Má Ṣe Jẹ́ Kí Iyèméjì Ba Ìgbàgbọ́ Rẹ Jẹ́
Má Ṣe Jẹ́ Kí Iyèméjì Ba Ìgbàgbọ́ Rẹ Jẹ́
Lọ́jọ́ kan, o rò pé ara rẹ yá gágá. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, o nímọ̀lára pé ara rẹ ò yá. Lójijì, o ò lókun tàbí agbára kankan mọ́. Orí bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ẹ, gbogbo ara sì ń ro ẹ́ gógó. Kí ló fà á? Kòkòrò àrùn búburú kan ti wọnú ara rẹ, ó sì ti gbógun ti àwọn ẹ̀yà ara pàtàkì nínú rẹ. Tóò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i, àwọn kòkòrò tí ń gbógun tini wọ̀nyí lè sọ ẹ́ di olókùnrùn—wọ́n tiẹ̀ lè gbẹ̀mí rẹ pàápàá.
TÓ BÁ wá lọ jẹ́ pé ìgbà tí ara rẹ kò yá ni kòkòrò àrùn dé sí ọ lára, ó lè dọ̀ràn sí ẹ lọ́rùn. Fún àpẹẹrẹ, Peter Wingate, tó jẹ́ òǹkọ̀wé lórí ọ̀ràn ìṣègùn sọ pé, bí àìjẹunre kánú bá ti sọ ọ́ di aláìlera, agbára tóo fi máa gbógun ti àrùn “a ti kéré gan-an tó fi jẹ́ pé àkóràn àrùn kékeré báyìí lè di èyí tọ́wọ́ ò ní ká.”
Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ta ló máa fẹ́ fi oúnjẹ aṣaralóore du ara rẹ̀? Ó dájú pé wàá sa gbogbo ipá rẹ láti jẹunre kánú, kí ara rẹ lè yá gágá. Wàá sì tún fẹ́ ṣe gbogbo ohun tóo bá lè ṣe láti yẹra fún àwọn kòkòrò tí ń kó àrùn síni lára. Àmọ́, ǹjẹ́ o máa ń kíyè sára bákan náà lórí ọ̀ràn jíjẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́”? (Títù 2:2) Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o máa ń wà lójúfò sí àwọn ewu tí iyèméjì ń fà? Ìwọ̀nyí lè tètè gba gbogbo èrò inú àti ọkàn rẹ, kí ó ba ìgbàgbọ́ rẹ àti àjọṣe tóo ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ó dà bí ẹni pé àwọn kan kì í fura sí ewu yìí. Wọ́n ń fàyè gba iyèméjì nípa fífi ebi nǹkan tẹ̀mí pa ara wọn. Ṣé kì í ṣe pé ìwọ náà ń ṣe báyẹn?
Iyèméjì—Ṣé Gbogbo Ìgbà Ló Ń Pani Lára?
Ká sọ tòótọ́, kì í ṣe gbogbo iyèméjì ló burú. Ìgbà mìíràn wà tí wàá lọ́ tìkọ̀ láti fara mọ́ ohun kan títí tóo fi máa wádìí rẹ̀ dájú. Ìsìn tó bá ń gbà ọ́ níyànjú pé kóo ṣáà gbà gbọ́, kóo má sì ṣe iyèméjì nípa nǹkan kan jẹ́ ewu, ẹ̀tàn sì ni. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Ó dájú pé Kristẹni kan tó nífẹ̀ẹ́ yóò múra tán láti gba àwọn èèyàn tó ṣeé fọkàn tán látilẹ̀wá gbọ́. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún kìlọ̀ fún wá pé kí a má ‘gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́.’ (Òwe 14:15) Ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé ìwà ẹnì kan látẹ̀yìnwá lè mú kó pọndandan láti fura sí onítọ̀hún. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Bí [ẹlẹ́tàn] tilẹ̀ mú ohùn rẹ̀ kún fún oore ọ̀fẹ́, má gbà á gbọ́.”—Òwe 26:24, 25.
Àpọ́sítélì Jòhánù náà tún kìlọ̀ fáwọn Kristẹni láti má ṣe gba nǹkan gbọ́ láìwádìí rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́.” Dípò ìyẹn, “ẹ dán àwọn 1 Jòhánù 4:1) “Àgbéjáde” kan, ìyẹn ẹ̀kọ́ tàbí èrò kan, lè dà bí èyí tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Àmọ́, ṣé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ti wá lóòótọ́? Níní iyèméjì, tàbí fífura lè jẹ́ ojúlówó ààbò nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ ọ́, “ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé.”—2 Jòhánù 7.
àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Iyèméjì Tí Kò Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀
Dájúdájú, àyẹ̀wò aláìṣàbòsí táa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe láti mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ sábà máa ń pọndandan. Àmọ́, èyí yàtọ̀ pátápátá sí fífàyè gba iyèméjì tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tó sì ń pani lára láti dìde nínú èrò inú àti ọkàn wa—ìyẹn iyèméjì tó lè ba ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ àti àjọṣe tímọ́tímọ́ jẹ́. A túmọ̀ iyèméjì yìí gẹ́gẹ́ bí “ìgbàgbọ́ tàbí èrò tí kò dáni lójú, èyí to sábà máa ń bẹ́gi dínà ṣíṣe ìpinnu.” Ǹjẹ́ o rántí bí Sátánì ṣe gbin iyèméjì nípa Jèhófà sínú Éfà? Ó béèrè pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1) Iyèméjì tí ìbéèrè tó dún bíi ti aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yẹn dá sílẹ̀ nípa lórí ìpinnu tí Éfà ṣe. Bí ọgbọ́n tí Sátánì ń dá ṣe rí gan-an nìyẹn. Bíi ti ẹni tó máa ń kọ lẹ́tà ìbanilórúkọjẹ́ ni òun náà ṣe jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú lílo ìfẹ̀sùnkanni, àti yíyí irọ́ pọ̀ mọ́ òtítọ́. Sátánì ti fi iyèméjì burúkú, tó ń gbìn síni lọ́kàn lọ́nà yìí, ba àárín ọ̀pọ̀ èèyàn tó fọkàn tán ara wọn jẹ́.—Gálátíà 5:7-9.
Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù, lóye ipa tí ń pani lára tí irú iyèméjì yìí lè ní lórí ẹni. Ó kọ̀wé nípa àǹfààní àgbàyanu táa ní láti tọ Ọlọ́run lọ fàlàlà kó lè ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò ìṣòro. Ṣùgbọ́n, Jákọ́bù kìlọ̀ pé, nígbà tóo bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá.” Ṣíṣe iyèméjì nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ń jẹ́ ká “dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì, tí a sì ń fẹ́ káàkiri.” A óò wá dà bí ‘aláìnípinnu èèyàn, tí kò dúró sójú kan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.’ (Jákọ́bù 1:6, 8) Ohun táa gbà gbọ́ kò tiẹ̀ ní wá dá wa lójú mọ́, èyí á sì sọ wá di aláìnípinnu. Lẹ́yìn náà, bó ṣe ṣẹlẹ̀ sí Éfà, á wá ṣòro fún wa láti kọ onírúurú ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ẹ̀mí èṣù.
Dídúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí
Báwo la ṣe máa wá dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ iyèméjì tí ń pani lára? Ìdáhùn rẹ̀ kò ṣòro rárá: nípa kíkọ ìgbékèéyíde Sátánì sílẹ̀ pátápátá, ká sì lo gbogbo ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe láti mú kí a ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’—1 Pétérù 5:8-10.
Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni fífi oúnjẹ tẹ̀mí tí ń ṣara lóore bọ́ ara ẹni. Ọ̀gbẹ́ni Wingate táa mẹ́nu kàn níṣàájú, ṣàlàyé pe: “Kódà nígbà tí ara bá ń sinmi pàápàá, ó nílò láti máa gba agbára láìdabọ̀ nítorí àwọn ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà inú ara àti nítorí iṣẹ́ tí àwọn ẹ̀yà ara pàtàkì ń ṣe; àti nítorí àwọn èròjà inú ọ̀pọ̀ iṣan ara tó nílò fífi òmíràn rọ́pò wọn ní gbogbo ìgbà.” Bákan náà ló ṣe rí pẹ̀lú ìlera wa nípa tẹ̀mí. Láìjẹ́ pé a ń bọ́ ara wa nípa tẹ̀mí déédéé, ìgbàgbọ́ wa yóò máa bà jẹ́ díẹ̀díẹ̀, yóò sì kú ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, bí ara tí a fi oúnjẹ dù. Jésù Kristi tẹnu mọ́ èyí nígbà tó sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—Mátíù 4:4.
Ronú nípa ìyẹn. Báwo la ṣe gbé ìgbàgbọ́ tó lágbára ró láti ìbẹ̀rẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Ohun tó ní lọ́kàn ni pé a kọ́kọ́ gbé ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa ró nínú Jèhófà, nínú àwọn ìlérí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ nípa fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ara wa. Àmọ́, kì í ṣe pé a kàn gbà gbogbo ohun tí wọ́n sọ fún wa gbọ́ láìronú lé e lórí o. A ṣe ohun táwọn tó ń gbé ní ìlú ńlá Bèróà ṣe. A ‘fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ láti mọ̀ dájú pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.’ (Ìṣe 17:11) A ‘ṣàwárí fúnra wa ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé,’ a sì rí i dájú pé òótọ́ ni ohun táa gbọ́. (Róòmù 12:2; 1 Tẹsalóníkà 5:21) Látìgbà yẹn la ti ń fún ìgbàgbọ́ wa lágbára báa ti túbọ̀ rí i kedere pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀ kò lè kùnà láé.—Jóṣúà 23:14; Aísáyà 55:10, 11.
