Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | SÁRÀ

Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”

Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”

Ó TI ṣe díẹ̀ tí Sárà ti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́, ẹ̀yìn sì ti ń ro ó, ó wá dìde dúró kó lè nàyìn díẹ̀, ó sì gbójú wo ọ̀ọ́kán. Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn náà ń ṣe ohun tí ọ̀gá wọn ní kí wọ́n ṣe, wọ́n sì ń fayọ̀ ṣe é. Sárà náà ò kẹ̀rẹ̀, torí pé òṣìṣẹ́ kára ni. Fọkàn yàwòrán bó ṣe ń wọ́ ọwọ́ rẹ̀, kí ara lè tù ú. Ó lé jẹ̀ pé aṣọ àgọ́ wọn tó ti fàya ló ń rán látàárọ̀, tó sì ti wá rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Ó ṣeé ṣe kí aṣọ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣá, torí pé ọjọ́ pẹ́ tí oòrùn àti òjò ti ń pa á, èyí sì lè mú kí Sára rántí pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá báyìí táwọn ti ń kó kiri. Oòrùn ti wọ̀, ilẹ̀ sì ti fẹ́ máa ṣú. Ojú rẹ̀ ni Ábúráhámù * ọkọ rẹ̀ ṣe jáde nílé láàárọ̀, torí náà ó ti ń retí rẹ̀, ó sì ń wo ọ̀nà ibi tó máa gbà yọ. Ó rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe rí i tí orí ọkọ rẹ̀ yọ ṣóńṣó láti orí òkè náà.

Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí tí Ábúráhámù kó ìdílé rẹ̀ kọjá Odò Yúfírétì, tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ Kénáánì. Sárà ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tinútinú bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí wọ́n ń lọ, àmọ́ ó mọ̀ pé ipa pàtàkì lòún máa kó nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọmọ kan tó máa di orílẹ̀-èdè ńlá. Ipa wo wá ni Sárà máa kó nínú ìlérí náà? Àgàn ni Sárà, ó sì ti lé lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] báyìí. Ó ṣeé ṣe kó tún máa ronú pé, ‘Báwo ni ìlérí Jèhófà ṣe máa ṣẹ nígbà tó jẹ́ pé èmi ni ìyàwó Ábúráhámù?’ Kò lè yà wá lẹ́nu tí ọ̀rọ̀ náà bá ń jẹ ẹ́ lọ́kàn tàbí tára rẹ̀ kò balẹ̀.

Àwa náà lè máa ronú nípa ìgbà táwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ. Nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣe sùúrù, pàápàá tá a bá ń retí ohun kan tá a nífẹ̀ẹ́ sí i gan-an. Kí la lè rí kọ́ nínú ìgbàgbọ́ obìnrin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí?

“JÈHÓFÀ TI SÉ MI MỌ́”

Ìdílé yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ pa dà dé láti ilẹ̀ Íjíbítì ni. (Jẹ́nẹ́sísì 13:​1-4) Wọ́n wá pàgọ́ sí òkè kan tí wọ́n ń pè ní Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn ibi táwọn ará Kénáánì ń pè ní Lúsì. Láti orí òkè yìí, ó ṣeé ṣe kí Sárà máa wo Ilẹ̀ Ìlérí tó fẹ̀ lọ salalu. Ó tún máa rí àwọn abúlé tó wà nílẹ̀ Kénáánì àtàwọn ọ̀nà táwọn arìnrìn-àjò ń gbà lọ sáwọn ilẹ̀ tó jìnnà gan-an. Síbẹ̀, kò sí ibì kankan tó dà bí ìlú tí wọ́n bí Sárà sí nínú gbogbo ẹ̀. Ìlú Úrì ló dàgbà sí, ìyẹn ìlú kan lágbègbè Mesopotámíà tó jẹ́ ìrìn àjò nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì kìlómítà [1,900] síbi tí wọ́n wà. Ó fi ọ̀pọ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀ àtàwọn nǹkan amáyédẹrùn tó máa ń wà láàárín ìgboro, títí kan àwọn ọjà ńláńlá. Ó tún fi ilé tó tura tó ní òrùlé àti ògiri tó lágbára àti omi ẹ̀rọ sílẹ̀! Ǹjẹ́ o rò pé Sárà á máa banú jẹ́, táá sì máa wù ú lójú méjèèjì pé kó pa dà sí ìlú tó láwọn nǹkan amáyédẹrùn tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà yìí? Tá a bá rò bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé a ò tíì mọ obìnrin tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run yìí dáadáa nìyẹn.

