“Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” Péjọ Tayọ̀tayọ̀
“Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” Péjọ Tayọ̀tayọ̀
ÌWÀKIWÀ, ìṣòro ọrọ̀ ajé àti ti ìṣèlú ń dá rúgúdù sílẹ̀ lágbàáyé. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo rúkèrúdò yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kóra jọ láti ṣe Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko. Láti May 2002, la ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àpéjọ yìí káàkiri ayé.
Ńṣe ni ìdùnnú ń ṣubú layọ̀ lásìkò àwọn àpéjọ wa yìí. Ẹ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gbéni ró náà, tá a gbé karí Bíbélì.
Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ Àkọ́kọ́ Dá Lórí Ìtara Jésù
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ yìí ni “Ẹ Fara Wé Ìtara Jésù Olúwa Wa.” (Jòhánù 2:17) Ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ náà “Inú Wa Dùn Bá A Ṣe Kóra Jọ Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” fi ọ̀yàyà ké sí àwọn tó wá sí àpéjọ láti nípìn-ín nínú ayọ̀ tí àwọn èèyàn Ọlọ́run sábà máa ń rí nígbà àpéjọ wọn gbogbo. (Diutarónómì 16:15) Lẹ́yìn àsọyé yìí, a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn olùfi ìtara pòkìkí ìhìn rere lẹ́nu wò.
Ọ̀rọ̀ náà “Máa Ní Inú Dídùn Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà” ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 37:1-11 lẹ́sẹẹsẹ. Olùbánisọ̀rọ̀ rọ̀ wá pé ká “má ṣe gbaná jẹ” nítorí àṣeyọrí tó dà bíi pé àwọn ẹni burúkú ń ṣe. Àwọn aṣebi lè máa purọ́ mọ́ wa o, àmọ́ láìpẹ́, Jèhófà á fi àwọn tó jẹ́ èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ hàn kedere. Ọ̀rọ̀ náà “Ẹ Máa Kún fún Ọpẹ́” sọ nípa bí a ṣe lè máa fẹ̀mí ìmoore hàn sí Ọlọ́run. Gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ máa “rú ẹbọ ìyìn” sí Jèhófà. (Hébérù 13:15) Àmọ́ ṣá, ìwọ̀n àkókò tí kálukú ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sinmi lórí bá a ṣe lẹ́mìí ìmoore sí àti ipò tó yí wa ká nígbèésí ayé.
Àkòrí lájorí àsọyé wa ni “A Mú Ìtara Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run Jó Lala.” Ó fi hàn pé Jésù Kristi ni àwòkọ́ṣe wa tó dára jù lọ ní ti ká lo ìtara. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run fìdí múlẹ̀ lọ́run tán lọ́dún 1914, àwọn Kristẹni tòótọ́ nílò ìtara láti máa fi kéde ìhìn rere yẹn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà rán wa létí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ ti ìlú Cedar Point, Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lọ́dún 1922, nígbà tí a gba ìpè mánigbàgbé náà pé: “Ẹ fọn rere Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀”! Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìtara àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sún wọn láti wàásù òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run yìí kárí gbogbo orílẹ̀ èdè.
Àsọyé náà “Ẹ Má Bẹ̀rù Nítorí Tí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa,” tá a gbọ́ ní ọ̀sán ọjọ́ àkọ́kọ́ fi hàn pé Sátánì dìídì dójú sọ àwọn èèyàn Ọlọ́run ni. Àmọ́ láìfọ̀tápè, tá a bá ń ronú nípa àwọn ẹni àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó wà nínú Bíbélì àtàwọn tòde òní ó máa ń fún wa nígboyà tá a fi ń lè kojú ìdánwò láìbẹ̀rù.—Aísáyà 41:10.
Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé èyí lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà ni àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àsọtẹ́lẹ̀ Míkà Ń fún Wa Lókun Láti Máa Rìn ní Orúkọ 2 Pétérù 3:11, 12.
