Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀

Àwọn Nǹkan Tó Lè Ṣẹlẹ̀

Àwọn Nǹkan Tó Lè Ṣẹlẹ̀

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé oríṣiríṣi ìpele ni ọ̀rọ̀ ṣíṣọ̀fọ̀ pín sí, ọ̀nà tó yàtọ̀ síra sì làwọn èèyàn máa ń gbà ṣòfọ̀. Àmọ́, ṣé ìyàtọ̀ tó wà nínú báwọn èèyàn ṣe ń ṣọ̀fọ̀ yìí wá fi hàn pé inú àwọn kan kì í bà jẹ́ púpọ̀ tí èèyàn wọn bá kú, àbí ńṣe ni wọ́n kàn ń pa ìbànújẹ́ náà mọ́ra? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé tí ẹnì kan bá fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ hàn nígbà tó ń ṣọ̀fọ̀, ó lè jẹ́ kí ara ẹ̀ tètè balẹ̀, àmọ́ kò sí ọ̀nà pàtó kan tá a lè sọ pé ó dára jù lọ láti gbà ṣọ̀fọ̀. Àwọn nǹkan tó máa ń fa ìyàtọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ni àṣà ìbílẹ̀, irú ẹni tí èèyàn jẹ́, ohun tójú èèyàn ti rí àtàwọn nǹkan tó tan mọ́ ikú ẹnì kan.

ÀWỌN NǸKAN WO LÓ LÈ ṢẸLẸ̀?

Àwọn tí èèyàn wọn kú lè má mọ àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú èèyàn wọn. Àmọ́, àwọn ìmọ̀lára àti ìṣòro kan wà tó sábà máa ń yọjú, tí èèyàn sì lè retí pé ó máa ṣẹlẹ̀. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó tẹ̀ lé e yìí:

Nǹkan lè máa tojú súni. Lára nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ ni ẹkún àsun-ùn-dá, kí àárò ẹni tó ti kú máa sọni gan-an, kí ìṣesí èèyàn máa ṣàdédé yí pa dà. Èèyàn tiẹ̀ lè máa rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí kó lá àwọn àlá tó máa ń dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Nígbà míì sì rèé, àyà rẹ á kọ́kọ́ já, wàá wá sọ pé kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Tiina rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tí ọkọ ẹ̀ Timo kú ikú òjijì. Ó ní: “Kò kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé nǹkan kan ṣẹlẹ̀. Ńṣe ni ojú mi dá wáí, mi ò tiẹ̀ lè sunkún rárá. Gbogbo nǹkan wá tojú sú mi débi pé mi ò kì í lè mí dáadáa nígbà míì. Ńṣe ló dà bíi pé àlá ni mò ń lá.”

Àìbalẹ̀ ọkàn, ìbínú àti dídá ara ẹni lẹ́bi. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ivan sọ pé: “Láwọn àkókò kan lẹ́yìn tí ọmọ wa Eric tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún [24] kú. Inú bí èmi àti Yolanda ìyàwó mi gan-an! Ẹnu yà wá gan-an, torí pé a mọ̀ pé a kì í ṣe oníbìínú ẹ̀dá. Nígbà tó yá, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ká ní a tún gbìyànjú díẹ̀ sí i ni bóyá ọmọ wa ò ní kú, bá a tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara wa lẹ́bi nìyẹn.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alejandro náà dá ara rẹ̀ lẹ́bi lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ kú lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́-pípẹ́ kan, ó ní: “Ohun tó kọ́kọ́ wá sí mi lọ́kàn ni pé tí Ọlọ́run bá lè gbà kí n máa jìyà tó báyìí, á jẹ́ pé èèyàn burúkú ni mí. Bó tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dùn mí nìyẹn pé mò ń dá Ọlọ́run lẹ́bi fún ohun tó ṣẹlẹ̀.” Kostas tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú náà sọ pé: “Nígbà míì, inú á máa bí mi sí Sophia fún bó ṣe kú. Tó bá tún yá, màá bẹ̀rẹ̀ sí dá ara mi lẹ́bi pé mò ń ronú bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, kì í ṣe ẹ̀bi tiẹ̀ náà.”