Gbọ́ ohun tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ nípa obìnrin yìí ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún lẹ́yìn náà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ Ábúráhámù àti Sárà, ó ní: “Bí wọ́n bá ti ń bá a nìṣó ní tòótọ́ ní rírántí ibi tí wọ́n ti jáde lọ, àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti padà.” (Hébérù 11:​8, 11, 15) Kò sẹ́nì kankan nínú àwọn méjèèjì tó ronú pé òun fẹ́ pa dà sílé. Ká ní wọ́n ronú bẹ́ẹ̀ ni, wọn ì bá ti pinnu láti pa dà sílé. Ká sì ní wọ́n pa dà sílùú Úrì ni, wọn ò bá pàdánù àǹfààní tí Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí wọn. Ó sì dájú pé, kò sẹ́ni tó máa rántí wọn mọ́, àmọ́ ní báyìí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.

Dípò tí Sárà á fi máa ronú ohun tó fi sílẹ̀, ọjọ́ iwájú ló ń rò. Ìdí nìyẹn tó fi ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń kó káàkiri. Ó máa ń ṣèrànwọ́ láti tú àgọ́, tí wọ́n á sì tún lọ pàgọ́ sí ibòmíì. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn kiri. Ó tún fara da àwọn ìṣòro àti àyípadà míì. Jèhófà tún ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù sọ, síbẹ̀ kò sọ̀rọ̀ nípa Sárà!​—Jẹ́nẹ́sísì 13:​14-17; 15:​5-7.

Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Sárà pinnu láti sọ àbá kan tó ti ń wá sí i lọ́kàn tipẹ́ fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀. Fọkàn yàwòrán bí ojú rẹ̀ ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tó fẹ́ sọ̀rọ̀, ó ní: “Wàyí o, jọ̀wọ́! Jèhófà ti sé mi mọ́ kúrò nínú bíbímọ.” Ó wá sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kó fi ìránṣẹ́bìnrin òun, ìyẹn Hágárì ṣe aya, kó lè bímọ fún un. Ṣé ẹ mọ bó ṣe máa rí lára Sárà bó ṣe ń sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kó fẹ́ ìyàwó míì? Lójú wa, ó lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe, àmọ́ kì í ṣe ohun àjèjì láyé ìgbà yẹn pé kí ọkùnrin fẹ́ ìyàwó kejì, tàbí pé kó ní àlè, kó báa lè bí ọmọ. * Ṣé ó lè jẹ́ pé Sárà ń ronú pé ọ̀nà yìí ni ìlérí Ọlọ́run máa gbà ṣẹ pé àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù máa di orílẹ̀-èdè ńlá?Ohun yòówù kó wà lọ́kàn rẹ̀, ohun tá a mọ̀ ni pé ó múra tán láti yááfì ohun kan. Kí ni Ábúráhámù sọ? Bíbélì sọ pé: “[Ábúráhámù] fetí sí ohùn [Sárà].”​—Jẹ́nẹ́sísì 16:​1-3.

Ǹjẹ́ ibi kankan wà tó sọ pé Jèhófà ló mú kí Sárà dá àbá yẹn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, a rí i pé ojú èèyàn ni Sárà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Ohun tó rò ni pé Ọlọ́run ló fa àwọn ìṣòro tí òun ní àti pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan mọ́ fún òun. Àmọ́ ojútùú tí òun alára mú wá máa kó ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn bá a. Síbẹ̀, àbá tó mú wá fi hàn pé kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan. Nínú ayé tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ro ti ẹlòmíì mọ tiwọn, àmọ́ irú ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan tí Sárà ní yìí wúni lórí gan-an. Tí àwa náà bá fi ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣáájú, tá a sì yẹra fún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, àpẹẹrẹ Sárà là ń tẹ̀ lé yẹn.

