Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora- Ẹni-Wò—Ń Jẹ́ Ká Ní Ojú Àánú àti Ìyọ́nú
Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora- Ẹni-Wò—Ń Jẹ́ Ká Ní Ojú Àánú àti Ìyọ́nú
HELEN Keller kọ̀wé pé: “Bó o bá lè pẹ̀rọ̀ sí ìrora ẹlòmíràn, á jẹ́ pé o ti gbélé ayé ṣe ohun gidi.” Dájúdájú, Keller mọ ohun tá à ń pè ní àròdùn. Nígbà tó pé ọmọ ọdún kan àti oṣù méje ni àìsàn kan tó ṣe é sọ ọ́ di afọ́jú àti adití. Àmọ́ olùkọ́ kan tó lójú àánú fi ìwé àwọn afọ́jú kọ́ Helen ní mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Nígbà tó yá, ó tún kọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ sísọ.
Ann Sullivan, ìyẹn olùkọ́ Keller, mọ̀ pé ohun tójú àwọn abirùn ń rí kúrò ní kèrémí. Díẹ̀ ló kù kí ojú òun alára fọ́ pátápátá. Àmọ́ Ann wá fi sùúrù ṣètò ọ̀nà tóun lè gbà bá Helen sọ̀rọ̀. Ó “sípẹ́lì” gbogbo lẹ́tà inú ábídí lọ́kọ̀ọ̀kan lórí ìka ọwọ́ Helen. Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí olùkọ́ Helen ní yìí mú kí Helen pinnu pé òun máa fi ìgbésí ayé òun jin ríran àwọn afọ́jú àti adití lọ́wọ́. Níwọ̀n bí ikún imú rẹ̀ ọ̀tún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí tòsì kó tó lè borí ìṣòro tirẹ̀, àánú àwọn tó nírú ìṣòro bẹ́ẹ̀ wá ń ṣe gan-an. Ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé nínú ayé onímọtara-ẹni-nìkan yìí, ó rọrùn kéèyàn “sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀,” kí ó sì dágunlá sí ìṣòro àwọn ẹlòmíràn. (1 Jòhánù 3:17) Àmọ́, a pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn, kí wọ́n sì ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 22:39; 1 Pétérù 4:8) Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o mọ òtítọ́ yìí, pé: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè fẹ́ fi tọkàntọkàn nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn, ọ̀pọ̀ ìgbà lojú wa máa ń fò ó nígbà tí àǹfààní bá yọ láti pẹ̀rọ̀ sí àròdùn wọn. Ó wulẹ̀ lè jẹ́ nítorí pé a ò mọ ibi tí bàtà ti ń ta wọ́n lẹ́sẹ̀. Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ló lè jẹ́ ká ní ojú àánú àti ìyọ́nú.
Ki Ni Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò?
Ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò jẹ́ mímọ ipò àti ìṣòro àwọn ẹlòmíì lára, ká sì bá wọn kẹ́dùn. A tún lè pè é ní fífi ara ẹni sí ipò tí ẹlòmíràn wà. Nítorí náà, ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ń jẹ́ ká kọ́kọ́ lóye ipò tí ẹnì kan wà, lẹ́yìn náà kí àwa pẹ̀lú mọ̀ ọ́n lára bí òun náà ṣe ń mọ̀ ọ́n lára. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò wé mọ́ kí ohun tó ń ṣe ẹlòmíràn máa dùn wá nínú ọkàn wa.
Ọ̀rọ̀ náà “ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò” kò sí nínú Bíbélì, ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ kò ṣàì tọ́ka sí ànímọ́ yìí. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n ‘máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí wọ́n máa ní ìfẹ́ni ará, kí wọ́n sì máa fi ìyọ́nú hàn.’ (1 Pétérù 3:8) Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a tú sí “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” túmọ̀ ní tààràtà sí “bíbá ẹlòmíràn jìyà” tàbí “láti ní ìyọ́nú.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ó yẹ ká nírú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ nígbà tó rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí ‘wọ́n máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; kí wọ́n máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.’ Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Irú èrò inú kan náà tí ẹ ní sí ara yín ni kí ẹ ní sí àwọn ẹlòmíràn.” (Róòmù 12:15, 16) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pé kò ní ṣeé ṣe láti fẹ́ràn aládùúgbò wa bí ara wa bí a kò bá fi ara wa sípò tí ó wà?
Ṣàṣà lẹni tí kò ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Ta ni inú rẹ̀ kì í bà jẹ́ nígbà tó bá rí àwòrán bíbanilọ́kànjẹ́ ti àwọn ọmọ tébi ń pa tàbí ti àwọn olùwá-ibi-ìsádi tọ́ràn ara wọ́n sú wọn poo? Abiyamọ wo ló máa rí ọmọ rẹ̀ tó ń sunkún tójú rẹ̀ á gbà á? Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìjìyà lèèyàn lè tètè rí báyẹn. Ẹ wo bó ṣe ṣòro tó láti rí ìmí ẹ̀dùn ẹnì kan tó sorí kọ́, tàbí tó ní àbùkù ara tí kò hàn síta tàbí ti ẹni tó ní ìṣòro oúnjẹ jíjẹ pàápàá—bí àwa alára kò bá tíì nírú ìṣòro wọ̀nyẹn rí! Síbẹ̀síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó yẹ ká máa gba ti àwọn èèyàn tí ipò wọn yàtọ̀ sí tiwa rò.
Àpẹẹrẹ Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò Nínú Ìwé Mímọ́
Jèhófà ló kọ́kọ́ fi àpẹẹrẹ ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò lélẹ̀ fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun alára jẹ́ ẹni pípé, kò retí ìjẹ́pípé lọ́dọ̀ wa, “nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14; Róòmù 5:12) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, níwọ̀n bó ti mọ ibi tí agbára wa mọ, ‘kì í jẹ́ kí a dẹ wá wò ré kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra.’ (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ó máa ń tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ kó wa yọ nínú ìṣòro.—Jeremáyà 25:4, 5; Ìṣe 5:32.
Jèhófà máa ń mọ̀ ọ́n lára nígbà tí ìyà bá ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀. Ó sọ fáwọn Júù tó padà dé láti Bábílónì pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8) Nítorí pé Dáfídì tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì mọ̀ dáadáa pé Ọlọ́run ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, ó sọ fún un pé: “Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ. Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?” (Sáàmù 56:8) Ó mà ń tuni nínú o, pé Jèhófà rántí omijé tó ń dà lójú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ bí wọ́n ti ń làkàkà láti pa ìwà títọ́ mọ́—àní ńṣe ló dà bíi pé omijé wọ́n wà ní àkọọ́lẹ̀!
Bíi ti Baba rẹ̀ ọ̀run, Jésù Kristi pẹ̀lú ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò. Nígbà tó fẹ́ wo adití kan sàn, ó mú un kúrò láàárín èrò, bóyá kí ìmúláradà rẹ̀ máà kó ìtìjú bá a tàbí kó mú un ta gìrì. (Máàkù 7:32-35) Ní àkókò mìíràn, Jésù rí opó kan tó ń lọ sìnkú ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí. Ojú ẹsẹ̀ ni ẹ̀dùn ọkàn obìnrin náà di mímọ̀ fún un. Ó lọ bá àwọn tó fẹ́ lọ sìnkú náà, ó sì jí ọ̀dọ́kùnrin náà dìde.—Lúùkù 7:11-16.
Lẹ́yìn àjíǹde Jésù, nígbà tó yọ sí Sọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Damásíkù, ó jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù mọ̀ bí inúnibíni burúkú tó ń ṣe sáwọn ọmọlẹ́yìn ṣe rí lára òun. Ó sọ fún un pé: “Èmi ni Jésù, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.” (Ìṣe 9:3-5) Jésù mọ ìyà tó ń jẹ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lára, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti ń mọ̀ ọ́n lára nígbà tí ara ọmọ rẹ̀ ò bá yá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù tí í ṣe Àlùfáà Àgbà wa ní ọ̀run, ‘ń bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.’—Hébérù 4:15.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń mọ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn lára, ó sì ń gba tiwọn rò. Ó béèrè pé: “Ta ní jẹ́ aláìlera, tí èmi kò sì jẹ́ aláìlera? Ta ní a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò sì gbaná jẹ?” (2 Kọ́ríńtì 11:29) Nígbà tí áńgẹ́lì kan dá Pọ́ọ̀lù àti Sílà nídè kúrò nínú túbú kan ní Fílípì lọ́nà ìyanu, ohun tó kọ́kọ́ wá sọ́kàn Pọ́ọ̀lù ni láti jẹ́ kí onítúbú náà mọ̀ pé kò sẹ́ni tó sá lọ. Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ló jẹ́ kó tètè ronú pé onítúbú náà lè pa ara rẹ̀. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí àṣà Róòmù, ìyà kékeré kọ́ ni wọ́n fi ń jẹ onítúbú tí ẹlẹ́wọ̀n bá sá lọ mọ́ lọ́wọ́—àgàgà bí wọ́n bá ti pàṣẹ fún un tẹ́lẹ̀ pé ẹlẹ́wọ̀n náà ò gbọ́dọ̀ sá mọ́ ọn lọ́wọ́. (Ìṣe 16:24-28) Ojú àánú tí ń gba ẹ̀mí là tí Pọ́ọ̀lù fi hàn yìí wú onítúbú náà lórí gan-an, òun àti agboolé rẹ̀ sì di Kristẹni.—Ìṣe 16:30-34.
