KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN WO LÓ Ń GBÉ NÍ Ọ̀RUN
Àwọn Ìran Tó Sọ Àwọn Tó Ń Gbé Ní Ọ̀run
Bíbélì sọ nípa àwọn ìran kan tó fani mọ́ra tó jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run. A rọ̀ ẹ́ pé kó o máa fọkàn bá wa lọ, bá a ṣe ń gbé wọn yẹ̀wò. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìran náà ló jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gidi. Síbẹ̀, èyí máa jẹ́ kó o lè fọkàn yàwòrán àwọn tó ń gbé ọ̀run, wà á sì tún mọ bí èyí ṣe kàn ẹ́.
JÈHÓFÀ NI ẸNI GÍGA JÙ LỌ
“Ìtẹ́ kan wà ní ipò rẹ̀ ní ọ̀run, ẹnì kan sì wà tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. Ẹni tí ó jókòó, ní ìrísí, sì dà bí òkúta jásípérì àti òkúta aláwọ̀ pupa tí ó ṣeyebíye, àti yí ká ìtẹ́ náà òṣùmàrè kan wà tí ó dà bí òkúta émírádì ní ìrísí.”—Ìṣípayá 4:2, 3.
“Ó sì ní ìtànyòò yí ká. Ohun kan wà tí ìrísí rẹ̀ dà bí ti òṣùmàrè tí ó lé sí ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ní ọjọ́ ọ̀yamùúmùú òjò. Bí ìrísí ìtànyòò náà ti rí nìyẹn yíká-yíká. Ìrísí ti ìrí ògo Jèhófà ni.”—Ìsíkíẹ́lì 1:27, 28.
Ìran tí àpọsítélì Jòhánù àti wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé ibi tó rẹwà lọ́nà tó kàmàmà ni Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ ń gbé. Ó ní àwọn nǹkan tá a lè fọkàn yàwòrán rẹ̀. Àwọn nǹkan bí òkúta iyebíye, òṣùmàrè àti ìtẹ́ ọba aláṣẹ. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ibi tó rẹwà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ni Jèhófà wà, ó tura, ó sì pa rọ́rọ́.
Àwọn àpèjúwe nípa ibi tí Ọlọ́run wà yìí bá ọ̀rọ̀ tí ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ mu, ó ní: “Nítorí pé Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi. Ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ. Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run pàápàá. Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú rẹ̀; okun àti ẹwà ń bẹ nínú ibùjọsìn rẹ̀.”—Sáàmù 96:4-6.
Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ, síbẹ̀ ó fẹ́ ká sún mọ́ òun nínú àdúrà, ó sì fi dá wa lójú pé òun máa gbọ́ tiwa. (Sáàmù 65:2) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sí tún ń tọ́jú wa débi tí àpọ́sítélì Jòhánù fi sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.
JÉSÙ WÀ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN
“[Sítéfánù ọmọ ẹ̀yìn Jésù], bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó sì wí pé: ‘Wò ó! Mo rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.’”—Ìṣe 7:55, 56.
Jésù ti kú ṣáájú kí Sítéfánù tó rí ìran yìí, ọ̀dọ̀ àwọn tó sì ṣokùnfà ikú rẹ̀ ni Sítéfánù wà, tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù. Ìran yìí jẹ́ ká rí i dájú pé Jésù wà láàyè, ó ti jíǹde, ó sì ti wà nípò gíga. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: Éfésù 1:20, 21.
“[Jèhófà] gbé [Jésù] dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ní àwọn ibi ọ̀run, lókè fíofío ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí nìkan, ṣùgbọ́n nínú èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.”—Yàtọ̀ sí pé Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ipò gíga ni Jésù wà, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù bìkítà fún àwa èèyàn bíi Jèhófà. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó mú àwọn aláàbọ̀ ara lára dá, ó sì jí òkú dìde. Bó tún ṣe kú láti fi ara rẹ̀ rúbọ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwa èèyàn dọ́kàn. (Éfésù 2:4, 5) Bí Jésù ṣe wà lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run fi hàn pé láìpẹ́, ó máa lo ipò ńlá tó wà yìí láti bù kún aráyé lọ́pọ̀ jaburata jákèjádò ayé.
ÀWỌN AŃGẸ́LÌ Ń ṢE ÌRÁNṢẸ́ FÚN ỌLỌ́RUN
“Mo [wòlíì Dáníẹ́lì] ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé [Jèhófà] sì jókòó. . . . Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.”—Dáníẹ́lì 7:9, 10.
Nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí nípa ọ̀run yìí, kì í ṣe ańgẹ́lì kan ṣoṣo ló rí, bí kò ṣe àwọn tí kò lóǹkà. Ìran àgbàyanu mà lèyí á jẹ́ o! Ẹni ògo tí a kò lè fojú rí làwọn ańgẹ́lì, wọ́n gbọ́n, wọ́n sì lágbára. Àwọn ni séráfù àti kérúbù. Ó lé ní ìgbà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé àádọ́ta [250] tí Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ańgẹ́lì.
Àwọn ańgẹ́lì kì í ṣe àwọn èèyàn tó ti gbé lórí ilẹ̀ ayé rí. Ọlọ́run ti dá àwọn ańgẹ́lì kó tó dá àwa èèyàn. Àwọn ańgẹ́lì wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá ayé, wọ́n ń wo bí nǹkan ṣe ń lọ, wọ́n sì ń pàtẹ́wọ́.—Jóòbù 38:4-7.
Ọ̀kan lára ọ̀nà tí àwọn ańgẹ́lì ń gba ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run ni pé wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí. (Mátíù 24:14) Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran nípa bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí, ó sì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣípayá 14:6) Àwọn ańgẹ́lì kì í bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ṣe nígbà kan sẹ́yìn, àmọ́ wọ́n máa ń darí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù sọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́.
SÁTÁNÌ Ń ṢI ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́NÀ
“Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì [Jésù Kristi] àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:7-9.
Àwọn ìgbà kan wà tí kò sí àlàáfíà lọ́run. Nígbà tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ dá àwọn èèyàn, ańgẹ́lì kan tó fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Nígbà tó yá, àwọn ańgẹ́lì míì dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti dìtẹ̀ sí Ọlọ́run, àwọn ló wá di àwọn ẹ̀mí èṣù. Ìwà ibi ló kún ọwọ́ wọn, wọ́n ń tako Jèhófà lójú méjèèjì, wọ́n sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Jèhófà.
Onírúurú ìwà ìbàjẹ́ ló kún ọwọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, wọ́n sì ya òdájú. Ọ̀tá àwa èèyàn ni wọ́n jẹ́, àwọn lò sì ń fa èyí tó pọ̀ jù lára ìyà tó ń jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì pa gbogbo ohun ọ̀sìn Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pa ọmọ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí Jóòbù bí, nípa mímú kí “ẹ̀fúùfù ńláǹlà” fẹ́ lu ilé tí wọ́n wà. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fi “oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.”—Jóòbù 1:7-19; 2:7.
Àmọ́, láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa Sátánì run. Látìgbà tí wọ́n ti lé e sí sàkáání ilẹ̀ ayé ló ti mọ̀ pé “àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Sátánì máa pa run láìpẹ́, ìròyìn ayọ̀ sì ni ìyẹn jẹ́ fún wa!
ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ MÁA LỌ SÍ Ọ̀RUN
“O [Jésù] sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.
Bí Ọlọ́run ṣe jí Jésù dìde láti orí ilẹ̀ ayé sí ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa jí ọ̀pọ̀ àwọn míì dìde sí ọ̀run. Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, . . . èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ Jòhánù 14:2, 3.
ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.”—Àwọn tó ń lọ sọ́run ń lọ síbẹ̀ fún ìdí kan ni. Wọ́n fẹ́ lọ bá Jésù ṣe Ìjọba tó máa ṣàkóso gbogbo aráyé, tí á sì mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún wa. Ìjọba yìí ni Jésù ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa gbàdúrà fún nínú àdúrà àwòkọ́ṣe, ó ní: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
OHUN TÍ WỌ́N FẸ́ LỌ ṢE NÍ Ọ̀RUN
“Mo [àpọ́sítélì Jòhánù] gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, . . . yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ìran yìí ń tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run, nígbà tí Jésù àtàwọn tó jíǹde látinú ayé á máa ṣàkóso, tí wọ́n á sì fòpin sí ìṣàkóso Sátánì. Àlááfíà máa wá gbilẹ̀ kárí ayé nínú Párádísè. Gbogbo ohun tó ń fa ìrora àti ìbànújẹ́ fún aráyé kò ní sí mọ́. Ikú pàápàá kò ní sí mọ́.
Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn tó ti kú, tí wọn kò sì ní jíǹde sí ọ̀run? Lọ́jọ́ iwájú, Ọlọ́run máa jí wọn dìde, wọ́n á sì wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Lúùkù 23:43.
Àwọn ìran yìí ti mú kó dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀, títí kan àwọn ańgẹ́lì olóòótọ́ àtàwọn tí Ọlọ́run rà láti ayé bìkítà fún wa gan-an, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ wọ́n lógún. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí wọ́n máa ṣe, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o lọ sí ìkànnì wa, www.jw.org/yo, kó o sì wa ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? jáde.