Jèhófà.” Ẹni tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ sọ pé bí ìwàkiwà, ẹ̀sìn apẹ̀yìndà àti ẹ̀mí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ṣe gbòde kan láyé ìgbà Míkà gẹ́lẹ́ ló ṣe wà láyé ìgbà tiwa yìí. Ó ní: “Ìrètí wa fún ọjọ́ ọ̀la yóò dájú bí a bá ní àyà ìgbàṣe, tí a sì rí i dájú pé ìwà wa jẹ́ mímọ́, tí ìgbésí ayé wa kún fún àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run—tí a ò sì gbàgbé láé pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé.”—Ẹni tó sọ̀rọ̀ ṣìkejì nínú àpínsọ àsọyé yẹn sọ nípa bí Míkà ṣe bẹnu àtẹ́ lu àwọn olórí Júdà. Ńṣe ni wọ́n ń fojú àwọn òtòṣì, aláìlágbára gbolẹ̀. Ṣùgbọ́n Míkà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ìsìn tòótọ́ yóò lékè. (Míkà 4:1-5) Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ti ń fún wa lágbára, ìpinnu wa ni pé a ó máa bá a lọ láti máa polongo ìhìn afúnni-nírètí tó ń tuni lára yìí. Àmọ́ ká wá sọ pé àìsàn tàbí ìṣòro mìíràn kò jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe ń fẹ́ ńkọ́? Ẹnì kẹta tó sọ̀rọ̀ sọ pé: “Àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa bọ́gbọ́n mu, apá wa sì ká a.” Ó wá ṣe àlàyé onírúurú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Míkà 6:8, èyí tó kà pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”
Níwọ̀n bí ìwà ìbàjẹ́ ayé ti lè ran àwa Kristẹni, gbogbo wa la jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tó ní àkòrí náà, “Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nípa Dídáàbò Bo Ọkàn Rẹ.” Bí àpẹẹrẹ, tá a bá jẹ́ oníwà mímọ́, àwa àti aya tàbí ọkọ wa á lè gbé pọ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà. Àti pé àwa Kristẹni ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ máa rò ó lọ́kàn rárá pé a fẹ́ ṣe ìṣekúṣe.—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Àsọyé náà “Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn” fi hàn pé ìwà ọlọgbọ́n tó yẹ ká hù ni pé ká máa fi ojú májèlé wo ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀yìndà tó ń yí òtítọ́ po, tí wọ́n ń fi irọ́ lú òótọ́, àní tí wọ́n tiẹ̀ máa ń dìídì parọ́ láìfi bò. (Kólósè 2:8) Bákan náà, ká má ṣe tan ara wa jẹ o, ká máa rò pé a lè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wa lọ́rùn láìní tìka àbámọ̀ bọnu tó bá yá.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọparí ọjọ́ àkọ́kọ́ ni “Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.” Bí ipò
àwọn nǹkan ṣe túbọ̀ ń le koko sí i lóde òní, ó mà dùn mọ́ni gan-an o láti mọ̀ pé Jèhófà yóò mú ayé tuntun òdodo rẹ̀ dé láìpẹ́! Àwọn wo ni yóò gbé ibẹ̀? Kìkì àwọn tó bá ń sin Jèhófà ni o. Olùbánisọ̀rọ̀ wá mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan jáde tí ń jẹ́ Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, èyí tí yóò ran àwa, àwọn ọmọ wa àti akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí ọwọ́ wa lè tẹ góńgó yìí. Áà, inú wa mà dùn o láti rí ìwé náà gbà!Ọjọ́ Kejì Dá Lórí Fífi Ìtara Ṣe Ohun Rere
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kejì àpéjọ ni “Ẹ Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere.” (1 Pétérù 3:13) Olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọjọ́ náà. Ó ṣàlàyé pé kíka ẹsẹ ojoojúmọ́ déédéé, lọ́nà téèyàn fi ń rí nǹkan jèrè máa ń fi kún ìtara wa.
Bẹ́ẹ̀ lọpọ́n sún kan àpínsọ àsọyé náà “Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Tí Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wọn Lógo.” Apá àkọ́kọ́ tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ ká máa fi ọwọ́ tó tọ́ mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tímótì 2:15) Lílò tá a bá ń lo Bíbélì lọ́nà tó múná dóko máa ń jẹ́ kó lè “sa agbára” nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn. (Hébérù 4:12) A ní láti máa pàfiyèsí àwọn èèyàn sí Bíbélì ká sì máa ṣàlàyé rẹ̀ yéni yékéyéké. Apá kejì àpínsọ àsọyé náà rọ̀ wá pé ká máa lọ padà bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò léraléra. (1 Kọ́ríńtì 3:6) Ó gba ìmúrasílẹ̀ àti ìgboyà láti lè máa lọ padà bẹ gbogbo àwọn tó bá fìfẹ́ hàn wò kíákíá. Apá kẹta àpínsọ àsọyé náà gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa wo gbogbo ẹni tá a bá bá pàdé lóde ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó lè di ọmọ ẹ̀yìn, ó sì fi hàn pé fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ lè yọrí sí ayọ̀ ti ríran onítọ̀hún lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé tó tẹ̀ lé e ni “Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa ‘Gbàdúrà Láìdabọ̀.’” Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa yíjú sí Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. A ní láti máa wáyè láti dá gbàdúrà. Ẹ̀wẹ̀, a ní láti máa gbàdúrà láìdabọ̀, nítorí Jèhófà lè mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ ká gbàdúrà fúngbà díẹ̀ ná kó tó hàn sí wa pé ó ń gbọ́ àdúrà wa.—Jákọ́bù 4:8.
