Ẹni Tó Ń Ran Aláìní Lọ́wọ́ Máa Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé nílò oúnjẹ àti ibùgbé. Àwọn kan ń fẹ́ ohun tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Tá a bá sapá láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run?
OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ
“Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan, á sì san án pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.”—ÒWE 19:17.
BÍ A ṢE LÈ RAN ALÁÌNÍ LỌ́WỌ́
Jésù sọ àkàwé ọkùnrin kan táwọn olè dá lọ́nà, tí wọ́n ṣe léṣe, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ kó kú. (Lúùkù 10:29-37) Àjèjì kan rí ọkùnrin tí wọ́n ti ṣe léṣe yìí, ó dúró láti ràn án lọ́wọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọmọ ìlú kan náà.
Ọkùnrin aláàánú yìí kọ́kọ́ tọ́jú ẹni tí wọ́n ṣe léṣe náà, ó pèsè ohun tó nílò, ó sì tù ú nínú kí ara rẹ̀ lè wálẹ̀.
Kí lá rí kọ́ nínú àkàwé yìí? Jésù kọ́ wa pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà tá a bá lè gbé e gbà. (Òwe 14:31) Ìwé Mímọ́ kọ́ wa pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìyà àti ìṣẹ́ tó ń bá aráyé fínra. Àmọ́, a lè wá béèrè pé, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe é, ìgbà wo ló sì máa ṣe é? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa sọ ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Ẹlẹ́dàá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa ti pinnu pe òun máa fún wa.