Èròkérò. Èèyàn lè máa ronú lódìlódì nígbà míì tàbí kó máa ro nǹkan tí kò bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tí èèyàn ẹ̀ kú lè máa ronú pé òun lè gbọ́ ohùn ẹni tó ti kú náà, òun lè fọwọ́ kàn án tàbí pé òun lè rí i. Ó sì lè ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀ tàbí láti rántí nǹkan. Tiina sọ pé: “Nígbà míì tí èmi àti ẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, màá kàn rí i pé ọkàn mi ò sí níbẹ̀ mọ́ rárá! Ńṣe ni ọkàn mi á máa ro tibí ro tọ̀hún nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí Timo tó kú. Ó máa ń tojú súni gan-an tí èèyàn ò bá lè pọkàn pọ̀.”

Èèyàn lè má fẹ́ dá sí ẹnikẹ́ni. Tẹ́nì kan bá ń ṣọ̀fọ̀ ikú èèyàn rẹ̀, ara onítọ̀hún lè má balẹ̀ tó bá wà láàárín àwọn èèyàn. Kostas sọ pé: “Tí mo bá wà láàárín àwọn tọkọtaya, mo máa ń rí ara mi bí ẹni tí kò wúlò. Tí mo bá tún wà láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya, mo máa ń rí i pé ọ̀rọ̀ wa ò jọra rárá.” Yolanda ìyàwó Ivan sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi láti wà pẹ̀lú àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro wọn, nígbà tó jẹ́ pé kékeré làwọn ìṣòro wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwa! Bákan náà, táwọn kan bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń ṣe dáadáa sí, mo máa ń bá wọn yọ̀ o, àmọ́ kì í rọrùn fún mi láti tẹ́tí sí wọn. Èmi àti ọkọ mi kúkú mọ̀ pé ọmọ wa ti kú, kò sì sóhun tá a lè ṣe sí i, àmọ́ a ò ṣe tán láti gbà bẹ́ẹ̀, ká sì fara balẹ̀.”

Àìlera. Àyípadà lè bá bó o ṣe ń jẹun, bó o ṣe tẹ̀wọ̀n tó àti bó o ṣe ń sùn tó. Aaron sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, ó ní: “Mi ò kì í rí oorun sùn. Ó ti ní àkókò kan tí oorun máa ń dá lójú mi ní gbogbo òru, tí màá sì máa ronú nípa ikú bàbá mi.”

Alejandro rántí pé òun ò tiẹ̀ lè ṣàlàyé bó ṣe ń ṣe òun rárá, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni dókítà ti ṣàyẹ̀wò mi tí wọ́n sì sọ pé kò sóhun tó ń ṣe mí. Mo fura pé ẹ̀dùn ọkàn tó bá mi nítorí ikú ìyàwó mi ni ò jẹ́ kí n gbádùn ara mi.” Nígbà tó yá, ara ẹ̀ wá balẹ̀. Síbẹ̀ náà, ó bọ́gbọ́n mu bí Alejandro ṣe lọ rí dókítà. Ìdí ni pé tí èèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀, àwọn nǹkan tó ń gbógun ti àìsàn nínú ara lè má ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, ó sì lè ti àwọn àìsàn kan tó tí wà nínú ara tẹ́lẹ̀ jáde tàbí kí àìsàn tí kò ṣeni tẹ̀lẹ́ wá bẹ̀rẹ̀.

Ó lè ṣòro láti ṣe àwọn nǹkan tó pọn dandan. Ivan sọ pé: “Lẹ́yìn ikú Eric, ó pọn dandan pé ká sọ fún tẹbí-tọ̀rẹ́, tó fi mọ́ ọ̀gá àti onílé rẹ̀. Àwọn ìwé òfin kan tún wà tó yẹ ká fọwọ́ sí. Ó tún yẹ ká yẹ àwọn ẹrù Eric wò. Gbogbo nǹkan yìí ló sì gba pé kéèyàn pọkàn pọ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé ìrònú wa ò já geere lákòókò yẹn, ara wa ò le dáadáa, a sì tún ní ẹ̀dùn ọkàn.”

