“Ó Dí Àlàfo Tó Wà Lọ́kàn Mi”
“Ó Dí Àlàfo Tó Wà Lọ́kàn Mi”
“MO Ń fi gbogbo ara dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ẹ̀bùn dáradára náà ìyẹn ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Ó dí àlàfo tó wà lọ́kàn mi—ìyẹn ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun pé ó sì tún mọyì òun. Mo ti wá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n báyìí. Gbogbo èèyàn pátá ni mo fẹ́ polongo ìwé yìí fún mo sì fẹ́ fún gbogbo àwọn èèyàn mi ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan.” Ohun tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sọ rèé nípa ìwé tuntun olójú ìwé 320, tá a mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” tá a ṣe lọ́dún 2002 sí 2003. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé tuntun yìí àti ìdí tá a fi tẹ̀ ẹ́ jáde.
Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tuntun Náà
Kí ló wà nínú ìwé tuntun yìí? Gbogbo ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ la kọ sínú àpilẹ̀kọ méjèèjì tó wà nínú ìtẹ̀jáde yìí—àtàwọn nǹkan mìíràn tó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ! Orí mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ìwé yìí ní, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ sì gùn tó àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ kan nínú Ilé Ìṣọ́. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìṣáájú àti orí mẹ́ta àkọ́kọ́, a pín ìyókù ìwé yìí sí ìsọ̀rí mẹ́rin, ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ànímọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó gbawájú jù lọ nínú ànímọ́ Jèhófà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, wàá kọ́kọ́ rí àkópọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ náà. Orí mélòó kan lábẹ́ ìsọ̀rí yẹn yóò wá ṣàlàyé nípa bí Jèhófà ṣe ń lo ànímọ́ yẹn. Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ló ní àkòrí kan tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù. Kí nìdí? Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Jésù fìwà jọ Jèhófà láìkù síbì kan, ìyẹn ló ṣe lè ṣe àwọn nǹkan tó ń fi bí ànímọ́ Ọlọ́run ṣe jẹ́ hàn wá kedere. Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan máa ń ní àkòrí kan níparí rẹ̀ tó máa ń kọ́ wa ní bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú fífi ànímọ́ tí ìsọ̀rí yẹn ń sọ hàn. Bí ìwé tuntun yìí ṣe ń ṣàlàyé àwọn ànímọ́ Jèhófà yìí, kò sí ìwé inú Bíbélì tí kò ti fa ọ̀rọ̀ yọ.
Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà yìí tún ní àwọn nǹkan àrà ọ̀tọ̀ kan. Bẹ̀rẹ̀ láti Orí 2, orí kọ̀ọ̀kan ní àpótí kan tá a pè ní “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò.” Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti ìbéèrè tó wà nínú àpótí yìí kò wà fún ṣíṣe àyẹ̀wò orí tí àpótí yẹn wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ṣe wọ́n kí wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lo Bíbélì láti fi ṣàṣàrò jinlẹ̀ lórí kókó tí àkòrí yẹn dá lé lórí. Fara balẹ̀ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, kó o wá ronú lórí ìbéèrè ibẹ̀ dáadáa, kó o sì gbìyànjú láti wo bó ṣe kan ìwọ fúnra rẹ. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ lè ru ọkàn rẹ sókè, kó sì mú ọ túbọ̀ máa fà mọ́ Jèhófà.—Sáàmù 19:14.
A tún fara balẹ̀ yan àwọn àwòrán inú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, a sì ṣètò wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì súnni ṣiṣẹ́. Orí mẹ́tàdínlógún inú ìwé yìí ló ní àwòrán ìtàn inú Bíbélì tó gba odindi ojú ewé kọ̀ọ̀kan.
Kí Nìdí Tá A Fi Tẹ̀ Ẹ́ Jáde?
Kí nìdí tá a fi tẹ ìwé Sún Mọ́ Jèhófà jáde? Lájorí ète ìwé tuntun yìí ni láti ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà sí i kí àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run wa sì lè túbọ̀ gún régé sí i.
Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ẹnì kan tí ìwé Sún Mọ́ Jèhófà lè ṣe láǹfààní, ó lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí Kristẹni arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́? Ìwọ fúnra rẹ ńkọ́—ṣó o ti bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé tuntun yìí? Tó ò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí kà á, oò ṣe kúkú ṣètò àkókò rẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á bó bá ti lè yá tó? Fara balẹ̀ ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà. Ǹjẹ́ kí ìwé yìí ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, kó o lè máa fi ayọ̀ àti ìtara tó ga polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀!