Ìlú Tó Wà Lórí Òkè
Ìlú Tó Wà Lórí Òkè
“Ẹ̀YIN ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá.” Jésù ló sọ bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí Lórí Òkè.—Mátíù 5:14.
Ọ̀pọ̀ ìlú ní Júdà àti Gálílì ló wà lórí òkè, dípò kí wọ́n wà ní àfonífojì nísàlẹ̀. Ọ̀ràn ààbò ni lájorí ìdí tí wọ́n fi ń yàn láti tẹ ìlú dó sórí òkè. Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ ogun agbóguntini, àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí tún máa ń gbé sùnmọ̀mí wá sílùú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (2 Àwọn Ọba 5:2; 24:2) Ó máa ń rọrùn fún àwọn tó láyà bíi kìnnìún láàárín ìlú láti gbèjà àwọn agbo ilé tá a kọ́ sójú kan lórí òkè ju ìlú tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, èyí tó ń béèrè odi fífẹ̀.
Níwọ̀n bí àwọn Júù ti sábà máa ń kun ilé wọn lẹ́fun, àwọn agbo ilé tá a kọ́ pa pọ̀ sójú kan lórí òkè, tá a sì kùn lẹ́fun á ṣeé rí kedere láti ọ̀nà jíjìn. (Ìṣe 23:3) Pẹ̀lú bí oòrùn ṣe máa ń ràn yòò ní Palẹ́sìnì, ńṣe làwọn ìlú tó wà lórí òkè wọ̀nyí máa mọ́lẹ̀ rokoṣo, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú àgbègbè Mẹditaréníà ṣe ń mọ́lẹ̀ lóde òní.
Jésù lo ìran tí ń pe àfiyèsí lágbègbè àrọko Gálílì àti Jùdíà yìí láti fi ṣàlàyé ipa tí Kristẹni tòótọ́ ń kó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kò ṣe iṣẹ́ àtàtà wọn láti gba ìyìn lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, àwọn èèyàn ń kíyè sí ìwà rere wọn.—Mátíù 6:1.
Irú ìwà rere bẹ́ẹ̀ máa ń hàn kedere nígbà àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí ìwé ìròyìn kan ní Sípéènì ń sọ̀rọ̀ nípa àpéjọ kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ròyìn pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣú já ọ̀ràn ẹ̀sìn mọ́ nínú àwọn ìjọ yòókù, ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Níwọ̀n bí wọn ò ti fẹ́ kí Bíbélì di ìwé tí kò bóde mu mọ́, wọ́n ń fi í sílò nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.”
Thomas, tó ń bójú tó pápá ìṣiré kan táwọn Ẹlẹ́rìí ń lò déédéé ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Sípéènì, máa ń fẹ́ wà ní sàkáání àwọn tó ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Ó sún àkókò ìfẹ̀yìntì rẹ̀ síwájú fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, kí ó lè wà níbẹ̀ nígbà àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọ̀ náà, títí kan àwọn ọmọdé, wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn àpéjọ ọ̀hún nítorí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ láti àwọn ọdún tó ti kọjá, kí wọ́n sì kí i pé àkókò ìfẹ̀yìntì rẹ̀ á san án o, ńṣe ló bú sẹ́kún. Ó sọ pé: “Mímọ ẹ̀yin aráabí yìí jẹ́ ọ̀kan lára ìrírí mánigbàgbé nínú ìgbésí ayé mi.”
Ìlú tó wà lórí òkè máa ń pe àfiyèsí òǹwòran nítorí pé ó wà lókè téńté àti nítorí pé gbogbo ilé funfun tó wà níbẹ̀ ni yóò máa gbé ìtànṣán oòrùn yọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ dá yàtọ̀ nítorí pé wọ́n ń sapá láti tẹ̀ lé ìlànà gíga tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ nípa ìṣòtítọ́, ìwà rere àti ìyọ́nú.
Láfikún sí i, àwọn Kristẹni ń ṣàgbéyọ ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: ‘Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ní ìbámu pẹ̀lú àánú tí a fi hàn sí wa, àwa kò juwọ́ sílẹ̀ . . . ṣùgbọ́n nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.’ (2 Kọ́ríńtì 4:1, 2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dojú kọ inúnibíni níbi gbogbo tí wọ́n ti wàásù, Jèhófà bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn débi pé nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé a ti wàásù ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.
Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú kò fọwọ́ kékeré mú ojúṣe wọn láti jẹ́ kí ‘ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn níwájú àwọn ènìyàn,’ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pa á láṣẹ. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu àti nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ yí ká ayé. Kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Bíbélì lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tó bá lè ṣeé ṣe kí ó dé, àwọn ìtẹ̀jáde wọn tá a gbé ka Bíbélì ń jáde ní ọgbọ̀n-dín-nírínwó [370] èdè.—Mátíù 24:14; Ìṣípayá 14:6, 7.
Ọ̀pọ̀ ibi ló ti jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti tọrùn bọ wàhálà kíkọ́ èdè àwọn tó ṣí wọ̀lú láti àwọn orílẹ̀-èdè tó ká iṣẹ́ ìwàásù náà lọ́wọ́ kò. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ti orílẹ̀-èdè China àti Rọ́ṣíà rọ́ wá sí àwọn ìlú ńláńlá tó wà ní Àríwá Amẹ́ríkà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú táwọn èèyàn wọ̀nyí ṣí wá ti sapá láti kọ́ èdè Chinese, èdè Russian àtàwọn èdè mìíràn, kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere náà fún wọn. A tilẹ̀ tún ń ṣe àwọn ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó máa mú kí kíkọ́ èdè wọ̀nyí yá, kí ó lè ṣeé ṣe láti wàásù ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i nígbà tí pápá ṣì “funfun fún kíkórè.”—Jòhánù 4:35.
Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀.” Ìwà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fi ń ran àwọn èèyàn níbi gbogbo lọ́wọ́ láti wá sí orí “òkè ńlá ilé Jèhófà,” ká lè kọ́ wọ́n nípa ọ̀nà Ọlọ́run, kí wọ́n sì kọ́ bá a ṣe ń rìn ní ipa ọ̀nà Ọlọ́run. (Aísáyà 2:2, 3) Ohun ayọ̀ tí ń tìdí rẹ̀ yọ, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, ni pé gbogbo wọn lápapọ̀ ‘ń fi ògo fún Baba wọn ọ̀run,’ èyíinì ni Jèhófà Ọlọ́run.—Mátíù 5:16; 1 Pétérù 2:12.