2 | “Ìtùnú Látinú Ìwé Mímọ́”
BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí á lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.”—RÓÒMÙ 15:4.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí
Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń jẹ́ ká lè fara dà á tí èrò òdì bá ń wá sí wa lọ́kàn. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé láìpẹ́, gbogbo ìṣòro tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wa ò ní sí mọ́.
Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
Gbogbo wa ni nǹkan máa ń tojú sú nígbà míì, àmọ́ ní tàwọn tó ní ìdààmú ọkàn tàbí tí àníyàn máa ń gbà lọ́kàn, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an. Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan rere tá a lè máa ronú lé lórí tí ò ní jẹ́ ká máa ro èrò òdì. (Fílípì 4:8) Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń tù wá nínú, ó máa ń tù wá lára, kò sì ní jẹ́ ká ṣinú rò.—Sáàmù 94:18, 19.
Tá a bá ń ronú pé a ò wúlò fún nǹkan kan, Bíbélì á jẹ́ ká gbé èrò náà kúrò lọ́kàn.—Lúùkù 12:6, 7.
Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì ló fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa wà pẹ̀lú wa, àti pé ó mọ gbogbo bó ṣe ń ṣe wá.—Sáàmù 34:18; 1 Jòhánù 3:19, 20.
Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa mú gbogbo èrò tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wa kúrò. (Àìsáyà 65:17; Ìfihàn 21:4) Tá a bá ń rántí ìlérí yìí nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn, ó máa fún wa lókun.