BÍ ÌṢÒRO NÁÀ ṢE MÁA YANJÚ PÁTÁPÁTÁ
Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé, ó sì máa mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ kárí ayé. Ọlọ́run ṣèlérí nínú Sáàmù 72:7 pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” máa wà. Àmọ́ ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé? Báwo ló ṣe máa ṣe é? Báwo sì ni o ṣe lè jàǹfààní nínú ìṣàkóso yẹn?
ÌGBÀ WO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO?
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì máa wáyé tó máa fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó para pọ̀ jẹ́ “àmì” náà ni ogun kárí ayé, ìyàn, àìsàn, ọ̀pọ̀ ìmìtìtì ilẹ̀, àti ìwà àìlófin tó máa gbòde kan.—Mátíù 24:3, 7, 12; Lúùkù 21:11; Ìṣípaya 6:2-8.
Àsọtẹ́lẹ̀ míì tún sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-4) Lóòótọ́, àwọn ìwà yìí ò ṣàjèjì sí wa, àmọ́ ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń peléke sí i báyìí.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ṣẹ láti ọdún 1914. Kódà, àwọn òpìtàn, àwọn àgbà òṣèlú, àti àwọn òǹkọ̀wé sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì yẹn ṣe mú kí ayé yí pa dà láti ọdún 1914. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Denmark kan tó ń jẹ́ Peter Munch sọ pé: “Ogun tó wáyé ní ọdún 1914 jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gbòógì kan tó yí ìtàn ìran ẹ̀dá èèyàn pa dà pátápátá. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn èèyàn ń gbé ní ìrọ̀rùn dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa sí i, . . . àmọ́ láti ọdún yẹn ni aráyé ti kàgbákò. Wàhálà, ìkórìíra àti ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú gbòde kan, kò sì sí ààbò mọ́.”
Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ kan ni pé ohun tó le ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀. Ó ṣe tán, adùn ní í gbẹ̀yìn ewúro. Torí pé ńṣe ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ń jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé. Jésù tún wá fi ìṣẹ̀lẹ̀ rere kan kún ara àmì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti dé. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Ìhìn rere yẹn ni lájorí ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù fún aráyé. Kódà, orúkọ ìwé ìròyìn wa tí àwọn èèyàn mọ̀ jù ni Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Ìwé yẹn sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé wa yìí.
BÁWO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN ṢE MÁA BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO?
Àwọn kókó pàtàkì mẹ́rin yìí máa ṣàlàyé:
-
Ìjọba yẹn kò ní yan èyíkéyìí lára àwọn olóṣèlú ayé yìí láti ṣàkóso.
-
Àwọn olóṣèlú ayé yìí kò ní fẹ́ gbà pé kí Ìjọba Ọlọ́run gba àkóso nítorí pé wọ́n á fẹ́ máa ṣàkóso lọ.—Sáàmù 2:2-9.
-
Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run pátápátá, á sì fòpin sí àkóso wọn lórí aráyé. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 19:17-21) Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣípayá 16:14, 16.
-
Gbogbo àwọn tó bá fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ló máa la Amágẹ́dọ́nì já, tí wọ́n á sì wọ inú ayé tuntun. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa là á já, àwọn sì ni Bíbélì pè ní “ogunlọ́gọ̀ ńlá.”—Ìṣípayá 7:9, 10, 13, 14.
BÁWO LO ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌṢÀKÓSO YẸN?
Ohun àkọ́kọ́ tó máa jẹ́ kéèyàn di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni pé kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù fi èyí hàn nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Tí àwọn èèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n sì sún mọ́ ọn, wọ́n máa rí àǹfààní tó pọ̀. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì péré lára àwọn àǹfààní náà: Àkọ́kọ́, wọ́n máa ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run. Ìdí sì ni pé wọ́n máa rí àwọn ohun tó máa jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ìjọba Ọlọ́run wà lóòótọ́, kò sì ní pẹ́ dé mọ́. (Hébérù 11:1) Ìkejì ni pé wọ́n á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wọn. Ìfẹ́ tí wọ́n bá ní fún Ọlọ́run á jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣègbọràn sí i látọkàn wá. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún aládùúgbò wọn máa jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe ohun tí Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”—Lúùkù 6:31.
Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa dà bíi bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ohun tó dáa jù lọ ló ń fẹ́ fún wa. Ó fẹ́ ká ní ohun tí Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́.” (1 Tímótì 6:19) “Ìyè tòótọ́” kọ́ là ń gbádùn láyé tá a wà yìí. Àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn ṣáà ń rọ́jú, wọn ò gbádùn ayé wọn rárá. Tó o bá fẹ́ mọ bí “ìyè tòótọ́” ṣe máa rí, wo díẹ̀ lára àwọn ohun àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà.