Tí Ẹnì Kejì Rẹ Bá Ṣe Ìṣekúṣe
Ó MÁA ń bani nínú jẹ́ gan-an tẹ́nì kan bá mọ̀ pé ẹnì kejì òun ti ṣe ìṣekúṣe. Òótọ́ ni pé, a rí àwọn kan tó dárí ji ẹnì kejì wọn nígbà tí wọ́n rí i pé wọ́n ti ronú pìwà dà. a Àmọ́, bóyá irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ ṣì ń fẹ́ ara wọn àbí wọ́n tú ká, ìbànújẹ́ ńláǹlà tí ẹni tí wọ́n hùwà àìtọ́ sí máa ní máa ń kọjá àfẹnusọ. Báwo ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe lè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn?
ÌMỌ̀RÀN TÓ WÚLÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹnì kejì wọn ṣe ìṣekúṣe ló ti rí ìtùnú nínú Bíbélì, láìka bí ẹ̀dùn ọkàn wọn ṣe lágbára sí. Wọ́n ti rí i pé Ọlọ́run ń rí omijé àwọn, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn àwọn.—Málákì 2:13-16.
“Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”—Sáàmù 94:19.
Bill sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, gẹ́gẹ́ bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń ṣe.”
“Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin.”—Sáàmù 18:25.
Carmen tí ọkọ rẹ̀ ti ń ṣe ìṣekúṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù sọ pé: “Ó ti pẹ́ tí ọkọ mi ti ń hùwà àìṣòótọ́ sí mi kí n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀. Àmọ́, ó dá mi lójú pé Jèhófà ò ní fi mí sílẹ̀. Kò sì ní já mi kulẹ̀ láé.”
“ Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ . . . ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín.”—Fílípì 4:6, 7.
Sasha sọ pé: “Àkàtúnkà ni mo máa ń ka ẹsẹ Bíbélì yìí. Bí mo ṣe ń gbàdúrà lemọ́lemọ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fún mi ní àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀.”
Nígbà kan, àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí ti ro ara wọn pin. Àmọ́, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì rí okun gbà láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bill tiẹ̀ sọ pé: “Nígbà tó dà bíi pé gbogbo nǹkan ti dojú rú, ìgbàgbọ́ mi ló fún mi lókun. Bí mo tilẹ̀ ń rìn nígbà kan ‘nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,’ Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.”—Sáàmù 23:4.
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá ó yẹ kó o dárí ji ẹnì kejì rẹ tàbí kò yẹ kó o dárí jì í, ka àpilẹ̀kọ tó wà nínú Jí! May 8, 1999, “Bí Ẹnì Kejì Wa Nínú Ìgbéyàwó Bá Hùwà Àìṣòótọ́.”