“Ẹni Tí ó Kéré” Ti Di “Ẹgbẹ̀rún”
“Ẹni Tí ó Kéré” Ti Di “Ẹgbẹ̀rún”
“Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.”—AÍSÁYÀ 60:22.
1, 2. (a) Èé ṣe ti òkùnkùn fi bo ilẹ̀ ayé lónìí? (b) Báwo ni ìmọ́lẹ̀ Jèhófà ṣe túbọ̀ ń tàn sára àwọn ènìyàn rẹ̀?
“ÒKÙNKÙN pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò tàn sára rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lára rẹ.” (Aísáyà 60:2) Lọ́nà tó ṣe rẹ́gí, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣàpèjúwe bí ipò nǹkan ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé láti ọdún 1919 wá. Kirisẹ́ńdọ̀mù ti kọ̀ láti kọbiara sí àmì wíwàníhìn-ín Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹni tó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòhánù 8:12; Mátíù 24:3) Nítorí “ìbínú ńlá” Sátánì, olórí “àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí,” ọ̀rúndún ogún yìí ló burú jù lọ, tó sì tún jẹ́ èyí tí nǹkan tí bà jẹ́ jù lọ nínú ìtàn ìran ènìyàn. (Ìṣípayá 12:12; Éfésù 6:12) Àwọn ènìyàn tó pọ̀ jù lọ ló ń gbé nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí.
2 Síbẹ̀, ìmọ́lẹ̀ ṣì ń tàn lónìí. Jèhófà ‘ń tàn jáde’ sára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, tí wọ́n jẹ́ aṣojú lórí ilẹ̀ ayé fún “obìnrin” rẹ̀ ti òkè ọ̀run. (Aísáyà 60:1) Ní pàtàkì láti ìgbà tí a ti tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì ní ọdún 1919, làwọn wọ̀nyí ti ń fi ògo Ọlọ́run hàn, tí wọ́n sì ti jẹ́ ‘kí ìmọ́lẹ̀ wọn tàn níwájú àwọn ènìyàn.’ (Mátíù 5:16) Ní ọdún 1919 sí 1931, ìmọ́lẹ̀ Ìjọba túbọ̀ ń tàn yòò sí i bí àwọn wọ̀nyí ti ń já àwọn ìdè Bábílónì tó ṣẹ́ kù kúrò. Wọ́n pọ̀ sí i níye dórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá-mẹ́wàá bí Jèhófà ṣe ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Láìsí àní-àní, èmi yóò kó àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì jọpọ̀. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran, bí agbo ẹran ọ̀sìn láàárín pápá ìjẹko rẹ̀; ibẹ̀ yóò sì kún fún ariwo àwọn ènìyàn.” (Míkà 2:12) Ọdún 1931 ni ògo Jèhófà wá túbọ̀ hàn sí i lára àwọn ènìyàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísáyà 43:10, 12.
3. Báwo ló ṣe wá hàn kedere pé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà yóò tàn sára àwọn ẹlòmíràn yàtọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró?
3 Ṣé ara ìyókù “agbo kékeré” nìkan ni Jèhófà yóò tàn sí ni? (Lúùkù 12:32) Ó tì o. Ilé Ìṣọ́ September 1, 1931(Gẹ̀ẹ́sì), sọ nípa ẹgbẹ́ mìíràn. Nínú àlàyé kan tó gún régé tó ṣe lórí Ìsíkíẹ́lì 9:1-11, ó fi hàn pé ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé lọ́wọ́ tí a mẹ́nu kan nínú àwọn ẹsẹ yẹn ṣàpèjúwe ìyókù àwọn ẹni àmì òróró. Àwọn wo ni “ọkùnrin” yẹn sàmì sí níwájú orí? Àwọn “àgùntàn mìíràn” ni, àwọn tí wọ́n ní ìrètí gbígbé títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 10:16; Sáàmù 37:29) Ní ọdún 1935, a lóye pé ẹgbẹ́ “àgùntàn mìíràn” yìí ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran. (Ìṣípayá 7:9-14) Láti ọdún 1935 títí di ìsinsìnyí la ti ń darí àfiyèsí sí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà.
4. Àwọn wo ni “àwọn ọba” àti “àwọn orílẹ̀-èdè” tí a tọ́ka sí nínú Aísáyà 60:3?
