Ìhìn Rere Àlàáfíà Dé Àwọn Ìlú Olókè ní Chiapas
Ìhìn Rere Àlàáfíà Dé Àwọn Ìlú Olókè ní Chiapas
“Nígbà tí ìpakúpa tó tíì burú jù lọ wáyé ní ìpínlẹ̀ Chiapas, àwọn ọkùnrin kan . . . tó dìhámọ́ra, tí wọ́n sì da nǹkan bojú pa àwọn mẹ̀kúnnù márùndínláàádọ́ta tí wọn kò ní ohun tí wọ́n fi lè gbèjà ara wọn, títí kan àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ mẹ́tàlá.” Bí ìwé ìròyìn “El Universal” ṣe sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Acteal, ní Ìpínlẹ̀ Chiapas ní December 22, 1997 nìyẹn.
CHIAPAS ni ìpínlẹ̀ tó tíì jìnnà jù lọ ní apá ìhà gúúsù ilẹ̀ Mẹ́síkò, ó sì pààlà pẹ̀lú ilẹ̀ Guatemala. Nítorí ipò òṣì àti àìní tó ti ń bá ilẹ̀ náà fínra láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ tàwọn ọmọ Íńdíà ní ilẹ̀ Maya ṣètò àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tó dìhámọ́ra ní January 1994, lábẹ́ àsíá Ọmọ Ogun Ajàjàgbara Orílẹ̀-Èdè ti Ejército Zapatista (EZLN). Wọ́n fi ọ̀rọ̀ bí aáwọ̀ náà á ṣe yanjú lọ́nà pẹ̀lẹ́tù falẹ̀. Bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn ọmọ ogun ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ara wọn tí wọ́n sì ń gbogun ti ara wọn, èyí yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ikú. Wàhálà náà mú kí ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù tó wà ní àgbègbè náà sá lọ síbi ààbò.
Láàárín irú àwọn ipò tí kò fini lọ́kàn balẹ̀ bí èyí, ẹgbẹ́ kan wà tó jẹ́ olùfẹ́ àlàáfíà, tí wọn kò dá sí ọ̀kankan nínú rògbòdìyàn òṣèlú náà. Tìtaratìtara ni wọ́n fi ń dárí àfiyèsí àwọn ènìyàn sí Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kanṣoṣo fún yíyanjú àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wọn ládùúgbò àti yíká ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Àwọn wo ni? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ní ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jésù, wọ́n ń tiraka láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ sí àwọn ibi tó jẹ́ àdádó jù lọ láwọn ìlú olókè ní Chiapas. (Mátíù 24:14) Báwo ni wíwàásù lábẹ́ irú àwọn ipò yẹn ṣe rí, kí sì ni àwọn ìyọrísí rẹ̀?
“Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Mi”
Adolfo, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde Ìjọba ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ rédíò lọ́jọ́ kan ní Ocosingo. Lójijì, ó gbọ́ tí wọ́n ń kan ilẹ̀kùn láti ìta. Làwọn ọkùnrin kan tó da nǹkan bojú bá já wọlé tí wọ́n sì na ìbọn wọn sí i lórí. Wọ́n rọ́ wọ yàrá tí wọ́n ti ń gbé ìròyìn sáfẹ́fẹ́, wọ́n bọ́ sídìí ẹ̀rọ náà, wọ́n sì kéde fáyé gbọ́ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìjọba jagun.
Àwọn ọkùnrin tó dìhámọ́ra náà yíjú sí Adolfo, wọ́n sì pàṣẹ fún un pé kó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Adolfo kò tíì ṣe batisí, ó dá wọn lóhùn pé: “Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.” Ó ṣàlàyé pé ìrètí kan ṣoṣo fún àlàáfíà ni Ìjọba Ọlọ́run, ó sì kọ̀ jálẹ̀, kò gba aṣọ àti ìbọn tí wọ́n kó fún un. Nígbà tí wọ́n rí i pé kò yẹsẹ̀ nínú ìpinnu rẹ̀, ni wọ́n bá fi sílẹ̀. Bí Adolfo ṣe ń rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn fún ìgbàgbọ́ mi lókun gan-an ni.”
Nígbà tó yá ipò nǹkan rọlẹ̀ díẹ̀, àmọ́ abẹ́ àkóso àwọn ológun ni àgbègbè yẹn ṣì wà. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn, tayọ̀tayọ̀ ni Adolfo fi gba ìkésíni àwọn alàgbà ìjọ àdúgbò náà láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwùjọ àdádó ti àwọn Kristẹni ní àgbègbè náà. Ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń yẹ ìwé wò lójú ọ̀nà tó ní láti gbà kọjá, àwọn
sójà bọ̀wọ̀ fún un nígbà tó fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣe batisí lẹ́yìn náà, ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ríran àwùjọ àdádó náà lọ́wọ́ láti di ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Adolfo sọ pé: Nísinsìnyí ti mo ti ṣe batisí, mo lè wá fi gbogbo ẹnu sọ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mi!”“Jèhófà Fún Wa Lókun”
Kété lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun EZLN kéde lórí rédíò pé àwọn ti ń bá ìjọba jagun, ni gbogbo àwọn ará ìlú ti fẹsẹ̀ fẹ. Francisco, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan tàbí aṣáájú ọ̀nà, ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe fún òun àtìyàwó òun lókun nínú ohun tí wọ́n ní láti là kọjá.
“A pinnu láti wa ibi ààbò ságbègbè kan tó jẹ́ ìrìn wákàtí mẹ́ta síbi táa wà. Ìjọ kan wà níbẹ̀, nítorí náà àá lè wà pẹ̀lú àwọn ará. Kò pẹ́ tí àkókò fi tó fún àpéjọ àyíká wa, èyí tí a ó ṣe ní Palenque. Èmi àtìyàwó mi kò fẹ́ pa àkànṣe ìpàdé fún àwọn aṣáájú ọ̀nà jẹ, àmọ́ a gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun EZLN ti gba ojú ọ̀nà tó lọ síbi àpéjọ náà kan. La bá pinnu láti gba inú ẹgàn já síbẹ̀, ìyẹn sì gbà wá ní wákàtí mẹ́sàn-án. Báa ṣe ń débẹ̀ ni ìpàdé àwọn aṣáájú ọ̀nà náà ń bẹ̀rẹ̀, a gbádùn ẹ̀ gan-an
ni, a sì tún gbádùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká náà pẹ̀lú.“Nígbà táa fi máa padà délé, a rí i pé wọ́n ti sun ilé wa, wọ́n sì ti jí àwọn ẹran ọ̀sìn wa kó lọ. Gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù kò ju kìkì àpò aṣọ kékeré kan lọ. Inú wa bàjẹ́ fún àwọn ohun táa pàdánù, àmọ́ àwọn ará tó wà ní Ocosingo fi tìfẹ́tìfẹ́ gbà wá sínú ilé wọn. Wọ́n tún kọ́ wa ní bí wọn ṣe ń ṣe àwọn nǹkan kan tó jẹ́ pé àwa táa jẹ́ àgbẹ̀ kò tíì ṣe rí láyé wa. Arákùnrin kan kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń ya fọ́tò, òmíràn sì kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń tún bàtà ṣe. Bó ṣe ṣeé ṣe fún èmi àtìyàwó mi láti lè gbọ́ bùkátà ara wa nìyẹn o títí di báa ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, tí kò sì sí pé a ń dáwọ́ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà dúró. Ní ríronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, a lè rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wa láti fara dà á, Jèhófà fún wa lókun.”
Èso Iṣẹ́ Ìwàásù
Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Ìpínlẹ̀ Chiapas kò jẹ́ kí ìyà àti ipò eléwu náà dí àwọn lọ́wọ́ nínú ìsapá àkànṣe tí wọ́n ń ṣe láti mú ìhìn rere náà tọ àwọn ènìyàn àgbègbè náà lọ. Fún àpẹẹrẹ, ní oṣù April àti May ọdún 1995, wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn jákèjádò ayé láti pín Ìròyìn Ìjọba No. 34, pẹ̀lú àkọlé tó báa mu wẹ́kú náà, Èé Ṣe Tí Ìgbésí-Ayé Fi Kún fún Ìṣòro Tó Bẹ́ẹ̀?
Ciro, tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé pàdé ìdílé kan tó fìfẹ́ hàn lásìkò táa ń pín ìwé náà ní ibì kan tí wọ́n ń pè ní Pueblo Nuevo. Bó ṣe padà dé lọ́jọ́ kẹta, ó ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ciro àti ẹni tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ padà lọ pé káwọn lọ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń bá ìdílé náà ṣe nìṣó, ọkùnrin tó ni ilé náà kò sí níbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwùjọ àwọn ọkùnrin kan tó da nǹkan bojú ni wọ́n bá tí wọ́n ń dúró de ọkùnrin náà láti ṣe é ní jàǹbá. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ Ciro àti ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé kí ni wọ́n ń wá, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ wọn pé pípa làwọn ó pa wọ́n. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà, àwọn Kristẹni méjì náà fi ìgboyà ṣàlàyé pé ńṣe làwọ́n wá láti kọ́ ìdílé náà ní Bíbélì. Nígbà táwọn ọkùnrin tó da nǹkan bojú yẹn gbọ́ bẹ́ẹ̀, ni wọ́n bá ní kí wọ́n máa lọ. Fún ìdí kan ṣá, ọkùnrin tó ni ilé náà kò padà wálé rárá lọ́jọ́ yẹn.
Lọ́jọ́ kan, ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ya Ciro lẹ́nu láti rí ọkùnrin náà lẹ́nu ọ̀nà rẹ̀. Inú Ciro mà dùn o láti gbọ́ pé gbogbo ìdílé náà ló ti ṣe batisí àti pé wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan ní Guatemala báyìí! Kódà, ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin wọn tiẹ̀ ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé.
