Ẹ̀KỌ́ 4
Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé
KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI JẸ́ ẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ?
Ẹni tó bá ṣeé gbára lé jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ó máa ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún un, ó sì máa ń parí rẹ̀ lákòókò.
Àwọn ọmọdé náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí wọ́n ṣe lè dẹni tó ṣeé gbára lé láìka ọjọ́ orí wọn sí. Ìwé kan tó ń jẹ́ Parenting Without Borders sọ pé: “Tí ọmọ bá wà ní ọdún kan àti oṣù mẹ́ta, ohun táwọn òbí ẹ̀ bá sọ fún un ni á máa ṣe, àmọ́ láti ọmọ ọdún kan àtààbọ̀ lọ sókè, ohun tó bá rí táwọn òbí ẹ̀ ń ṣe lòun náà á máa ṣe. Torí náà, ọ̀pọ̀ òbí ló sábà máa ń gbé àwọn iṣẹ́ kan fáwọn ọmọ tó wà ní ọdún márùn-ún sí méje. Ó sì dùn mọ́ni láti rí i pé irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún wọn.”
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÉÈYÀN ṢEÉ GBÁRA LÉ?
Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń kúrò nílé kí wọ́n lè máa dá bójú tó ara wọn, àmọ́ wọ́n máa kó sínú ọ̀pọ̀ ìṣòro tí wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń fa ìṣòro yìí ni pé àwọn ọ̀dọ́ náà ò tíì mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, béèyàn ṣe ń bójú tó ilé àti béèyàn ṣe ń ṣètò ara ẹni dáadáa.
Torí náà, ohun tó máa ṣàǹfààní ni pé kó o kọ́ ọmọ ẹ ní ohun tó yẹ, kó lè ṣeé gbára lé. Ìwé náà, How to Raise an Adult sọ pé: “Kò yẹ kó jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n máa gbára lé títí di ọmọ ọdún méjìdínlógún, tí wọ́n á wá jáde nílé tán, tí wọn ò ní lè bójú tó ara wọn.”
BÍ ỌMỌ RẸ ṢE LÈ DẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ
Yan iṣẹ́ ilé fún wọn.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”—Òwe 14:23.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ló máa ń fẹ́ bá àwọn òbí wọn ṣiṣẹ́. Ó máa dáa kó o lo àǹfààní yẹn láti yan iṣẹ́ fún wọn nínú ilé, kó o lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.
Àwọn òbí kan kì í fẹ́ ṣe ohun tá a sọ yìí, èrò wọn ni pé ńṣe ni àwọn á mú ayé sú àwọn ọmọ táwọn bá tún gbé iṣẹ́ ilé fún wọn, torí pé iṣẹ́ ilé ìwé táwọn ọmọ ń ṣe ti pọ̀ jù.
Àmọ́, àwọn ọmọdé tó bá máa ń ṣiṣẹ́ ilé sábà máa ń ṣàṣeyọrí nílé ìwé torí pé ó ti mọ́ wọn lára láti máa ṣiṣẹ́ táwọn òbí wọn bá fún wọn kí wọ́n sì parí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìwé Parenting Without Borders sọ pé, “tá ò bá jẹ́ káwọn ọmọ wa máa ṣiṣẹ́ ilé nígbà tí wọ́n ṣì kéré, ó lè mú kí wọ́n rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan láti máa ṣiṣẹ́ ilé . . . Tó bá wá yá, wọ́n á máa retí pé káwọn míì máa ṣe gbogbo nǹkan fún wọn.”
Bí ìwé yẹn ṣe sọ, tá a bá jẹ́ káwọn ọmọ wa máa ṣe iṣẹ́ ilé déédéé, á mọ́ wọn lára láti máa ran àwọn míì lọ́wọ́ dípò kí wọ́n máa retí pé káwọn èèyàn máa bá wọn ṣe gbogbo nǹkan. Táwọn ọmọ bá ń ṣiṣẹ́ ilé, ó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn ń kópa pàtàkì nínú ìdílé àti pé ohun tó yẹ kí àwọn máa ṣe nìyẹn.
Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ohun tí wọ́n bá gbìn ni wọ́n máa ká.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.”—Òwe 19:20.
Tí ọmọ rẹ bá ṣàṣìṣe, bóyá ó ba nǹkan oní nǹkan jẹ́, má ṣe sọ pé ohun tó ṣe ò tó nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, kó tọrọ àforíjì tàbí kó tiẹ̀ gbìyànjú láti tún nǹkan yẹn ṣe.
Tó o bá kọ́ ọmọ rẹ láti máa gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi:
-
á jẹ́ olóòótọ́
-
kò ní máa di ẹ̀bi ru àwọn míì
-
kò ní máa ṣe àwáwí
-
á máa tọrọ àforíjì nígbà tó bá yẹ