“O RẸ́RÌN-ÍN NÍ TÒÓTỌ́”

Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Hágárì lóyún fún Ábúráhámù. Ó ṣeé ṣe kí Hágárì máa ronú pé oyún tí òun ní tí wá mú kóun ṣe pàtàkì ju Sárà lọ, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ Sárà tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ nílẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí dun Sárà tí kò rọ́mọ bí gan-an! Ábúráhámù wá fún Sárà láṣẹ láti fún Hágárì ní ìbáwí tó yẹ, Ọlọ́run sì fọwọ́ sí i. Nígbà tó yá, Hágárì bí ọmọkùnrin kan, ìyẹn Íṣímáẹ́lì, ọ̀pọ̀ ọdún sì kọjá lẹ́yìn náà. (Jẹ́nẹ́sísì 16:​4-9, 16) Ìtàn fi hàn pé nígbà tí Jèhófà tún bá wọn sọ̀rọ̀, Sárà ti di ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89], Ábúráhámù sì ti dẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99]. Ọ̀rọ̀ pàtàkì sì ni Ọlọ́run bá wọn sọ!

Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé òun máa sọ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di púpọ̀. Ọlọ́run tún wá yí orúkọ rẹ̀ pa dà. Títí fi di àkókò tí Ọlọ́run yí orúkọ rẹ̀ pa dà yẹn Ábúrámù lorúkọ tó ń jẹ́. Àmọ́, Jèhófà fún un lórúkọ míì, ìyẹn Ábúráhámù, tó túmọ̀ sí “Baba Ogunlọ́gọ̀.” Ní báyìí, fún ìgbà àkọ́kọ́, Jèhófà sọ ipa tí Sárà máa kó nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Ó yí orúkọ rẹ̀ pa dà láti Sáráì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àríyànjiyàn.” Ó wá pè é ní Sárà, ìyẹn orúkọ tá a wá mọ̀ dáadáa. Kí ni Sárà túmọ̀ sí? “Ìyá Ọba”! Jèhófà sọ ìdí tó fi fún obìnrin àtàtà yìí lórúkọ yẹn, ó ní: “Èmi yóò sì bù kún un, èmi yóò sì tún fi ọmọkùnrin kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; èmi yóò sì bù kún un, òun ó sì di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn ènìyàn yóò sì wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”​—Jẹ́nẹ́sísì 17:​5, 15, 16.

Májẹ̀mú tí Jèhófà dá pé òun máa mú irú ọmọ kan wá máa ní ìmúṣẹ nípasẹ̀ ọmọ tí Sárà máa bí! Ọlọ́run ní kí wọ́n sọ ọmọ náà ní Ísákì, tó túmọ̀ sí “Ẹ̀rín.” Nígbà tí Ábúráhámù gbọ́ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé Sárà máa bí ọmọ tiẹ̀, ńṣe ló “dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:17) Ọ̀rọ̀ náà yà á lẹ́nu, ayọ̀ rẹ̀ sì kún. (Róòmù 4:​19, 20) Sárá wá ńkọ́, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀?

Kò tíì pẹ́ tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ àlejò dé sí àgọ́ Ábúráhámù. Ọ̀sán gangan ni wọ́n dé, àmọ́ kíá làwọn tọkọtaya àgbàlagbà yìí dìde láti ṣaájò wọn. Ábúráhámù sọ fún Sárà pé: “Ṣe wéré! Pèsè òṣùwọ̀n séà mẹ́ta ìyẹ̀fun kíkúnná, po àpòrọ́ kí o sì ṣe àwọn àkàrà ribiti.” Iṣẹ́ ńlá ni gbígbà àlejò nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Àmọ́, Ábúráhámù kò dá iṣẹ́ náà dá ìyàwó rẹ̀; ó yára lọ pa màlúù kan, ó sì pèsè oúnjẹ àtàwọn ohun mímu. (Jẹ́nẹ́sísì 18:​1-8) Àṣé áńgẹ́lì Jèhófà làwọn “ọkùnrin” yẹn! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ má gbàgbé aájò àlejò, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀, àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” (Hébérù 13:2) Ṣé ìwọ náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí aájò àlejò tí Ábúráhámù àti Sárà fi lélẹ̀?