Ìmọrírì fún Oúnjẹ Tẹ̀mí
Láìka ìṣòro tí kò dáwọ́ dúró ní Chiapas sí, alábòójútó àgbègbè kan ròyìn pé àwọn Ẹlẹ́rìí lágbègbè náà mọyì ìjẹ́pàtàkì pípàdé pọ̀ gidigidi. (Hébérù 10:24, 25) Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ àpéjọ àkànṣe kan tó wáyé láìpẹ́ yìí, èyí tí wọ́n ṣètò pé kó tètè bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ káwọn tó bá wá lè tètè padà sílé lójú mọmọ tí ààbò díẹ̀ ṣì wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló ní láti rin ìrìn tó ju wákàtí mẹ́ta lọ la aginjù já kí wọ́n tó lè dé ọ̀gangan ibi ìpàdé náà, nígbà tó máa fi di aago méje òwúrọ̀, gbogbo wọn ti wà lórí ìjókòó. Lára àwọn tó wà nínú àwùjọ náà ni, mẹ́fà lára àwọn mẹ́ńbà ọmọ ogun EZLN táwọn náà ń fetí sílẹ̀, tí wọ́n ń pàtẹ́wọ́, tó sì hàn kedere pé wọ́n ń gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Àwọn náà rin ìrìn wákàtí mẹ́ta láti lè wà ní àpéjọ náà. Ogún lára wọn tún wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi pẹ̀lú, èyí tí wọ́n ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ládùúgbò náà.
Ọ̀dọ́kùnrin mìíràn tóun náà tún wà lára àwọn adàlúrú, làwọn ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó lọ máa pààrà ẹgàn kan tó wà ládùúgbò ibì kan. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i pé gbogbo àwọn tó ń gbébẹ̀, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti sá lọ. Ló bá kúkú fìdí kalẹ̀ sínú ọ̀kan lára àwọn ilé tí wọ́n ti pa tì náà. Nígbà tí kò ríkan ṣèkan, ó mú díẹ̀ lára àwọn ìwé tó rí láyìíká ilé náà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kà wọ́n. Àwọn wọ̀nyí wá lọ jẹ́ ara àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà fi sílẹ̀. Níbi àdádó tó wà yìí, ọ̀dọ́kùnrin náà ní àkókò tí ó tó láti ronú lórí ohun tó ń kà. Ó pinnu pé òun máa yí ìgbésí ayé òun padà, òun ò sì ní gbé nǹkan ogun mọ́. Kíá ló wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín oṣù mẹ́fà, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà fáwọn ẹlòmíràn. Òun àtàwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀, táwọn náà ti fìgbà kan wà lára àwọn adàlúrú yẹn, ti wa di Kristẹni tó ti ṣe batisí báyìí.
Rírí Ohun Kan Tó Dára Níbẹ̀
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìnira gbáà ni rògbòdìyàn náà mú wá, ó dájú pé ó ní ipa tó dára lórí ìṣarasíhùwà tí àwọn ènìyàn ní sí iṣẹ́ ìwàásù náà. Alàgbà kan tó ń gbé ní ìlú tí wàhálà náà ti bẹ̀rẹ̀ gan-an ṣàlàyé pé: “Nǹkan bí ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn tí ìjà náà bẹ̀rẹ̀ ni a ti ṣètò fún iṣẹ́ ìwàásù, ní àárín ìlú àti lágbègbè rẹ̀. Àwọn ènìyàn ń hára gàgà láti tẹ́tí sí wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la fi sóde a sì tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan. Ládùúgbò kan, ọ̀pọ̀ ló ti máa ń ṣàtakò sí òtítọ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ nítorí gbọ́nmisi-omi-ò-to tó ń wáyé, wọ́n ti wá ń gbọ́ báyìí, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń wá sáwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ.”
Inú àwọn ará dùn pé ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá ìgbòkègbodò tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run lọ láìka àwọn ipò nǹkan tí kò fara rọ sí. Níwọ̀n bí àwọn ọmọ ogun ìjọba àtàwọn ọmọ ogun EZLN ti mọ̀ sí ìgbòkègbodò wọn, wọ́n ń báa nìṣó láti máa ṣe àwọn àpéjọ wọn, èyí tó ń fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tún ti jẹ́ èyí tí ń fúnni lókun láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ. Ó dùn mọ́ni pé, ńṣe ni ìṣírí tún ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tó ń kópa nínú rògbòdìyàn náà, tí wọ́n sì máa ń rọ àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́pọ̀ ìgbà pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àkókò ti ń lọ ni àwọn ìdánwò àti ìnira táwọn èèyàn ní Chiapas ní láti fara dà ń dín kù lọ́nà kan, síbẹ̀, wọn ò tíì parí. Àmọ́ láìfi ìyẹn pè, ohun kan dájú—àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pinnu láti máa bá ìsapá wọn nìṣó láti mú ìhìn rere àlàáfíà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì tọ àwọn ènìyàn lọ láìdáwọ́dúró. (Ìṣe 10:34-36; Éfésù 6:15) Wọ́n gbà pẹ̀lú ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àyàfi Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo níkàáwọ́ ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, ló lè yanjú àìṣòdodo àti ipò òṣì tó wà nínú ayé.—Mátíù 6:10.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìyawọlẹ̀ omi Mẹ́síkò
CHIAPAS
GUATEMALA
Òkun Pàsífíìkì
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn ìlú olókè ní Chiapas