Bá A Ṣe Lè Ní Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò
Léraléra ni Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé ká máa fara wé Baba wa ọ̀run àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. Fún ìdí yìí, kòṣeémánìí ni ànímọ́ ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Báwo la ṣe lè ní ànímọ́ yìí? Ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì la lè gbà túbọ̀ kọbi ara sí ìṣòro àti ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn, èyíinì ni: nípa fífetísílẹ̀, nípa fífojúsílẹ̀, àti nípa fífojú inú wo nǹkan.
Fetí sílẹ̀. Nípa fífetísílẹ̀ dáadáa la fi lè mọ ìṣòro táwọn ẹlòmíràn ń bá yí. Bá a bá sì ṣe fetí sílẹ̀ dáadáa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò sọ tinú wọn jáde, tí wọn yóò sì jẹ́ ká mọ bó ṣe rí lára wọn. Miriam ṣàlàyé pé: “Mo lè sọ̀rọ̀ ara mi fún alàgbà, bí ó bá dá mi lójú pé á fetí sí mi. Màá fẹ́ mọ̀ bóyá lóòótọ́ ló lóye ìṣòro mi. Ọkàn mi á túbọ̀ balẹ̀ bó bá ń béèrè àwọn ìbéèrè tí ń lani lóye, tó fi hàn pé ó gbọ́ mi lágbọ̀ọ́yé.”
Fojú sílẹ̀. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa dìídì wá bá wa, tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn fún wa tàbí gbogbo ohun tójú wọn ń rí. Àmọ́ ẹni tó bá fojú sílẹ̀ dáadáa á mọ ìgbà tó bá dà bíi pé Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sorí kọ́, tàbí nígbà tí ọ̀dọ́langba kan bá di ẹni tí àwọn èèyàn ò rójú rẹ̀ nílẹ̀ mọ́, tàbí nígbà tí òjíṣẹ́ onítara kan kò bá túra ká mọ́. Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí mọ bá a ṣe tètè ń kíyè sí ìṣòro ní gbàrà tó bá yọjú. Marie sọ pé: “Lọ́nà kan ṣá, màmá mi máa ń mọ bó ṣe ń ṣe mí, kí n tiẹ̀ tó sọ fún un rárá. Nítorí náà, ó máa ń rọrùn fún mi láti sọ àwọn ìṣòro mi fún un láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ.”
Lo ojú inú rẹ. Ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lo ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni láti bi ara rẹ pé: ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi, ká ní èmi ni mo wà nírú ipò yìí? Kí ni mo máa ṣe? Kí ni màá nílò?’ Àwọn olùtùnú èké mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó láwọn wá tu Jóòbù nínú kò fi ara wọn sípò Jóòbù rárá. Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́bi fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n rò pé ó ti dá.
Ó ń rọ ẹ̀dá aláìpé lọ́rùn láti kù gìrì tọ́ka sí àṣìṣe ẹni ju láti báni kẹ́dùn. Àmọ́ tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí ìrora ọkàn ẹni tí wàhálà bá, a óò bá a kẹ́dùn dípò bíbẹnu àtẹ́ lù ẹni náà. Alàgbà kan tó jẹ́ onírìírí, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Juan sọ pé: “Ìmọ̀ràn mi máa ń múná dóko, bí mo bá kọ́kọ́ gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ fún mi lágbọ̀ọ́yé kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí mú àbá jáde.”
