ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7
Jẹ́ Ọlọ́kàn Tútù Kó O Lè Múnú Jèhófà Dùn
“Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé . . . Ẹ wá ọkàn-tútù.”—SEF. 2:3.
ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa Mósè, kí ló sì ṣe? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá ká lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù?
BÍBÉLÌ sọ pé Mósè “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Núm. 12:3) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ọ̀lẹ ni Mósè àti pé kò lè dá ìpinnu ṣe, àbí pé ó máa ń bẹ̀rù táwọn míì bá ta kò ó? Àwọn kan máa ń ronú pé ojo lẹni tó bá lọ́kàn tútù, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Akínkanjú ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Mósè, ó sì fìgboyà gbé ìgbésẹ̀ nígbà tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti kojú ọba Íjíbítì tó jẹ́ alágbára. Yàtọ̀ síyẹn, ó darí àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n tó mílíọ̀nù mẹ́ta gba inú aginjù, ó sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn.
2 A lè má kojú àwọn ìṣòro tí Mósè kojú, àmọ́ ó dájú pé ojoojúmọ́ là ń kojú àwọn ipò tàbí àwọn èèyàn tó lè mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Síbẹ̀, Bíbélì sọ ìdí kan tó fi yẹ ká sapá láti ní ànímọ́ yìí. A rí ìdí yìí nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sm. 37:11) Ṣé o lè sọ pé ọlọ́kàn tútù ni ẹ́? Ṣé àwọn míì sì gbà pé lóòótọ́ lo jẹ́ ọlọ́kàn tútù? Ká tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yẹn, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI JẸ́ ỌLỌ́KÀN TÚTÙ
3-4. (a) Kí la lè fi ọkàn tútù wé? (b) Àwọn ànímọ́ mẹ́rin wo ló yẹ ká ní ká tó lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù, kí sì nìdí?
3 A lè fi ọkàn tútù * wé àwòrán mèremère kan. Lọ́nà wo? Bí ayàwòrán kan ṣe máa ń lo onírúurú àwọ̀ láti kun àwòrán kan kó bàa lè gbé ẹwà rẹ̀ yọ, bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ pàtàkì kan kó tó lè hàn pé a jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Lára àwọn ànímọ́ náà ni, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìtẹríba tàbí ìgbọràn, ìwà tútù àti ìgboyà. Kí nìdí táwọn ànímọ́ yìí fi ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn?
4 Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ló máa ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí lédè míì wọ́n máa ń ṣègbọràn sí i. Lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká jẹ́ onínú tútù. (Mát. 5:5; Gál. 5:23) Inú Sátánì kì í dùn rárá pé à ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, tá a bá tiẹ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá a sì jẹ́ onínú tútù, àwọn èèyàn inú ayé Sátánì ṣì máa kórìíra wa. (Jòh. 15:18, 19) Ìdí nìyẹn tá a fi nílò ìgboyà ká lè kojú Sátánì.
5-6. (a) Kí nìdí tí Sátánì fi kórìíra àwọn ọlọ́kàn tútù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
5 Àwọn tí kò bá lọ́kàn tútù máa ń gbéra ga, wọ́n máa ń bínú lódìlódì, wọn kì í sì í ṣègbọràn sí Jèhófà. Irú ẹni tí Sátánì jẹ́ gan-an nìyẹn, abájọ tó fi kórìíra àwọn ọlọ́kàn tútù. Ti pé ẹ̀dá èèyàn lè ní ọkàn tútù fi hàn pé ẹni burúkú ni Sátánì àti pé òpùrọ́ ni. Kí nìdí? Ìdí ni pé láìka ohun tí Sátánì ń sọ àtohun tó ń ṣe sí, àwọn ọlọ́kàn tútù kì í fi Jèhófà sílẹ̀.—Jóòbù 2:3-5.
6 Àwọn ìgbà wo ló máa ń ṣòro láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mósè, àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta náà àti Jésù.