4 Iṣẹ́ ìkójọ yìí ni a dọ́gbọ́n mẹ́nu kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nígbà tó sọ pé: “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.” (Aísáyà 60:3) “Àwọn ọba” wo là ń tọ́ka sí níhìn-ín? Ìyókù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni, àwọn tí wọ́n jẹ́ àjùmọ̀jogún Ìjọba ọ̀run pẹ̀lú Jésù Kristi, tí wọ́n sì ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà. (Róòmù 8:17; Ìṣípayá 12:17; 14:1) Lónìí, ìwọ̀nba ẹgbẹ̀rún díẹ̀ tó kù lára àwọn ẹni àmì òróró kéré níye gan-an lẹ́gbẹ̀ẹ́ “àwọn orílẹ̀-èdè,” ìyẹn ni àwọn tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jèhófà fún ìtọ́ni, tí wọ́n sì ń pe àwọn mìíràn láti wá ṣe ohun táwọn ń ṣe.—Aísáyà 2:3.
Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Tó Nítara
5. (a) Kókó wo ló fi hàn pé ìtara àwọn ènìyàn Jèhófà kò tíì dín kù? (b) Àwọn orílẹ̀-èdè wo ló ní ìbísí àrà ọ̀tọ̀ ní ọdún 1999? (Wo ṣáàtì tó wà ní ojú ìwé 17 sí 20.)
5 Ẹ wo irú ìtara tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní fi hàn jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé pákáǹleke ń pọ̀ sí i, síbẹ̀ ìtara wọn ò dín kù bí ọdún 2000 ti ń sún mọ́lé. Wọ́n ṣì ń mú àṣẹ Jésù yẹn lọ́kùn-únkúndùn pé: “Kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Iye àwọn akéde ìhìn rere náà tó ń ṣiṣẹ́ déédéé dé orí góńgó tuntun kan tó jẹ́ 5,912,492 ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kẹ́yìn nínú ọ̀rúndún ogún yìí. Wọ́n lo wákàtí tó jọni lójú, èyí tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ 1,144,566,849 láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀. Wọ́n ṣe ìpadàbẹ̀wò tí iye rẹ̀ jẹ́ 420,047,796 sọ́dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí wọ́n darí lọ́fẹ̀ẹ́ sì jẹ́ 4,433,884. Àgbàyanu iṣẹ́ ìsìn onítara mà lèyí o!
6. Ètò tuntun wo la ṣe fún àwọn aṣáájú ọ̀nà, ẹ̀mí wo sì làwọn èèyàn fi hàn?
6 Ní January ọdún tó kọjá, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso yí wákàtí tí a béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà padà. Ọ̀pọ̀ ló lo àǹfààní yìí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí ti olùrànlọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, láàárín oṣù mẹ́rin àkọ́kọ́ nínú ọdún 1999, iye ìwé ìforúkọsílẹ̀ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Netherlands gbà jẹ́ ìlọ́po mẹ́rin èyí tí wọ́n gbà ní àkókò kan náà lọ́dún tó ṣáájú. Gánà ròyìn pé: “Láti ìgbà tí àyípadà ti dé bá iye wákàtí tí à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà ni iye àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé wa ti ń lọ sókè ṣáá.” Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1999, iye àwọn aṣáájú ọ̀nà jákèjádò ayé dé orí 738,343—ìyẹn jẹ́ ọ̀nà àgbàyanu láti fi ‘ìtara fún iṣẹ́ àtàtà’ hàn.—Títù 2:14.
7. Báwo ni Jèhófà ti ṣe bù kún iṣẹ́ onítara tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń ṣe?
7 Ǹjẹ́ Jèhófà ti bù kún iṣẹ́ onítara yìí? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ó tipasẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Gbé ojú rẹ sókè yí ká, kí o sì wò! A ti kó gbogbo wọn jọpọ̀; wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ. Ibi jíjìnnàréré ni àwọn ọmọkùnrin rẹ ti ń bọ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ tí a óò tọ́jú ní ìhà rẹ.” (Aísáyà 60:4) Àwọn ẹni àmì òróró “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin” tí a ti kó jọ ṣì ń fìtara sin Ọlọ́run. Lákòókò tí a wà yìí sì rèé, a tún ti kó àwọn àgùntàn mìíràn ti Jésù jọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin” ẹni àmì òróró Jèhófà ní 234 ilẹ̀ àti àwọn erékúṣù òkun.
