Ẹlẹ́dàá Wa Máa Bù Kún Ẹ Títí Láé
Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ló máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún “gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ta ni àtọmọdọ́mọ yẹn?
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run fún Jésù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní agbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè máa rí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù gbà nípasẹ̀ Jésù—Gálátíà 3:14.
Àwọn ìṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run yàn láti bù kún aráyé, wọ́n tún jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa lo Jésù láti bù kún aráyé títí láé. Kíyè sí bí àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó fani mọ́ra.
Ìwà tútù—Jésù wo àwọn aláìsàn.
Ìgbà kan wà tí adẹ́tẹ̀ kan bẹ Jésù pé kó wo òun sàn. Jésù fọwọ́ kàn án, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà kúrò lára rẹ̀.—Máàkù 1:40-42.
Ìwà ọ̀làwọ́—Jésù bọ́ àwọn tí ebi ń pa.
Jésù ò fẹ́ kí ebi máa pa àwọn èèyàn. Láwọn ìgbà kan, Jésù fi iṣẹ́ ìyanu bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, ó sọ búrẹ́dì díẹ̀ àti ẹja kékeré mélòó kan di púpọ̀. (Mátíù 14:17-21; 15:32-38) Gbogbo wọn jẹ àjẹyó, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ ló sì ṣẹ́ kù.
Àánú—Jésù jí òkú dìde.
Opó kan ń ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo tó kú, kò sì ní ẹlòmíì tó máa tọ́jú rẹ̀. “Àánú rẹ̀ ṣe” Jésù, ló bá jí ọmọ náà dìde.—Lúùkù 7:12-15.