Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn Ń Kan Sáárá Sáwọn “Ẹni Mímọ́” Lóde Òní

Àwọn Èèyàn Ń Kan Sáárá Sáwọn “Ẹni Mímọ́” Lóde Òní

Àwọn Èèyàn Ń Kan Sáárá Sáwọn “Ẹni Mímọ́” Lóde Òní

“Ǹjẹ́ o rántí ayé ìgbà kan tó jẹ́ pé ńṣe ni inú máa ń bí wa tá a bá gbọ́ táwọn èèyàn dárúkọ àwọn tí wọ́n kà sí àṣàyàn èèyàn Ọlọ́run? Ó dà bíi pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ ní ti àwọn ará Amẹ́ríkà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin tí wọ́n wo ìsìnkú Màmá Teresa ní September 13. Àtìgbà tó ti kú ní September 5, làwọn èèyàn ti ń ránṣẹ́ lọ́tùn-ún lósì sí ìlú Róòmù tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba Póòpù pé kí wọ́n sọ obìnrin yìí di ọ̀kan lára àwọn ẹni mímọ́. Ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló rò pé èyí ò lè ṣeé ṣe.”—Ìwé Ìròyìn Sun-sentinel, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, October 3, 1997.

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ka iṣẹ́ àánú àti oore tí Màmá Teresa tó jẹ́ míṣọ́nnárì ẹ̀sìn Kátólíìkì ṣe sí ohun tó yẹ kí ojúlówó ẹni mímọ́ máa ṣe. Àwọn ẹ̀sìn mìíràn náà ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń rá bàbà fún. Àmọ́ ṣá, ó jọ pé kò sí èyí tó gbajúmọ̀ tó èyí tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì bá pẹnu pọ̀ pè ní ẹni mímọ́.

Iye èèyàn tí Póòpù John Paul Kejì ti sọ di ẹni mímọ́ látìgbà tó ti dórí oyè ti ju àádọ́talénírínwó lọ. Iye yìí pọ̀ ju iye tí àpapọ̀ àwọn póòpù tó kù sọ dẹni mímọ́ ní ọ̀rúndún ogún. a Kí ló mú káwọn èèyàn ṣì máa jọ́sìn àwọn “ẹni mímọ́,” tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn làwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀?

Lawrence Cunningham, tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní Yunifásítì Notre Dame, sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó bá ti jẹ mọ́ ìjẹ́mímọ́ láyé yìí. Gbígbà táwọn èèyàn gbà pé ẹni mímọ́ wà fi hàn pé ó ṣeé ṣe ká rí àwọn kan tó ń gbé ìgbésí ayé lọ́nà tá a fi lè pè wọ́n ní àṣàyàn èèyàn Ọlọ́run, kódà lóde òní pàápàá.” Kò tán síbẹ̀ o, àwọn èèyàn gbà pé “ẹni mímọ́” máa ń ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí ló mú kí wọ́n jẹ́ ojúlówó alárinà láàárín Ọlọ́run àtènìyàn. Táwọn èèyàn bá rí ohun ìrántí “ẹni mímọ́” kan tàbí òkú rẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń bọ ọ́ nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé á fún àwọn ní agbára kún agbára.

Katikísìmù tí wọ́n ṣe níbi àpérò kan nílùú Trent, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, láti fìdí ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì múlẹ̀, sọ pé: “Kò sóhun tó kù díẹ̀ káàtó nínú bá a ṣe ń bọlá fún àwọn ẹni mímọ́ ‘tí wọ́n sùn nínú Olúwa.’ Kò sì sóhun tó burú nínú bá a ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí wọn láti ṣe alárinà wa, tá à ń bọ ohun ìrántí wọn àti eérú òkú wọn tó jẹ́ mímọ́. Èyí kò bu ògo Ọlọ́run kù rárá, ńṣe ló ń mú kó pọ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń fún ìrètí àwọn Kristẹni lókun. Ó tún ń fún wọn níṣìírí láti fara wé ìwà funfun àwọn ẹni mímọ́ yìí.” (The Catechism of the Council of Trent, 1905) Lóòótọ́, àwọn Kristẹni fẹ́ gbé ìgbésí ayé tó mọ́, wọ́n fẹ́ tọ Ọlọ́run lọ lọ́nà tó yẹ, wọ́n sì fẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́. (Jákọ́bù 4:7, 8) Tá a bá fi ojú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ wò ó, àwọn wo ló tóótun láti jẹ́ ẹni mímọ́ ní ti tòótọ́? Ipa wo sì ni wọ́n ń kó?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí wọ́n bá sọ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan tó ti kú di ẹni mímọ́, ó túmọ̀ sí pé gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ máa wárí fún ẹni náà.