Sárà fẹ́ràn kó máa ṣàwọn èèyàn lálejò

Inú àgọ́ lọ́hùn-ún ni Sárà wà nígbà tí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì náà tún ìlérí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé Sárà máa bí ọmọkùnrin kan, àmọ́ ó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Sárà ò lè mú ọ̀rọ̀ náà mọ́ra torí pé ó ṣàjèjì lójú rẹ̀, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ara rẹ̀ rẹ́rìn-ín, ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti gbó tán, èmi yóò ha ní ìdùnnú ní ti gidi?” Áńgẹ́lì náà wá fi ìbéèrè tó sojú abẹ níkòó yìí tún èrò Sárà ṣe, ó ní: “Ohunkóhun ha ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà bí?” Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwa èèyàn, ohun tí Sárà sọ fi hàn pé ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwáwí. Kíá ló dáhùn pé: “Èmi kò rẹ́rìn-ín!” Áńgẹ́lì náà sì fún un lésì pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́! ṣùgbọ́n o rẹ́rìn-ín ní tòótọ́.”​—Jẹ́nẹ́sísì 18:​9-15.

Ṣé ẹ̀rín tí Sárà rín fi hàn pé kò ní ìgbàgbọ́ ni? Rárá o. Torí Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà fúnra rẹ̀ pẹ̀lú gba agbára láti lóyún irú-ọmọ, nígbà tí ó ti ré kọjá ààlà ọjọ́ orí pàápàá, níwọ̀n bí ó ti ka ẹni tí ó ṣèlérí sí olùṣòtítọ́.” (Hébérù 11:11) Sárà mọ̀ pé kò sí ìlérí tí Jèhófà ṣe tí kò ní nímùúṣẹ. Gbogbo wa la nílò irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ohun tó dáa ni pé ká mọ Ọlọ́run tó ṣe Bíbélì lámọ̀dunjú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ ká rí i pé Sárà tọ̀nà láti nírú ìgbàgbọ́ tó ní. Olóòótọ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà míì, ó máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lọ́nà tó máa yà wá lẹ́nu débì pé àá fẹ́ẹ̀ lè máa ṣiyèméjì pàápàá!

“FETÍ SÍ OHÙN RẸ̀”

Jèhófà san Sárà lẹ́san nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó lágbára

Nígbà tí Sárà wà lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, ọwọ́ rẹ̀ tẹ ohun tó ti ń fojú sọ́nà fún látìgbà tó ti wà nílé ọkọ. Ó bí ọmọkùnrin kan fún olólùfẹ́ rẹ̀ tó ti pé ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún! Ábúráhámù sọ ọmọ náà ní Ísákì tàbí “Ẹ̀rín,” bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un. Àwa náà lè fọkàn yàwòrán bí Sárà ìyá arúgbó ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà tó sọ pé: “Ọlọ́run ti pèsè ẹ̀rín sílẹ̀ fún mi: gbogbo ènìyàn tí yóò gbọ́ nípa rẹ̀ yóò fi mí rẹ́rìn-ín.” (Jẹ́nẹ́sísì 21:6) Ó dájú pé ẹ̀bùn ìyanu tí Jèhófà fún un yìí máa múnú rẹ̀ dùn títí tó fi kú. Àmọ́ ṣá, iṣẹ́ ńlá ló já lé Sárà léjìká yìí o.

Nígbà tí Ísákì wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, ìdílé náà ṣe ayẹyẹ tí wọ́n fi já a lẹ́nu ọmú. Àmọ́, nǹkan ò lọ dáadáa. Bíbélì sọ pé Sárà “kíyè sí” ìwà kan tó ń kọni lóminú. Íṣímáẹ́lì ọmọ Hágárì ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ó sì máa ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́. Èyí kì í ṣọ̀rọ̀ pé ó kàn ń bá a dá àpárá o. Kódà nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé inúnibíni ni Íṣímáẹ́lì ń ṣe sí Ísákì. Lójú Sárà, ìwà burúkú gbáà ni Íṣímáẹ́lì ń hù yìí, torí pé ó máa ṣàkóbá fún ìlera Ísákì. Sárà mọ̀ pé Ísákì kì í kàn ṣe ọmọ òun lásán; ó ní ojúṣe pàtàkì tí Jèhófà yàn fún un. Torí náà, Sárà ṣọkàn akin, ó sì sojú abẹ níkòó fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀. Ó sọ fún un pé kó lé Hágárì àti ọmọ rẹ̀ jáde.​—Jẹ́nẹ́sísì 21:​8-10; Gálátíà 4:​22, 23, 29.

Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Ábúráhámù? Bíbélì sọ pé: “Ohun náà kò dùn mọ́ Ábúráhámù nínú rárá, ní ti ọmọkùnrin rẹ̀.” Torí pé ó fẹ́ràn Íṣímáẹ́lì, àjọṣe bàbá sọ́mọ tó wà láàárín wọn kò jẹ́ kó ronú nípa ewu tó ṣeé ṣe kó wáyé. Àmọ́, Jèhófà lóye ọ̀rọ̀ náà kedere, torí náà ó bá wọn dá sí i. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sárà ń sọ fún ọ di ohun tí kò dùn mọ́ ọ nínú nípa ọmọdékùnrin náà àti nípa ẹrúbìnrin rẹ. Fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí pé nípasẹ̀ Ísákì ni ohun tí a ó pè ní irú-ọmọ rẹ yóò wà.’ ” Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun máa bojú tó Hágárì àti ọmọ rẹ̀. Ábúráhámù tó jẹ́ olóòótọ́ sì gbà.​—Jẹ́nẹ́sísì 21:​11-14.

Ìyàwó rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ni Sárà jẹ́ fún Ábúráhámù, olùrànlọ́wọ́ tòótọ́ sì ni. Kì í ṣe ohun tí ọkọ rẹ̀ máa fẹ́ gbọ́ nìkan ló máa ń sọ fún un. Tó bá rí ìṣòro kan tó lè ṣàkóbá fún ìdílé náà lọ́jọ́ iwájú, kì í pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀. Àmọ́ ká má ṣe ronú pé ńṣe lèyí ń fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ o. Kódà, àpọ́sítélì Pétérù tí òun náà jẹ́ baálé ilé sọ nípa Sárà pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá dọ̀rọ̀ kí ìyàwó bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 9:5; 1 Pétérù 3:​5, 6) Ká sòótọ́, ká ní Sárà ò sọ tinú ẹ̀ jáde lórí ọ̀rọ̀ yìí ni, ìyẹn gan-an ló máa fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, torí pé ìpalára tó máa yọrí sí fún òun àti ìdílé náà lápapọ̀ máa lágbára gidigidi. Sárà fi ìfẹ́ sọ ohun tó yẹ lásìkò tó yẹ.

Ọ̀pọ̀ ìyàwó ló mọyì àpẹẹrẹ Sárà. Wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa sọ tinú wọn fáwọn ọkọ wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Nígbà míì, ó lè máa wu àwọn ìyàwó kan pé kí Jèhófà dá sọ́rọ̀ tàwọn náà bó ṣe dá sọ́rọ̀ Sárà. Síbẹ̀, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti sùúrù Sárà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Jèhófà pe Sárà ní “Ìyá Ọba,” àmọ́ Sárà ò retí pé káwọn èèyàn máa gbé òun gẹ̀gẹ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló pe obìnrin yìí ní “Ìyá Ọba,” síbẹ̀ kò retí pé káwọn èèyàn máa gbé òun gẹ̀gẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tó kú lẹ́ni ọdún mẹ́tà-dín-láàádóje [127], Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ‘pohùn réré ẹkún Sárà, ó sì sunkún lórí rẹ̀.’ * (Jẹ́nẹ́sísì 23:​1, 2) Kò sí àní-àní pé ó máa ṣàárò “Ìyá Ọba” tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ yìí. Ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run náà máa ṣàárò obìnrin olóòótọ́ yìí, ó sì ní in lọ́kàn láti jí i dìde kó lè gbádùn ìwàláàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Sárà àti gbogbo àwọn tó bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ máa gba ìbùkún tí kò lópin.​—Jòhánù 5:​28, 29.

^ ìpínrọ̀ 3 Níbẹ̀rẹ̀, Ábúrámù àti Sáráì lorúkọ tí tọkọtaya yìí ń jẹ́ títí dìgbà tí Ọlọ́run yí orúkọ wọn pa dà, àmọ́ ká lè máa fọkàn bá ìtàn náà lọ, Ábúráhámù àti Sárà táwọn èèyàn mọ̀ wọ́n sí la máa lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 10 Nígbà yẹn, Jèhófà gbà wọ́n láyé láti fẹ́ ju ìyàwó kan lọ tàbí kí wọ́n ní àlè, àmọ́ nígbà tó yá Jèhófà fún Jésù Kristi láṣẹ pé kó dá ìgbéyàwó pa dà sí bó ṣe wà ní ìbẹ̀rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn ọkọ kan aya kan.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:​3-9.

^ ìpínrọ̀ 25 Sárà nìkan ni obìnrin tí Bíbélì sọ ọjọ́ orí rẹ̀ nígbà tó kú.