ÌGBÀ TÓ MÁA Ń ṢÒRO LÁTI JẸ́ ỌLỌ́KÀN TÚTÙ
7-8. Kí ni Mósè ṣe nígbà táwọn míì sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa?
7 Tá a bá wà nípò àṣẹ: Ó lè ṣòro fáwọn tó wà nípò àṣẹ láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù tí ẹnì kan tó wà lábẹ́ wọn bá yájú sí wọn tàbí tí kò fara mọ́ ìpinnu tí wọ́n ṣe. Ṣé ẹnì kan tó kéré sí ẹ ti yájú sí ẹ rí? Tó bá jẹ́ inú ìdílé rẹ lẹnì kan ti ṣe bẹ́ẹ̀ sí ẹ, kí lo máa ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Mósè ṣe nígbà tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí i.
8 Jèhófà yan Mósè láti jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì mú kó ṣàkọsílẹ̀ àwọn òfin táá máa darí orílẹ̀-èdè náà. Kò sí àní-àní pé Jèhófà wà lẹ́yìn Mósè. Síbẹ̀, Míríámù àti Áárónì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa nítorí ìyàwó tó fẹ́. Ká sọ pé Núm. 12:1-13) Kí nìdí tí Mósè fi ṣe bẹ́ẹ̀?
àwọn míì nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, tí wọ́n sì wà nípò Mósè, wọ́n á bínú, wọ́n á sì fẹ́ gbẹ̀san. Àmọ́ Mósè ò ṣe bẹ́ẹ̀, kódà kò bínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló tún bẹ Jèhófà pé kó jọ̀ọ́ kó dẹ́kun ìyà tó fi ń jẹ Míríámù. (9-10. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni Jèhófà kọ́ Mósè? (b) Kí làwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà lè rí kọ́ lára Mósè?
9 Ohun tó mú kí Mósè lọ́kàn tútù ni pé ó jẹ́ kí Jèhófà dá òun lẹ́kọ̀ọ́ torí pé kì í ṣe ọlọ́kàn tútù látilẹ̀, ó sì máa ń tètè bínú. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ogójì (40) ọdún ṣáájú. Nígbà tá à ń sọ yìí, Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba Íjíbítì. Lọ́jọ́ kan, ó pa ọkùnrin kan tó kà sí aṣebi, ó sì ronú pé ó yẹ kí Jèhófà fọwọ́ sí ohun tóun ṣe. Òótọ́ ni pé Mósè ní ìgboyà, àmọ́ ó tún yẹ kó jẹ́ ọlọ́kàn tútù kó tó lè di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jèhófà dá a lẹ́kọ̀ọ́ fún ogójì (40) ọdún, kó lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù, kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì jẹ́ onígbọràn. Ó fi ẹ̀kọ́ náà sílò, ó sì di aṣáájú tàbí alábòójútó tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́.—Ẹ́kís. 2:11, 12; Ìṣe 7:21-30, 36.
10 Àpẹẹrẹ àtàtà ni Mósè jẹ́ fáwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà lónìí. Ẹ má tètè máa bínú táwọn míì bá yájú sí yín. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kẹ́ ẹ sì gbà pé ẹ̀yin náà máa ń ṣàṣìṣe. (Oníw. 7:9, 20) Bákan náà, ìlànà Jèhófà ni kẹ́ ẹ máa lò tẹ́ ẹ bá fẹ́ yanjú ìṣòro, kẹ́ ẹ sì máa fohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn míì sọ̀rọ̀. (Òwe 15:1) Tẹ́yin olórí ìdílé àtẹ̀yin alàgbà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà á dùn sí yín, ẹ̀ẹ́ mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé àti nínú ìjọ, ẹ̀ẹ́ sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn míì.
11-13. Àpẹẹrẹ wo làwọn Hébérù mẹ́ta náà fi lélẹ̀ fún wa?