Àsọyé náà “Fífọ̀rọ̀wérọ̀ Nípa Nǹkan Tẹ̀mí Ń Gbéni Ró” rọ̀ wá pé ká máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa láti ṣe ara wa àtàwọn ẹlòmíràn láǹfààní. (Fílípì 4:8) Ó yẹ kí tọkọtaya àtàwọn ọmọ wọn máa jọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí nǹkan tẹ̀mí lójoojúmọ́. Láti lè ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ìdílé gbìyànjú láti máa jẹun pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ ó kéré tán, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró.
Àsọyé tó dùn mọ́ni náà “Bí Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi Ṣe Ń Yọrí sí Ìgbàlà” ló kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀. Àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ti kọ́kọ́ gba ìmọ̀, wọ́n lo ìgbàgbọ́, wọ́n ronú pìwà dà wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Olùbánisọ̀rọ̀ wá sọ pé tí wọ́n bá ṣèrìbọmi tán wọ́n tún ní láti túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kí wọ́n máa lo ìtara kí wọ́n sì máa hùwà rere nìṣó.—Fílípì 2:15, 16.
Ní ọ̀sán, àsọyé yìí “Ẹ Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà, Kí Ojú Yín sì Mú Ọ̀nà Kan” tẹnu mọ́ kókó pàtàkì méjì. Ìyẹn ni pé jíjẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà túmọ̀ sí pé ká mọ̀wọ̀n ara wa ká sì mọ ipò tá a wà níwájú Ọlọ́run. Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà á mú ká jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan,” ìyẹn ni pé kí á fi ọkàn wa sí Ìjọba Ọlọ́run, dípò tá a ó fi kó ọ̀rọ̀ ohun ìní ti ara sọ́kàn. Bí a bá ṣe èyí, kò ní sídìí fún wa láti máa ṣàníyàn rárá nítorí pé Jèhófà á pèsè àwọn ohun tá a bá ṣàìní.—Mátíù 6:22-24, 33, 34.
Olùbánisọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e sọ ìdí tó fi yẹ ká “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njú.” Báwo la ó ṣe wá kojú àwọn ìṣòro bí àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ ẹni, ìṣòro ọ̀rọ̀ ajé tàbí ti àìlera ara? Ńṣe ni ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lọ́gbọ́n tá a lè lò ká sì tún máa wá ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Dípò ká jẹ́ kí ìpayà bò wá tàbí ká sọ̀rètí nù, ńṣe ni ká máa fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Ọlọ́run lókun nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Róòmù 8:35-39.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpínsọ àsọyé tó kẹ́yìn nínú àpéjọ wa ni “Onírúurú Àdánwò Ń Dán Bí Ìgbàgbọ́ Wa Ṣe Jẹ́ Ojúlówó Tó Wò.” Apá àkọ́kọ́ nínú àpínsọ àsọyé yìí rán wa létí pé gbogbo Kristẹni ló ń dojú kọ inúnibíni. Ó máa ń jẹ́ ẹ̀rí fáwọn èèyàn, ó ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ó sì máa ń jẹ́ 1 Pétérù 3:16.