“Iṣẹ́ Rere Gbogbo”
8. Irú ‘iṣẹ́ rere’ wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi aápọn ṣe?
8 Ẹrù iṣẹ́ àwọn Kristẹni ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà àti láti ran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, wọ́n “gbára dì . . fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:17) Ìdí rèé tí wọ́n fi ń fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó ìdílé wọn, tí wọ́n ń ṣe aájò àlejò, tí wọ́n sì ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí ara wọn kò le. (1 Tímótì 5:8; Hébérù 13:16) Bẹ́ẹ̀ náà làwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tún ń kópa nínú àwọn iṣẹ́ mìíràn bíi kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—iṣẹ́ kan tó tún ń jẹ́rìí fáwọn ènìyàn. Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ gbọ̀ngàn kan tán ní Tógò, àwọn kan tó jẹ́ bí ọ̀gá lára àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìímẹ́mìí ládùúgbò náà fẹ́ mọ ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ ilé tiwọn fúnra wọn, tó sì jẹ́ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó kù ní láti háyà àwọn ènìyàn kí wọ́n tó lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Tógò ròyìn pé kíkọ́ irú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó jọjú bẹ́ẹ̀ ti ní ipa rere lórí àwọn aládùúgbò débi pé àwọn èèyàn kan tiẹ̀ ń gbìyànjú láti gba ilé sí àwọn àgbègbè tí a óò kọ́ àwọn gbọ̀ngàn sí, àwọn mìíràn sì fẹ́ wá kọ́lé tiwọn sí àgbègbè ibẹ̀.
9. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀?
9 Àwọn iṣẹ́ mìíràn tún máa ń yọjú nígbà mìíràn. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ni ìjábá ti ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, lọ́pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ́kọ́ máa ń wá ṣèrànwọ́. Fún àpẹẹrẹ, apá tó pọ̀ jù ní Honduras ni ìjì líle bà jẹ́ gan-an. Ojú ẹsẹ̀ ni ẹ̀ka tó wà níbẹ̀ gbé ìgbìmọ̀ pàjáwìrì dìde láti ṣètò fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Honduras àti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ mìíràn ló dá aṣọ, oúnjẹ, oògùn, àti àwọn ohun pàtàkì mìíràn jọ. Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn lo òye iṣẹ́ wọn láti tún àwọn ilé tó bà jẹ́ kọ́. Kò pẹ́ tí àwọn arákùnrin wa tí ìjábá náà dé bá fi rí ìrànwọ́ gbà tí wọ́n sì padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wọn tó wà ní Ecuador nígbà tí omíyalé tó lágbára ba àwọn ilé kan jẹ́ níbẹ̀. Lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ ìjọba kan wo ọ̀nà tí wọ́n gbà fọgbọ́n bójú tó ipò náà, ó sọ pé: “Ká ní pé mo ní irú àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́dọ̀ ni, máa ṣe bẹbẹ! Ó yẹ kí irú àwọn èèyàn bíi tiyín wà káàkiri ayé.” Irú iṣẹ́ rere bẹ́ẹ̀ ń fi ìyìn fún Jèhófà Ọlọ́run, ó sì tún jẹ́ ẹ̀rí pé a ní “ìfọkànsin Ọlọ́run [tó] ṣàǹfààní fún ohun gbogbo.”—1 Tímótì 4:8.
Wọ́n “Ń Fò Bọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Àwọsánmà”
10. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ẹni àmì òróró ń dín kù, èé ṣe tí orúkọ Jèhófà fi di èyí tí à ń polongo ju ti ìgbàkigbà rí lọ?
10 Jèhófà wá béèrè pé: “Ta ni ìwọ̀nyí tí ń fò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà, àti bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn? Nítorí pé èmi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa retí, àti àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́, láti lè kó àwọn ọmọ rẹ láti ibi jíjìnnàréré wá . . . Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yóò sì mọ àwọn ògiri rẹ ní ti tòótọ́, àwọn ọba wọn yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ.” (Aísáyà 60:8-10) Àwọn tó kọ́kọ́ dáhùn padà sí ‘títàn jáde’ Jèhófà ni àwọn “àwọn ọmọ” rẹ̀, ìyẹn ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” dé, ìyẹn ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí wọ́n ń fi ẹ̀mí ìdúróṣinṣin ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà darí wọn láti wàásù ìhìn rere náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ẹni àmì òróró ń dín kù, síbẹ̀ a ti polongo orúkọ Jèhófà ní gbogbo ayé ju ti ìgbàkigbà rí lọ.