11 Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa: Kì í ṣòní, kì í ṣàná làwọn aláṣẹ ti máa ń ṣe inúnibíni sáwa èèyàn Jèhófà. Onírúurú ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn wá, àmọ́ ohun tó ń bí wọn nínú ni pé a yàn láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Nígbà míì, wọ́n lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n lè fìyà burúkú jẹ wá. Àmọ́ lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, a ò ní gbẹ̀san, àá sì jẹ́ onínú tútù láìka ohun yòówù kí wọ́n ṣe sí wa.
12 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tí àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta ìyẹn Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà fi lélẹ̀ fún wa. * Ọba Bábílónì pàṣẹ pé kí wọ́n forí balẹ̀ fún ère wúrà tó gbé kalẹ̀. Àmọ́ wọ́n fohùn pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé ìdí táwọn ò fi ní jọ́sìn ère náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba halẹ̀ mọ́ wọn pé òun máa jù wọ́n sínú iná ìléru, síbẹ̀ wọ́n yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Wọ́n sọ pé àwọn á fara mọ́ ohunkóhun tí Jèhófà bá fàyè gbà. (Dán. 3:1, 8-28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tiẹ̀ retí pé kí Jèhófà gba àwọn sílẹ̀ lọ́nà ìyanu, ohun tí Jèhófà ṣe gan-an nìyẹn. Àpẹẹrẹ wọn jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó lọ́kàn tútù máa ń nígboyà. Torí náà, kò sí àṣẹ ọba, ìhàlẹ̀ tàbí ìyà tí wọ́n lè fi jẹ wọ́n táá mú kí wọ́n dẹ́kun àtimáa fún Jèhófà ní “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.”—Ẹ́kís. 20:4, 5.
13 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta yẹn nígbà táwọn míì bá fúngun mọ́ wa pé ká ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ Jèhófà? A gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 118:6, 7) Táwọn èèyàn bá fẹ̀sùn kàn wá, a máa ń fohùn pẹ̀lẹ́ dá wọn lóhùn, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. (1 Pét. 3:15) Bó ti wù kó rí, a kì í gbà kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni ba àjọṣe wa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run jẹ́.
14-15. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ní ìdààmú ọkàn? (b) Bí Aísáyà 53:7, 10 ṣe sọ, kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ ọlọ́kàn tútù lábẹ́ ipò tó nira?
14 Tá a bá ní ìdààmú ọkàn: Onírúurú nǹkan ló lè mú ká ní ìdààmú ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè ní ìdààmú ọkàn tá a bá fẹ́ ṣe ìdánwò nílé ìwé tàbí tá a bá ní iṣẹ́ ńlá kan tá a fẹ́ ṣe níbi iṣẹ́. A tún lè ní ìdààmú ọkàn tá a bá ń ṣàìsàn. Òótọ́ kan ni pé ó máa ń ṣòro láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù téèyàn bá ní ìdààmú ọkàn. Àwọn nǹkan kéékèèké tá a kì í kà sí tẹ́lẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í bí wa nínú. Láìmọ̀ọ́mọ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sáwọn míì tàbí ká tiẹ̀ máa kanra mọ́ wọn. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí la lè kọ́ lára Jésù?
15 Jésù ní ìdààmú ọkàn gan-an láwọn oṣù tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ó mọ̀ pé òun máa jìyà, wọ́n sì máa pa òun. (Jòh. 3:14, 15; Gál. 3:13) Ní oṣù díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, òun fúnra ẹ̀ sọ pé wàhálà ọkàn bá òun. (Lúùkù 12:50) Láwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù sọ pé: “Ọkàn mi dààmú.” Jésù wá gbàdúrà kan tó jẹ́ kó hàn kedere pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti pé ó ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó ní: “Baba, gbà mí là kúrò nínú wákàtí yìí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí nìyí tí mo fi wá sí wákàtí yìí. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” (Jòh. 12:27, 28) Nígbà táwọn ọ̀tá Ọlọ́run dé láti wá mú un, Jésù ò bẹ̀rù, ṣe ló jọ̀wọ́ ara ẹ̀ fún wọn. Àwọn ọ̀tá yìí fìyà jẹ ẹ́ gan-an, wọ́n sì pa á ní ìpa ìkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní ìdààmú ọkàn tí wọ́n sì fìyà burúkú jẹ ẹ́, ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìjanpata. Kò sí àní-àní pé Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ ọlọ́kàn tútù béèyàn tiẹ̀ ní ìdààmú ọkàn.—Ka Aísáyà 53:7, 10.
