Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?

Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?

“Kò sẹ́ni tí ọkàn ẹ̀ balẹ̀ tán, àmọ́ ọkàn tèmi ò tiẹ̀ balẹ̀ rárá. Ìṣòro ńlá kan ṣoṣo kọ́ ló fà á, ọ̀pọ̀ nǹkan ni, lára ẹ̀ ni wàhálà ojoojúmọ́ àti bí mo ṣe ń fi ọ̀pọ̀ ọdún tọ́jú ọkọ mi tí ara rẹ̀ kò yá, tó sì tún ní àìsàn ọpọlọ.”​—Jill. a

“Ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ lọ, mo wá ń dá tọ́ àwọn ọmọ wa méjèèjì. Kò rọrùn rárá láti jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ. Iṣẹ́ tún bọ́ lọ́wọ́ mi, mi ò rówó gba àwọn ìwé ọkọ̀ mi, mi ò sì mọ ohun tí mo lè ṣe. Ìdààmú tó bá mi pọ̀ jù, mo mọ̀ pé kò dáa kí n pa ara mi, ni mo bá bẹ Ọlọ́run pé kó kúkú gbẹ̀mí mi.”​—Barry.

Bíi ti Jill àti Barry, ṣé nǹkan máa ń tojú sú ẹ, tí ọkàn ẹ kì í sì í balẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yìí máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, wọ́n á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wọ́n á tún sọ àwọn ohun tó sábà máa ń fa àìbalẹ̀ ọkàn àti àkóbá tó ń ṣe fúnni, wọ́n á sì tún sọ béèyàn ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà ìdààmú.

a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.