Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Máa Ń Pinnu Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Rí?

Kí Ló Máa Ń Pinnu Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Rí?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé agbára abàmì kan ló ń pinnu bí ọjọ́ ọ̀la àwọn ṣe máa rí. Torí náà, wọ́n máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n gbà pé ó máa mú kí wọ́n rìnnà kore tàbí tó máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn dáa.

OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́

WÍWO ÌRÀWỌ̀: Ìgbàgbọ́ àwọn kan ni pé ohun tó máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la ọmọ kan ṣe máa rí ni báwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run ṣe tò tẹ̀ léra nígbà tí wọ́n bí ọmọ náà. Torí náà, tí wọ́n bá fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la àti ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe láti dènà aburú, ńṣe ni wọ́n máa ń lọ bá àwọn awòràwọ̀.

ÀṢÀ KAN TÍ WỌ́N PÈ NÍ FENG SHUI: Àwọn kan gbà gbọ́ nínú àṣà kan tí wọ́n ń pè ní feng shui. Àwọn tó ń lọ́wọ́ sí àṣà yìí gbà pé táwọn bá kọ́lé lọ́nà kan tàbí táwọn ṣètò ohun tó wà níbẹ̀ lọ́nà pàtó kan, ìyẹn á jẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa fún wọn. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lo Wing, * tó ń gbé ní Hong Kong, sọ pé: “Ẹnì kan tó jẹ́ aṣáájú nínú àṣà feng shui sọ fún mi pé tí mo bá fi gíláàsì kan tó ń dán yinrin sápá ibì kan nínú ṣọ́ọ̀bù tí mo ti ń tajà, ńṣe lọjà mi á máa tà wàràwàrà.”

JÍJỌ́SÌN ÀWỌN BABA ŃLÁ: Ìgbàgbọ́ àwọn kan ni pé àwọn gbọ́dọ̀ máa júbà àwọn baba ńlá àwọn tó ti kú, kí wọ́n lè máa súre fáwọn kí wọ́n sì máa dáàbò bo àwọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Van tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Vietnam sọ pé: “Mo gbà pé tí mo bá ń júbà àwọn baba ńlá mi tó ti kú, ìyẹn á jẹ́ káyé mi dáa, á sì jẹ́ kí ọkàn èmi àtàwọn ọmọ mi balẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.”

ÀTÚNWÁYÉ: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé téèyàn bá kú, wọ́n tún lè pa dà bí i sáyé láìmọye ìgbà. Torí náà, ìgbàgbọ́ wọn ni pé ohun téèyàn bá gbélé ayé ṣe nígbà tó wá sáyé kẹ́yìn ló máa pinnu bóyá inú ìgbádùn ló máa wà tàbí ńṣe lonítọ̀hún á máa jìyà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbà pé kò sóòótọ́ kankan nínú irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ àwọn náà ṣì máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn woṣẹ́woṣẹ́ tàbí àwọn awòràwọ̀, wọ́n máa ń tẹ yanrìn, wọ́n máa ń wo àtẹ́lẹwọ́ láti sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn nǹkan míì. Wọ́n gbà pé ọ̀nà táwọn lè gbà mọ ọjọ́ ọ̀la àwọn nìyẹn.

ṢÉ ÀWỌN ÀṢÀ YẸN Ń MÚ KÁYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN DÁA LÓÒÓTỌ́?

Ṣé ọkàn àwọn tó ń lọ́wọ́ sáwọn àṣà yìí balẹ̀ lóòótọ́, ṣó sì dájú pé èyí máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn dáa?

Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hào, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Vietnam. Ó máa ń wo ìràwọ̀, ó máa ń lọ́wọ́ sí àṣà feng shui, ó sì máa ń júbà àwọn baba ńlá ẹ̀ tó ti kú. Báwo ni nǹkan ṣe wá rí fún Hào? Ó sọ pé: “Owó ò wọlé fún mi mọ́, mo wọko gbèsè, èmi àti ìdílé mi ò gbọ́ra wa yé, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Qiuming lórílẹ̀-èdè Taiwan náà máa ń wo ìràwọ̀, ó gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé àti àyànmọ́, ó máa ń lọ́wọ́ sí àṣà feng shui, ó sì máa ń júbà àwọn baba ńlá ẹ̀ tó ti kú. Lẹ́yìn tó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àṣà yìí, ó sọ pé: “Mo wá rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà yìí ta ko ara wọn, kò sì nítumọ̀. Mo rí i pé ọ̀pọ̀ ìgbà lohun táwọn awòràwọ̀ máa ń rí kì í jóòótọ́. Ní ti àtúnwáyé, tó bá jẹ́ pé èèyàn ò lè rántí ohun tó gbélé ayé ṣe nígbà tó wáyé kẹ́yìn, báwo ló ṣe máa lè ṣàtúnṣe nígbà tí wọ́n bá tún pa dà bí i sáyé?”

“Mo wá rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà yìí ta ko ara wọn, kò sì nítumọ̀.”​—QIUMING, TAIWAN

Ohun tí Hào, Qiuming àti ọ̀pọ̀ àwọn míì sọ fi hàn pé àyànmọ́, wíwo ìràwọ̀, ìjọsìn àwọn baba ńlá tàbí àtúnwáyé kọ́ ló ń pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. Ṣé èyí wá fi hàn pé a ò lè ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dáa?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé téèyàn bá fẹ́ kí ọkàn òun balẹ̀ kí ọjọ́ ọ̀la òun sì dáa, àfi kó kàwé dáadáa kó sì rí towó ṣe. Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀?

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e.

^ ìpínrọ̀ 16 Inú Bíbélì lọ̀rọ̀ yìí wà, ní Gálátíà 6:7. Ó sì bá ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n sábà máa ń sọ nílẹ̀ Éṣíà mu pé: “Tó o bá gbin ẹ̀gúsí, ẹ̀gúsí lo máa kórè; tó o bá sì gbin ẹ̀wà, ẹ̀wà náà ló máa kórè.”