ÌJỌBA TÓ MÁA YANJÚ ÌṢÒRO NÁÀ
“Àlàáfíà Kì Yóò Lópin”
Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń rọ àwọn èèyàn kárí ayé pé kí wọ́n fìmọ̀ ṣọ̀kan láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ gbogbo aráàlú àti àyíká wa. Kí nìdí? Ọ̀gbẹ́ni Maher Nasser sọ ìdí rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn UN Chronicle pé: “Ojú ọjọ́ ń yí pa dà, ìwà ọ̀daràn ń pọ̀ sí i, ohun àmúṣọrọ̀ ò kárí, ìjà lọ́tùn-ún ìjà lósì, ọ̀pọ̀ èèyàn ń sá kúrò nílùú wọn nítorí àìfararọ, àwọn afẹ̀míṣòfò ń pa àwọn èèyàn nípakúpa, oríṣiríṣi àìsàn sì ń gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn. Ìṣòro tó kan gbogbo ayé sì ni àwọn nǹkan yìí.”
Àwọn kan tiẹ̀ ń sọ pé tí ìjọba kan ṣoṣo bá ń ṣàkóso gbogbo ayé, nǹkan máa yàtọ̀. Lára àwọn tó sọ bẹ́ẹ̀ ni onímọ̀ ọgbọ́n orí tó ń jẹ́ Dante (1265-1321) àti onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Physics tó ń jẹ́ Albert Einstein (1879-1955). Dante sọ pé tí ìjọba bá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ bó ṣe rí yìí, kò lè sí àlàáfíà láyé. Ó wá fi ọ̀rọ̀ Jésù Kristi kún un pé: ‘Ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run.’—Lúùkù 11:17.
Kété lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, nínú èyí tí wọ́n ti lo bọ́ńbù runlé-rùnnà méjì, Albert Einstein kọ lẹ́tà kan nínú ìwé ìròyìn sí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ó ní: “Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe láti ṣètò ààbò kárí ayé, kí wọ́n sì fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìjọba kan tó máa ṣàkóso kárí ayé lọ́nà tó bójú mu.”
Àmọ́, ṣé ó dá wa lójú pé àwọn olóṣèlú tó máa ṣàkóso nínú ìjọba bẹ́ẹ̀ máa lè darí àwọn èèyàn lọ́nà tó yẹ? Ṣé wọn ò ní ni àwọn èèyàn lára? Ṣé wọn ò sì ní hùwà ìbàjẹ́? Àbí, ṣé bí nǹkan ṣe rí lágbo òṣèlú náà ni á máa rí lọ tí àwọn olóṣèlú tuntun bá gba àkóso? Àwọn ìbéèrè yìí mú ká rántí ọ̀rọ̀ òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Lord Acton, tó sọ pé: “Agbára máa ń gun alágbára, tá a bá wá gbé gbogbo agbára lé ẹnì kan lọ́wọ́, gàràgàrà ni yóò máa gun onítọ̀hún.”
Kí ìran èèyàn tó lè gbádùn àlàáfíà tó wà pẹ́ títí, a gbọ́dò wà ní ìṣọ̀kan. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe é? Ṣé ó tiẹ̀ ṣeé ṣe? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe. Lọ́nà wo? Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ìjọba oníwà ìbàjẹ́ ayé yìí. Ó máa jẹ́ nípasẹ̀ ìjọba tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba yẹn máa fi hàn pé Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àti ọ̀run. Ìjọba wo nìyẹn? Bíbélì pè é ní “Ìjọba Ọlọ́run.”—Lúùkù 4:43.
“JẸ́ KÍ ÌJỌBA RẸ DÉ”
Nínú àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ . . . lórí ilẹ̀ ayé.” Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù ní lọ́kàn nínú àdúrà yẹn. (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe ìfẹ́ àwọn tí agbára ń gùn gàràgàrà tí wọn ò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ.
Bíbélì tún pe Ìjọba Ọlọ́run ní “ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 5:3) Kí nìdí? Ìdí ni pé Ìjọba yẹn á máa ṣàkóso ayé láti ọ̀run. Ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí. A ò ní máa san owó orí àti àwọn owó míì láti fi ti ìjọba yìí lẹ́yìn. Ẹ ò rí i pé ìtura gbáà lèyí máa jẹ́ fún àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba yẹn!
Jésù Kristi ni Ọlọ́run fún ní àṣẹ láti jẹ́ Ọba Ìjọba yẹn. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó ní:
-
“Ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. . . Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.”—Aísáyà 9:6, 7.
- “A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun. Agbára ìṣàkóso rẹ . . . kì yóò kọjá lọ.”—
-
“Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa [Ọlọ́run] àti ti Kristi rẹ̀.”—Ìṣípayá 11:15.
Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bí Jésù ṣe sọ nínú àdúrà tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lábẹ́ Ìjọba yìí, gbogbo èèyàn máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí ayé lẹ́wà kó sì dùn-ún gbé bó ṣe rí ní ìbẹ̀rẹ̀.
Pabanbarì rẹ̀ ni pé Ìjọba Ọlọ́run máa kọ́ gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ní ìlànà kan náà. Kò ní sí ìpínyà kankan. Aísáyà 11:9 sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí . . . nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”
Nígbà yẹn, ohun tí Ìparapọ̀ Orílè-èdè ti ń sapá tipẹ́tipẹ́ láti ṣe máa wá di ṣíṣe, ìyẹn ni pé gbogbo aráyé máa wà ní àlááfíà àti ìṣọ̀kan. Sáàmù 37:11 sọ pé àwọn èèyàn máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a ò ní máa gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìwà ọ̀daràn,” “ìbàyíkájẹ́,” “ìṣẹ́ àti òṣì,” àti “ogun” mọ́. Àmọ́ ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀? Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé? Báwo ló ṣe máa ṣe é? Báwo sì ni o ṣe lè jàǹfààní nínú ìṣàkóso yẹn? Jẹ́ ká gbé kókó yẹn yẹ̀ wò.