Yẹra fún Ebi Nípa Tẹ̀mí
Wàyí o, ìpèníjà tó wà níbẹ̀ ni pé kí a di ìgbàgbọ́ wa mú ṣinṣin, kí a sì yẹra fún ṣíṣe iyèméjì, tó lè jin ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní nínú Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ lẹ́sẹ̀. Láti ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé, “ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan [tí wọ́n lè dà bí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára lákọ̀ọ́kọ́] yóò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1) Àwọn àsọjáde àti ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà wọ̀nyí ń gbin iyèméjì sọ́kàn àwọn kan, ó sì ń yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kí ló lè dáàbò bò wá? Ká máa bá a lọ láti jẹ́ ẹni “tí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́ àti ti ẹ̀kọ́ àtàtà tí [a] ti tẹ̀ lé pẹ́kípẹ́kí.”—1 Tímótì 4:6.
Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan lóde òní kọ̀ láti jẹ́ ẹni “tí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́”—kódà nígbà tí irú oúnjẹ afúnnilókun bẹ́ẹ̀ wà ní àrọ́wọ́tó wọn. Bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Òwe ṣe fi hàn, ó ṣeé ṣe kí oúnjẹ tó dáa nípa tẹ̀mí yí ẹnì kan ká, ìyẹn àsè nípa tẹ̀mí, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ kí onítọ̀hún kọ̀ láti jẹ oúnjẹ náà ní ti gidi.—Òwe 19:24; 26:15.
Èyí léwu gan-an. Ọ̀gbẹ́ni Wingate sọ pé: “Gbàrà tí ara bá ti bẹ̀rẹ̀ sí lo èròjà protein tó fi pa mọ́ sínú ara, ó ti ń di aláìlera nìyẹn.” Nígbà tí o kò bá rí oúnjẹ jẹ, ara rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn èròjà afáralókun tí gbogbo ara ní sí ìpamọ́. Nígbà tó bá lo gbogbo èyí tán, ara á wá bẹ̀rẹ̀ sí lo èròjà protein tó ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè àti àtúnṣe ara. Àwọn ẹ̀yà ara pàtàkì a bẹ̀rẹ̀ sí daṣẹ́ sílẹ̀. Kíákíá ni ara á bẹ̀rẹ̀ sí di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ nípa tẹ̀mí sí àwọn kán nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Wọ́n gbìyànjú láti lo ohun tí wọ́n tọ́jú pa mọ́ nípa tẹ̀mí tán pátá. Wọ́n lè ti pa ìdákẹ́kọ̀ọ́ tì, kí wọ́n sì di aláìlera nípa tẹ̀mí. (Hébérù 5:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ewu tó wà nínú ṣíṣe èyí nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé: “Ó pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.” Ó mọ bó ṣe rọrùn tó láti sú lọ sínú ìwà búburú bí a bá “ṣàìnáání ìgbàlà tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀.”—Hébérù 2:1, 3.
Ó yẹ fún àfiyèsí pé, kò pọndandan kí ẹni tí kò jẹunre kánú rí bí aláàárẹ̀ tàbí kí ó rù. Bákan náà, ó lè máà tètè hàn síta pé ẹnì kan ń fi ebi tẹ̀mí pa ara rẹ̀. O lè dà bí ẹni tí ara rẹ̀ le nípa tẹ̀mí, kódà nígbà tí o kò jẹ oúnjẹ aṣaralóore—àmọ́ fúngbà díẹ̀ nìyẹn ṣá o! Bópẹ́ bóyá, wàá di aláìlera nípa tẹ̀mí ṣáá ni, wàá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, yóò sì ṣòro fún ọ láti ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́. (Júúdà 3) Ìwọ fúnra rẹ mọ ibi tí ò ń fi nǹkan tẹ̀mí bọ́ ara rẹ dé, bí ẹlòmíì kò tiẹ̀ mọ̀.