ká láǹfààní láti fi ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run hàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní fẹ̀mí ara wa wewu, síbẹ̀ a kò ní gba ọ̀nà tó lòdì sí Ìwé Mímọ́ láti fi yẹra fún inúnibíni.—Olùbánisọ̀rọ̀ kejì nínú àpínsọ àsọyé yìí dáhùn àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ àìdásí-tọ̀túntòsì. Kì í ṣe gbogbo ogun pátá làwọn Kristẹni ìjímìjí lòdì sí, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run làwọn ní láti fún ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìfọkànsìn wọn. Bákan náà lóde òní, ìlànà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rọ̀ mọ́ ni: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Níwọ̀n bí ìdánwò nípa àìdásí-tọ̀túntòsì ti lè dédé yọjú nígbàkigbà, ó yẹ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan wáyè láti ṣàtúnyẹ̀wò ìlànà Bíbélì nípa ọ̀ràn àìdásí-tọ̀túntòsì. Gẹ́gẹ́ bí àsọyé kẹta nínú àpínsọ àsọyé yìí ṣe fi hàn, ète Sátánì lè má fi dandan jẹ́ láti gbẹ̀mí wa, bí kò ṣe pé kò fúngun mọ́ wa ká bàa lè di aláìṣòótọ́. Nípa fífarada ìfiniṣẹ̀sín, ìrọni láti ṣe ìṣekúṣe, ìrora ọkàn àti àìlera ara lóríṣiríṣi, à ń yin Jèhófà lógo.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé tó kẹ́yìn lọ́jọ́ náà fi ọ̀yàyà rọ̀ wá láti “Sún Mọ́ Jèhófà.” Tá a bá lóye àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó gba iwájú jù lọ nínú ànímọ́ Jèhófà, ìyẹn á fà wá sún mọ́ ọn. Ó máa ń lo agbára rẹ̀ tí kò lópin láti fi dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, pàápàá nípa tẹ̀mí. Ìdájọ́ òdodo rẹ̀ kò le koko, bí kò ṣe pé ó ń mú kó fún gbogbo ẹni tó bá ṣiṣẹ́ òdodo ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ọgbọ́n Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀nà tó gbà lo àwọn èèyàn aláìpé láti kọ Bíbélì. Ànímọ́ tó fani lọ́kàn mọ́ra jù lọ ni ìfẹ́ rẹ̀, èyí tó sún un láti pèsè ìgbàlà fún aráyé nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Jòhánù 3:16) Olùbánisọ̀rọ̀ yìí wá mú ìwé náà Sún Mọ́ Jèhófà jáde níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ọjọ́ Kẹta Dá Lórí Níní Ìtara fún Iṣẹ́ Àtàtà
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kẹta àpéjọ ni “Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà.” (Títù 2:14) Àyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọjọ́ náà ni ìdílé kan fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ ọjọ́ náà. Lẹ́yìn ìyẹn la gbọ́ àsọyé náà “Ṣé Jèhófà Lo Gbẹ́kẹ̀ Lé?” Àwọn orílẹ̀-èdè fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn síbi tí kò tọ́ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé ọgbọ́n àti agbára tiwọn fúnra wọn. Àmọ́ àwọn èèyàn Jèhófà kò dà bí tiwọn nítorí pé Jèhófà làwọn máa ń fi ìgboyà gbẹ́kẹ̀ lé tayọ̀tayọ̀ láìka àjálù yòówù kí wọ́n ní sí.—Sáàmù 46:1-3, 7-11.
Ọ̀rọ̀ náà “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Gbé Ọjọ́ Ọ̀la Yín Ka Ètò Àjọ Jèhófà” dáhùn ìbéèrè náà: Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wọn dùn bí oyin? Lílépa owó, dúkìá, tàbí ipò iyì kọ́ ló lè mú ìgbésí ayé dùn bí oyin. Ẹlẹ́dàá wa rọ àwọn ọ̀dọ́ tìfẹ́tìfẹ́ pé kí wọ́n rántí òun nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Olùbánisọ̀rọ̀ fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn kan tó ti lo ìgbà èwe wọn fún iṣẹ́ ìsìn Kristẹni lẹ́nu wò, a sì rí bí wọ́n ṣe láyọ̀ tó. Ó mà sì dùn mọ́ni gan-an o láti gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe?, tá a ṣe láti fi ran àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la ayérayé nínú ètò àjọ Jèhófà!
Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wọni lọ́kàn náà, “Dúró Gbọn-in ní Àkókò Ìṣòro” ló tẹ̀ lé e. Ó sọ ìtàn iṣẹ́ ìsìn Jeremáyà láti ìgbà èwe rẹ̀ títí dìgbà ìparun Jerúsálẹ́mù, èyí tóun fúnra rẹ̀ ti fi ìtara sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Jeremáyà ronú pé òun ò tóótun láti ṣe iṣẹ́ yẹn, ṣùgbọ́n ó padà ṣe é yọrí àní lójú àtakò pàápàá, Jèhófà sì gbà á là.—Jeremáyà 1:8, 18, 19.
