Ǹjẹ́ O Lè Tún Ayé Ṣe?
Ǹjẹ́ O Lè Tún Ayé Ṣe?
“Ayé ti dà rú, ìṣèlú kò lè tún un ṣe mọ́. Kò lè dá àwọn ìwà ọmọlúwàbí àtayébáyé padà. Àwọn ìlànà tó dára jù lọ kò lè dá ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó padà sí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀, kó mú kí àwọn baba máa bójú tó àwọn ọmọ wọn, kó jẹ́ káwọn èèyàn máa wá rìrì kí wọ́n sì lójútì bíi ti tẹ́lẹ̀ . . . Òfin kò lè bá wa mú èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìṣòro ìwà híhú tó ń bá wa fínra kúrò.”
ǸJẸ́ ó ṣe ọ́ bíi pé kó o fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí igbá kejì olórí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ wọ̀nyẹn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni ojútùú sí ọ̀pọ̀ ìṣòro tá a ní lóde òní, tó jẹ́ àbájáde ìwà ìwọra, àìsí ìfẹ́ nínú ìdílé, ìwàkiwà, àìmọ̀kan, àti àwọn ohun búburú mìíràn tó ń jẹ ìpìlẹ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wa wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ bí ìgbà tí ikán ń jẹlé? Àwọn kan rò pé kò sí ojútùú kankan, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n wulẹ̀ ń lo ilé ayé bó ṣe wù wọ́n ni. Àwọn mìíràn ń retí pé ní ọjọ́ kan, aṣáájú kan tó ní agbára àrà ọ̀tọ̀, tí orí rẹ̀ pé, bóyá tó tiẹ̀ jẹ́ aṣáájú ìsìn pàápàá, yóò yọjú, yóò sì wá tọ́ka wọn sí ọ̀nà tí ó tọ́.
Àní sẹ́, ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn fẹ́ fi Jésù Kristi jẹ ọba wọn nítorí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló rán an wá, yóò sì jẹ́ aṣáájú tí ó tóótun jù lọ. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jésù mọ èrò ọkàn wọn, kíá ló sá kúrò níbẹ̀. (Jòhánù 6:14, 15) Ó wá ṣàlàyé fún gómìnà Róòmù kan níkẹyìn pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Àmọ́, lóde òní, ìwọ̀nba kéréje làwọn tó ń mú irú ìdúró tí Jésù mú yẹn—kódà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n sọ pé ọmọlẹ́yìn rẹ̀ làwọn pàápàá kò ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lára àwọn wọ̀nyí ti gbìyànjú láti tún ayé ṣe, yálà nípa gbígbìyànjú láti fa ojú àwọn aláṣẹ ayé mọ́ra tàbí káwọn fúnra wọn di ipò kan mú nínú ìṣèlú. A lè rí ohun tá a ń wí yìí tá a bá wo bí nǹkan ṣe rí láwọn ọdún 1960 àtàwọn ọdún 1970.
Akitiyan Tí Ìsìn Ń Ṣe Láti Máyé Sunwọ̀n Sí I
Lápá ìparí àwọn ọdún 1960, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan láti àwọn orílẹ̀-èdè Látìn-Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí jà fitafita fáwọn òtòṣì àtàwọn tójú ń pọ́n. Kí èyí lè kẹ́sẹ járí, wọ́n dá ẹ̀kọ́ ìsìn nípa ìjìjàgbara sílẹ̀, nínú èyí tí wọ́n ti sọ pé Kristi kì í wulẹ̀ ṣe irú olùgbàlà tí Bíbélì pè é nìkan, àmọ́ pé ó jẹ́ olùgbàlà lọ́nà ìṣèlú àti ti ìṣúnná owó pẹ̀lú. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì bíi mélòó kan tí wọ́n ń ṣàníyàn gan-an nípa bí ìlànà ìwà rere ṣe ń yìnrìn dá àjọ kan sílẹ̀ tí wọ́n pè ní Moral Majority. Ète wọn ni láti jẹ́ káwọn tó máa fìdí ètò ìdílé tó gbámúṣé múlẹ̀ rọ́wọ́ mú nínú ètò ìṣèlú. Bákan náà, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó jẹ́ ti àwọn Mùsùlùmí, àwọn onírúurú ẹgbẹ́ ti gbìyànjú láti fòpin sí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà àìníjàánu nípa gbígba àwọn ènìyàn níyànjú láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Kùránì.
Ṣé o gbà pé irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ ti wá mú kí ilé ayé dára sí i? Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, lápapọ̀, ìwà rere túbọ̀ ń dín kù ni, àlàfo tó wà láàárín
ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì sì ń fẹ̀ sí i, títí dé àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀kọ́ ìsìn nípa ìjìjàgbara ti gbilẹ̀.Nítorí kíkùnà tí ẹgbẹ́ Moral Majority kùnà láti mú ète rẹ̀ ṣẹ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni Jerry Falwell, tó dá a sílẹ̀, ṣe tú ẹgbẹ́ náà ká lọ́dún 1989. Àwọn ẹgbẹ́ mìíràn ti gba ipò rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, Paul Weyrich, tó kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “moral majority,” kọ̀wé sínú ìwé ìròyìn Christianity Today pé: “Kódà nígbà tọ́mọ ẹgbẹ́ wa bá wọlé, wíwọlé tó wọlé kò sọ pé ká ráyè gbé àwọn ìlànà tó jẹ wá lógún kalẹ̀.” Ó tún kọ̀wé pé: “Àṣà ìgbàlódé ti wá ń di kòtò tó túbọ̀ ń fẹ̀ sí i. Ó ti gbé àwọn àṣà àbáláyé mì ráúráú, ibi tí ọ̀ràn ọ̀hún sì ti dé báyìí, apá ìṣèlú kò ká a mọ́.”
Cal Thomas, tó ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn, tó sì tún jẹ́ òǹṣèwé sọ ohun tó gbà pé ó jẹ́ àléébù pàtàkì nínú gbígbìyànjú láti tún àwùjọ ṣe nípasẹ̀ ìṣèlú pé: “Látinú ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ojúlówó ìyípadà ti ń wá, kì í ṣe nípa ìbò dídì, nítorí pé àwọn ohun tó jẹ́ olórí ìṣòro wa kì í ṣe ti ìṣúnná owó àti ìṣèlú bí kò ṣe ìṣòro tó jẹ mọ́ ìwà híhù àti nǹkan tẹ̀mí.”
Àmọ́, báwo lèèyàn ṣe máa yanjú ìṣòro tó jẹ mọ́ ìwà híhù àti nǹkan tẹ̀mí nínú ayé kan tí kò ní ìlànà kankan, níbi tí kálukú ti ń fúnra rẹ̀ pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́? Nígbà tí àwọn tó yọrí ọlá, tí wọ́n sì ní èrò rere—yálà àwọn ẹlẹ́sìn tàbí àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn—kò bá lè tún ayé yìí ṣe, ta ló wá lè tún un ṣe? Ìdáhùn wà, bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e. Àní, ìdáhùn yẹn gan-an ni ìdí pàtàkì tí Jésù fi sọ pé Ìjọba òun kì í ṣe ti ayé yìí.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Omi dídọ̀tí: Fọ́tò WHO/UNICEF; àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ọmọdé: Fọ́tò àjọ UN; àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.