Àwọn Ohun Tó Ń Pagi Run
Àwọn Ohun Tó Ń Pagi Run
LÁKÒÓKÒ tá a kọ Bíbélì, ohun iyebíye ni igi jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Ábúráhámù ra ibi tó sìnkú Sárà, aya rẹ̀ ọ̀wọ́n sí, igi wà lára nǹkan tó rà mọ́ ilẹ̀ náà.—Jẹ́nẹ́sísì 23:15-18.
Bẹ́ẹ̀ náà ni igi ṣe níye lórí gan-an lóde òní, àwọn èèyàn jákèjádò ayé sì ń ṣe gudugudu méje láti rí sí i pé a dá igbó sí. Ìwé náà, State of the World 1998, sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè àríwá ayé ló ń ṣàníyàn nípa igbó tó wà nílẹ̀ olóoru, wọ́n lè má fura pé igbó tó wà lórílẹ̀-èdè tàwọn gan-an ló ti dìdàkudà jù lọ, tó sì ń bà jẹ́ ju gbogbo igbó yòókù lọ.” Kí ló ń ba igbó tó wà láwọn orílẹ̀-èdè ìhà àríwá Yúróòpù àti ti Àríwá Amẹ́ríkà jẹ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ pé sísọ igbó di ìgboro ló ń fà á. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan tún wà tó rọra ń pa àwọn igi kú lọ́kọ̀ọ̀kan. Kí ni àwọn nǹkan náà? Afẹ́fẹ́ olóró àti òjò ásíìdì ni. Àwọn ohun aṣèbàjẹ́ wọ̀nyí lè máa ba igi jẹ́ díẹ̀díẹ̀, kó wá jẹ́ kó rọrùn fún àwọn kòkòrò àti àrùn láti pa wọ́n.
Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn onímọ̀ nípa àyíká àtàwọn míì tí ọ̀ràn náà ká lára ti ń kì wá nílọ̀ pé ká má ṣe jẹ́ kí àjọṣe àárín àwọn ohun alààyè bà jẹ́. Láwọn ọdún 1980, lẹ́yìn táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Jámánì rí ìbàjẹ́ tí afẹ́fẹ́ olóró àti òjò ásíìdì ń ṣe fún àyíká, wọ́n kéde pé: ‘Bí a ò bá wá nǹkan ṣe sí i, tó bá fi máa di nǹkan bí ọdún 2000, inú àwọn ògbólógbòó fọ́tò àti sinimá nìkan làwọn èèyàn á ti máa rí ohun tá a ń pè ní igbó.’ Àmọ́, a dúpẹ́ pé agbára àmúdọ̀tun tí ilẹ̀ ayé ní kò tíì jẹ́ kí aburú tí wọ́n sọ yẹn wáyé.
Ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ọlọ́run ni yóò kó àwọn ohun alààyè yọ nínú ewu. “Ó ń bomi rin àwọn òkè ńláńlá láti àwọn ìyẹ̀wù rẹ̀ òkè,” ó sì “ń mú kí koríko tútù rú jáde fún àwọn ẹranko, àti ewéko fún ìlò aráyé.” Ó sì ti ṣèlérí pé òun yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 104:13, 14; Ìṣípayá 11:18) Ẹ wo bí yóò ti lárinrin tó nígbà táwọn olùgbé ayé bá ń gbé títí láé nínú ayé tí kò ní afẹ́fẹ́ olóró!—Sáàmù 37:9-11.