Àsọyé náà “Fara Wé Jeremáyà—Máa Polongo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìbẹ̀rù” ló tẹ̀ lé àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà. Àwọn tó ń polongo èké sábà máa ń dìídì parọ́ mọ́ àwọn tó ń pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run lóde òní láti bà wọ́n lórúkọ jẹ́. (Sáàmù 109:1-3) Àmọ́ àwa náà lè ṣe bíi ti Jeremáyà, ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà máa dùn mọ́ wa, èyí tí kò ní jẹ́ ká gba ìrẹ̀wẹ̀sì láyè. Ó sì dá wa lójú pé àwọn tó ń bá wa jà kì yóò borí.
Àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́: “Ìrísí Ìran Ayé Yìí Ń Yí Padà” bọ́ sákòókò gan-an ni. Ayé ti yí padà lọ́nà tó bùáyà nígbà tiwa yìí. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀, títí kan igbe “àlàáfíà àti ààbò,” ló máa yọrí sí ọjọ́ ìdájọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 5:3) Yóò mú àwọn ìyípadà tó ga lọ́lá wá. Ogun, ìwà ọ̀daràn, ìwà ìkà àti àìsàn pàápàá yóò dópin. Nítorí náà, dípò tá a ó fi gbẹ́kẹ̀ lé ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ìgbà yìí ló yẹ ká máa lépa ìfọkànsin Ọlọ́run, ká sì jẹ́ oníwà mímọ́.
Lẹ́yìn àkópọ̀ Ilé Ìṣọ́ a gbọ́ ọ̀rọ̀ àsọparí fún àpéjọ náà, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ẹ̀yin Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, Ẹ Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Àtàtà Yín Máa Pọ̀ Sí I.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe gbé wa ró nípa tẹ̀mí, ó sì gbà wá níyànjú láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó rọ̀ wá pé ká jẹ́ mímọ́, onífẹ̀ẹ́ àti olùfi ìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run.—1 Pétérù 2:12.
Ní tòótọ́, bó ṣe rí fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé ìgbà Nehemáyà náà ló ṣe rí fún wa o, nítorí pé bá a ṣe ń padà lọ sílé, ńṣe ni inú wa ń dùn tara wa sì yá gágá nítorí àwọn ìbùkún tá a ti rí gbà nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” yìí. (Nehemáyà 8:12) Ǹjẹ́ àpéjọ yìí kò mú kí ayọ̀ rẹ kún rẹ́rẹ́, kó sì mú ọ túbọ̀ pinnu láti máa bá a lọ láti jẹ́ olùfi ìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tuntun!
Ní ìparí ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ, inú àwọn tó wá sí àpéjọ dùn láti rí ìwé tuntun náà tá a mú jáde, Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. A ṣe é fún bíbá àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun parí ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ó sì dájú pé yóò fún ìgbàgbọ́ àwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” lókun.—Ìṣe 13:48.
[Credit Line]
Àwòrán èèpo ẹ̀yìn ìwé: Fọ́tò U.S. Navy
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìrànlọ́wọ́ Kan Tí Yóò Mú Ká Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ẹni tó sọ àsọyé kẹ́yìn lọ́jọ́ kejì àpéjọ kéde pé a ti mú ìwé tuntun kan tó ń jẹ́ Sún Mọ́ Jèhófà jáde. Ìwé yìí ní ìsọ̀rí mẹ́rin nínú, ọ̀kọ̀ọ̀kan ìsọ̀rí náà sì dá lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan lájorí ànímọ́ mẹ́rin tí Jèhófà ń lò, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́. Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ní àkòrí kan tó ń fi àpẹẹrẹ bí Jésù Kristi ṣe gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run wọ̀nyí yọ nínú ìṣe rẹ̀ hàn kedere. Ète ìwé tuntun yìí ní pàtàkì jẹ́ láti ran àwa àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó túbọ̀ lágbára tó sì ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Amọ̀nà Tẹ̀mí Fáwọn Ọ̀dọ́
Ohun pàtàkì kan tó wáyé lọ́jọ́ kẹta àpéjọ yìí ni ìmújáde ìwé àṣàrò kúkúrú kan tó ń jẹ́ Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? Wọ́n ṣe ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun yìí láti fi ran àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa ọjọ́ ọ̀la wọn. Ó fúnni nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́ nípa bí a ṣe lè fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe iṣẹ́ tá a ó máa ṣe títí ayérayé.