Ọrẹ Tí Ń Máyọ̀ Wá
Ọrẹ Tí Ń Máyọ̀ Wá
OWÓ táṣẹ́rẹ́ tí Genival, tó ń gbé ìletò kan ní àríwá ìlà oòrùn Brazil, ń gbà nílé ìwòsàn tó ti ń ṣe iṣẹ́ ọdẹ ló fi ń gbọ́ bùkátà ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀. Tọkàntọkàn ni Genival sì fi ń san ìdá mẹ́wàá rẹ̀ láìfi ipò òṣì tó wà pè. Bó ṣe ń fọwọ́ ra ikùn rẹ̀ bí ẹni tébi ń pa ló ń sọ pé: “Ìgbà mìíràn wà tí ìdílé mi ò ní rí oúnjẹ jẹ, àmọ́ mo fẹ́ fún Ọlọ́run ní ohun tó dára jù lọ, láìfi ohun yòówù tó lè ná mi pè.”
Kódà Genival ṣì ń san ìdá mẹ́wàá rẹ̀ lọ lẹ́yìn tíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àlùfáà rẹ̀ sọ fún un pé kí ó dán Ọlọ́run wò nípa dídá owó tó pọ̀ gan-an. Àlùfáà náà mú un dá a lójú pé Ọlọ́run yóò san èrè ńlá fún un. Genival wá pinnu láti ta ilé rẹ̀ kó lè kó owó tó bá rí níbẹ̀ fún ṣọ́ọ̀ṣì.
Genival nìkan kọ́ ló ń fi òótọ́ inú ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ò rí já jẹ ló gbà pé dandan ni káwọn san ìdá mẹ́wàá nítorí ṣọ́ọ̀ṣì wọn ti kọ́ wọn pé sísan ìdá mẹ́wàá jẹ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ká ṣe. Ṣé òótọ́ ni?
Òfin Mósè àti Sísan Ìdá Mẹ́wàá
Àṣẹ láti san ìdá mẹ́wàá wà lára Òfin tí Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá ìgbàanì ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta-ààbọ̀ [3,500] sẹ́yìn. Òfin yẹn sọ pé ìdá mẹ́wàá irè oko ilẹ̀ náà, àti ti èso igi wọn, àti ìdá mẹ́wàá àwọn ohun tó jẹ́ ìbísí ọ̀wọ́ ẹran wọn ni wọ́n gbọ́dọ̀ mú wá fún àwọn ẹ̀yà Léfì láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe nínú àgọ́ ìjọsìn.—Léfítíkù 27:30, 32; Númérì 18:21, 24.
Jèhófà mú un dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé Òfin náà ‘kò ní í ṣòro rárá fún wọn.’ (Diutarónómì 30:11) Bí wọ́n bá ṣáà ti ń fi ìṣòtítọ́ pa àṣẹ Jèhófà mọ́, títí kan sísan ìdá mẹ́wàá, wọ́n á kórè ohun púpọ̀. Nítorí pé ọ̀wọ́n oúnjẹ lè dé, ìdá mẹ́wàá mìíràn tún wà tí wọ́n máa ń yà sọ́tọ̀ déédéé lọ́dọọdún, òun ni wọ́n máa ń lò nígbà tí orílẹ̀-èdè náà bá kóra jọ fún ayẹyẹ ìsìn wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ‘àtìpó, ọmọdékùnrin aláìníbaba, àti opó’ yóò láǹfààní àtijẹ àjẹtẹ́rùn.—Diutarónómì 14:28, 29; 28:1, 2, 11-14.
Òfin náà kò sọ ìyà kan pàtó tí wọ́n máa fi jẹ ẹni tí kò bá san ìdá mẹ́wàá, àmọ́ ó pọn dandan fún ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ lọ́nà yìí. Kódà, Jèhófà fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò san ìdá mẹ́wàá wọn nígbà ayé Málákì pé wọ́n ‘ń ja òun lólè nínú ìdá mẹ́wàá àti nínú àwọn ọrẹ.’ (Málákì 3:8, New International Version) Ǹjẹ́ a lè fi ẹ̀sùn yẹn kan àwọn Kristẹni tí ko bá san ìdá mẹ́wàá?
