“Nípasẹ̀ Ìmọ́lẹ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Rẹ Ni Àwa Fi Lè Rí Ìmọ́lẹ̀”
“Nípasẹ̀ Ìmọ́lẹ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Rẹ Ni Àwa Fi Lè Rí Ìmọ́lẹ̀”
ÌGBÀ tíná bá lọ, tí ibi gbogbo ṣókùnkùn, la tó máa ń mọyì ìmọ́lẹ̀. A dúpẹ́ pé oòrùn, “ẹ̀rọ amúnáwá” tí ń bẹ lájùlé ọ̀run, kò lè ṣe kí ó máà fún wa ní ìmọ́lẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ oòrùn ló sì ń jẹ́ ká ríran, ká rí oúnjẹ jẹ, ká máa mí, ká sì wà láàyè.
Níwọ̀n bí ìmọ́lẹ̀ ti jẹ́ kòṣeémánìí fún ìwàláàyè, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu láti kà á nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì pé ọjọ́ àkọ́kọ́ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ni ìmọ́lẹ̀ tàn. “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: ‘Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà.’ Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ wá wà.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:3) Àwọn olùfọkànsìn, bíi Dáfídì Ọba gbà tọkàntọkàn pé Jèhófà ni orísun ìyè àti ìmọ́lẹ̀. Dáfídì kọ̀wé pé: “Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwa fi lè rí ìmọ́lẹ̀.”—Sáàmù 36:9.
Ọ̀rọ̀ Dáfídì yìí ń tọ́ka sí ìmọ́lẹ̀ gidi àti ìmọ́lẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ ló ń jẹ́ ká ríran.” Ó wá fi kún un pé: “Ìsọfúnni tó ń tipasẹ̀ ojú wọnú ọpọlọ pọ̀ ju ìsọfúnni tó ń tipasẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara mìíràn wọnú ọpọlọ.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nípa rírí là ń kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan—a sì mọ̀ pé a ò lè ríran dáadáa láìsí ìmọ́lẹ̀—ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ tún fi lo ìmọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.
Abájọ tí Jésù fi sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Jòhánù 8:12) Ìmọ́lẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ tí Jésù tọ́ka sí ni òtítọ́ tó ń wàásù rẹ̀, èyí tó lè tànmọ́lẹ̀ sí èrò inú àti ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti fi ọ̀pọ̀ ọdún wà lókùnkùn nípa tẹ̀mí, níkẹyìn, wọ́n wá lóye ète Ọlọ́run fáráyé, wọ́n sì wá ní ìrètí Ìjọba náà. Èyí gan-an ni “ìmọ́lẹ̀ ìyè,” torí pé ìmọ̀ yẹn lè sinni lọ sí ìyè ayérayé. Jésù gbàdúrà sí Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ẹ má ṣe jẹ́ ká kóyán ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí yìí kéré o!