11. (a) Kí ló ṣì ń tẹ̀ síwájú, kí sì ni àbájáde rẹ̀ lọ́dún 1999? (b) Àwọn orílẹ̀-èdè wo ló ní iye tó ta yọ jù lọ nínú àwọn tí a batisí ní 1999? (Wo ṣáàtì ojú ìwé 17 sí 20.)
11 Àbájáde rẹ̀ ni pé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ń fò “bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn,” tí wọ́n ń wá ààbò láàárín ìjọ Kristẹni. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ló ń dara pọ̀ lọ́dọọdún, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀nà ṣì tún ṣí sílẹ̀ fún púpọ̀ sí i. Aísáyà sọ pé: “Ní ti tòótọ́, a óò ṣí àwọn ẹnubodè rẹ sílẹ̀ nígbà gbogbo; a kì yóò tì wọ́n àní ní ọ̀sán tàbí ní òru, láti lè mú ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sọ́dọ̀ rẹ.” (Aísáyà 60:11) Ní èṣí, àwọn 323,439 ló fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà hàn nípa ṣíṣe batisí, síbẹ̀ kò tíì pa àwọn ẹnu ibodè náà dé. “Àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè,” ìyẹn ni àwọn mẹ́ńbà ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣì ń gbabẹ̀ wọlé. (Hágáì 2:7) Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fi òkùnkùn sílẹ̀ ni a kì í lé padà sẹ́yìn. (Jòhánù 12:46) Kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe sọ ìmọrírì tí wọ́n ní fún ìmọ́lẹ̀ náà nù láé!
Níní Ìgboyà Lójú Àtakò
12. Ọ̀nà wo làwọn tó nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn ti gbà láti paná ìmọ́lẹ̀ náà?
12 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn kórìíra ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. (Jòhánù 3:19) Àwọn kan tilẹ̀ fẹ́ pa iná ìmọ́lẹ̀ náà. Èyí ò yani lẹ́nu. Wọ́n fi Jésù pàápàá, tó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ń fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo onírúurú ènìyàn,” ṣẹ̀sín, wọ́n lòdì sí i, àwọn ará ìlú rẹ̀ sì wá pa á níkẹyìn. (Jòhánù 1:9) Jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí ni wọ́n ti fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣe ẹlẹ́yà, tí wọ́n ti fi wọ́n sẹ́wọ̀n, tí wọ́n fòfin dè wọ́n, wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n pàápàá, bí wọ́n ṣe ń fi tòótọ́tòótọ́ tan ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn alátakò ti bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láti tan irọ́ kálẹ̀ nípa àwọn tí ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run ń tàn lára wọn. Àwọn kan fẹ́ káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé eléwu èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń sọ pé ó yẹ kí a ká wọn lọ́wọ́ kò tàbí kí a fòfin dè wọ́n. Ǹjẹ́ àwọn alátakò bẹ́ẹ̀ ṣàṣeyọrí?
13. Kí ni fífi ọgbọ́n ṣàlàyé òtítọ́ nípa iṣẹ́ wa fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ti yọrí sí?
13 Rárá o. Ní àwọn ibi tó ti ṣeé ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lọ sí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí gan-an. Èyí ti wá yọrí sí, sísọ orúkọ Jèhófà di èyí tí a mọ̀ níbi gbogbo, nínú àwọn ìwé ìròyìn àti lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Èyí sì ti ní ipa rere lórí iṣẹ́ ìwàásù náà. Fún àpẹẹrẹ, ní Denmark, ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Ìdí tí ìgbàgbọ́ àwọn ará Denmark fi ń jó rẹ̀yìn.” Bí wọ́n ṣe fọ̀rọ̀ wá onírúurú àwọn aṣojú ẹ̀sìn lẹ́nu wò náà ni wọ́n ṣe fọ̀rọ̀ wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú lẹ́nu wò. Lẹ́yìn náà, obìnrin kan tó wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ pé: “Àwọn tó ní ẹ̀mí Ọlọ́run kò fara sin rárá.” Ó bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
