fi iṣẹ́ ìyanu dáàbò bo ẹ̀mí àwọn tàbí àwọn tó ń dúpẹ́ pé òun ló jẹ́ kí àìsàn tó ń ṣe àwọn fò lọ tún kú ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Mímú àìsàn àti ikú kúrò àti ‘nínú omijé gbogbo nù’ kúrò lójú ẹ̀dá èèyàn ṣì di ọjọ́ iwájú.—Ìṣípayá 21:1-4.
Kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀, a nílò ohun kan tó gbòòrò tó sì kárí ayé ju kí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀ràn èèyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó pè ní “ọjọ́ ńlá Jèhófà.” (Sefanáyà 1:14) Ní àkókò tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀ràn lọ́nà tó kárí ayé yìí, yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò. Ọmọ aráyé yóò láǹfààní àtiwà láàyè lórí ilẹ̀ ayé títí láé lábẹ́ ipò pípé, tó jẹ́ pé “àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Kódà àwọn òkú yóò jí dìde, àgbákò tó burú jù lọ yìí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ di èyí tá a mú kúrò. (Jòhánù 5:28, 29) Ọlọ́run tí ìfẹ́ àti oore rẹ̀ kò lópin yóò ti yanjú gbogbo ìṣòro ọmọ aráyé pátápátá nígbà yẹn.
Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Dá sí Ọ̀ràn Ẹ̀dá Èèyàn Lónìí
Àmọ́, èyí ò wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Ọlọ́run wulẹ̀ ń wòran nísinsìnyí tí kò sì bìkítà nípa báwọn 1 Tímótì 2:3, 4) Ọ̀nà tí Jésù gbà ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ yìí ni pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Ọlọ́run ń fa àwọn olóòótọ́ ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ ìhìn Ìjọba táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń polongo jákèjádò ayé.
èèyàn ṣe ń kérora. Lóde òní, gbogbo èèyàn pátá ni Ọlọ́run fún láǹfààní láti mọ òun kí wọ́n sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun, láìfi ẹ̀yà tàbí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ pè. (Láfikún sí i, Ọlọ́run máa ń dìídì darí ìgbésí ayé àwọn tó fẹ́ kó máa tọ́ àwọn sọ́nà. Ọlọ́run ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ‘ṣí ọkàn-àyà wọn sílẹ̀’ láti lóye ìfẹ́ rẹ̀ àti láti ṣe ohun tó béèrè lọ́wọ́ wọn. (Ìṣe 16:14) Dájúdájú, àǹfààní tí Ọlọ́run fún wa láti mọ òun, láti mọ Ọ̀rọ̀ òun, àti láti mọ ohun tí òun máa ṣe fí ẹ̀rí hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Jòhánù 17:3.
Lákòótán, Ọlọ́run kì í fi iṣẹ́ ìyanu gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lóde òní, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti fara da ipòkípò tí wọ́n bá bá ara wọn. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye [Jèhófà Ọlọ́run] tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.
Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ ká sì tún máa tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́ fún wíwà tá a wà láàyè àti fún ìrètí tó fún wa láti wà láàyè títí láé nínú ayé tí kò ti ní sí ìjìyà mọ́. Onísáàmù béèrè pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀? Ife ìgbàlà títóbi lọ́lá ni èmi yóò gbé, orúkọ Jèhófà ni èmi yóò sì máa ké pè.” (Sáàmù 116:12, 13) Kíka ìwé ìròyìn yìí déédéé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe, ohun tó ń ṣe nísinsìnyí, àti ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú tó lè fún ọ ní ayọ̀ nísinsìnyí tó sì lè mú kó o ní ìrètí tó ṣeé gbára lé fún ọjọ́ iwájú.—1 Tímótì 4:8.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 65:17
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, Jèhófà ò dí àwọn èèyàn lọ́wọ́ sísọ Sekaráyà lókùúta . . .
bẹ́ẹ̀ náà ni kò dí Hẹ́rọ́dù lọ́wọ́ pípa tó pa àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àkókò ti sún mọ́lé, nígbà tí ìjìyà kò ní sí mọ́; àní àwọn tó ti kú pàápàá yóò jíǹde