Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn èèyàn tó bá la ọjọ́ ìkẹyìn já máa gbé inú Párádísè

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé báyìí?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” (2 Tímótì 3:1) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí fi hàn pé “ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Lára ohun tá a máa fi mọ̀ pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni ogun, ìyàn, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí.​—Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:11.

  • Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìwàkiwà àti ìṣekúṣe máa kún ọwọ́ àwọn èèyàn, wọn á sì jìnnà sí Ọlọ́run.​—2 Tímótì 3:2-5.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú?

Èrò àwọn kan ni pé . . .

ńṣe ni ayé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ máa pa run kí ọjọ́ ìkẹyìn tó lọ sópin, àwọn míì sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”​Sáàmù 37:29.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Kí ọjọ́ ìkẹyìn tó lọ sópin, Ọlọ́run máa kọ́kọ́ mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé.​—1 Jòhánù 2:17.

  • Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè.​—Aísáyà 35:1, 6.