14. Láìpẹ́, ìtìjú wo ni yóò bá àwọn alátakò wọ̀nyí?
14 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ni yóò takò àwọn nínú ayé yìí. (Jòhánù 17:14) Síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń fún wọn lókun, ó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ sì ni àwọn ọmọ àwọn tí ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́ yóò wá, ní títẹríba; gbogbo àwọn tí ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọ yóò sì tẹ̀ ba síbi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ gan-an, dájúdájú, wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú ńlá Jèhófà, Síónì tí í ṣe ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Aísáyà 60:14) Láìpẹ́, ìtìjú ńlá yóò bá àwọn alátakò wọ̀nyí, ìgbà yẹn ni wọn yóò wá mọ̀ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ làwọn ń bá jà. Ta ló wá lè borí irú ìjà bẹ́ẹ̀?
15. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu,” báwo sì ni èyí ṣe hàn nínú iṣẹ́ kíkọ́ni àti ti wíwàásù ìhìn rere tí wọ́n ń ṣe?
15 Jèhófà tún ṣèlérí mìíràn pé: “Ṣe ni èmi yóò tilẹ̀ sọ ọ́ di ohun ìyangàn fún àkókò tí ó lọ kánrin . . . Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò sì fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu, ìwọ yóò sì mu ọmú àwọn ọba; dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ni Olùgbàlà rẹ.” (Aísáyà 60:15, 16) Dájúdájú, Jèhófà ni Olùgbàlà àwọn ènìyàn rẹ̀. Bí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé e, wọn ó wà láàyè “fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Wọn ó sì “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu,” nípa lílo àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìlọsíwájú ìjọsìn tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, fífi ọgbọ́n lo kọ̀ǹpútà àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lórí ètò ìbánisọ̀rọ̀ ti mú kó rọrùn láti tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè mọ́kànlélọ́gọ́fà a sì ń tẹ Jí! jáde ní èdè méjìlélọ́gọ́ta nígbà kan náà pẹ̀lú ti Gẹ̀ẹ́sì. A ti ṣe ètò kan lórí kọ̀ǹpútà báyìí, èyí tó ń ṣèrànwọ́ láti mú kí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun di èyí tí a tú sí àwọn èdè tuntun, irú ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀ sì mú wa láyọ̀ gan-an. Nígbà tí a mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí a tú sí èdè Croat jáde ní ọdún 1999, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló da omi ayọ̀ lójú. Arákùnrin àgbàlagbà kan sọ pé: “Ó ti pẹ́ tí mo ti ń dúró de Bíbélì yìí. Mo lè wá kú báyìí!” Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a ti pín káàkiri, yálà lódindi tàbí lápá kan ní èdè mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n.
Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ìwà Rere Tó Ga
16, 17. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro, èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí a jẹ́ kí ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí Jèhófà ń lò máa darí wa? (b) Ìrírí wo ló fi hàn pé àwọn èwe lè yẹra fún ìbàjẹ́ ayé?
16 Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù kórìíra ìmọ́lẹ̀.” (Jòhánù 3:20) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó dúró nínú ìmọ́lẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí Jèhófà ń lò. Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Àti ní ti àwọn ènìyàn rẹ, gbogbo wọn yóò jẹ́ olódodo.” (Aísáyà 60:21a) Ó lè jẹ́ ohun tó ṣòro gan-an láti jẹ́ olódodo nínú ayé kan tí ìṣekúṣe, irọ́ pípa, ìwọra, àti ìgbéraga ti wọ́pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ilẹ̀ kan wà tí ètò ọrọ̀ ajé wọn ti bú rẹ́kẹ́, ó sì rọrùn láti kó sínú fífi torí-tọrùn lépa ọrọ̀ àlùmọ́nì níbẹ̀. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tímótì 6:9) Ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ ló mà jẹ́ o, nígbà tí ẹnì kan bá lọ fi gbogbo àkókò rẹ̀ fún òwò kan tó jẹ́ pé yóò mú kó fi àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ rúbọ, ìyẹn ni àwọn nǹkan bíi wíwà ní ìpàdé àwọn Kristẹni, iṣẹ́ ìsìn mímọ́, ìlànà ìwà rere, àti ẹrù iṣẹ́ ìdílé!
17 Ọ̀ràn jíjẹ́ olódodo tilẹ̀ lè wá nira fáwọn ọ̀dọ́, nígbà tí wọ́n bá ń rí ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúgbà wọn tó ń joògùn yó, tí wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe. Ní Suriname, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó rẹwà lọ bá ọmọbìnrin kan ní ilé ìwé, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni ọmọbìnrin yìí, ọmọkùnrin náà ní òun fẹ́ káwọn jọ máa ní àjọṣepọ̀. Ọmọbìnrin náà kọ̀, ó sì ṣàlàyé pé Bíbélì lòdì sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó. Ni àwọn ọmọbìnrin yòókù tí wọ́n jọ wà ní ilé ìwé bá dá yẹ̀yẹ́ ẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì gbìyànjú láti fagbára mú un láti yí èrò rẹ̀ padà, wọ́n sọ pé gbogbo obìnrin ló ń fẹ́ kí ọmọkùnrin yẹn bá àwọn sùn. Síbẹ̀, ọmọbìnrin yìí kò yí ìpinnu rẹ̀ padà. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà ni wọ́n yẹ ọmọkùnrin náà wò, tí wọ́n sì rí i pé ó ní àrùn éèdì lára lẹ́yìn èyí ni àìsàn dá a wólẹ̀. Inú ọmọbìnrin náà dùn pé òun ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kí a ‘ta kété sí àgbèrè.’ (Ìṣe 15:28, 29) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín wọn yangàn, ìyẹn ni àwọn tó dúró gbọn-in láti ṣe ohun tí ó tọ́. Ìgbàgbọ́ wọn àti ti àwọn òbí wọn ‘bu ẹwà kún’—orúkọ Jèhófà Ọlọ́run—ó sì bọlá fún un.—Aísáyà 60:21b.
Jèhófà Ti Mú Ìbísí Wá
18. (a) Kí ni ohun ńlá tí Jèhófà ti ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀? (b) Kí ló fí hàn pé ìbísi náà yóò máa bá a lọ, kí sì ni ìrètí ológo tó ń dúró de àwọn tó dúró nínú ìmọ́lẹ̀ náà?
18 Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ sára àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ń bù kún wọn, ó ń ṣamọ̀nà wọn, ó sì ń fún wọn lókun. Láàárín ọ̀rúndún ogún yìí, wọ́n ti rí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà náà pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísáyà 60:22) Ká sòótọ́, láti inú ìwọ̀nba kéréje tó wà ní ọdún 1919, “ẹni tí ó kéré” ti ju “ẹgbẹ̀rún” lọ. Ìbísi náà kò sì tíì dópin o! Ní èṣí, àwọn 14,088,751 ló wá síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Jésù. Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni kò tíì di Ẹlẹ́rìí ní ti gidi. Inú wa dùn pé wọ́n wá síbi ayẹyẹ pàtàkì yẹn, a sì tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n túbọ̀ máa rìn sún mọ́ ìmọ́lẹ̀ náà. Jèhófà ṣì ń tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ rokoṣo sára àwọn ènìyàn rẹ̀. Ilẹ̀kùn ètò àjọ rẹ̀ ṣì wà ní ṣíṣí sílẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti dúró sínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. Ẹ wo ìbùkún ńlá tí ìyẹn ń yọrí sí fún wa báyìí! Ẹ sì wo bí ìyẹn yóò ṣe fún wa láyọ̀ tó lọ́jọ́ iwájú, nígbà tí gbogbo ẹ̀dá bá ń fìyìn fún Jèhófà, tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú ògo rẹ̀ tó ń tàn yinrin!—Ìṣípayá 5:13, 14.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Àwọn wo ló fi ògo Jèhófà hàn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
• Kí ló fi hàn pé ìtara àwọn ènìyàn Jèhófà kò tíì dín kù?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí fún?
• Bí wọ́n tilẹ̀ ń ta kò wá, ìgbẹ́kẹ̀lé wo la ní?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 17-20]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1999 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ènìyàn ṣì ń rọ́ wá sínú ètò àjọ Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Inú wa dùn pé Jèhófà ṣì jẹ́ kí ilẹ̀kùn náà wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìmọ́lẹ̀