16-17. (a) Báwo làwọn ọ̀rẹ́ Jésù ṣe mú kó ṣòro fún un láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
16 Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ṣe ohun tó mú kó ṣòro fún un láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Ẹ ronú nípa ohun táá máa jà gùdù lọ́kàn rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ṣé ó máa jẹ́ olóòótọ́ títí dojú ikú? Ohun tó bá ṣe ló máa pinnu bóyá aráyé máa rí ìgbàlà tàbí wọn ò ní rí i. (Róòmù 5:18, 19) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ìpinnu tó bá ṣe lè sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ́ tàbí kó tàbùkù sí i. (Jóòbù 2:4) Nígbà tóun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ ń jẹun lálẹ́ ọjọ́ yẹn, “awuyewuye gbígbónájanjan kan” bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ “lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti tún èrò wọn ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà! Síbẹ̀, Jésù ò kanra mọ́ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀. Bó ti wù kó rí, Jésù ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó ṣàlàyé bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe síra wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣàlàyé fún wọn tẹ́lẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ló gbóríyìn fún wọn fún bí wọ́n ṣe dúró ti òun nígbà ìṣòro.—Lúùkù 22:24-28; Jòh. 13:1-5, 12-15.
17 Ká sọ pé ìwọ nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí lo máa ṣe? A lè fara wé Jésù, ká sì ṣe sùúrù kódà tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká fi tinútinú ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé ká “máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Kól. 3:13) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé gbogbo wa la máa ń ṣe ohun tó lè múnú bí àwọn míì, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa fara dà á fún ara wa. (Òwe 12:18; Ják. 3:2, 5) Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa gbóríyìn fáwọn míì nítorí àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní.—Éfé. 4:29.
ÌDÍ TÍ KÒ FI YẸ KÁ ṢÍWỌ́ ÀTIMÁA JẸ́ ỌLỌ́KÀN TÚTÙ
18. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn ọlọ́kàn tútù lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́, àmọ́ kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?
18 Àá ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. Tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù ká tó lè rí ìrànlọ́wọ́ náà gbà. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa tẹ́tí sí “ìfẹ́-ọkàn àwọn ọlọ́kàn tútù.” (Sm. 10:17) Yàtọ̀ sí pé ó máa ń tẹ́tí sí wa, Bíbélì tún ṣèlérí pé: “Òun yóò mú kí àwọn ọlọ́kàn tútù máa rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀, yóò sì kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.” (Sm. 25:9) Jèhófà máa ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a nílò nípasẹ̀ Bíbélì, àwọn ìwé wa, * fídíò àtàwọn nǹkan míì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń gbé jáde. (Mát. 24:45-47) Ká tó lè jàǹfààní látinú àwọn ìpèsè yìí, a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì gbà pé lóòótọ́ la nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. A tún gbọ́dọ̀ máa ka àwọn ìtẹ̀jáde yìí, ká sì máa fàwọn ohun tá a kọ́ níbẹ̀ sílò.
19-21. Àṣìṣe wo ni Mósè ṣe ní Kádéṣì, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
19 A ò ní ṣàṣìṣe táá mú ká pàdánù ojú rere Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká tún ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ ọlọ́kàn tútù tó sì ṣe ohun tó múnú Jèhófà dùn. Àmọ́ nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì (40) ọdún nínú aginjù, Mósè ṣi inú bí. Kò pẹ́ tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin kú tí wọ́n sì Núm. 20:1-5, 9-11.