Àwọn ìtẹ̀jáde tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pín kiri ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yìí. Àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti jíròrò àwọn ìṣòro dídíjú, bí ìsoríkọ́ àti híhùwà àìdáa sọ́mọdé. Ìsọfúnni tó bákòókò mu yìí ti jẹ́ kí àwọn tó ń kà wọ́n túbọ̀ máa gba ti àwọn tó ń fojú winá ìṣòro wọ̀nyẹn rò. Bákan náà, ìwé Awọn Ìbéèrè Tí
Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè ti ran ọ̀pọ̀ òbí lọ́wọ́ láti mọ irú ìṣòro táwọn ọmọ wọn ń dojú kọ.Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò Wúlò Nínú Ìgbòkègbodò Kristẹni
Ṣàṣà nínú wa ló lè rí ọmọ tébi ń pa, tó máa ṣe bíi pé òun ò rí i nígbà tóúnjẹ wà tá a lè fún un. Bákan náà, bá a bá ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, a óò kíyè sí ipò tẹ̀mí ẹlòmíràn. Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló wà nírú ipò tẹ̀mí yẹn lónìí, wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lọ́jọ́ Jésù, ó lè di dandan ká pa ẹ̀tanú tàbí àṣà tó ti mọ́ni lára tì, ká tó lè dénú ọkàn èèyàn kan. Òjíṣẹ́ tó bá ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò máa ń sapá láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ níbi tí èdè òun àtẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ ti yéra tàbí kí ó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí àwọn èèyàn, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè wọni lọ́kàn. (Ìṣe 17:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 9:20-23) Inú rere tí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò bá jẹ́ kí a fi hàn tún lè mú kí àwọn olùgbọ́ tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà, bó ṣe rí nínú ọ̀ràn onítúbú ará Fílípì yẹn.
Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò jẹ́ kòṣeémánìí, nítorí pé ẹ̀mí yìí ló máa jẹ́ ká gbójú fo àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Bá a bá gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á tí arákùnrin kan fi ṣe ohun tó bí wa nínú, ó dájú pé yóò túbọ̀ rọrùn fún wa láti dárí jì í. Bóyá bẹ́ẹ̀ làwa náà ì bá ṣe, ká ní a bá ara wa nínú ipò kan náà. Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jèhófà ní ló jẹ́ kó máa “rántí pé ekuru ni wá.” Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò sún àwa náà láti máa ro ti ẹ̀dá aláìpé táwọn ẹlòmíràn jẹ́, ká sì máa ‘dárí jì wọ́n ní fàlàlà’?—Sáàmù 103:14; Kólósè 3:13.
Nígbà tá a bá fẹ́ fúnni nímọ̀ràn, a ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ ọ́, bá a bá ro ti ẹ̀dùn ọkàn àti ìmọ̀lára ẹni tó ṣàṣìṣe náà. Kristẹni alàgbà tó ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò máa ń rán ara rẹ̀ létí pé: ‘Èmi náà lè ṣe irú àṣìṣe yìí o. Mo lè bá ara mi nírú ipò yìí o.’ Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi dámọ̀ràn pé: “Gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù, bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì, kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.”—Gálátíà 6:1.
Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tún lè sún wa láti ṣe ìrànlọ́wọ́ gidi, bá a bá lágbára ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lè máa lọ́ tìkọ̀ láti béèrè fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀? . . . Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 Jòhánù 3:17, 18.
Ká tó lè nífẹ̀ẹ́ “ní ìṣe àti òtítọ́,” a óò kọ́kọ́ mọ ohun náà gan-an tó jẹ́ àìní arákùnrin wa. Ǹjẹ́ a máa ń fara balẹ̀ kíyè sí àìní àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ète àtiràn wọ́n lọ́wọ́? Ohun tí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò túmọ̀ sí gan-an nìyẹn.
Ẹ Ní Ìmọ̀lára fún Ọmọnìkejì
A lè máà lẹ́bùn ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, àmọ́ a lè mú ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì dàgbà. Bá a bá túbọ̀ ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, tí à ń fojú sílẹ̀ dáadáa, tí a sì ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti fi ara wa sípò tí ẹlòmíràn wà, a óò túbọ̀ máa ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ ní ìfẹ́, inú rere, àti ìyọ́nú sí àwọn ọmọ wa, sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, àti sí àwọn aládùúgbò wa.
Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan paná ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò rẹ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe máa ro tara rẹ̀ nìkan, àmọ́ kẹ́ ẹ máa ro tàwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4, Phillips) Ọjọ́ ọ̀la wa ayérayé sinmi lórí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jèhófà àti Jésù Kristi, Àlùfáà Àgbà, ní. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kòṣeémánìí ni ànímọ́ yìí jẹ́ fún wa. Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò á jẹ́ ká di òjíṣẹ́ rere àti òbí rere. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò yóò jẹ́ ká rí i pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò wé mọ́ fífarabalẹ̀ kíyè sí àìní àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ète àtiràn wọ́n lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ǹjẹ́ a lè kọ́ láti ní irú ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí abiyamọ ń ní sí ọmọ rẹ̀