Bí Àdúrà Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Nígbà tí Pamela ń ṣàìsàn tó le, ó lọ wá ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn dókítà tó mọṣẹ́ dáadáa. Àmọ́, ó tún gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun lágbára láti fara da ìṣòro náà. Ṣé àdúrà ràn án lọ́wọ́?
Pamela sọ pé: “Nígbà tí mò ń gba ìtọ́jú nítorí àrùn jẹjẹrẹ tí mo ní, ẹ̀rù máa ń bà mí gan-an. Àmọ́ nígbà tí mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, ọkàn mi balẹ̀, mo wá ní okun láti fara dà á. Mo ṣì máa ń ní ìrora tó pọ̀ gan-an, àmọ́ àdúrà ràn mí lọ́wọ́ láti mọ́kàn le. Nígbà táwọn èèyàn bá bi mí pé báwo lára ẹ ṣe rí? Màá ní, ‘Ara mi ò yá, ṣùgbọ́n mo láyọ̀!’”
Àmọ́ ṣá o, kò dìgbà tẹ̀mí èèyàn bá wà nínú ewu kéèyàn tó máa gbàdúrà. Gbogbo wa la ní ìṣòro tá à ń bá yí, bóyá ó kéré ni o tàbí ó tóbi, a sì ń fẹ́ ìrànwọ́ láti borí wọn. Ṣé àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́?
Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.” (Sáàmù 55:22) Ẹ ò rí i pé ìyẹn tuni nínú gan-an! Báwo ni àdúrà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tó o bá gbàdúrà sí Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, ó máa fún ẹ ní ohun tó o nílò láti borí àwọn ìṣòro ẹ.—Wo àpótí náà, “ Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú Àdúrà.”