Ẹ̀kọ́ Tó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa tún ayé yìí ṣe láìpẹ́. Ó máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, ó sì máa mú kí ayé yìí dùn-ún gbé fún wa. (Sáàmù 37:11) Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ṣe ohun tó sọ yìí? Bíbélì ló fi dá wa lójú, ó ní: “Ọlọ́run kì í ṣe èèyàn lásánlàsàn tó máa ń parọ́.” (Nọ́ńbà 23:19) Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe.
Ọlọ́run Máa Pa Àwọn Èèyàn Burúkú Run
“Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bíi koríko tí gbogbo àwọn aṣebi sì gbilẹ̀, kí wọ́n lè pa run títí láé ni.”—SÁÀMÙ 92:7.
Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ojoojúmọ́ ni ìwà burúkú ń gbilẹ̀ sí i. Kò sì yà wá lẹ́nu, torí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ ní 2 Tímótì 3:1-5 pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìwà àwọn èèyàn máa burú gan-an. Kí ni ọjọ́ ìkẹyìn yẹn? Ó jẹ́ ìgbà táwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run maa lò kẹ́yìn kí ìparun wọn tó dé. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn burúkú tó kọ̀ láti yí pa dà run. Àwọn èèyàn rere nìkan ló máa wá kù láyé, ìyẹn àwọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—Sáàmù 37:29.
Ọlọ́run Máa Pa Sátánì Run
‘Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà máa tẹ Sátánì rẹ́.’—RÓÒMÙ 16:20.
Tí Ọlọ́run bá ti pa àwọn èèyàn burúkú run, títí kan Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù, àlàáfíà á wá gbilẹ̀ ní gbogbo ayé. Ẹlẹ́dàá wa ṣèlérí pé: “Ẹnì kankan ò ní dẹ́rù bà [yín].”—Míkà 4:4.
Ọlọ́run Máa Mú Àìsàn àti Ikú Kúrò
“Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—ÌFIHÀN 21:3, 4.
A ò ní ṣàìsàn mọ́, a ò sì ní jìyà mọ́, torí Ọlọ́run máa tún gbogbo ohun tí Sátánì ti bà jẹ́ ṣe, ó sì máa fòpin sí gbogbo wàhálà tí Ádámù, Éfà àti àìpé ara wa dá sílẹ̀. Kódà, “ikú ò ní sí mọ́.” Àwọn èèyàn tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu ló máa wà láàyè títí láé. Àmọ́, ibo ni wọ́n á máa gbé?
Ọlọ́run Máa Sọ Ayé Di Párádísè
“Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.”—ÀÌSÁYÀ 35:1.
Tí Ọlọ́run bá ti pa àwọn èèyàn burúkú run, ayé yìí á di Párádísè! Ó máa lẹ́wà gan-an, oúnjẹ sì máa pọ̀ rẹpẹtẹ. (Sáàmù 72:16) Kò ní sí ìdọ̀tí nínú òkun, odò, àtàwọn adágún omi mọ́, gbogbo wọn á mọ́ lóló, àwọn ohun alààyè á sì kún inú wọn. Kódà, àwọn èèyàn ò tiẹ̀ ní rántí mọ́ pé ayé yìí ti bà jẹ́ nígbà kan rí! Àwọn èèyàn á máa gbé inú ilé tí wọ́n fọwọ́ ara wọn kọ́. Àìríjẹ àìrímu ò ní sí mọ́ láé, kò sì ní sí àìrílé gbé àti ipò òṣì mọ́.—Àìsáyà 65:21, 22.
Ọlọ́run Máa Jí Àwọn Tó Ti Kú Dìde
‘Àjíǹde yóò wà.’—ÌṢE 24:15.
Ṣó wù ẹ́ kó o tún pa dà rí àwọn èèyàn ẹ tó ti kú? Ọlọ́run Olódùmarè máa jí wọn dìde sínú Párádísè ní ayé yìí. Wàá dá wọn mọ̀, àwọn náà á sì dá ẹ mọ̀. Wo bínú ẹ á ṣe dùn tó lọ́jọ́ náà, táwọn náà á sì máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀! Àmọ́, kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ṣe ohun tó sọ yìí? Bíbélì ló mú kó dá wa lójú, torí ó sọ nípa àwọn ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà tó ti kú, àmọ́ tí wọ́n jíǹde, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn wọn. Ohun míì tó mú kó dá wa lójú ni pé ìṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn ni Jésù ti jí àwọn òkú dìde.—Lúùkù 8:49-56; Jòhánù 11:11-14, 38-44.