Tóò, ẹ jẹ́ ká ronú nípa rẹ̀ ná. Àwọn òfin orílẹ̀-èdè kan kì í sábà gbéṣẹ́ lórílẹ̀-èdè mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, òfin tó mú kí àwọn awakọ̀ máa gba apá òsì nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò kan àwọn awakọ̀ tó wà nílẹ̀ Faransé. Bákan náà, òfin tó kan ìdá mẹ́wàá jẹ́ ara májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan ṣoṣo dá. (Ẹ́kísódù 19:3-8; Sáàmù 147:19, 20) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ló wà lábẹ́ òfin yìí.
Láfikún sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kì í yí padà, síbẹ̀ àwọn ohun tó béèrè máa ń yí padà. (Málákì 3:6) Bíbélì là á mọ́lẹ̀ kedere pé ikú ìrúbọ tí Jésù kú ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa “pa” Òfin náà “rẹ,” tàbí pé ó “fi òpin sí” i, ara rẹ̀ sì ni “àṣẹ láti gba ìdá mẹ́wàá” wà.—Kólósè 2:13, 14; Éfésù 2:13-15; Hébérù 7:5, 18.
Ìtọrẹ Tí Kristẹni Máa Ń Ṣe
Àmọ́ ṣá o, a ṣì nílò ọrẹ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. Jésù ti pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ‘láti jẹ́ ẹlẹ́rìí òun títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.’ (Ìṣe 1:8) Bí iye àwọn onígbàgbọ́ ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà la túbọ̀ ń fẹ́ àwọn olùkọ́ àtàwọn alábòójútó tí yóò máa ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ tí wọ́n á sì máa fún wọn lókun. Ìgbà mìíràn tún wà tá a ní láti bójú tó àwọn opó, àwọn ọmọ òrukàn, àtàwọn aláìní. Báwo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe rí owó tí wọ́n lò?
Ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, a ké gbàjarè sáwọn Kèfèrí tó jẹ́ Kristẹni ní Yúróòpù àti ní Éṣíà Kékeré nítorí ìjọ tó wà nínú ìpọ́njú ní Jùdíà. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣètò ‘àkójọ náà èyí tí ó wà fún àwọn ẹni mímọ́.’ (1 Kọ́ríńtì 16:1) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ọ̀nà tí Kristẹni ń gbà ṣètọrẹ yìí lè yà ọ́ lẹ́nu.
Kì í ṣe pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fi ẹnu dídùn rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ṣètọrẹ. Àní, ńṣe làwọn Kristẹni ará Makedóníà tí wọ́n wà “lábẹ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́” àti nínú “ipò òṣì paraku” ní láti ‘máa bẹ̀ ẹ́ ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere àti fún ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún àwọn ẹni mímọ́.’—2 Kọ́ríńtì 8:1-4.
Lóòótọ́, Pọ́ọ̀lù gba àwọn tó rí já jẹ ní Kọ́ríńtì níyànjú láti fara wé àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ọ̀làwọ́ ní Makedóníà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé kan tí a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ sọ pe, ‘àṣẹ kọ́ ló ń pa, dípò ìyẹn ńṣe ló ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè, tó ń dábàá, tó ń fún wọn níṣìírí, tàbí kó jírẹ̀ẹ́bẹ̀. Ọrẹ táwọn ará Kọ́ríńtì fúnni kò ní jẹ́ èyí tí wọ́n fi tinútinú àti tọ̀yàyàtọ̀yàyà ṣe mọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe la fipá mú wọn ṣe é.’ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà,” kì í ṣe ẹni tó ń fúnni “pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.
Ó ní láti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ àti ìmọ̀ pẹ̀lú ojúlówó ìfẹ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn lohun tó mú káwọn ará Kọ́ríńtì ṣètọrẹ àtọkànwá.—2 Kọ́ríńtì 8:7, 8.
‘Gẹ́gẹ́ Bí Ó Ti Pinnu Nínú Ọkàn Rẹ̀’
Dípò sísọ iye kan tàbí ìdá kan pàtó nínú ìpín ọgọ́rùn-ún, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ dábàá pé “ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, olúkúlùkù . . . gbọ́dọ̀ ya iye owó kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìbámu pẹ̀lú iye tí ń wọlé fún un.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; 1 Kọ́ríńtì 16:2, NIV) Nípa mímúra sílẹ̀ àti yíya iye kan pàtó sọ́tọ̀ déédéé, àwọn ará Kọ́ríńtì kò ní í ronú pé à ń fipá mú wọn débi tí wọ́n á fi máa lọ́ tìkọ̀ tàbí tí wọ́n á máa fi tipátipá ṣètọrẹ nígbà tí Pọ́ọ̀lù bá dé. Ọ̀ràn ara ẹni ni iye téèyàn pinnu láti máa fi ṣètọrẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ fún Kristẹni kọ̀ọ̀kan, kó jẹ́ èyí ‘tó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀.’—2 Kọ́ríńtì 9:5, 7.