Àmọ́ àwọn míì wà tó jẹ́ pé ìgbà tí nǹkan máa ń le jù fún wọn ni tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ pé èèyàn wọn tó ti kú yẹn ló máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tiina nìyẹn. Ó sọ pé: “Timo ló máa ń bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ báǹkì àti iṣẹ́ wa. Àmọ́, ó ti wá di iṣẹ́ mi báyìí, ńṣe ni ìyẹn sì tún wá mú kí nǹkan túbọ̀ tojú sú mi. Ṣé mo lè ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí láṣeyanjú ṣá?”

Tá a bá ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú, bí ìrònú èèyàn ò ṣe ní já geere àti àárẹ̀ tó máa ń múni, a máa gbà lóòótọ́ pé àkókò tí kò bára dé gbáà ni àkókò ọ̀fọ̀. Ká sòótọ́, kò rọrùn rárá láti fara da ìbànújẹ́ ńlá tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú, àmọ́ tí èèyàn bá ti mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀, ó lè mú káwọn tí èèyàn wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kú lè fara dà á. Ó yẹ ká tún fi sọ́kàn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìrírí gbogbo nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá ń ṣọ̀fọ̀. Bákan náà, ó lè tuni nínú láti mọ̀ pé kì í ṣe ohun tó ṣàjèjì tí èèyàn bá ní ẹ̀dùn ọ̀kan tó lágbára gan-an tí èèyàn ẹni bá kú.

ṢÉ MO ṢÌ LÈ LÁYỌ̀?

Ohun tó lè ṣẹlẹ̀: Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìbànújẹ́ ńlá tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú ṣì máa lọ sílẹ̀. Èyí ò túmọ̀ sí pé ẹ̀dùn ọkàn yẹn máa lọ pátápátá tàbí pé a máa gbàgbé èèyàn wa tó ti kú. Àmọ́, díẹ̀díẹ̀ ni ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára yẹn á máa lọ sílẹ̀. Irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀ tún lè pa dà wá láwọn ìgbà tá ò tiẹ̀ rò rárá tàbí kó jẹ́ láwọn àkókò ayẹyẹ ọdọọdún kan tá a máa ń ṣe pẹ̀lú èèyàn wa tó kú náà. Àmọ́, fún àwọn èèyàn tó pọ̀ jù, tó bá ti tó àkókò kan, wọ́n á ti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn dé ìwọ̀n àyè kan, tí wọ́n á sì máa bá àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ nìṣó bíi ti tẹ́lẹ̀. Èyí sábà máa ń rí bẹ́ẹ̀ tí tẹbí-tọ̀rẹ́ bá ṣe àwọn nǹkan pàtàkì láti dúró ti ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà.

Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó? Fún àwọn kan, ó pẹ́ tán, oṣù bíi mélòó kan. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ó máa ń tó ọdún kan tàbí ọdún méjì kí wọ́n tó rí i pé ara àwọn ti wá ń balẹ̀. Ní ti àwọn míì, ọgbẹ́ ọkàn wọn ṣì máa ń wà síbẹ̀ fún àkókò gígùn. a Alejandro sọ pé: “Ó tó nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí mo fi ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an.”

Máa ṣe sùúrù. Má ṣe kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn, má sì ṣe ohun tó ju agbára ẹ lọ. Fi sọ́kàn pé ìbànújẹ́ tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú kì í wà bẹ́ẹ̀ títí ayé. Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan kan wà tó o lè máa ṣe tó lè jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ lọ sílẹ̀, tí kò sì ní jẹ́ kó o ṣọ̀fọ̀ kọjá bó ṣe yẹ?

Kì í ṣe ohun tó ṣàjèjì tí èèyàn bá ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an tí èèyàn ẹni bá kú

a Àwọn èèyàn díẹ̀ kan wà tó jẹ́ pé ọgbẹ́ ọkàn wọn máa ń lágbára, ó sì máa ń pẹ́ gan-an débi tá a fi lè sọ pé ó ti kọjá bó ṣe yẹ. Ó ṣe pàtàkì pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ rí dókítà tó ń rí sí ìlera ọpọlọ, kí wọ́n lè gba ìtọ́jú tó yẹ.