sin ín sí Kádéṣì. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ó jọ pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yìí ló dá ẹ̀mí rẹ̀ sí nígbà tó wà lọ́mọdé. Àsìkò yẹn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé Mósè ò pèsè ohun táwọn nílò. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ń “bá Mósè ṣe aáwọ̀” torí pé kò sí omi tí wọ́n máa mu. Láìka gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà tipasẹ̀ Mósè ṣe àti bí Mósè ṣe fara ẹ̀ jìn fáwọn èèyàn náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ṣì ń ráhùn. Kì í ṣe torí omi nìkan, wọ́n tún ń ráhùn sí Mósè bíi pé òun ni ò jẹ́ kí wọ́n rómi mu.—20 Inú bí Mósè gan-an, èyí sì mú kó gbaná jẹ. Dípò kó ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kó bá àpáta náà sọ̀rọ̀, ṣe ló sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn èèyàn náà, ó sì gbógo fún ara rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ó lu àpáta náà lẹ́ẹ̀mejì, omi sì bú jáde. Ìgbéraga àti ìbínú ló mú kí Mósè ṣe àṣìṣe ńlá yẹn. (Sm. 106:32, 33) Torí pé Mósè ṣi inú bí fúngbà díẹ̀, Jèhófà ò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Núm. 20:12.
21 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ sapá ká lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù nígbà gbogbo. Tá a bá jẹ́ kí ànímọ́ yìí sọnù kódà fúngbà díẹ̀, ìgbéraga lè mú ká sọ̀rọ̀ tàbí ká ṣe ohun tá a máa pa dà kábàámọ̀. Ìkejì, ìdààmú ọkàn lè jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì, torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù kódà tá a bá ní ìdààmú ọkàn.
22-23. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa jẹ́ ọlọ́kàn tútù nìṣó? (b) Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sefanáyà 2:3?
22 Ó ń dáàbò bò wá. Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn èèyàn burúkú run, àwọn ọlọ́kàn tútù nìkan ló sì máa kù láyé, ìyẹn á wá mú kí àlàáfíà jọba. (Sm. 37:10, 11) Ṣé wàá wà lára àwọn ọlọ́kàn tútù tó máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé? O lè wà lára wọn tó o bá ṣe ohun tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Sefanáyà sọ.—Ka Sefanáyà 2:3.
23 Kí nìdí tí Sefanáyà 2:3 fi sọ pé: “Bóyá a lè pa yín mọ́”? Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà ò lágbára láti dáàbò bo àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó túmọ̀ sí ni pé tá a bá fẹ́ kí Jèhófà pa wá mọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa. A lè la “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” já, ká sì wà láàyè títí láé tá a bá jẹ́ ọlọ́kàn tútù nísinsìnyí, tá a sì ń ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sí.
ORIN 120 Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi
^ ìpínrọ̀ 5 Wọn ò bí ọkàn tútù mọ́ ẹnikẹ́ni, àfi kéèyàn kọ́ ọ. Ó lè rọrùn láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù tí nǹkan bá dà wá pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó lẹ́mìí àlàáfíà, àmọ́ ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn tó bá jẹ́ pé àwọn agbéraga la bá da nǹkan pọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tó yẹ ká borí ká tó lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù.
^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ọkàn tútù. Àwọn ọlọ́kàn tútù sábà máa ń jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, wọn kì í sì í fara ya kódà tí wọ́n bá múnú bí wọn. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í gbéra ga, wọ́n sì gbà pé àwọn míì sàn ju àwọn lọ. Tí Bíbélì bá sọ pé Jèhófà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ó máa ń fìfẹ́ bá àwọn tó rẹlẹ̀ sí i lò, ó sì máa ń ṣàánú wọn.
^ ìpínrọ̀ 12 Orúkọ táwọn ará Bábílónì fún àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta yẹn ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò.—Dán. 1:7.
^ ìpínrọ̀ 18 Bí àpẹẹrẹ, wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga,” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2011.
^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Dípò kí Jésù bínú, ṣe ló fi pẹ̀lẹ́tù tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ́nà nígbà tí wọ́n ń bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù lọ.