Kí àwọn ará Kọ́ríńtì lè ká ọ̀pọ̀ yanturu, wọ́n ní láti fúnrúgbìn yanturu pẹ̀lú. Kì í ṣe ọ̀ràn ti dídáwó títí àpò á fi gbẹ́. Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ mú un dá wọn lójú pé, ‘èmi kò ní in lọ́kàn pé kí ó nira fún yín.’ Ọrẹ máa ‘ń ṣètẹ́wọ́gbà jù lọ nígbà tá a bá ṣe é níbàámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, tí kì í ṣe níbàámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.’ (2 Kọ́ríńtì 8:12, 13; 9:6) Nínú lẹ́tà kan tí àpọ́sítélì náà kọ níkẹyìn, ó kìlọ̀ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn . . . tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Pọ́ọ̀lù kò fọwọ́ sí fífúnni tó lòdì sí ìlànà yìí.
Ó yẹ fún àfiyèsí pé Pọ́ọ̀lù ló bójú tó ‘ọrẹ fún àwọn ẹni mímọ́’ tó jẹ́ aláìní. A ò kà á nínú Ìwé Mímọ́ pé Pọ́ọ̀lù tàbí àwọn àpọ́sítélì mìíràn ṣètò ọrẹ tàbí pé wọ́n gba ìdá mẹ́wàá láti rówó ná sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tiwọn fúnra wọn. (Ìṣe 3:6) Gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń fi ìmọrírì hàn fún ọrẹ táwọn ìjọ ń fi ránṣẹ́ sí i, àmọ́ ó fi tọkàntọkàn yẹra fún dídi “ẹrù ìnira tí ń wọni lọ́rùn” lé àwọn arákùnrin rẹ̀ lórí.—1 Tẹsalóníkà 2:9; Fílípì 4:15-18.
Fífi Tinútinú Ṣètọrẹ Lónìí
Ó hàn kedere pé ńṣe láwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní ọ̀rúndún kìíní fi tinútinú ṣètọrẹ, wọn ò san ìdá mẹ́wàá. Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì bóyá ìyẹn ṣì jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ láti rówó ná sórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà àti láti bójú tó àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní.
Gbé ohun tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò. Ní ọdún 1879, olóòtú ìwé ìròyìn yìí sọ ní gbangba pé àwọn “ò ní ṣagbe bẹ́ẹ̀ làwọn ò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn fáwọn.” Ǹjẹ́ ìpinnu yẹn ti dí ìsapá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti tan òtítọ́ Bíbélì kiri lọ́wọ́?
Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí ń pin Bíbélì, àwọn ìwé tó jẹ́ ti Kristẹni, àtàwọn ìwé mìíràn ní igba àti márùndínlógójì [235] ilẹ̀. Tẹ́lẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́, ìyẹn ìwé ìròyìn tí ń la Bíbélì yéni ni à ń tẹ̀ jáde lóṣù ní èdè kan ṣoṣo. Ó ti wá di èyí tó ń jáde lẹ́ẹ̀mejì lóṣù báyìí, tá a sì ń tẹ ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógún ẹ̀dà rẹ̀ jáde ní èdè ogóje ó lé mẹ́fà. Káwọn Ẹlẹ́rìí lè ṣètò iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe kárí ayé, wọ́n ti ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ sí àádọ́fà orílẹ̀-èdè. Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n tún ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ìpàdé títí kan àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá tí ó tóbi tó láti gba àwọn tó nífẹ̀ẹ́ láti túbọ̀ gba ìtọ́ni síwájú sí i látinú Bíbélì.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bíbójútó àìní àwọn èèyàn nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù, síbẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbójú fo àìní nípa tara àwọn tí wọ́n jọ jẹ onígbàgbọ́
dá. Nígbà táwọn arákùnrin wọn bá dójú kọ ìṣòro ogun, ìsẹ̀lẹ̀, ọ̀dá, tàbí ìjì, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n máa ń pèsè oògùn, oúnjẹ, aṣọ, àti àwọn ohun kòṣeémáàní mìíràn fún wọn. Owó táwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan dá tàbí èyí táwọn ìjọ dá la máa ń ná lórí èyí.Bí fífi tinútinú ṣètọrẹ ṣe gbéṣẹ́ náà ló tún máa ń gbé ẹrù wíwúwo kúrò ní èjìká àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, bíi Genival tá a mẹ́nu kàn níṣàájú. A dúpẹ́ pé kí Genival tó ta ilé rẹ̀, Maria tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Genival sọ pé: “Ìjíròrò yẹn kó ìdílé mi yọ nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú tí kò yẹ kó wáyé rárá.”
