KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?
Ṣé Àwọn Áńgẹ́lì Burúkú Wà?
Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn áńgẹ́lì burúkú wà. Ibo ni wọ́n ti wá? Má gbàgbé pé Ọlọ́run fún àwọn áńgẹ́lì ní òmìnira láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, áńgẹ́lì pípé kan lo òmìnira tí Ọlọ́run fún un ní ìlòkulò, ó sì dá ìwà ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ nínú ayé. Ó wá mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7; Ìṣípayá 12:9) Bíbélì kò sọ orúkọ tí ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ń jẹ́, kò sì sọ ipò tó wà lọ́run kó to ṣọ̀tẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tó ṣọ̀tẹ̀, Bíbélì pè é ní orúkọ tó bá a mu, ìyẹn Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò” àti Èṣù, tó túmọ̀ sí “Abanijẹ́.”—Mátíù 4:8-11.
Ó dùn wá pé ìwà ọ̀tẹ̀ yẹn ò tán síbẹ̀. Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì kan tá ò mọye wọn “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” láàárín ìdílé Ọlọ́run lókè ọ̀run. Wọ́n wá para dà di èèyàn, wọ́n wá sórí ilẹ̀ ayé láti wá hùwà ìbàjẹ́ tó ń dójú tini, wọ́n sì yà bàrà kúrò nínú ohun tí Ọlọ́run torí ẹ̀ dá wọn.—Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4; 1 Pétérù 3:19, 20.
Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì yẹn? Nígbà tí Ọlọ́run mú kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá rọ̀ láti fi fọ ilẹ̀ ayé mọ́, wọ́n tún para dà di áńgẹ́lì wọ́n sì pa dà sí ọ̀run. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ò gba àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn láyè láti pa dà sí “ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi wọ́n sínú “òkùnkùn biribiri,” tá a mọ̀ sí Tátárọ́sì, tó túmọ̀ sí pé wọn ò lè ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. (Júúdà 6; 2 Pétérù 2:4) Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí ti fi ara wọn sábẹ́ Sátánì Èṣù tó jẹ́ “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” Sátánì sì máa ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.”—Mátíù 12:24; 2 Kọ́ríńtì 11:14.
Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba Mèsáyà, tó jẹ́ ìjọba kan tó máa ṣàkóso láti ọ̀run múlẹ̀ lọ́dún 1914. * Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yẹn, wọ́n lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run wá sí sàkání ilẹ̀ ayé. Ìwà ìbàjẹ́ àti ìṣekúṣe tó bùáyà tó kúnnú ayé báyìí jẹ́ ẹ̀rí pé Sátánì ń bínú kíkankíkan.—Ìṣípayá 12:9-12.
Àmọ́ ṣá o, bí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ipá tó ń bani lẹ́rù ṣe ń pọ̀ sí i fi hàn pé ìṣàkóso ẹhànnà Sátánì máa tó dópin. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú yìí run. Lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bá ti ṣàkóso ayé fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún, àwọn ẹ̀mí burúkú yìí máa ní àkókò kúkúrú láti ṣe ìdánwò ìkẹyìn fáwọn èèyàn. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n á wá pa run títí láé.—Mátíù 25:41; Ìṣípayá 20:1-3, 7-10.
^ ìpínrọ̀ 6 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run, wo orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì wa www.jw.org/yo.