Ayọ̀ àti Ìfọ̀kànbalẹ̀ Níbi Iṣẹ́ Kò Dà Bíi Ti Tẹ́lẹ̀ Mọ́
Ayọ̀ àti Ìfọ̀kànbalẹ̀ Níbi Iṣẹ́ Kò Dà Bíi Ti Tẹ́lẹ̀ Mọ́
ÌWÉ Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe jáde sọ pé gbogbo èèyàn ló ní “ẹ̀tọ́ láti ṣiṣẹ́.” Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn lọwọ́ rẹ̀ máa ń tẹ ẹ̀tọ́ yìí. Ìfọ̀kànbalẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ sinmi lórí ọ̀pọ̀ nǹkan—látorí bípò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè kan ṣe rí títí dórí ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé. Síbẹ̀, nígbà tíṣẹ́ bá bọ́ tàbí tíṣẹ́ bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn, ìwọ́de, ìjà ìgboro, àti ìyanṣẹ́lódì sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Orílẹ̀-èdè tí èyí kì í ti í wáyé ò wọ́pọ̀. Òǹkọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́, jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tó lè mú kí orí èèyàn kanrin.”
Ọ̀nà púpọ̀ ni iṣẹ́ fi ṣe pàtàkì fún wa. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń jẹ́ ká lè gbọ́ bùkátà ara wa, ó tún máa ń jẹ́ kórí wa wú kí ara wa sì yá gágá. Iṣẹ́ ṣíṣe máa ń jẹ́ kéèyàn ṣe ohun tó tọ́ tó sì yẹ láwùjọ, kí ìgbésí ayé èèyàn sì nítumọ̀. Ó tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fúnni. Ìdí nìyẹn táwọn tó ti lówó tó pọ̀ tó láti gbọ́ bùkátà ara wọn tàbí àwọn tó ti dàgbà tó láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ kì í fẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, iṣẹ́ ṣe pàtàkì gan-an débi pé àìríṣẹ́ṣe máa ń fa ìṣòro ńláǹlà láwùjọ.
Pẹ̀lú èyí náà, àwọn kan sì tún wà tí wọ́n níṣẹ́ lọ́wọ́ àmọ́ tí wàhálà tó bá wọn lẹ́nu iṣẹ́ pọ̀ débi pé wọn ò gbádùn iṣẹ́ wọn mọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ilé iṣẹ́ ṣe ń pọ̀ sí i ṣáá lóde òní ti mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn dín iye òṣìṣẹ́ kù kí ìnáwó lè dín kù. Ìyẹn sì wá ń jẹ́ kíṣẹ́ pá àwọn òṣìṣẹ́ tó ṣẹ́ kú lórí.
Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní tó yẹ kó máyé dẹrùn kí iṣẹ́ sì túbọ̀ jẹ́ ojúlówó ló wá ń pa kún wàhálà ẹnu iṣẹ́ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, kọ̀ǹpútà, ẹ̀rọ tí n fi àdàkọ ìsọfúnni ránṣẹ́, àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti máa múṣẹ́ relé lẹ́yìn tíṣẹ́ bá parí lójúmọ́, èyí ò wá jẹ́ ká mọ̀yàtọ̀ láàárín ibi iṣẹ́ àti ilé mọ́. Òṣìṣẹ́ kan rí i pé ẹ̀rọ péńpé tí wọ́n fi ń peni nílé iṣẹ́ òun àti fóònú alágbèérìn dà bí okùn tí ò ṣe é fojú rí lára òṣìṣẹ́ tí ọ̀gá lè fi fà á láti ibikíbi tó bá wà.
Ẹ̀rù tó ń ba ọ̀pọ̀ àgbà nítorí ipò ọrọ̀ ajé àti ibi iṣẹ́ tí kò dúró sójú kan ni pé wọ́n lè ní káwọn lọ fẹ̀yìn tì láìtọ́jọ́. Èyí ló mú kí Chris Sidoti, tó fìgbà kan jẹ́ Alága Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, sọ pé: “Ó dà bíi pé àṣejù ni ìlànà tí wọ́n gbé kalẹ̀ pé tó o
bá ti lé lẹ́ni ogójì ọdún o ò lè lo kọ̀ǹpútà àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé mìíràn mọ́.” Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ tó dáńgájíá, tá a máa ń sọ nígbà kan rí pé wọ́n wà ní àkókò tí wọ́n wúlò jù lọ, ti wá dẹni tí à ń sọ pé wọ́n ti dàgbà kọjá iṣẹ́ ṣíṣe lóde òní. Ọ̀ràn burúkú gbáà lèyí!Abájọ, tó fi jẹ́ pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ò fi taápọntaápọn ṣiṣẹ́ mọ́, wọn ò sì ṣòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìwé ìròyìn Libération ti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Dídà táwọn ilé iṣẹ́ máa ń da àwọn òṣìṣẹ́ sílẹ̀ tí ètò ọrọ̀ ajé bá ti lè mẹ́hẹ díẹ̀ ló fà á táwọn èèyàn ò fi ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn mọ́. Wàá ṣiṣẹ́ lóòótọ́ o, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún àǹfààní ilé iṣẹ́ tó o ti ń ṣiṣẹ́ bí kò ṣe nítorí àtirí nǹkan dà sápò ara rẹ.”
Pẹ̀lú bí wàhálà ṣe pọ̀ tó yìí, ó ṣì di dandan kéèyàn ṣiṣẹ́. Nítorí náà, lákòókò tí nǹkan ò dúró lójú kan mọ́ yìí, báwo lèèyàn ṣe lè fojú tó yẹ wo iṣẹ́ ṣíṣe kó sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ayọ̀ níbi iṣẹ́ lákòókò kan náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ti lè fi kún wàhálà ibi iṣẹ́