Genival wáá rí i pé iṣẹ́ Olúwa kò sinmi lórí ìdá mẹ́wàá. Ká sọ tòótọ́, ìdá mẹ́wàá kò sí lára ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè lọ́wọ́ wa mọ́. Ó wá mọ̀ pé a máa ń bù kún àwọn Kristẹni nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ, àmọ́ a kì í fipá mú wọn ṣe kọjá ibi tágbára wọ́n mọ.
Fífínnúfíndọ̀ ṣètọrẹ ti jẹ́ kí Genival ní ayọ̀ tòótọ́. Ohun tó sọ nìyí: “Mo lè fi ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún ṣètọrẹ, mo sì lè máà ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ inú mi dùn sí owó tí mo fi ń ṣètọrẹ, ó sì dá mi lójú pé inú Jèhófà náà dùn sí i pẹ̀lú.”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ǹjẹ́ Àwọn Baba Ìjọ Ìjímìjí Fi Ìdá Mẹ́wàá Kọ́ni?
“Àwọn ọlọ́rọ̀ tó wà láàárín wa ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́ . . . Àwọn tó rí já jẹ, tí wọ́n sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ń fi ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn rò pé ó bójú mu tọrẹ.”—The First Apology, Justin Martyr, nǹkan bí ọdún 150 Sànmánì Tiwa.
“Àwọn Júù ya ìdá mẹ́wàá ohun ìní wọn sí mímọ́ fún Un ní ti gidi, àmọ́ àwọn tí wọ́n ti gba òmìnira ya gbogbo ohun ìní wọn sọ́tọ̀ fún ète Olúwa, . . . gẹ́gẹ́ bí tálákà opó nì ti ṣe, ẹni tó kó gbogbo ohun tó ní sínú àpótí ìṣúra Ọlọ́run.”—Against Heresies, Irenaeus, nǹkan bí ọdún 180 Sànmánì Tiwa.
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní àpótí ìṣúra tiwa, owó tá a fi ń ra ìgbàlà kọ́ ló wà nínú rẹ̀, bíi tàwọn ẹ̀sìn kan tó ní iye owó tí wọ́n máa ń san. Lẹ́ẹ̀kan lóṣù, téèyàn bá fẹ́, á fi owó díẹ̀ sínú rẹ̀; àmọ́ kìkì tó bá wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni o, àti kìkì tó bá ní agbára rẹ̀: nítorí pé kò sí àfipáṣe; gbogbo rẹ̀ jẹ́ àfínnúfíndọ̀ ṣe.”—Apology, Tertullian, nǹkan bí ọdún 197 Sànmánì Tiwa.
“Bí Ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń gbòòrò sí i, tí onírúurú ètò àjọ sì ń yọjú, ó wá di dandan láti ṣe àwọn òfin tó máa jẹ́ kí owó tó tó wà láti ṣètìlẹ́yìn fáwọn àlùfáà kó sì máa báa lọ bẹ́ẹ̀. Bí sísan ìdá mẹ́wàá ṣe jáde nìyẹn látinú Òfin Àtijọ́ . . . Ó dà bíi pé òfin àkọ́kọ́ pàá lórí kókó náà wà nínú lẹ́tà àwọn bíṣọ́ọ̀bù tó pàdé pọ̀ nílùú Tours lọ́dún 567 àti nínú [àwọn òfin] Àpérò Macon kejì lọ́dún 585.”—The Catholic Encyclopedia.
[Credit Line]
Ẹyọwó, òkè lápá òsì: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Fífínnúfíndọ̀ ṣètọrẹ ń máyọ̀ wá
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ọrẹ àtọkànwá là ń ná lórí iṣẹ́ ìwàásù, kíkọ́ àwọn ibi ìpàdé, àti ìrànlọ́wọ́ pàjáwìrì