Nítorí ìdí èyí, má ṣe pa ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ tì. Fi gbogbo agbára gbógun ti iyèméjì. Táa bá fojú di ohun tó dà bí àrùn tí kò fi bẹ́ẹ̀ le, táa ò bá lé iyèméjì tí ń dà wá láàmù dànù, ó lè yọrí sí jàǹbá ńlá. (2 Kọ́ríńtì 11:3) ‘Ṣé lóòótọ́ là ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? Ṣé gbogbo ohun tí Bíbélì wí lo lè gbà gbọ́? Ṣé ètò àjọ Jèhófà nìyí lóòótọ́?’ Sátánì yóò fẹ́ gbin irú iyèméjì wọ̀nyí sí ọ lọ́kàn. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ṣíṣàìka oúnjẹ tẹ̀mí sí sọ ọ́ di ìjẹ fún àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ rẹ̀. (Kólósè 2:4-7) Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táa fún Tímótì. Jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ “Ìwé Mímọ́” kí o lè “máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.”—2 Tímótì 3:13-15.
O lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣe èyí. Òǹkọ̀wé táa ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú ń bá a lọ ní sísọ pé: “Bí ẹnì kan bá fi ebi pa ara rẹ̀ gan-an, àwọn ẹ̀yà ara tó ń mú kí oúnjẹ dà yóò di èyí táa pa lára gan-an nítorí àìní èròjà fítámì àti àwọn nǹkan mìíràn tó pọndandan débi pé bí wọn bá tiẹ̀ rí oúnjẹ, kò ní lọ lẹ́nu wọn mọ́. Àwọn tó wà nírú ipò yìí lè fi àkókò díẹ̀ wà lórí jíjẹ kìkì oúnjẹ tí dídà rẹ̀ kò gba aápọn rárá.” Ó ń béèrè ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀ láti mú àwọn àkóbá tí àìjẹunre kánú ti ṣe fún ara kúrò. Bákan náà ni ẹnì kan tó ti pa ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ tì lè nílò ọ̀pọ̀ ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí kó tó lè di ẹni tí oúnjẹ tẹ̀mí tún ń wù ú jẹ. Tó bá jẹ́ pé ipò tóo wà nìyẹn, wá ìrànlọ́wọ́, kóo sì fi tayọ̀tayọ̀ gba ìrànwọ́ táa bá ṣe fún ọ kí ara rẹ lè kọ́fẹ nípa tẹ̀mí.— Jákọ́bù 5:14, 15.
Má Ṣe “Mikàn Nínú Àìnígbàgbọ́”
Táa bá gbé ipò tí baba ńlá náà, Ábúráhámù, wà yẹ̀ wò, àwọn kan lè ronú pé Ábúráhámù kò jẹ̀bi rárá tó bá ṣiyèméjì. Ó lè dà bí ohun tó bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí pé ‘kò sí ìrètí kankan fún un láti di baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mọ́’—bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀. Kí nìdí? Tóò, táa bá fojú ti ẹ̀dá ènìyàn wò ó, kò dà bí ẹni pé ìrètí wà. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé, ‘ó ronú nípa ara tirẹ̀, tí a ti sọ di òkú nísinsìnyí, àti kíkú ilé ọlẹ̀ Sárà pẹ̀lú.’ Síbẹ̀ ó kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí iyèméjì nípa Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀ ta gbòǹgbò nínú èrò inú àti ọkàn òun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò di aláìlera nínú ìgbàgbọ́,” bẹ́ẹ̀ ni “kò mikàn nínú àìnígbàgbọ́.” Ábúráhámù “gbà gbọ́ ní kíkún pé ohun tí [Ọlọ́run] ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.” (Róòmù 4:18-21) Ó ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́, tó gbámúṣé pẹ̀lú Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó yẹra pátápátá fún iyèméjì èyíkéyìí tó lè ba àjọṣe yẹn jẹ́.
O lè ṣe bákan náà tóo bá ń “di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera . . . mú”—ìyẹn, bí o bá ń bọ́ ara rẹ dáadáa nípa tẹ̀mí. (2 Tímótì 1:13) Má fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ewu tó wà nínú ṣíṣe iyèméjì. Ìjà tẹ̀mí táa lè pè ní ogun tí àwọn kòkòrò àrùn ń gbé koni ni Sátánì ń jà báyìí. Bí o bá pa jíjẹ oúnjẹ tó dára nípa tẹ̀mí táa ń rí nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti nípasẹ̀ lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni tì, èyí lè jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tètè bà ọ́. Lo àwọn ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè lọ́pọ̀ yanturu ní àkókò tó bá a mu wẹ́kú. (Mátíù 24:45) Máa bá a lọ láti “fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,” kí o sì jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 6:3; Títù 2:2) Má ṣe jẹ́ kí iyèméjì ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Báwo lo ṣe ń bọ́ ara rẹ dáadáa tó nípa tẹ̀mí?